إِنَّ وَلِـِّۧيَ ٱللَّهُ ٱلَّذِي نَزَّلَ ٱلۡكِتَٰبَۖ وَهُوَ يَتَوَلَّى ٱلصَّٰلِحِينَ 196
Dajudaju alaranse mi, olukunlọwọ mi eyiti o nsọ mi ni Allah, nko le gbero ẹlomiran, nko si le paya nkankan nipa awọn oosa yin, Oun ni O sọ Alukuraani kalẹ fun gẹgẹ bi imọna fun awọn eniyan, Oun ni O si la ọrọ awọn ẹniire ninu ẹru Rẹ bọrun, O nsọ wọ, O si nran wọn se.
وَٱلَّذِينَ تَدۡعُونَ مِن دُونِهِۦ لَا يَسۡتَطِيعُونَ نَصۡرَكُمۡ وَلَآ أَنفُسَهُمۡ يَنصُرُونَ 197
Awọn ti ẹ npe - ẹyin ọlọsẹbọ yii - ninu awọn oosa yii, wọn ko lagbara lati ran yin se, wọn ko si lagbara lati ran ara wọn se, wọn jẹ olukagara, kilode ti ẹ fi wa npe wọn yatọ si Allah?!
وَإِن تَدۡعُوهُمۡ إِلَى ٱلۡهُدَىٰ لَا يَسۡمَعُواْۖ وَتَرَىٰهُمۡ يَنظُرُونَ إِلَيۡكَ وَهُمۡ لَا يُبۡصِرُونَ 198
Ti ẹ ba npe - ẹyin ọlọsẹbọ - awọn ẹbọ yin eyiti ẹ nsin yatọ si Ọlọhun Ọba Allah lọ si ibi iduro sinsin, wọn ko le gbọ ipepe yin, ẹ yoo maa ri wọn, ti wọn yoo maa pade yin pẹlu awọn oju aworan lasan, ọbọrọ gidi ti ko lee riran sini, wọn ti kọkọ se ere ti aworan ọmọ adamọ tabi ti awọn ẹranko, o ni ọwọ, o si ni ẹsẹ ati awọn oju sugbọn ọbọrọgidi ni, ko si ẹmin, bẹẹ ni ko le gbepa kankan.
خُذِ ٱلۡعَفۡوَ وَأۡمُرۡ بِٱلۡعُرۡفِ وَأَعۡرِضۡ عَنِ ٱلۡجَٰهِلِينَ 199
Gba - ire ojise - lọdọ awọn eniyan nkan ti o fi se amojukuro fun wọn, ati eyiti o rọ wọn lọrun ninu isẹ ati iwa, wọn se la bọ wọn lọrun nkan ti adamọ wọn ko ba gba fun wọn, toripe eleyi yoo le wọn sa, maa pasẹ pẹlu gbogbo ọrọ ti o rẹwa ati ise ti o dara ni, gunri kuro ni ọdọ awọn alaimọkan, mase fi aimọkan pade wọn, ẹniti o ba se ọ ni suta, mase se ni suta, ẹniti o ba se ohunkihun ni eewọ fun ọ, mase ni eewọ fun un.
وَإِمَّا يَنزَغَنَّكَ مِنَ ٱلشَّيۡطَٰنِ نَزۡغٞ فَٱسۡتَعِذۡ بِٱللَّهِۚ إِنَّهُۥ سَمِيعٌ عَلِيمٌ 200
Ti o ba fura mọ - ire ojise - wipe esu fi roiroi kan ọ, tabi isẹni lori kuro nibi rere lugọ si ọdọ Ọlọhun Ọba Allah, wa isọ si ọdọ Rẹ, toripe olugbọ ọrọ rẹ ni I se, onimimọ pẹlu ilugọ rẹ ni, Yoo si sọ ọ kuro ni ọdọ esu.
إِنَّ ٱلَّذِينَ ٱتَّقَوۡاْ إِذَا مَسَّهُمۡ طَٰٓئِفٞ مِّنَ ٱلشَّيۡطَٰنِ تَذَكَّرُواْ فَإِذَا هُم مُّبۡصِرُونَ 201
Dajudaju awọn ti wọn npaya Ọlọhun Ọba Allah pẹlu titẹle asẹ Rẹ ati jijinna si awọn ohun ti O kọ, ti esu ba ko roiroi ba wọn pẹlu wipe wọn da ẹsẹ; wọn yoo ranti titobi Ọlọhun Ọba Allah ati iya Rẹ ti o wa fun awọn ẹlẹsẹ ati ẹsan ti o wa fun awọn olutẹle asẹ, wọn yoo wa ronu piwada kuro nibi ẹsẹ wọn wọn yoo si sẹri si ọdọ Ọlọhun Ọba wọn, ti wọn ba ti waa duri sinsin lori ododo, ti wọn si se atunse nkan ti wọn wa lori rẹ, ti wọn si jawọ.
وَإِخۡوَٰنُهُمۡ يَمُدُّونَهُمۡ فِي ٱلۡغَيِّ ثُمَّ لَا يُقۡصِرُونَ 202
Awọn ọmọ iya esu ninu awọn poki ati keferi, esu ko nii yẹ ko nii gbo ni ẹniti yoo maa se alekun fun wọn nibi isina pẹlu dida ẹsẹ kan lẹyin ẹsẹ kan, wọn ko si nii kora duro, kii se esu sisẹri ati isini lọna, ki sii se poki ninu awọn eniyan lati ma tẹriba tabi se aburu.
وَإِذَا لَمۡ تَأۡتِهِم بَِٔايَةٖ قَالُواْ لَوۡلَا ٱجۡتَبَيۡتَهَاۚ قُلۡ إِنَّمَآ أَتَّبِعُ مَا يُوحَىٰٓ إِلَيَّ مِن رَّبِّيۚ هَٰذَا بَصَآئِرُ مِن رَّبِّكُمۡ وَهُدٗى وَرَحۡمَةٞ لِّقَوۡمٖ يُؤۡمِنُونَ 203
Ti o ba mu - ire ojise - amin kan wa, wọn yoo pe ọ nirọ, wọn yoo si gunri kuro nibẹ, ti o ko ba si mu amin wa, wọn yoo sọ wipe, se o ko le hun amin kan ni ọdọ rẹ ni, ki iwọ si daa se, sọ fun wọn –ire ojise- ko tọ fun mi, ki nmaa mu amin ki amin wa lati ọdọ mi, emi ko si le tẹle nkankan ju imisi lati ọdọ Ọlọhun Ọba mi lọ tii se Alukuraani eyiti mo nka fun yin, o jẹ awijare ati awọn ẹri lati ọdọ Ọlọhun Ọba Allah ti O da yin, O si jẹ oludari awọn alamọri yin, olutọni sọna ati ikẹ fun awọn olugbagbọ ododo ni ori ilẹ, sugbọn awọn ti kii baa se olugbagbọ, awọn ni ẹni anu olori buru.
وَإِذَا قُرِئَ ٱلۡقُرۡءَانُ فَٱسۡتَمِعُواْ لَهُۥ وَأَنصِتُواْ لَعَلَّكُمۡ تُرۡحَمُونَ 204
Ti wọn ba ka Alukuraani, ẹ tẹti ẹ gbọ kika rẹ, ki ẹ ma sọrọ, ki ẹ si ma se nkan miran; ki Ọlọhun Ọba Allah le ba kẹ yin.
وَٱذۡكُر رَّبَّكَ فِي نَفۡسِكَ تَضَرُّعٗا وَخِيفَةٗ وَدُونَ ٱلۡجَهۡرِ مِنَ ٱلۡقَوۡلِ بِٱلۡغُدُوِّ وَٱلۡأٓصَالِ وَلَا تَكُن مِّنَ ٱلۡغَٰفِلِينَ 205
Ki o se ranti i - ire ojise - Ọlọhun Ọba Allah niti iyẹpẹrẹ ara ẹni, itẹriba, ipaya, ki o si fi adura rẹ si aarin igbohun soke ati rirẹ ohun silẹ, ni ibẹrẹ ọsan ati ipari rẹ nitori ọla ti nbẹ fun asiko meji yii, wọn wa ninu awọn olufọnu nipa iranti Ọlọhun Ọba Allah ti ọla Rẹ ga.
إِنَّ ٱلَّذِينَ عِندَ رَبِّكَ لَا يَسۡتَكۡبِرُونَ عَنۡ عِبَادَتِهِۦ وَيُسَبِّحُونَهُۥ وَلَهُۥ يَسۡجُدُونَۤ۩ 206
Dajudaju awọn ti wọn wa ni ọdọ Ọlọhun Ọba rẹ - ire ojise - bi awọn Malaika, wọn kii gunri kuro nibi iranti Ọlọhun Ọba ti mimọ nbẹ fun, bikose wipe wọn ma ngba fun Un, ti o nwo lulẹ ti ko si nii ja kuro nibẹ, wọn si ma nfọ Ọlọhun Ọba Allah mọ loru ati lọsan kuro nibi nkan ti ko tọ si I, Oun nikan ni o si nfi ori balẹ fun.
Ohun ti o jẹ dandan fun ẹniti o ni laakaye ni ki o maa sin Ọlọhun Ọba Allah ti ọla Rẹ ga; toripe Oun ni O nse anfaani ẹsin fun un pẹlu sisọ iwe ti o kun fun imọ ti o tobi kalẹ ninu ẹsin, ati awọn anfaani ile aye pẹlu lila idaabobo Rẹ bọrun fun awọn ẹniire ninu ẹru Rẹ ati iso re fun won ati sise aranse fun wọn, ọta kankan ti o ba nwọn sọta, ko le ko inira ba wọn.
Ifuni niro idunnu fun awọn olugbagbọ ododo ti o duro deede loju ọna Anọbi wọn (ki ike ati ola Olohun ko ma ba) wa ninu awọn aayah naa wipe Ọlọhun Ọba Allah yoo ran wọn se gẹgẹ bi O ti ran awọn anọbi Rẹ ati awon eni re se.
Awọn iwa ti o pe tan wa ninu awọn aayah naa, dandan ni fun ẹrusin ki o se amojukuro fun ẹniti o ba se abosi si I, ki o si maa fun ẹnikẹni ti o ba se oun ti o ni leewọ fun ni oun ti o ba ni, ki o si maa da ẹniti o ba jina si pọ.
Dandan ni fun ẹrusin nigbati aburu kan ba kan lati ọdọ esu - boya o da ẹsẹ pẹlu sise nkan eewọ, tabi gbe ọranyan ju silẹ - ki o wa aforijin lọsi ọdọ Ọlọhun Ọba Allah ti ọla Rẹ ga, ki o si le oun ti o bọ mọ lọwọ ba pẹlu rironu piwada ti o mọ, ati daradara ti o le pa a rẹ.