فَٱسۡتَجَابَ لَهُمۡ رَبُّهُمۡ أَنِّي لَآ أُضِيعُ عَمَلَ عَٰمِلٖ مِّنكُم مِّن ذَكَرٍ أَوۡ أُنثَىٰۖ بَعۡضُكُم مِّنۢ بَعۡضٖۖ فَٱلَّذِينَ هَاجَرُواْ وَأُخۡرِجُواْ مِن دِيَٰرِهِمۡ وَأُوذُواْ فِي سَبِيلِي وَقَٰتَلُواْ وَقُتِلُواْ لَأُكَفِّرَنَّ عَنۡهُمۡ سَئَِّاتِهِمۡ وَلَأُدۡخِلَنَّهُمۡ جَنَّٰتٖ تَجۡرِي مِن تَحۡتِهَا ٱلۡأَنۡهَٰرُ ثَوَابٗا مِّنۡ عِندِ ٱللَّهِۚ وَٱللَّهُ عِندَهُۥ حُسۡنُ ٱلثَّوَابِ 195
Ni Ọlahun Ọba wọn waa dahun ipe wọn: pe dajudaju Emi o, Mi o nii ra ẹsan awọn isẹ yin lare, o kere ni tabi o pọ, yala ẹniti o sisẹ jẹ ọkunrin ni tabi obirin, toripe idajọ apakan yin si apakan ninu ilana kan naa ẹyọkan ni, wọn ko nii se alekun fun ọkunrin, wọn ko si nii se adinku fun obirin, o ko ri awọn ti wọn se irin-ajo si oju ọna Ọlọhun Ọba Allah, ati wipe awọn alaigbagbọ mu wọn jade kuro ninu awọn ile wọn, ti suta si tun kan wọn pẹlu okunfa titẹle wọn ti wọn tẹle Ọlọhun Ọba wọn, ati wipe wọn tun jagun si oju ọna Ọlọhun Ọba Allah, wọn si pa wọn ki gbolohun Ọlọhun Ọba Allah le ba jẹ ohun ti yoo ga, Maa se aforijin awọn asise wọn ni Ọjọ Igbende, ati wipe Maa se amojukuro nibẹ, ati wipe Maa fi wọn wọ Ọgba Idẹra ti awọn akeremọdo yoo maa san ni awọn abẹ aafin rẹ, yoo maa jẹ ẹsan lati ọdọ Ọlọhun Ọba Allah, ati wipe Ọlọhun Ọba Allah ni ẹsan ti o dara, ti ko ni afiwe nbẹ ni ọdọ Rẹ.
لَا يَغُرَّنَّكَ تَقَلُّبُ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ فِي ٱلۡبِلَٰدِ 196
Ko ma se tan ọ jẹ -irẹ Anọbi- lilọ bibọ awọn alaigbagbọ ninu awọn ilu, ati riri ifọkanbalẹ wọn nibẹ ati gbigbaaye awọn owo wọn ati awọn arisiki wọn ti yoo fi waa maa ni ifuramọ pẹlu ibanujẹ ati ẹdun-ọkan lati ibi isesi wọn.
مَتَٰعٞ قَلِيلٞ ثُمَّ مَأۡوَىٰهُمۡ جَهَنَّمُۖ وَبِئۡسَ ٱلۡمِهَادُ 197
Ile aye yii, igbadun kan ti o kere ni, ti ko si bibẹ lọ gbere fun un, lẹyin nkan naa ibupada si wọn eyiti wọn yoo sẹri pada sibẹ ni Ọjọ Igbende, yoo jẹ Jahannamọ, ati wipe ina buru fun wọn ni ibusun.
لَٰكِنِ ٱلَّذِينَ ٱتَّقَوۡاْ رَبَّهُمۡ لَهُمۡ جَنَّٰتٞ تَجۡرِي مِن تَحۡتِهَا ٱلۡأَنۡهَٰرُ خَٰلِدِينَ فِيهَا نُزُلٗا مِّنۡ عِندِ ٱللَّهِۗ وَمَا عِندَ ٱللَّهِ خَيۡرٞ لِّلۡأَبۡرَارِ 198
Sugbọn awọn ti wọn paya Ọlọhun Ọba wọn, pẹlu mima mu awọn asẹ Rẹ wa si imusẹ ati jijinna si awọn ohun ti O kọ, yoo maa bẹ fun wọn awọn Ọgba Idẹra ti awọn ibudu yoo maa san ni abẹ awọn aafin Rẹ, ti wọn yoo si maa gbe ibẹ lọ gbere, ẹsan kan ni, ti wọn pese rẹ kalẹ fun wọn lati ọdọ Ọlọhun Ọba Allah (ti ọla Rẹ ga) , ati wipe ohun ti Ọlọhun Ọba Allah pese fun awọn ẹniire ninu awọn ẹrusin Rẹ ni oore ati ọla ju ohun ti awọn alaigbagbọ nyilọyibọ nibẹ ninu awọn igbadun aye.
وَإِنَّ مِنۡ أَهۡلِ ٱلۡكِتَٰبِ لَمَن يُؤۡمِنُ بِٱللَّهِ وَمَآ أُنزِلَ إِلَيۡكُمۡ وَمَآ أُنزِلَ إِلَيۡهِمۡ خَٰشِعِينَ لِلَّهِ لَا يَشۡتَرُونَ بَِٔايَٰتِ ٱللَّهِ ثَمَنٗا قَلِيلًاۚ أُوْلَٰٓئِكَ لَهُمۡ أَجۡرُهُمۡ عِندَ رَبِّهِمۡۗ إِنَّ ٱللَّهَ سَرِيعُ ٱلۡحِسَابِ 199
Awọn ti o ni tira kii se bakannaa, dajudaju o nbẹ ninu wọn, awọn ikọ kan ti wọn ma nni igbagbọ si Ọlọhun Ọba Allah ati pẹlu ohun ti o sọkalẹ si ọdọ yin ninu ododo ati imọna ati wipe wọn si ma nni igbagbọ pẹlu ohun ti o sọkalẹ si ọdọ wọn ninu awọn tira wọn, wọn kii si se onpinya laarin awọn ojisẹ Ọlọhun Ọba Allah, ni olutẹriba oluyẹpẹ ara wọn fun Ọlọhun Ọba Allah ni rirankan ohun ti nbẹ ni ọdọ Rẹ, wọn ko nii fi iye ti o kere ninu igbadun aye paarọ pẹlu awọn aayah Ọlọhun Ọba Allah, awọn ti wọn nroyin wọn pẹlu awọn iroyin yii, yoo maa bẹ fun wọn ẹsan wọn ti o tobi ni ọdọ Ọlọhun Ọba wọn, dajudaju Ọlọhun Ọba Allah ni Oluyara ni isiro lori awọn isẹ, ati Oluyara san ẹsan le lori.
يَٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ ٱصۡبِرُواْ وَصَابِرُواْ وَرَابِطُواْ وَٱتَّقُواْ ٱللَّهَ لَعَلَّكُمۡ تُفۡلِحُونَ 200
Ẹyin ti ẹ ni igbagbọ pẹlu Ọlọhun Ọba Allah, ti wọn si tun ntẹle ojisẹ Rẹ, ẹ se suuru lori awọn alabọrun Ṣẹria, ati lori ohun ti o sẹri waa ba yin ninu awọn adanwo aye, ati wipe ki ẹ bori awọn alaigbagbọ nibi suuru, ki wọn mọ le ba jẹ ẹniti o le ni suuru ju yin lọ, ati wipe ki ẹ se igbeduro lori jijagun si oju ọna Ọlọhun Ọba Allah, ati wipe ki ẹ paya Ọlọhun Ọba Allah pẹlu mimu awọn asẹ Rẹ wa si imusẹ ati jijinna si awọn ohun ti O kọ, ki ẹ le ba jẹ ẹniti ọwọ yin yoo tẹ ohun ti ẹ nwa pẹlu lila kuro nibi ina ati wiwọ Alujannah.
Suta eyiti yoo kan olugbagbọ ododo nibi oju ọna Ọlọhun Ọba Allah, ti yoo waa ti lọ si ibi sise irin-ajo, ati jijade ati jijagun wa ninu eyiti o tobi ju ninu awọn okunfa pipa awọn ẹsẹ rẹ, ati sise adipele awọn ẹsan.
Sise ariwoye ko lee jẹ pẹlu ohun ti o seese ki alaini igbagbọ maa gbadun pẹlu rẹ ni ile aye ninu owo ati idẹra koda bi o tobi; toripe ile aye, ohun ti yoo yẹ ni, ati wipe dajudaju iwoye yoo maa bẹ pẹlu paapaa ibupadasi rẹ ni Ọjọ Ikẹyin, ni ile gbere.
O nbẹ ninu awọn ti o ni tira, awọn ti o ma njẹri pẹlu ododo eyiti o nbẹ ninu awọn tira wọn, ti wọn yoo waa ni igbagbọ pẹlu ohun ti wọn sọkalẹ fun wọn, ati pẹlu ohun ti wọn sọkalẹ fun awọn olugbagbọ ododo, awọn eleyi, o nbẹ fun wọn ẹsan wọn ni ẹẹmeji.
Sise suuru lori ododo ati bibori awọn oluparọ pẹlu rẹ ati jijagun si oju ọna Rẹ, ohun ni ọna iyege ni Ọjọ Ikẹyin.