وَٱقۡتُلُوهُمۡ حَيۡثُ ثَقِفۡتُمُوهُمۡ وَأَخۡرِجُوهُم مِّنۡ حَيۡثُ أَخۡرَجُوكُمۡۚ وَٱلۡفِتۡنَةُ أَشَدُّ مِنَ ٱلۡقَتۡلِۚ وَلَا تُقَٰتِلُوهُمۡ عِندَ ٱلۡمَسۡجِدِ ٱلۡحَرَامِ حَتَّىٰ يُقَٰتِلُوكُمۡ فِيهِۖ فَإِن قَٰتَلُوكُمۡ فَٱقۡتُلُوهُمۡۗ كَذَٰلِكَ جَزَآءُ ٱلۡكَٰفِرِينَ 191
Ẹ maa pa wọn ni gbogbo ibikibi ti ẹ ba ti pade wọn, ki ẹ si maa mu wọn jade kuro nibi aaye ti awọn naa ti mu yin jade kuro nibẹ ohun naa ni Mẹkka, ati wipe adanwo eyiti o sẹlẹ pẹli didina mọ olugbagbọ ododo kuro nibi ẹsin rẹ, ati ki o le pada lọ si ibi aini igbagbọ, ohun ti o tobi ju pipa lọ ni, ẹ mase bẹrẹ pẹlu mima ba wọn ja ni Mọsalaasi abeewọ nni, lati gbe titobi fun un titi wọn yoo fi bẹrẹ lati ba yin ja nibẹ, ti wọn ba bẹrẹ pẹlu ibanija nibi Mọsalaasi Abeewọ, ki ẹ yaa pa wọn, iru ẹsan yii - ohun naa ni pipa wọn nigbati wọn ba gbẹru gbọnri nibi Mọsalaasi Abeewọ - ni yoo jẹ ẹsan awọn alaigbagbọ.
فَإِنِ ٱنتَهَوۡاْ فَإِنَّ ٱللَّهَ غَفُورٞ رَّحِيمٞ 192
Ti wọn ba wa pada nibi mima ba yin ja, ati aini igbagbọ wọn, ki ẹyin naa ya kuro lọdọ wọn, dajudaju Ọlọhun Ọba Allah, Alaforijin ni fun ẹniti o ba ronu piwada, ko si nii ma mu wọn pẹlu awọn ẹsẹ wọn ti o siwaju, ti Yoo si kẹ wọn, ko si ni tete jẹ wọn niya.
وَقَٰتِلُوهُمۡ حَتَّىٰ لَا تَكُونَ فِتۡنَةٞ وَيَكُونَ ٱلدِّينُ لِلَّهِۖ فَإِنِ ٱنتَهَوۡاْ فَلَا عُدۡوَٰنَ إِلَّا عَلَى ٱلظَّٰلِمِينَ 193
Ẹ maa ba awọn alaigbagbọ ja titi ti ẹbọ sise ko fi nii sẹlẹ lọdọ wọn ati mima dina mọ awọn eniyan ni oju ọna Ọlọhun Ọba Allah, ati aini igbagbọ, ti ẹsin ti o han yoo fi jẹ ẹsin Ọlọhun Ọba Allah, ti wọn ba wa pada kuro nibi aigbagbọ wọn, ati didina wọn ni oju ọna Ọlọhun Ọba Allah, ki ẹyin naa gbe biba wọn ja silẹ, toripe ko si idoju ọta kọ ayaafi lori awọn alabosi pẹlu aigbagbọ ati kikọdi oju ọna Ọlọhun Ọba Allah.
ٱلشَّهۡرُ ٱلۡحَرَامُ بِٱلشَّهۡرِ ٱلۡحَرَامِ وَٱلۡحُرُمَٰتُ قِصَاصٞۚ فَمَنِ ٱعۡتَدَىٰ عَلَيۡكُمۡ فَٱعۡتَدُواْ عَلَيۡهِ بِمِثۡلِ مَا ٱعۡتَدَىٰ عَلَيۡكُمۡۚ وَٱتَّقُواْ ٱللَّهَ وَٱعۡلَمُوٓاْ أَنَّ ٱللَّهَ مَعَ ٱلۡمُتَّقِينَ 194
Osu Ẹwọ eyiti Ọlọhun Ọba Allah se wiwọ aaye ọwọ ni irọrun fun yin nibẹ ati sise Umrah ni ọdun keje, ohun jẹ ifipaarọ osu ọwọ eyiti awọn ọsẹbọ kọ di yin nibẹ lati wọ aaye ọwọ ni ọdun kẹfa, awọn nkan to ni ọwọ -gẹgẹ bi nini ọwọ ilu abeewọ ati osu ọwọ ati wiwọsọ ọwọ- igbẹsan yoo maa waye nibẹ lati ọdọ wọn ti o ba kọja aala, ẹniti o ba gbẹru-gbọnri si yin nibẹ, ki ẹ si naa ya balo pẹlu iru isẹ rẹ, ki ẹ si ma kọja odiwọn iru kan naa, dajudaju Ọlọhun Ọba Allah ko nifẹ awọn ti wọn ba ma nkọja aala Rẹ, ki ẹ paya Ọlọhun Ọba Allah nibi mima kọja aala ohun ti o yọnda fun yin nibẹ, ki ẹ si lọọ mọ wipe dajudaju Ọlọhun Ọba Allah nbẹ pẹlu awọn olupaya Rẹ pẹlu fifi wọn se kongẹ ati kikun wọn lọwọ.
وَأَنفِقُواْ فِي سَبِيلِ ٱللَّهِ وَلَا تُلۡقُواْ بِأَيۡدِيكُمۡ إِلَى ٱلتَّهۡلُكَةِ وَأَحۡسِنُوٓاْۚ إِنَّ ٱللَّهَ يُحِبُّ ٱلۡمُحۡسِنِينَ 195
Ẹ maa na owo si ibi titẹle ti Ọlọhun Ọba Allah, nibi jijagun ati ohun ti o yatọ sii, ki ẹ si mase mu ẹyin lọ si ibi iparun nipa pe ki ẹ gbe jijagun silẹ ati ninawo si oju ọna Rọ, tabi nipa ki ẹ fa ẹmi yin lọ si ibi ohun ti yoo se okunfa iparun yin, ẹ maa se daradara nibi ijọsin yin, ati ibasepọ yin ati awọn iwa yin, dajudaju Ọlọhun Ọba Allah ma nnifẹ awọn ti nse daadaa lori gbogbo alamọri wọn, Yoo si jẹ ki ẹsan wọn tobi, Yoo si fi wọn se kongẹ ọnaamọ.
وَأَتِمُّواْ ٱلۡحَجَّ وَٱلۡعُمۡرَةَ لِلَّهِۚ فَإِنۡ أُحۡصِرۡتُمۡ فَمَا ٱسۡتَيۡسَرَ مِنَ ٱلۡهَدۡيِۖ وَلَا تَحۡلِقُواْ رُءُوسَكُمۡ حَتَّىٰ يَبۡلُغَ ٱلۡهَدۡيُ مَحِلَّهُۥۚ فَمَن كَانَ مِنكُم مَّرِيضًا أَوۡ بِهِۦٓ أَذٗى مِّن رَّأۡسِهِۦ فَفِدۡيَةٞ مِّن صِيَامٍ أَوۡ صَدَقَةٍ أَوۡ نُسُكٖۚ فَإِذَآ أَمِنتُمۡ فَمَن تَمَتَّعَ بِٱلۡعُمۡرَةِ إِلَى ٱلۡحَجِّ فَمَا ٱسۡتَيۡسَرَ مِنَ ٱلۡهَدۡيِۚ فَمَن لَّمۡ يَجِدۡ فَصِيَامُ ثَلَٰثَةِ أَيَّامٖ فِي ٱلۡحَجِۡ وَسَبۡعَةٍ إِذَا رَجَعۡتُمۡۗ تِلۡكَ عَشَرَةٞ كَامِلَةٞۗ ذَٰلِكَ لِمَن لَّمۡ يَكُنۡ أَهۡلُهُۥ حَاضِرِي ٱلۡمَسۡجِدِ ٱلۡحَرَامِۚ وَٱتَّقُواْ ٱللَّهَ وَٱعۡلَمُوٓاْ أَنَّ ٱللَّهَ شَدِيدُ ٱلۡعِقَابِ 196
Ẹ maa se Hajj ati Umrah ki mejeeji pe perepere, ni ẹniti o fi nwa oju rere Allah ti ọla Rẹ ga, ti wọn ba waa kọ fun yin nibi pipee awọn mejeeji, pẹlu aarẹ, tabi ọta abi nkan ti o jo bee; o wa jẹ dandan fun yin lati dunbu eyiti o ba rọrun ninu ẹran itanran - ninu rakunmu, tabi maalu, tabi agutan - ki ẹ le ba bọra silẹ kuro nibi asọ ‘aarami’ yin, ẹ ko gbọdọ fa awọn ori yin tabi gee titi ti ẹran itanran yoo fi de aaye ti wọn yoo pa si, ti wọn ba kọọ ni aaye ọwọ naa (Al-Haram) , ki wọn yaa pa nibi ti won ba ti kọọ, ti ko ba waa kọọ, ni aaye ọwọ (Al-Haram) , ki wọn ya pa ninu aaye ọwọ naa, ni ọjọ igunran, ati eyiti o wa lẹyin rẹ ninu awọn ọjọ igunran. ẹniti o ba jẹ alaarẹ ninu yin, tabi o ni suta kan nibi irun ori rẹ, gẹgẹ bi ina ori tabi awọn ti o ba jọọ, ti o wa lọ fa ori rẹ nitori idi nkan naa, ko si ese nibe, o di dandan fun un lati san itanran nipa rẹ; ninu gbigba aawẹ mẹta tabi fifun awọn alaini mẹfa ni ounjẹ ninu awọn alaini aaye ọwọ naa (Al-Haram) , tabi pipa obukọ, ti wọn yoo pin fun awọn talaka aaye ọwọ naa (Al-Haram) , ti ẹ ba jẹ eni ti ko bẹru, ẹniti o ba waa se Umrah ni osu Hajj, ti o si waa jẹ igbadun pẹlu oun ti wọn se ni eewọ fun un, ninu awọn oun ti wọn wa isọra fun nibi wiwọ asọ ‘harami’, titi ti yoo fi gbe asọ ‘aarami’ wọ lati sisẹ Hajj ni ọdun rẹ; ki o ya dunbu oun ti o ba rọrun fun un ninu ewurẹ, tabi ki o kẹgbẹ awọn meje nibi didunbu rakunmi tabi maalu, ti ko ba waa lagbara lati pa ẹran itanran, o di dandan fun un lati gba aawẹ ọjọ mẹta ninu awọn ọjọ isẹ Hajj lati paarọ rẹ, o si jẹ dandan fun un lati gba aawẹ ọjọ meje leyin igbati o ba pada si ọdọ awọn ara ile rẹ, ki apapọ awọn ọjọ naa le ba jẹ mẹwa ti o pe perepere, sise Umrah ni osu Hajj ni ẹniti nreti Hajj ni osu rẹ, ati jijẹ dandan ẹran itanran tabi gbigba aawẹ fun ẹniti o ba kagara nibi ẹran itanran, ni yoo maa bẹ fun awọn ti kii ba se ara aaye ọwọ naa (Al-Haram) , eni ti o ba ngbe ni ibi ti o sun mọ aaye ọwọ naa, ki ẹ paya Ọlọhun Ọba Allah pẹlu titẹle ohun ti o se ni ofin, ati gbigbe awọn aala rẹ tobi, ki ẹ si lọ mọ wipe dajudaju Ọlọhun Ọba Allah ni Ẹniti iya Rẹ le koko fun ẹniti o ba yapa asẹ Rẹ.
Ero ogun jija ati ogongori rẹ ni lati fi idajọ fun Ọlọhun Ọba Allah ti ọla Rẹ ga, ati lati yẹ ohun ti yoo maa kọ fun awọn eniyan nibi gbigbọ ododo ati wiwọle si rẹ danu.
Gbigbe ogun jija ju silẹ ati jijoko tẹtẹrẹ nipa rẹ jẹ awọn okunfa iparun awọn ijọ yii; toripe dajudaju ohun yoo se okunfa lilẹ rẹ ati ki ọta maa rankan si ọdọ rẹ.
Jijẹ dandan pipe Hajj ati Umrah fun ẹniti o ba bẹrẹ awọn mejeeji, ati lilẹtọ bibọra silẹ kuro nibi awọn mejeeji pẹlu didunbu ẹran itanran fun ẹniti wọn ba kọ fun nibi aaye ọwọ naa (Al-Haram) .