وَٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ بِٱللَّهِ وَرُسُلِهِۦٓ أُوْلَٰٓئِكَ هُمُ ٱلصِّدِّيقُونَۖ وَٱلشُّهَدَآءُ عِندَ رَبِّهِمۡ لَهُمۡ أَجۡرُهُمۡ وَنُورُهُمۡۖ وَٱلَّذِينَ كَفَرُواْ وَكَذَّبُواْ بَِٔايَٰتِنَآ أُوْلَٰٓئِكَ أَصۡحَٰبُ ٱلۡجَحِيمِ 19
Awọn ti wọn nigbagbọ ninu Allah, ti wọn si nigbagbọ ninu awọn ojisẹ rẹ laise onpinya laarin wọn, awọn wọnyi ni olododo ati ẹlẹri ni ọdọ Ọlọhun wọn, ẹsan apọnle wọn nbẹ lọdọ Ọlọhun wọn ti o pese fun wọn, imọlẹ wọn ti yoo maa bẹ ni iwaju wọn ati ni ọtun wọn ni ọjọ igbende nbẹ fun wọn, awọn ti wọn si se keferi si Allah ati si awọn ojisẹ Rẹ, ti wọn si pe awọn amin Wa ti A sọkalẹ fun ojisẹ Wa nirọ, awọn wọnyi ni ẹni ina jahiimu, wọn yoo wọ ibẹ ni ọjọ igbende, wọn yoo si maa gbe ibẹ gbere ti wọn ko nii jade nibẹ.
ٱعۡلَمُوٓاْ أَنَّمَا ٱلۡحَيَوٰةُ ٱلدُّنۡيَا لَعِبٞ وَلَهۡوٞ وَزِينَةٞ وَتَفَاخُرُۢ بَيۡنَكُمۡ وَتَكَاثُرٞ فِي ٱلۡأَمۡوَٰلِ وَٱلۡأَوۡلَٰدِۖ كَمَثَلِ غَيۡثٍ أَعۡجَبَ ٱلۡكُفَّارَ نَبَاتُهُۥ ثُمَّ يَهِيجُ فَتَرَىٰهُ مُصۡفَرّٗا ثُمَّ يَكُونُ حُطَٰمٗاۖ وَفِي ٱلۡأٓخِرَةِ عَذَابٞ شَدِيدٞ وَمَغۡفِرَةٞ مِّنَ ٱللَّهِ وَرِضۡوَٰنٞۚ وَمَا ٱلۡحَيَوٰةُ ٱلدُّنۡيَآ إِلَّا مَتَٰعُ ٱلۡغُرُورِ 20
Ki ẹ mọ pe dajudaju isẹmin aye jẹ ere ti ara nse ati itanjẹ eyiti ọkan ngba ati ọsọ ti ẹ nfi nse ẹwa ati iyanran laarin yin nitori ọla ati igbadun ti o wa nibẹ ati isegbadun pẹlu ọpọlọpọ dukia ati ọpọlọpọ ọmọ gẹgẹ bi ojo ti awọn irugbin rẹ se ẹniti o gbin in ni eemọ, lẹyin naa ti ko pẹ ti awọn irugbin ti o tutu yii fi di gbigbẹ, ti iwọ yoo pada ri - irẹ oluworan - lẹyin tutu rẹ ni pipupa fẹsi fẹsi, lẹyin naa ti allah wa sọ di rirun ti o fan ka, iya ti o le koko si wa fun awọn keferi ati awọn sọbẹ selu ni ọrun ati aforijin lati ọdọ Allah fun awọn ẹsẹ awọn ẹru Rẹ ti wọn jẹ olugbagbọ ododo ati iyọnu lati ọdọ Rẹ, kinni isẹmin aye jẹ ti ko ba se adun ti yoo yẹ, ti ko ni ifẹsẹrinlẹ, ẹniti o ba gbọla fun igbadun rẹ eyiti yoo yẹ lori idẹkun ọrun, ẹni naa jẹ olofo ẹni ibolẹ.
سَابِقُوٓاْ إِلَىٰ مَغۡفِرَةٖ مِّن رَّبِّكُمۡ وَجَنَّةٍ عَرۡضُهَا كَعَرۡضِ ٱلسَّمَآءِ وَٱلۡأَرۡضِ أُعِدَّتۡ لِلَّذِينَ ءَامَنُواْ بِٱللَّهِ وَرُسُلِهِۦۚ ذَٰلِكَ فَضۡلُ ٱللَّهِ يُؤۡتِيهِ مَن يَشَآءُۚ وَٱللَّهُ ذُو ٱلۡفَضۡلِ ٱلۡعَظِيمِ 21
Ki ẹ gbawaju - ẹyin eniyan - lọsi ibi awọn isẹ rere, ti ẹ o fi ri aforijin nibi ẹsẹ yin; gẹgẹ bi ironu piwada ati ohun ti o yatọ si i ninu awọn isunmọ ati ki ẹ le ri ọgba idẹra ti fifẹ da gẹgẹ bi fifẹ sanmọ ati ilẹ, ọgba idẹra yii ni Allah pese fun awọn ti wọn nigbagbọ si I, ti wọn si nigbagbọ si awọn ojisẹ Rẹ, ẹsan yii jẹ ọla Allah ti O ma nfun awọn ẹniti o ba wu U ninu awọn ẹru Rẹ, bẹẹni Allah ti mimọ nbẹ fun jẹ ọlọla ti O tobi lori awọn ẹru Rẹ olugbagbọ ododo.
مَآ أَصَابَ مِن مُّصِيبَةٖ فِي ٱلۡأَرۡضِ وَلَا فِيٓ أَنفُسِكُمۡ إِلَّا فِي كِتَٰبٖ مِّن قَبۡلِ أَن نَّبۡرَأَهَآۚ إِنَّ ذَٰلِكَ عَلَى ٱللَّهِ يَسِيرٞ 22
Adanwo ti o ba kan ọmọniyan ni orilẹ gẹgẹ bi ọda ati ohun ti o yatọ si i tabi ohun ti o kan wọn ninu ẹmin wọn ko jẹ nkankan ayaafi ohun ti o ti rinlẹ ninu ọpọn ti a daabobo siwaju ki a to da ẹda naa, dajudaju eleyi rọrun fun Allah.
لِّكَيۡلَا تَأۡسَوۡاْ عَلَىٰ مَا فَاتَكُمۡ وَلَا تَفۡرَحُواْ بِمَآ ءَاتَىٰكُمۡۗ وَٱللَّهُ لَا يُحِبُّ كُلَّ مُخۡتَالٖ فَخُورٍ 23
Eleyi jẹ ki ẹ maa ba banujẹ -ẹyin eniyan- lori ohun ti o bọ mọ yin lọwọ ati ki ẹ maa ba yọ ayọ pọrọ pẹlu ohun ti wọn fun yin ninu awọn idẹkun ni ayọ ayọju, dajudaju Allah ko nifẹ si gbogbo onigberaga oniyanran si awọn eniyan pẹlu ohun ti Allah fun.
ٱلَّذِينَ يَبۡخَلُونَ وَيَأۡمُرُونَ ٱلنَّاسَ بِٱلۡبُخۡلِۗ وَمَن يَتَوَلَّ فَإِنَّ ٱللَّهَ هُوَ ٱلۡغَنِيُّ ٱلۡحَمِيدُ 24
Awọn ti wọn nse ahun pẹlu ohun ti o di dandan ki wọn na, ti wọn si tun pa ẹloniran lasẹ ahun jẹ ẹni ofo, ẹniti o ba gunri kuro nibi itẹle ti Allah ko le mu inira ba Allah bikosepe yoo mu inira ba ẹmin ara rẹ, dajudaju Allah ni ọlọrọ, ko si le ni bukaata si titẹle ẹru Rẹ, Oun ni ẹni ẹyin lori gbogbo isesi.
Irayesa ni ile aye ati awọn igbadun rẹ ati iseni loju kokoro si ọrun ati idẹkun gbere ti o wa nibẹ, mejeeji ma nran ni lọwọ lori titọ ojui ọna ti o duro tọ.
Jijẹ dandan nini igbagbọ si kadara.
Ninu awọn anfaani igbagbọ si kadara ni ki inu mase bajẹ lori ohun ti o bọ ninu awọn ipin aye.
Sise ahun ati pipasẹ rẹ jẹ ẹwa eebu meji kan ti olugbagbọ ododo kii gba iroyin pẹlu rẹ.