وَأَن لَّا تَعۡلُواْ عَلَى ٱللَّهِۖ إِنِّيٓ ءَاتِيكُم بِسُلۡطَٰنٖ مُّبِينٖ 19
ki wọn ma se igberaga si Allah pẹlu gbigbe ijọsin Rẹ ju silẹ ati sise igberaga si awọn ẹru Rẹ dajudaju emi yoo mu awijare ti o fi oju han wa.
وَإِنِّي عُذۡتُ بِرَبِّي وَرَبِّكُمۡ أَن تَرۡجُمُونِ 20
Bẹẹni dajudaju emi fi Ọlọhun mi ati Ọlọhun yin se idaabobo ki ẹ maa ba pa mi pẹlu oko sisọ.
وَإِن لَّمۡ تُؤۡمِنُواْ لِي فَٱعۡتَزِلُونِ 21
Ti ẹ ko ba gbe ohun ti mo mu wa lododo, ki ẹ yẹra fun mi, ki ẹ mase sun mọ mi pẹlu aburu.
فَدَعَا رَبَّهُۥٓ أَنَّ هَٰٓؤُلَآءِ قَوۡمٞ مُّجۡرِمُونَ 22
Musa ti ọla nbẹ fun pe Ọlọhun rẹ: dajudaju awọn ijọ wọnyi - fir'aona ati awọn ijọ rẹ - jẹ ijọ ẹlẹsẹ ti wọn lẹtọ si ikanju iya.
فَأَسۡرِ بِعِبَادِي لَيۡلًا إِنَّكُم مُّتَّبَعُونَ 23
Allah pa Musa lasẹ ki o mu awọn ijọ rẹ rin irin oru, o si fun un niro wipe dajudaju fir'aona ati awọn ijọ rẹ yoo tẹle e.
وَٱتۡرُكِ ٱلۡبَحۡرَ رَهۡوًاۖ إِنَّهُمۡ جُندٞ مُّغۡرَقُونَ 24
O si pa a lasẹ nigbati o ba kọja odo, ohun ati awọn ọmọ isirẹli ki wọn fi silẹ ni idakẹ rọrọ gẹgẹ bi o se wa, dajudaju fir'aona ati ọmọ gun rẹ yoo parun itẹri si inu odo.
كَمۡ تَرَكُواْ مِن جَنَّٰتٖ وَعُيُونٖ 25
Melo ni a fẹẹ ka ninu awọn abule ati awọn odo ti nsan eyiti fir'aona ati awọn ijọ fi sẹyin!
وَزُرُوعٖ وَمَقَامٖ كَرِيمٖ 26
Melo ni awọn irugbin ati awọn aaye ti o dara ti wọn gbe si ẹyin wọn!
وَنَعۡمَةٖ كَانُواْ فِيهَا فَٰكِهِينَ 27
Melo ni isẹmin ti wọn wa ninu rẹ ni ẹniti o ngbadun ti wọn gbe sibẹ ni ẹyin wọn!
كَذَٰلِكَۖ وَأَوۡرَثۡنَٰهَا قَوۡمًا ءَاخَرِينَ 28
Bayi ni o sẹlẹ si wọn, iru ohun ti wọn se iroyin rẹ fun yin, a si jogun awọn ijọ miran tii se arọmọdọmọ isirẹli nibi ọgba idẹra wọn ati awọn odo wọn ati awọn irugbin wọn ati awọn aaye wọn.
فَمَا بَكَتۡ عَلَيۡهِمُ ٱلسَّمَآءُ وَٱلۡأَرۡضُ وَمَا كَانُواْ مُنظَرِينَ 29
Sanmọ ati ilẹ ko yọmi loju lori fir'aona ati ijọ rẹ ti gbati wọn tẹri, bẹẹni wọn ko jẹ ẹniti a lọ lara ti wọn yoo fi wa ronu piwada.
وَلَقَدۡ نَجَّيۡنَا بَنِيٓ إِسۡرَٰٓءِيلَ مِنَ ٱلۡعَذَابِ ٱلۡمُهِينِ 30
Paapaa a ti yọ arọmọdọmọ isirẹli kuro nibi iya ti o yẹpẹrẹ ni nibi ti fir'aona ati awọn ijọ rẹ ti npa awọn ọmọ wọn, wọn si nda awọn ọmọbinrin wọn si.
مِن فِرۡعَوۡنَۚ إِنَّهُۥ كَانَ عَالِيٗا مِّنَ ٱلۡمُسۡرِفِينَ 31
A la wọn kuro nibi iya fir'aona, dajudaju o jẹ onigberaga ninu awọn olukọ ẹnu aala si asẹ Allah ati ẹsin Rẹ.
وَلَقَدِ ٱخۡتَرۡنَٰهُمۡ عَلَىٰ عِلۡمٍ عَلَى ٱلۡعَٰلَمِينَ 32
Paapaa a ti sa awọn ọmọ isirẹli lẹsa ninu imọ lati ọdọ Wa lori agbaye asiko ti wọn nitori pipọ anọbi wọn.
وَءَاتَيۡنَٰهُم مِّنَ ٱلۡأٓيَٰتِ مَا فِيهِ بَلَٰٓؤٞاْ مُّبِينٌ 33
A si fun wọn ni awọn itọka ati awọn awijare eyiti a fi kun Musa lọwọ, ti idẹkun ti o fi oju han fun wọn wa nibẹ gẹgẹ bi ẹran ẹyẹ ati saliwa ati nkan ti o yatọ si wọn.
إِنَّ هَٰٓؤُلَآءِ لَيَقُولُونَ 34
Dajudaju awọn ẹlẹbọ opurọ wọnyi yoo maa sọrọ niti titako ajinde:
إِنۡ هِيَ إِلَّا مَوۡتَتُنَا ٱلۡأُولَىٰ وَمَا نَحۡنُ بِمُنشَرِينَ 35
Ko jẹ nkankan ju iku wa akọkọ lọ, ko si isẹmin lẹyin rẹ, awa kii se ẹniti wọn yoo gbe dide lẹyin iku yii.
فَأۡتُواْ بَِٔابَآئِنَآ إِن كُنتُمۡ صَٰدِقِينَ 36
Ki o wa - irẹ Muhammad - iwọ ati ẹniti o wa pẹlu rẹ ninu awọn olutẹle ọ pẹlu awọn baba wa ti wọn ku ni alaaye, ti ẹ ba jẹ sootọ sootọ nibi ohun ti ẹ npe apemọra rẹ wipe dajudaju Allah yoo gbe awọn oku dide ni alaaye fun isiro ati ẹsan.
أَهُمۡ خَيۡرٌ أَمۡ قَوۡمُ تُبَّعٖ وَٱلَّذِينَ مِن قَبۡلِهِمۡ أَهۡلَكۡنَٰهُمۡۚ إِنَّهُمۡ كَانُواْ مُجۡرِمِينَ 37
Se awọn ẹlẹbọ ti o npe ọ nirọ yii - irẹ ojisẹ - loore ni agbara ati idaabobo tabi ijọ tuba’i ati awọn ti wọn siwaju wọn gẹgẹ bi hadi ati samuud, a pa wọn run lapapọ, dajudaju wọn jẹ ẹlẹsẹ.
وَمَا خَلَقۡنَا ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضَ وَمَا بَيۡنَهُمَا لَٰعِبِينَ 38
A ko da gbogbo sanmọ ati ilẹ ati ohun ti nbẹ laarin mejeeji ni ẹniti o nsere pẹlu isẹda rẹ.
مَا خَلَقۡنَٰهُمَآ إِلَّا بِٱلۡحَقِّ وَلَٰكِنَّ أَكۡثَرَهُمۡ لَا يَعۡلَمُونَ 39
A ko da gbogbo sanmọ ati ilẹ ayaafi nitori ọgbọn kan ti o de ogongo sugbọn ọpọ awọn ẹlẹbọ ko mọ eleyi.
Jijẹ dandan lilugọ olugbagbọ ododo si ọdọ Ọlọhun Ọba rẹ ki o le sọ nibi ete ọta rẹ.
Sise adura lofin leri awọn keferi nigbati wọn ko ba jẹpe ipepe ati igbati wọn ba nja awọn ẹniirẹ logun.
Aye ko nii banujẹ latari iku keferi nitori yiyẹrẹ rẹ lọdọ Allah.
Dida gbogbo sanmọ ati ilẹ jẹ tori ọgbọn ti o de ogongo, ti awọn alaimoore si se aimọkan si i.