وَمَا يَسۡتَوِي ٱلۡأَعۡمَىٰ وَٱلۡبَصِيرُ 19
Keferi ati olugbagbọ ododo ko le dọgba nibi ipo gẹgẹ bi afọju ati oluriran ko le dọgba.
وَلَا ٱلظُّلُمَٰتُ وَلَا ٱلنُّورُ 20
Bẹẹni keferi ati igbagbọ naa ko le dọgba gẹgẹ bi awọn okunkun ati imọlẹ naa ko le dọgba.
وَلَا ٱلظِّلُّ وَلَا ٱلۡحَرُورُ 21
Alujanna ati ina ko le dọgba nibi oripa awọn mejeeji gẹgẹ bi ooji ati atẹgun gbigbona ko le dọgba.
وَمَا يَسۡتَوِي ٱلۡأَحۡيَآءُ وَلَا ٱلۡأَمۡوَٰتُۚ إِنَّ ٱللَّهَ يُسۡمِعُ مَن يَشَآءُۖ وَمَآ أَنتَ بِمُسۡمِعٖ مَّن فِي ٱلۡقُبُورِ 22
Awọn olugbagbọ ododo ko le dọgba pẹlu awọn keferi gẹgẹ bi awọn alaaye ko se le dọgba pẹlu awọn oku, dajudaju Allah ma nfun ẹniti o ba wu U ni itọsọna Rẹ gbọ, iwọ kii se - irẹ ojisẹ - ẹniti o le mu keferi gbọrọ, awọn ti wa da gẹgẹbi oku ninu saare.
إِنۡ أَنتَ إِلَّا نَذِيرٌ 23
Iwọ ko jẹ nkankan ju olusekilọ fun wọn kuro nibi iya Allah.
إِنَّآ أَرۡسَلۡنَٰكَ بِٱلۡحَقِّ بَشِيرٗا وَنَذِيرٗاۚ وَإِن مِّنۡ أُمَّةٍ إِلَّا خَلَا فِيهَا نَذِيرٞ 24
Dajudaju Awa gbe ọ dide - irẹ ojisẹ - pẹlu ododo eyiti ko si iyemeji nibẹ ati olufunniro idunnu fun awọn olugbagbọ ododo lori ohun ti Allah se ni adehun fun wọn ni ẹsan alapọnle, o si tun jẹ olukilọ fun awọn keferi lori ohun ti o se ni adehun fun wọn lori iya ẹlẹta ero, ko si ijọ kan ninu awọn ijọ ti o ti re kọja lọ ayaafi ki ojisẹ kan ti re kọja lọ nibẹ lati ọdọ Allah, ti yoo maa se ikilọ fun un kuro nibi iya Rẹ.
وَإِن يُكَذِّبُوكَ فَقَدۡ كَذَّبَ ٱلَّذِينَ مِن قَبۡلِهِمۡ جَآءَتۡهُمۡ رُسُلُهُم بِٱلۡبَيِّنَٰتِ وَبِٱلزُّبُرِ وَبِٱلۡكِتَٰبِ ٱلۡمُنِيرِ 25
Ti awọn ijọ rẹ ba pe ọ nirọ - irẹ ojisẹ - ki o se suuru, iwọ kọ ni akọkọ ojisẹ ti awọn ijọ rẹ yoo pa rọ mọ, paapaa awọn ijọ ti o re kọja lọ yii ti pe awọn ojisẹ wọn nirọ, gẹgẹbi Hadi, samuud ati ijọ Luuth, awọn ojisẹ wọn wa lati ọdọ Allah pẹlu awọn awijare ti o fi oju han, ti o tọka lori ijẹ ododo wọn, bẹẹni awọn ojisẹ wọn si mu iwe wa fun wọn ati tira onimọlẹ fun ẹniti o ba ronu si i, ti o si nwoye.
ثُمَّ أَخَذۡتُ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْۖ فَكَيۡفَ كَانَ نَكِيرِ 26
Pẹlu eleyi naa, wọn se aimoore si Allah ati ojisẹ Rẹ, wọn ko gba wọn gbọ lododo nibi ohun ti wọn mu wa lati ọdọ Rẹ, Mo wa pa awọn keferi run, ki o ya ronu - irẹ ojisẹ - bi ikorira mi si wọn se to nipa pipa wọn run.
أَلَمۡ تَرَ أَنَّ ٱللَّهَ أَنزَلَ مِنَ ٱلسَّمَآءِ مَآءٗ فَأَخۡرَجۡنَا بِهِۦ ثَمَرَٰتٖ مُّخۡتَلِفًا أَلۡوَٰنُهَاۚ وَمِنَ ٱلۡجِبَالِ جُدَدُۢ بِيضٞ وَحُمۡرٞ مُّخۡتَلِفٌ أَلۡوَٰنُهَا وَغَرَابِيبُ سُودٞ 27
Se o ko ri ni - irẹ ojisẹ - dajudaju Allah ti mimọ nbẹ fun sọ omin ojo kalẹ lati sanmọ, A si ntibi omin naa mu awọn irugbin ti o yatọ si ara wọn ni awọ jade, pupa wa nibẹ ati awọ eweko ati pupa fẹsi fẹsi ati omiran lẹyin igbati a ti fun awọn igi ibẹ ni omin mu, awọn oju ọna funfun ati awọn oju ọna pupa ati awọn oju ọna ti o dudu biri tun wa ninu awọn oke.
وَمِنَ ٱلنَّاسِ وَٱلدَّوَآبِّ وَٱلۡأَنۡعَٰمِ مُخۡتَلِفٌ أَلۡوَٰنُهُۥ كَذَٰلِكَۗ إِنَّمَا يَخۡشَى ٱللَّهَ مِنۡ عِبَادِهِ ٱلۡعُلَمَٰٓؤُاْۗ إِنَّ ٱللَّهَ عَزِيزٌ غَفُورٌ 28
O wa ninu awọn eniyan ati awọn ẹda afayawọ ati awọn ẹranko (rakunmi, malu ati aguntan) ti awọ rẹ yatọ si ara wọn gẹgẹ bi eyiti a darukọ, dajudaju awọn ti o ma npataki ipo Allah ti o ga, ti wọn si nbẹru Rẹ ni awọn ti o nimimọ nipa Rẹ ti mimọ nbẹ fun; nitoripe dajudaju wọn mọ awọn iroyin Rẹ ati ofin Rẹ ati itọka agbara Rẹ, dajudaju Allah jẹ abiyi ti ẹnikankan ko le bori Rẹ, oluforijin ẹsẹ fun ẹniti o ba sẹri ninu awọn ẹru Rẹ.
إِنَّ ٱلَّذِينَ يَتۡلُونَ كِتَٰبَ ٱللَّهِ وَأَقَامُواْ ٱلصَّلَوٰةَ وَأَنفَقُواْ مِمَّا رَزَقۡنَٰهُمۡ سِرّٗا وَعَلَانِيَةٗ يَرۡجُونَ تِجَٰرَةٗ لَّن تَبُورَ 29
Awọn ti wọn ba nka tira Allah eyiti a sọkalẹ fun ojisẹ Wa, ti wọn si nse ohun ti o wa ninu rẹ, ti wọn npe irun wọn ni ojupọnna daadaa, ti wọn si nna ohun ti a se fun wọn ni ojupọnna saka ati omiran ni kọkọ ati gbangba, wọn ngbero lati ibi awọn isẹ yii isowo ni ọdọ Allah ti ko si nii pa run.
لِيُوَفِّيَهُمۡ أُجُورَهُمۡ وَيَزِيدَهُم مِّن فَضۡلِهِۦٓۚ إِنَّهُۥ غَفُورٞ شَكُورٞ 30
Ki Allah le san wọn lẹsan pipe lori awọn isẹ wọn, ki o si tun se alekun ninu ọla Rẹ Oun jẹ ẹniti o lẹtọ si, dajudaju Oun ti mimọ nbẹ fun jẹ alaforijin awọn ẹsẹ, awọn ti a fi awọn iroyin yii royin, olumọ riri awọn isẹ wọn ti o dara.
Kikọ dọgbandọgba laarin ododo ati awọn eniyan rẹ ni ojupọnna kan ati laarin ibajẹ ati awọn ẹniirẹ ni ojupọnna miran.
Pipọ onka awọn ojisẹ ti ọla nbẹ fun wọn siwaju ojisẹ wa ti ikẹ ati ọla nbẹ fun jẹ itọka lori ikẹ Allah ati orikunkun ẹda.
Pipa awọn opurọ run jẹ isesi Ọlọhun Ọba.
Awọn iroyin igbagbọ jẹ owo ere, bẹẹni awọn iroyin keferi jẹ owo ofo.