۞أَفَمَن يَعۡلَمُ أَنَّمَآ أُنزِلَ إِلَيۡكَ مِن رَّبِّكَ ٱلۡحَقُّ كَمَنۡ هُوَ أَعۡمَىٰٓۚ إِنَّمَا يَتَذَكَّرُ أُوْلُواْ ٱلۡأَلۡبَٰبِ 19
Ko le se dọgba ẹniti o mọ wipe ohun ti Ọlọhun Ọba Allah sọkalẹ fun ọ - irẹ ojisẹ - lati ọdọ Ọlọhun Ọba rẹ ni ododo eyiti ko si roiroi nibẹ, ẹni naa ni olugbagbọ ododo ti njẹpe Allah, ati ẹniti o jẹ afọju oun ni keferi ti ko jẹ ipe Allah, dajudaju ẹniti yoo woye ti yoo si gba ikilọ eleyi ni awọn ti wọn ni laakaye ti o mọ.
ٱلَّذِينَ يُوفُونَ بِعَهۡدِ ٱللَّهِ وَلَا يَنقُضُونَ ٱلۡمِيثَٰقَ 20
Awọn ti wọn jẹpe Allah ni awọn npe adehun ti wọn nse pẹlu Allah tabi eyiti wọn se pẹlu awọn ẹru Rẹ, ti wọn kii ja adehun ti o yi pẹlu Ọlọhun Ọba Allah tabi pẹlu ẹniti o yatọ si I.
وَٱلَّذِينَ يَصِلُونَ مَآ أَمَرَ ٱللَّهُ بِهِۦٓ أَن يُوصَلَ وَيَخۡشَوۡنَ رَبَّهُمۡ وَيَخَافُونَ سُوٓءَ ٱلۡحِسَابِ 21
Awọn ni wọn ma nda gbogbo ohun ti Ọlọhun Ọba Allah ba pasẹ didapọ rẹ ninu ibi pọ, wọn si npaya Ọlọhun Ọba ni ipaya ti yoo ti wọn lọ sibi sise awọn asẹ Ọlọhun Ọba Allah ati jijinna si awọn nkan ti O kọ, wọn si nbẹru ki Ọlọhun Ọba Allah mase sesiro wọn lori ohun ti wọn ko jọ ni ẹsẹ, ẹniti wọn ba bi leere isiro yoo parun.
وَٱلَّذِينَ صَبَرُواْ ٱبۡتِغَآءَ وَجۡهِ رَبِّهِمۡ وَأَقَامُواْ ٱلصَّلَوٰةَ وَأَنفَقُواْ مِمَّا رَزَقۡنَٰهُمۡ سِرّٗا وَعَلَانِيَةٗ وَيَدۡرَءُونَ بِٱلۡحَسَنَةِ ٱلسَّيِّئَةَ أُوْلَٰٓئِكَ لَهُمۡ عُقۡبَى ٱلدَّارِ 22
Awọn ni awọn ti wọn se suuru lori itẹle asẹ Allah ati lori awọn ohun ti Ọlọhun kadar le wọn lori ninu ohun ti o ndun mọ ni tabi ko inira bani, wọn si tun se suuru lori ẹsẹ rẹ ni ẹniti nwa iyọnu Allah, ti wọn si nkirun ni ojupọnna pipe, ti wọn si nna awọn ẹtọ ọranyan ninu ohun ti a fun wọn ni dukia, wọn nna niti tọkan tọkan ni ipamọ lati le jinna si sekarimi ati ni gbangba ki ẹlomiran le kọse wọn, wọn si nfi daadaa rọpo ẹniti o ba se aida si wọn, awọn ni ẹniti a fi iroyin yii royin, awọn ni wọn ni igbẹyin ọpẹ ni ọjọ igbende.
جَنَّٰتُ عَدۡنٖ يَدۡخُلُونَهَا وَمَن صَلَحَ مِنۡ ءَابَآئِهِمۡ وَأَزۡوَٰجِهِمۡ وَذُرِّيَّٰتِهِمۡۖ وَٱلۡمَلَٰٓئِكَةُ يَدۡخُلُونَ عَلَيۡهِم مِّن كُلِّ بَابٖ 23
Ọpẹ igbẹyin yii ni ọgba onidẹra eyiti wọn yoo maa wa nibẹ ni ẹniti yoo maa gbadun lailai ninu pipe idẹkun wọn nibẹ ni ki wọn o fi pẹlu wọn awọn ti wọn ba duro deedee ninu awọn baba wọn ati awọn iya wọn ati awọn iyawo wọn ati awọn ọmọ wọn ki ninaju pẹlu pipade wọn le jẹ pipe idẹkun naa, bẹẹ ni awọn Malaika yoo maa wọle ti wọn ni ẹniti o nba wọn yọ ni gbogbo ẹnu ọla wọn ni ile alujannah.
سَلَٰمٌ عَلَيۡكُم بِمَا صَبَرۡتُمۡۚ فَنِعۡمَ عُقۡبَى ٱلدَّارِ 24
Awọn malaika yoo maa ki wọn ni gbogbo igba ti wọn ba wọle ti wọn pẹlu gbolohun wọn wipe: alaafia ko ma ba yin; itumọ: ẹ ti la kuro nibi aburu nitori suuru yin ti ẹ nse nitori itẹle ti Allah ati lori kikoro awọn kadara, ati suuru yin kuro nibi ẹsẹ Rẹ, didara ile igbẹyin tii se igbẹyin yin.
Nigbati Ọlọhun Ọba Allah sọ nipa iroyin awọn olugbagbọ ododo, O tun fi iroyin awọn olugunri se ikeji rẹ, O si sọpe:
وَٱلَّذِينَ يَنقُضُونَ عَهۡدَ ٱللَّهِ مِنۢ بَعۡدِ مِيثَٰقِهِۦ وَيَقۡطَعُونَ مَآ أَمَرَ ٱللَّهُ بِهِۦٓ أَن يُوصَلَ وَيُفۡسِدُونَ فِي ٱلۡأَرۡضِ أُوْلَٰٓئِكَ لَهُمُ ٱللَّعۡنَةُ وَلَهُمۡ سُوٓءُ ٱلدَّارِ 25
Awọn ti wọn ja adehun Ọlọhun lẹyin kikanpa mọ ọ, ti wọn si nge oun ti Ọlọhun Ọba Allah pasẹ didaapọ gẹgẹ bi okun ibi, wọn si nba ilẹ jẹ pẹlu sisẹ Ọlọhun Ọba ti ọla Rẹ ga, awọn wọnyi ni ẹni ijina oloriibu, ileni kuro nibi ikẹ Allah nbẹ fun wọn, igbẹyin aburu si nbẹ fun wọn tii se ina.
ٱللَّهُ يَبۡسُطُ ٱلرِّزۡقَ لِمَن يَشَآءُ وَيَقۡدِرُۚ وَفَرِحُواْ بِٱلۡحَيَوٰةِ ٱلدُّنۡيَا وَمَا ٱلۡحَيَوٰةُ ٱلدُّنۡيَا فِي ٱلۡأٓخِرَةِ إِلَّا مَتَٰعٞ 26
Ọlọhun Ọba Allah ma nfẹ arisiki fun ẹniti o ba wu, O si ma nfun un le mọ ẹniti o ba wu U ninu awọn ẹru Rẹ, sugbọn fifẹ arisiki ko si ninu amin oriire, bẹẹ ni ko si ninu ifẹ Allah, bakanna fifun un le ko si ninu amin ori buburu, awọn keferi dunni pẹlu isẹmin aye, wọn si gbara le e, wọn si fi ọkan balẹ si i, isẹmin aye lẹgbẹ ọrun ju idẹkun diẹ ti yoo lọ lọ.
وَيَقُولُ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ لَوۡلَآ أُنزِلَ عَلَيۡهِ ءَايَةٞ مِّن رَّبِّهِۦۚ قُلۡ إِنَّ ٱللَّهَ يُضِلُّ مَن يَشَآءُ وَيَهۡدِيٓ إِلَيۡهِ مَنۡ أَنَابَ 27
Awọn keferi si Ọlọhun Ọba Allah ati awọn amin Rẹ nsọ wipe: se wọn o wa nii sọ amin ifuramọ lati ọdọ Ọlọhun Ọba Allah fun Muhammad ni, ti yoo maa tọka si jijẹ ootọ rẹ ki a le gba a gbọ, sọ -ire ojise- fun awọn onimọran yii: dajudaju Ọlọhun Ọba Allah ma nfi ẹniti o ba wu U sinu isina lati ibi deedee Rẹ, a si ma nfi mọna ẹniti o ba sẹri lọ ba lati ibi ọla Rẹ, imọna kii se ọwọ wọn ti wọn yoo wa fi so pọ mọ sisọ awọn amin kalẹ.
ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَتَطۡمَئِنُّ قُلُوبُهُم بِذِكۡرِ ٱللَّهِۗ أَلَا بِذِكۡرِ ٱللَّهِ تَطۡمَئِنُّ ٱلۡقُلُوبُ 28
Awọn ti Ọlọhun Ọba Allah fi mọna yii ni awọn ti o nigbagbọ, ti ọkan wọn si nnaju pẹlu iranti Allah lati ibi sise afọmọ fun Un ati didupẹ fun Un ati kika iwe Rẹ ati gbigbọ ọ, ati pẹlu eyiti o yatọ si yẹn ninu awọn iran iranti, tẹti o gbọ, pẹlu iranti Allah nikan ni ọkan fii naju, bẹẹ ni a da a mọ pẹlu eleyi ni.
Siseni loju kokoro si ọpọ awọn iwa ti o lọla ti o ma nsọ alujannah di dandan, ninu rẹ: idapọ daadaa, ipaya Allah ti O ga, mimu adehun sẹ, ati sise suuru ati inawo ati fifi daadaa pade aida pẹlu sise ikilọ fun ni kuro nibi idakeji rẹ.
Dajudaju okunfa arisiki wa ni ọwọ Allah ti o ga ati wipe gbigbaye arisiki tabi fifun mọ ẹru kan ko sọ di dandan ki o maa yọ tabi banujẹ toripe kii se ẹri lori iyọnu Ọlọhun tabi ibinu Rẹ lori ẹru naa.
Dajudaju imọna kii se dandan ki o so pọ ọm sisọ amin kalẹ ati isẹ iyanu eyiti awọn ẹlẹbọ nmu imọran fifi han rẹ wa.
Ninu oripa Alukuraani lori ẹru ti o nigbagbọ nipe yoo jogun ifọkanbalẹ sinu ọkan rẹ.