وَإِذۡ أَخَذَ ٱللَّهُ مِيثَٰقَ ٱلَّذِينَ أُوتُواْ ٱلۡكِتَٰبَ لَتُبَيِّنُنَّهُۥ لِلنَّاسِ وَلَا تَكۡتُمُونَهُۥ فَنَبَذُوهُ وَرَآءَ ظُهُورِهِمۡ وَٱشۡتَرَوۡاْ بِهِۦ ثَمَنٗا قَلِيلٗاۖ فَبِئۡسَ مَا يَشۡتَرُونَ 187
Ati wipe waa ranti irẹ Anọbi nigbati Ọlọhun Ọba Allah gba adehun ti o ni ikanpa mọ lori awọn alufa awọn ti wọn ni tira ninu awọn yahuudi ati awọn nasaara, pe ẹyin yoo maa se alaye tira Ọlọhun Ọba Allah fun awọn eniyan, ati wipe ẹ ko nii pa ohun ti o wa ninu rẹ ninu imọna mọ, ati ohun ti o ntọka lori rẹ ninu jijẹ ti Muhammad jẹ Anọbi (ki Ọlọhun se ikẹ ati igẹ fun un) , ko waa wa lati ọdọ wọn ayaafi jiju adehun naa nu, ati wipe wọn ko yiju wo, ni wọn wa pa ododo mọ, wọn si fi ibajẹ han, ati wipe wọn si tun fi iye ti ko ni asunsi paarọ adehun Ọlọhun Ọba Allah, gẹgẹ bi iyi ati owo eyiti o seese ki ọwọ wọn tẹẹ, iye yii ma buru jai, eyiti wọn fi paarọ adehun Ọlọhun Ọba Allah.
لَا تَحۡسَبَنَّ ٱلَّذِينَ يَفۡرَحُونَ بِمَآ أَتَواْ وَّيُحِبُّونَ أَن يُحۡمَدُواْ بِمَا لَمۡ يَفۡعَلُواْ فَلَا تَحۡسَبَنَّهُم بِمَفَازَةٖ مِّنَ ٱلۡعَذَابِۖ وَلَهُمۡ عَذَابٌ أَلِيمٞ 188
Mase lero - irẹ Anọbi - pe dajudaju awọn ti wọn nyọ pẹlu ohun ti wọn se ninu awọn aburu, ti wọn si tun nifẹ ki awọn eniyan maa yin wọn pẹlu ohun ti wọn ko se ninu daadaa, mase lero yiyege ati lila fun wọn nibi iya, bikose wipe ibudesi wọn ni Jahanamọ, ati wipe o nbẹ fun nibẹ iya ti o ma nmu inira wa.
وَلِلَّهِ مُلۡكُ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِۗ وَٱللَّهُ عَلَىٰ كُلِّ شَيۡءٖ قَدِيرٌ 189
Ati wipe ti Ọlọhun Ọba Allah nikan soso ni ti kii se ti ẹlomiran ọla awọn sanmọ ati ilẹ ati ohun ti nbẹ nibi mejeeji, ni ẹda ati idari ati wipe Ọlọhun Ọba Allah ni Alagbara lori gbogbo nkan.
إِنَّ فِي خَلۡقِ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِ وَٱخۡتِلَٰفِ ٱلَّيۡلِ وَٱلنَّهَارِ لَأٓيَٰتٖ لِّأُوْلِي ٱلۡأَلۡبَٰبِ 190
Dajudaju o nbẹ nibi mimu awọn sanmọ ati ilẹ bẹ lati ibi aisi laini apẹrẹ ti o siwaju, ati nibi bi oru ati ọsan se ngbẹyin ara wọn, ati bi awọn mejeeji se nju ara wọn lọ ni gigun ati ni kikuru, awọn itọka ti o fi oju han fun awọn onilaakaye ti o ni alaafia, ti yoo maa tọka wọn si ẹniti O da aye, Ẹniti o lẹtọ si ijọsin ni Oun nikan soso.
ٱلَّذِينَ يَذۡكُرُونَ ٱللَّهَ قِيَٰمٗا وَقُعُودٗا وَعَلَىٰ جُنُوبِهِمۡ وَيَتَفَكَّرُونَ فِي خَلۡقِ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِ رَبَّنَا مَا خَلَقۡتَ هَٰذَا بَٰطِلٗا سُبۡحَٰنَكَ فَقِنَا عَذَابَ ٱلنَّارِ 191
Ati wipe awọn ni awọn ti wọn ma nranti Ọlọhun Ọba Allah lori awọn isesi wọn, nibi isesi idunnu wọn ati isesi ijoko wọn ati nibi isesi iirọgbọku wọn, ati wipe wọn yoo si maa lo awọn irori wọn sibi ẹda awọn sanmọ ati ilẹ; ni ẹniti yoo maa sọ wipe: irẹ Ọlọhun Ọba wa, O ko da ẹda ti tobi yii lasan, O mọ kuro nibi erekere, waa gbe wa jinna si iya ina pẹlu fifi wa se kongẹ awọn isẹ oloore ati sisọ wa kuro nibi awọn asise.
رَبَّنَآ إِنَّكَ مَن تُدۡخِلِ ٱلنَّارَ فَقَدۡ أَخۡزَيۡتَهُۥۖ وَمَا لِلظَّٰلِمِينَ مِنۡ أَنصَارٖ 192
Toripe dajudaju Iwọ - irẹ Ọlọhun Ọba wa - ẹniti O ba mu wọ ina ninu awọn ẹda Rẹ, ẹ jẹ wipe ni paapaa O ti yẹpẹrẹ rẹ, O si tun yẹyẹ rẹ, ati wipe ko si fun awọn alabosi ni Ọjọ Igbende ninu awọn oluranlọwọ ti wọn yoo kọ iya Ọlọhun Ọba Allah, ati ijẹniniya Rẹ fun wọn.
رَّبَّنَآ إِنَّنَا سَمِعۡنَا مُنَادِيٗا يُنَادِي لِلۡإِيمَٰنِ أَنۡ ءَامِنُواْ بِرَبِّكُمۡ فََٔامَنَّاۚ رَبَّنَا فَٱغۡفِرۡ لَنَا ذُنُوبَنَا وَكَفِّرۡ عَنَّا سَئَِّاتِنَا وَتَوَفَّنَا مَعَ ٱلۡأَبۡرَارِ 193
Irẹ Ọlọhun Ọba wa, dajudaju awa gbọ olu pepe sibi nini igbagbọ - oun naa ni Anọbi Rẹ Muhammad (ki Ọlọhun se ikẹ ati igẹ fun un) - ti o npepe ni ẹniti o nsọ wipe: ẹ ni igbagbọ pẹlu Ọlọhun Ọba Allah, Ọlọhun Ọba yin, Ọba ọkan soso, ni awa waa ni igbagbọ pẹlu ohun ti o npepe sibẹ, a si tun waa tẹle ofin rẹ, waa daabobo awọn ẹsẹ wa, ki O si ma yẹyẹ wa, ati wipe ki O se amojukuro nibi awọn aida wa, ki O si ma gba wa mu pẹlu rẹ, ati wipe ki O pawa pẹlu awọn ẹniire pẹlu fifa wa si kongẹ sise awọn isẹ oloore, ati gbigbe awọn aida ju silẹ.
رَبَّنَا وَءَاتِنَا مَا وَعَدتَّنَا عَلَىٰ رُسُلِكَ وَلَا تُخۡزِنَا يَوۡمَ ٱلۡقِيَٰمَةِۖ إِنَّكَ لَا تُخۡلِفُ ٱلۡمِيعَادَ 194
Irẹ Ọlọhun Ọba wa, wa fun wa ni ohin ti O ba wa se adehun lori awọn ahọn awọn ojisẹ Rẹ ninu ifini mọna ati aranse ni ile aye, ati wipe mase yẹyẹ wa ni Ọjọ Igbende pẹlu wiwọ ina, dajudaju Iwọ, - Irẹ Ọlọhun Ọba wa - ni Alapọnle, ti Iwọ kii si yapa dehun.
Ninu awọn iroyn awọn alufa aburu ninu awọn ti o ni tira: ni fifi imọ pamọ ati titẹle ifẹ inu, ati mima yọ pẹlu ẹyin awọn eniyan pẹlu biburu awọn kọkọ wọn ati awọn isẹ wọn.
Rironu nipa ẹda Ọlọhun Ọba Allah (ti ọla Rẹ ga) nibi awọn sanmọ ati ilẹ, ati gbigbẹyin ti awọn asiko gbẹyin ara wọn, o ma njogun nini amodaju pẹlu titobi Ọlọhun Ọba Allah, ati pipe itẹriba fun Un, ti O niyi, ti O si gbọngbọn.
Bibẹ Ọlọhun Ọba Allah ati titẹriba ọkan fun Un (ti ọla Rẹ ga) wa ninu eyiti o pe ju ninu awọn afihan ijọsin.