أُحِلَّ لَكُمۡ لَيۡلَةَ ٱلصِّيَامِ ٱلرَّفَثُ إِلَىٰ نِسَآئِكُمۡۚ هُنَّ لِبَاسٞ لَّكُمۡ وَأَنتُمۡ لِبَاسٞ لَّهُنَّۗ عَلِمَ ٱللَّهُ أَنَّكُمۡ كُنتُمۡ تَخۡتَانُونَ أَنفُسَكُمۡ فَتَابَ عَلَيۡكُمۡ وَعَفَا عَنكُمۡۖ فَٱلۡـَٰٔنَ بَٰشِرُوهُنَّ وَٱبۡتَغُواْ مَا كَتَبَ ٱللَّهُ لَكُمۡۚ وَكُلُواْ وَٱشۡرَبُواْ حَتَّىٰ يَتَبَيَّنَ لَكُمُ ٱلۡخَيۡطُ ٱلۡأَبۡيَضُ مِنَ ٱلۡخَيۡطِ ٱلۡأَسۡوَدِ مِنَ ٱلۡفَجۡرِۖ ثُمَّ أَتِمُّواْ ٱلصِّيَامَ إِلَى ٱلَّيۡلِۚ وَلَا تُبَٰشِرُوهُنَّ وَأَنتُمۡ عَٰكِفُونَ فِي ٱلۡمَسَٰجِدِۗ تِلۡكَ حُدُودُ ٱللَّهِ فَلَا تَقۡرَبُوهَاۗ كَذَٰلِكَ يُبَيِّنُ ٱللَّهُ ءَايَٰتِهِۦ لِلنَّاسِ لَعَلَّهُمۡ يَتَّقُونَ 187
Paapaa, o nbẹ nibi alamọri akọkọ, wọn se ni eewọ fun ọkunrin nigbati o ba sun ni alẹ aawẹ, ti o wa ji siwaju alufajari, pe ki o jẹ, tabi ki o sun mọ ara ile rẹ, Ọlọhun Ọba Allah waa pa nkan naa rẹ, O si se ni ẹtọ fun yin - ẹyin olugbagbọ ododo- ni awọn alẹ aawẹ, biba awọn obirin yin sasepọ, toripe awọn jẹ ibora ati irẹ oju nilẹ fun yin, ẹyin naa si jẹ ibora ati irẹ oju nilẹ fun awọn naa, apakan yin ko le rọrọ kuro ni ọdọ apakan, Ọlọhun Ọba Allah mọ pe dajudaju ẹyin jẹ ẹniti o njamba awọn ẹmi yin pẹlu sise ohun ti Ọlọhun Ọba Allah kọ fun yin, ni O se waa kẹyin, ti O si gba tituuba yin, ti O si gbe ọrọ ni fifuyẹ fun yin, nisinsin yii, ẹ maa ba wọn se asepọ, ki ẹ si maa wa ohun ti Ọlọhun Ọba Allah kadara fun yin ninu awọn arọmọdọmọ, ẹ maa jẹ, ki ẹ si maa mu ni gbogbo oru titi yoo fi han si yin yiyọ alufajari ododo pẹlu fifunfun gboo alufajari, ati kikuro rẹ lara dudu oru, lẹyin igba naa ki ẹ waa pe aawẹ pẹlu kikora duro kuro nibi awọn ohun ti o nba aawẹ jẹ lati igbati alufajari ba ti yọ titi ti oorun yoo fi wọ, ẹ ko gbọdọ ba awọn obirin yin se asepọ nigbati ẹyin ba nse ikoraro lọwọ ninu awọn mọsalaasi; toripe nkan naa yoo ba jẹ, awọn idajọ ti A sọ yii ni aala Ọlọhun Ọba Allah laarin ohun ti o jẹ ẹtọ ati eewọ, ẹ ko gbọdọ sun mọ lailai; toripe ẹniti o ba sun mọ awọn aala Ọlọhun Ọba Allah, o seese ki o ko sinu eewọ pẹlu iru alaye ti o han yii, ti ko si pamọ yii fun awọn idajọ naa, Ọlọhun Ọba Allah nse alaye awọn aayah Rẹ fun awọn eniyan, ki wọn le ba jẹ ẹniti yoo paya Rẹ pẹlu mima se ohun ti O pasẹ, ati gbigbe ohun ti O kọ ju silẹ.
وَلَا تَأۡكُلُوٓاْ أَمۡوَٰلَكُم بَيۡنَكُم بِٱلۡبَٰطِلِ وَتُدۡلُواْ بِهَآ إِلَى ٱلۡحُكَّامِ لِتَأۡكُلُواْ فَرِيقٗا مِّنۡ أَمۡوَٰلِ ٱلنَّاسِ بِٱلۡإِثۡمِ وَأَنتُمۡ تَعۡلَمُونَ 188
Apakan yin ko si gbọdọ maa gba dukia apakan yin pẹlu ojupọna ti ko ba ofin mu, gẹgẹ bi ole jija, inja nkan gba lọwọ ẹni, ati eeru sise, ki ẹ si mama ba ara yin ja pẹlu rẹ lọsi ọdọ awọn adajọ, ki ẹ le ba gba apakan ninu awọn dukia awọn eniyan, ni ẹniti ngbe ẹsẹ wọ bi ẹwu, ti ẹyin si mọ pe dajudaju Ọlọhun Ọba Allah se nkan naa ni eewọ, ẹ ko waa ri sise aya gbangba si dida ẹsẹ pẹlu mima pe eewọ ni, eebu ti o buru gan an ni, ti iya rẹ si tobi.
۞يَسَۡٔلُونَكَ عَنِ ٱلۡأَهِلَّةِۖ قُلۡ هِيَ مَوَٰقِيتُ لِلنَّاسِ وَٱلۡحَجِّۗ وَلَيۡسَ ٱلۡبِرُّ بِأَن تَأۡتُواْ ٱلۡبُيُوتَ مِن ظُهُورِهَا وَلَٰكِنَّ ٱلۡبِرَّ مَنِ ٱتَّقَىٰۗ وَأۡتُواْ ٱلۡبُيُوتَ مِنۡ أَبۡوَٰبِهَاۚ وَٱتَّقُواْ ٱللَّهَ لَعَلَّكُمۡ تُفۡلِحُونَ 189
Wọn yoo bi ọ leere - irẹ ojisẹ - nipa kiko awọn iletesu ati yiyi awọn isesi rẹ pada, sọ ni ẹniti nda won lohun nipa idi nkan naa wipe: dajudaju o jẹ imọ asiko fun awọn eniyan, wọn yoo fi maa mọ asiko awọn ijọsin wọn; gẹgẹ bi awọn Osu Hajj, ati Osu Aawẹ, ati pipe odun nibi Saka, wọn yoo si maa fi mọ awọn asiko wọn nibi ibasepọ; gẹgẹ bi sise odiwọn asiko owo itanran, ati awọn gbese. Kii se daradara ati oore ni ki ẹ maa wọ inu awọn ile lati awọn ẹyin rẹ nigbati ẹ ba fẹ wọ asọ arami fun isẹ Hajj tabi Umrah - gẹgẹ bi ẹyin se ma nlero nigba aimọkan, sugbọn eyiti o jẹ daradara ni paapaa ni ẹniti o ba paya Ọlọhun Ọba Allah ni gbangba ati kọkọ, ki wiwa yin si awọn ile naa jẹ lati awọn ẹnu ọna rẹ, oun ni o fi nrọrun fun yin ju, ti o si fi njinna si inira julọ; toripe Ọlọhun Ọba Allah ko la oun ti inira ati ilekoko nbẹ nibẹ fun yin bọ yin lọrun, ki ẹ ya fi si aarin yin ati iya Ọlọhun Ọba Allah gaga kan pelu isẹ daadaa, ki ẹ le jere pẹlu ki ọwọ yin tẹ ohun ti ẹ nrankan, ati yiyege kuro ninu oun ti ẹ nbẹru rẹ.
وَقَٰتِلُواْ فِي سَبِيلِ ٱللَّهِ ٱلَّذِينَ يُقَٰتِلُونَكُمۡ وَلَا تَعۡتَدُوٓاْۚ إِنَّ ٱللَّهَ لَا يُحِبُّ ٱلۡمُعۡتَدِينَ 190
Ẹ maa gbogun ti - lati fi wa igbe gbolohun Ọlọhun Ọba Allah soke - awọn ti wọn ngbogun ti yin ninu awọn alaigbagbọ, ki wọn le ba di ọna mọ yin kuro nibi ẹsin Ọlọhun Ọba Allah, ki ẹ si ma kọja awọn ẹnu aala Ọlọhun Ọba Allah pẹlu mima pa awọn ọmọde, awọn obirin ati awọn agbalagba, tabi ki ẹ se awọn ti ẹ pa ni yanayana, ati ohun ti o jọọ, dajudaju Ọlọhun Ọba Allah ko nifẹ awọn ti wọn ba nkọja ẹnu aala Rẹ, nibi ohun ti O se ni ofin, ti O si da ẹjọ rẹ.
Sise mima koraduro ni ofin, ohun naa ni didunnimọ Mọsalaasi fun ijọsin sise; nitori idi eleyi ni wọn fi kọ gbogbo ohun ti o le kọdi eero ikoraduro yii, ninu rẹ naa ni mima ba awọn obirin se asepọ.
Kikọ mima jẹ dukia awọn eniyan pẹlu aitọ, ati sise gbogbo awọn atẹgun, tabi awọn ọna ti o le mu eeyan lọ si ibẹ ni eewọ ninu rẹ naa ni mima gba owo ẹyin.
Sise ikọja ẹnu aala ni eewọ, ati kikọọ; toripe ẹsin yii duro lori deede ati daradara.