وَٱتَّقُواْ ٱلَّذِي خَلَقَكُمۡ وَٱلۡجِبِلَّةَ ٱلۡأَوَّلِينَ 184
Ki ẹ si paya ẹniti o da yin, ti O si da awọn ijọ ti o siwaju yin pẹlu bibẹru Rẹ ki O ma sọ iya Rẹ kalẹ le yin lori.
قَالُوٓاْ إِنَّمَآ أَنتَ مِنَ ٱلۡمُسَحَّرِينَ 185
Awọn ijọ Shuaibu sọ fun Shuaibu wipe: dajudaju iwọ wa ninu ẹniti idan ti mu ni ọpọ igba titi ti idan fi bori laakaye rẹ, ti o si mu kuro nibẹ.
وَمَآ أَنتَ إِلَّا بَشَرٞ مِّثۡلُنَا وَإِن نَّظُنُّكَ لَمِنَ ٱلۡكَٰذِبِينَ 186
Iwọ kii se se nkankan ju abara bii ti wa lọ, ko si ẹsa fun ọ le wa lori, bawo ni o se fẹẹ jẹ ojisẹ? A ko ro ọ si nkankan ju opurọ lọ nibi ohun ti o npe ara rẹ gẹgẹ bi ojisẹ.
فَأَسۡقِطۡ عَلَيۡنَا كِسَفٗا مِّنَ ٱلسَّمَآءِ إِن كُنتَ مِنَ ٱلصَّٰدِقِينَ 187
Ki o ja egigi kan le wa lori lati sanmọ ti o ba jẹ olododo nibi ohun ti o npe ara rẹ.
قَالَ رَبِّيٓ أَعۡلَمُ بِمَا تَعۡمَلُونَ 188
Shuaibu sọ fun wọn: Ọlọhun Ọba mi mọ ohun ti ẹ nse ninu ẹbọ ati ẹsẹ, nkankan ko pomọ fun Un ninu isẹ yin.
فَكَذَّبُوهُ فَأَخَذَهُمۡ عَذَابُ يَوۡمِ ٱلظُّلَّةِۚ إِنَّهُۥ كَانَ عَذَابَ يَوۡمٍ عَظِيمٍ 189
Wọn tẹ siwaju lori pipe e nirọ, iya ti o tobi wa sẹlẹ si wọn nigbati ẹsu ojo waa bo wọn lẹyin ọjọ ti ooru rẹ le gidigidi, O si rọ ojo ina le wọn lori, bẹẹni o jo wọn, dajudaju ojo iparun jẹ ojo ti o tobi ni ibẹru.
إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَأٓيَةٗۖ وَمَا كَانَ أَكۡثَرُهُم مُّؤۡمِنِينَ 190
Dajudaju nibi pipa ijọ Shuaibu run ti a darukọ jẹ ariwoye fun awọn oluwoye, bayi ni ọpọ wọn ko jẹ olugbagbọ ododo.
وَإِنَّ رَبَّكَ لَهُوَ ٱلۡعَزِيزُ ٱلرَّحِيمُ 191
Ati wipe dajudaju Ọlọhun Ọba rẹ - ire ojise - jẹ alagbara eyiti o ngbẹsan ni ara awọn ọta Rẹ, O si jẹ Onikẹ fun ẹniti o ba ronu piwada ninu awọn ẹru Rẹ.
وَإِنَّهُۥ لَتَنزِيلُ رَبِّ ٱلۡعَٰلَمِينَ 192
Ati wipe dajudaju Alukuraani ti o sọkalẹ fun Muhammad ẹniti ikẹ ati ọla nbẹ fun jẹ nkan isọkalẹ kan lati ọdọ Ọlọhun Ọba olutọju gbogbo ẹda.
نَزَلَ بِهِ ٱلرُّوحُ ٱلۡأَمِينُ 193
Jibril ẹni ifọkantan - ti alaafia nbẹ fun - ni o sọkalẹ pẹlu rẹ.
عَلَىٰ قَلۡبِكَ لِتَكُونَ مِنَ ٱلۡمُنذِرِينَ 194
O sọ ọ kalẹ si ọkan rẹ - ire ojise - ki o le wa ninu awọn ojisẹ eyiti o nse ikilọ fun awọn eniyan, ti o si ndaẹruba wọn kuro nibi iya Allah.
بِلِسَانٍ عَرَبِيّٖ مُّبِينٖ 195
O sọ ọ kalẹ pẹlu ahọn larubawa ti o fi oju han.
وَإِنَّهُۥ لَفِي زُبُرِ ٱلۡأَوَّلِينَ 196
Ati wipe dajudaju Alukuraani jẹ ohun ti a ti darukọ nibi iwe awọn ẹni akọkọ, paapaa awọn tira sanmọ ti o siwaju ti mu iro rẹ wa.
أَوَ لَمۡ يَكُن لَّهُمۡ ءَايَةً أَن يَعۡلَمَهُۥ عُلَمَٰٓؤُاْ بَنِيٓ إِسۡرَٰٓءِيلَ 197
Se ko si amin lori ijẹ ododo rẹ fun awọn olupe ọ nirọ ni lati jẹ ki awọn onimimọ ọmọ isirẹli mọ paapaa ounti wọn sọkalẹ fun ọ gẹgẹ bi Abdullahi ọmọ Salaam.
وَلَوۡ نَزَّلۡنَٰهُ عَلَىٰ بَعۡضِ ٱلۡأَعۡجَمِينَ 198
Ti a ba sọ Alukuraani yii kalẹ fun awọn ti kii fii ahọn larubawa sọrọ.
فَقَرَأَهُۥ عَلَيۡهِم مَّا كَانُواْ بِهِۦ مُؤۡمِنِينَ 199
Ki o ka a fun wọn ohun ti yoo sọ wọn di olugbagbọ ododo; toripe dajudaju wọn yoo maa sọpe: a ko le gbọ ọ ye, ki wọn yaa maa dupẹ fun Allah lori sisọ ọ kalẹ pẹlu ede wọn.
كَذَٰلِكَ سَلَكۡنَٰهُ فِي قُلُوبِ ٱلۡمُجۡرِمِينَ 200
Bayi ni a se fi iparọ ati keferi si ọkan awọn ẹlẹsẹ.
لَا يُؤۡمِنُونَ بِهِۦ حَتَّىٰ يَرَوُاْ ٱلۡعَذَابَ ٱلۡأَلِيمَ 201
Wọn ko le yi pada lori keferi ti wọn wa, bẹẹni wọn ko le nigbagbọ titi wọn yoo fi ri iya inira naa.
فَيَأۡتِيَهُم بَغۡتَةٗ وَهُمۡ لَا يَشۡعُرُونَ 202
Ti iya naa yoo fi wa ba wọn lojiji, wọn ko si ni mọ wiwa rẹ ti yoo fi ja lu wọn.
فَيَقُولُواْ هَلۡ نَحۡنُ مُنظَرُونَ 203
Wọn yoo maa sọ nigbati iya naa ba nsọkalẹ le wọn lori lojiji nitori lile koko ofo rẹ: njẹ wọn le lọ wa lara ki a le ronu piwada lọsi ọdọ Allah bi?!
أَفَبِعَذَابِنَا يَسۡتَعۡجِلُونَ 204
Se iya wa ni awọn keferi yii nkanju rẹ ni ẹniti nsọ bayi wipe: a ko nii gba ọ gbọ titi ti sanmọ yoo fi ja gẹgẹ bi o se nlero le wa lori ni ẹja kan soso?!
أَفَرَءَيۡتَ إِن مَّتَّعۡنَٰهُمۡ سِنِينَ 205
Fun mi niro - irẹ ojisẹ - ti awọn keferi olugunni lori yii ba kọ fun wa lati ma nigbagbọ si ohun ti o mu wa pẹlu idẹkun ni asiko ti o ntẹsiwa.
ثُمَّ جَآءَهُم مَّا كَانُواْ يُوعَدُونَ 206
Lẹyin igba naa, ohun ti wọn se ni adehun ninu iya wa ba wọn lẹyin asiko ti idẹkun naa ti tẹ wọn lọwọ.
Bi Musulumi ba se jindo si ninu ede larubawa ni yoo se nikapa lati gbọ agbọye alukuraani.
Mimu awijare lori awọn ẹlẹbọ lati ọdọ awọn onideede ninu awọn ti a fun ni tira wa ninu fifi alukuraani rinlẹ wipe ọdọ Allah ni o ti wa.
Ohun ti awọn keferi ba ri ninu idẹkun jẹ idẹnilẹkẹ kii se apọnle.