فَمَنۡ خَافَ مِن مُّوصٖ جَنَفًا أَوۡ إِثۡمٗا فَأَصۡلَحَ بَيۡنَهُمۡ فَلَآ إِثۡمَ عَلَيۡهِۚ إِنَّ ٱللَّهَ غَفُورٞ رَّحِيمٞ 182
Ẹniti o ba mọ yiyẹ ẹniti o se asọtẹlẹ kuro nibi ododo tabi ikọja ẹnu aala kan nibi asọtẹlẹ, ti o waa se atunse ohun ti ẹniti o sọ asọtẹlẹ bajẹ pẹlu sise isiti fun un, ti o tun waa se atunse laarin awọn ti wọn nse ifanfa lori asọtẹlẹ, ko si ẹsẹ fun un, bikose wipe ẹniti wọn yoo san ni ẹsan ni lori atunse rẹ, dajudaju Ọlọhun Ọba Allah, Alaforijin ni fun ẹniti o ba tuuba ninu awọn ẹru Rẹ, Onikẹ wọn si ni.
يَٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ كُتِبَ عَلَيۡكُمُ ٱلصِّيَامُ كَمَا كُتِبَ عَلَى ٱلَّذِينَ مِن قَبۡلِكُمۡ لَعَلَّكُمۡ تَتَّقُونَ 183
Mo pe ẹyin ti ẹ gba Ọlọhun Ọba Allah gbọ, ti ẹ si ntẹle ojisẹ Rẹ, wọn se ni ọranyan leyin lori aawẹ gbigba lati ọdọ Ọlọhun Ọba Allah yin gẹgẹ bi wọn se se ni ọranyan le awọn ijọ ti o siwaju yin, ki ẹ le baa jẹ ẹniti yoo paya Ọlọhun Ọba Allah pẹlu pe ki ẹ fi si laarin yin, ati laarin iya rẹ, gaga kan pẹlu awọn isẹ oloore, ninu eyiti ti o tonbi nibẹ ni aawẹ wa.
أَيَّامٗا مَّعۡدُودَٰتٖۚ فَمَن كَانَ مِنكُم مَّرِيضًا أَوۡ عَلَىٰ سَفَرٖ فَعِدَّةٞ مِّنۡ أَيَّامٍ أُخَرَۚ وَعَلَى ٱلَّذِينَ يُطِيقُونَهُۥ فِدۡيَةٞ طَعَامُ مِسۡكِينٖۖ فَمَن تَطَوَّعَ خَيۡرٗا فَهُوَ خَيۡرٞ لَّهُۥۚ وَأَن تَصُومُواْ خَيۡرٞ لَّكُمۡ إِن كُنتُمۡ تَعۡلَمُونَ 184
Aawẹ ti o jẹ ọranyan fun yin, oun ni ki ẹ gba aawẹ awọn ọjọ ti o kere ninu ọdun, ẹniti o ba jẹ alaarẹ ninu yin, ni aarẹ kan ti o le fun lati gbaawẹ, tabi o jẹ onirin-ajo; o ni anfaani ki o ja aawẹ, leyin na o di dandan fun, ki o da deede ounti o ja pada ninu awọn ọjọ naa, o si jẹ dandan fun awọn ti ko ni agbara lati gba aawẹ, mima san itanran nigbati wọn ba ja aawẹ, ohun naa ni mima fun alaini ni ounjẹ ọjọ kọọkan ti wọn ba ja aawẹ nibẹ, enikeni ti o ba se alekun lori fifun alaini kan lounje, abi oun fun yen lounje pelu gbigbaawe oun lo loore fun, ki ẹ gba aawẹ ni o loore fun yin ju pe ki ẹ ja aawẹ lọ, ati ki ẹ maa san itanran, ti ẹ ba jẹ ẹniti o mọ oun ti nbẹ ninu aawẹ ninu ọla. Idajọ yii jẹ akọkọ igbati Ọlọhun Ọba Allah se aawẹ l’ofin ni o fi jẹ wipe ẹniti o ba wu yoo gba aawẹ, ẹniti o ba wu yoo si ja aawẹ, yoo si tun maa bọ alaini, lẹyin igba naa ni Ọlọhun Ọba Allah se aawẹ ni dandan, ti O si se ni ọranyan lori gbogbo ẹniti o ba ti balaga, ti o ni agbara.
شَهۡرُ رَمَضَانَ ٱلَّذِيٓ أُنزِلَ فِيهِ ٱلۡقُرۡءَانُ هُدٗى لِّلنَّاسِ وَبَيِّنَٰتٖ مِّنَ ٱلۡهُدَىٰ وَٱلۡفُرۡقَانِۚ فَمَن شَهِدَ مِنكُمُ ٱلشَّهۡرَ فَلۡيَصُمۡهُۖ وَمَن كَانَ مَرِيضًا أَوۡ عَلَىٰ سَفَرٖ فَعِدَّةٞ مِّنۡ أَيَّامٍ أُخَرَۗ يُرِيدُ ٱللَّهُ بِكُمُ ٱلۡيُسۡرَ وَلَا يُرِيدُ بِكُمُ ٱلۡعُسۡرَ وَلِتُكۡمِلُواْ ٱلۡعِدَّةَ وَلِتُكَبِّرُواْ ٱللَّهَ عَلَىٰ مَا هَدَىٰكُمۡ وَلَعَلَّكُمۡ تَشۡكُرُونَ 185
Osu Ramadan, eyiti sisọ Alukuraani bẹrẹ ni ibẹ fun Anọbi (ki ikẹ ati igẹ Ọlọhun ko maa ba) ni Oru Kadara, Ọlọhun Ọba Allah sọkalẹ ni jijẹ imọna fun awọn eniyan, o si nbẹ nibẹ awọn itọka ti o fi oju han ninu imọna, ati ohun ti o nse onpinya laarin ododo ati irọ, ẹniti Osu ramadan ba de ba, ti o si wa ni ile, ti o si ni alaafia, ki o ya gba a ni dandan, ẹniti o ba jẹ alaisan, ti aawẹ nira fun un, tabi onirin-ajo; o ni ẹtọ lati ja aawẹ, ti o ba wa ja aawẹ, ohun ti o jẹ dandan fun un ni ki o da awọn ọjọ ti o ba ja pada, Ọlọhun Ọba Allah gbero pẹlu ohun ti O se ni ofin fun yin lati mu yin gba oju ọna irọrun, kii se ti inira, ki ẹ si le ba pe gbogbo onka aarin osu naa, ki ẹ si le baa ma gbe Ọlọhun Ọba Allah tobi lẹyin ipari Osu Ramadan ati Ọjọ Ọdun lori pe O fi yin se kongẹ gbigba aawẹ Rẹ, ti O si ran yin lọwọ lori pipee, a ki ẹ le ba jẹ ẹniti yoo maa dupẹ fun Ọlọhun Ọba Allah lori bi O se fi yin mọna lọ si ibi ẹsin yii, eyiti O yọnu si fun yin.
وَإِذَا سَأَلَكَ عِبَادِي عَنِّي فَإِنِّي قَرِيبٌۖ أُجِيبُ دَعۡوَةَ ٱلدَّاعِ إِذَا دَعَانِۖ فَلۡيَسۡتَجِيبُواْ لِي وَلۡيُؤۡمِنُواْ بِي لَعَلَّهُمۡ يَرۡشُدُونَ 186
Ti wọn ba bi ọ leere -irẹ Anọbi- awọn ẹrusin Mi nipa bi Mo se sun mọ tabi bi Mo se ma ndahun ipe wọn, dajudaju Emi sun mọ wọn pẹkipẹki, ti Mo si mọ gbogbo awọn isesi wọn, ti Mo si ngbọ awọn ipe wọn, wọn ko ni bukaata si awọn alagbawi, ati gbigbe ohun soke, Mo ma ndahun ipe ẹniti o ba pe Mi, nigbati o ba pe Mi, ni ẹniti o se afọmọ nibi adua rẹ, ki wọn yaa rọ fun Mi ati fun awọn asẹ Mi, ki si duro sinsin lori igbagbọ wọn, toripe nkan naa ni atẹgun ti o se anfaani fun didahun Mi, ki wọn le baa tọ oju ọnaamọ naa nibi awọn alamọri wọn ti ẹsin ati ti aye.
Ọlọhun Ọba Allah gbe ọla fun Osu Ramadan pẹlu sise ni osu aawẹ ati pẹlu sisọ Alukuraani kalẹ nibẹ, o si jẹ Osu Alukuraani; tori idi eleyi ni Anọbi (ki Ọlọhun se ikẹ ati igẹ fun) se ma nse idanilẹkọ pẹlu Jibril ninu Ramadan, o si ma ngbiyanju nibẹ ti ko ki ngbiyanju rẹ ninu eyiti o yatọ sii.
Ofin Islam duro nibi awọn ipilẹ rẹ ati akẹtun rẹ lori irọrun ati mimu inira lọ, Ọlọhun Ọba Allah ko se nkankan le wa lori ninu ẹsin ninu inira.
Sisunmọ ti Ọlọhun Ọba Allah sunmọ awọn ẹru Rẹ ati bi O se rọkirika wọn, ati imọ Rẹ ti o pe pẹlu awọn isesi wọn; tori idi eleyi, Oun ma ngbọ ipe wọn, O si ma ndahun ibeere wọn.