لَّقَدۡ سَمِعَ ٱللَّهُ قَوۡلَ ٱلَّذِينَ قَالُوٓاْ إِنَّ ٱللَّهَ فَقِيرٞ وَنَحۡنُ أَغۡنِيَآءُۘ سَنَكۡتُبُ مَا قَالُواْ وَقَتۡلَهُمُ ٱلۡأَنۢبِيَآءَ بِغَيۡرِ حَقّٖ وَنَقُولُ ذُوقُواْ عَذَابَ ٱلۡحَرِيقِ 181
Paapaa Ọlọhun Ọba Allah ti gbọ gbolohun awọn yahuudi nigbati wọn sọ wipe: “dajudaju Ọlọhun Ọba Allah olosi ni, nibi ti o ti wa idogo ni ọdọ wa, ati wipe awọn si jẹ awọn ọlọrọ pẹlu ohun ti o nbẹ ni ọdọ wa ninu awọn dukia” Awa yoo kọ ohun ti wọn sọ ninu adapa irọ ati irọ ojukoroju lori Ọlọhun Ọba wọn, ati bi wọn se npa awọn Anọbi wọn laini ẹtọ, ati wipe a o sọ fun wọn wipe: ẹ maa tọ iya ti o ma njoni ninu ina wo.
ذَٰلِكَ بِمَا قَدَّمَتۡ أَيۡدِيكُمۡ وَأَنَّ ٱللَّهَ لَيۡسَ بِظَلَّامٖ لِّلۡعَبِيدِ 182
Iya naa jẹ pẹlu okunfa ohun ti awọn ọwọ yin ti siwaju - ẹyin yahuudi - ninu awọn iyapa ati awọn ọrọ iyẹpẹrẹ ati pẹlu wipe dajudaju Ọlọhun Ọba Allah ko nii se abosi ẹnikankan ninu awọn ẹru Rẹ.
ٱلَّذِينَ قَالُوٓاْ إِنَّ ٱللَّهَ عَهِدَ إِلَيۡنَآ أَلَّا نُؤۡمِنَ لِرَسُولٍ حَتَّىٰ يَأۡتِيَنَا بِقُرۡبَانٖ تَأۡكُلُهُ ٱلنَّارُۗ قُلۡ قَدۡ جَآءَكُمۡ رُسُلٞ مِّن قَبۡلِي بِٱلۡبَيِّنَٰتِ وَبِٱلَّذِي قُلۡتُمۡ فَلِمَ قَتَلۡتُمُوهُمۡ إِن كُنتُمۡ صَٰدِقِينَ 183
Ati wipe awọn naa ni awọn ti wọn sọ niti irọ ati adapa irọ wipe: dajudaju Ọlọhun Ọba Allah sọ asọtẹlẹ fun wa nibi awọn tira Rẹ ati lori awọnb ahọn Anọbi Rẹ pe ki a mọ ni igbagbọ si ojisẹ kankan, titi ti Yoo fi mu wa fun wa ohun ti yoo sọ rọ Rẹ di ododo, ati wipe nkan naa wa pẹlu ki o se asunmọ lọsi ọdọ Ọlọhun Ọba Allah pẹlu saara kan, ti ina kan ti o sọkalẹ yoo jo, ni wọn wa pa irọ mọ Ọlọhun Ọba Allah pẹlu sise afiti asẹtẹlẹ si ọdọ Rẹ, ati nibi kiko awọn itọka si ododo ojisẹ jọ sibi ohun ti wọn darukọ, tori idi eleyi ni Ọlọhun Ọba Allah fi pa Anọbi Rẹ Muhammad (ki Ọlọhun se ikẹ ati igẹ fun un) lasẹ pe ki o sọ fun wọn wipe: paapaa awọn ojisẹ ti wa ba yin siwaju mi pẹlu awọn awijare ti o fi oju han lori isododo wọn, ati pẹlu ohun ti ẹ darukọ ninu asunmọ eyiti ina kan yoo jo lati sanmọ, ki waa lo de ti ẹ fi pe wọn ni onirọ, ti ẹ si tun fi pa wọn, ti o ba jẹ wipe ẹ jẹ olusọ ododo nibi ohun ti ẹ nsọ? !
فَإِن كَذَّبُوكَ فَقَدۡ كُذِّبَ رُسُلٞ مِّن قَبۡلِكَ جَآءُو بِٱلۡبَيِّنَٰتِ وَٱلزُّبُرِ وَٱلۡكِتَٰبِ ٱلۡمُنِيرِ 184
Ti wọn ba wa pe ọ ni onirọ - irẹ Anọbi - mase banujẹ, toripe isesi awọn alaigbagbọ ni, ati wipe ni paapaa wọn ti pe awọn ojisẹ ti o pọ siwaju rẹ ni onirọ, ti wọn wa pẹlu awọn ẹri eyiti o fi oju han, ati pẹlu awọn tira eyiti o ko jọ lori awọn ọrọ isiti ati awọn eyiti o lẹ, ati tira ti o jẹ olutọni sọna pẹlu ohun ti o nbẹ nibẹ ninu awọn idajọ ati awọn ofin.
كُلُّ نَفۡسٖ ذَآئِقَةُ ٱلۡمَوۡتِۗ وَإِنَّمَا تُوَفَّوۡنَ أُجُورَكُمۡ يَوۡمَ ٱلۡقِيَٰمَةِۖ فَمَن زُحۡزِحَ عَنِ ٱلنَّارِ وَأُدۡخِلَ ٱلۡجَنَّةَ فَقَدۡ فَازَۗ وَمَا ٱلۡحَيَوٰةُ ٱلدُّنۡيَآ إِلَّا مَتَٰعُ ٱلۡغُرُورِ 185
Gbogbo ẹmin kọọkan biotiwulẹ ki o ri, ko si tabi sugbọn pe yoo tọ iku wo, ni ẹda ko fi gbọdọ gba itanjẹ pẹlu ile aye yii, ati wipe ni Ọjọ Igbende wọn yoo maa fun yin ni awọn ẹsan isẹ yin ni perepere laini ni adinku, ẹ ko waa ri ẹniti Ọlọhun Ọba Allah ba gbe jinna si ina, ati wipe ti O wa mu wọ Ọgba Idẹra, paapaa ọwọ rẹ ti tẹ ohun ti o nrokan ninu oore, ati wipe o si ti yege nibi ohun ti o npaya ninu aburu, ati wipe isẹmi ile aye yii ko jẹ nkankan ayaafi igbadun ti yoo yẹ, ati wipe ko nii rọ mọ ayaafi ẹni yẹpẹrẹ.
۞لَتُبۡلَوُنَّ فِيٓ أَمۡوَٰلِكُمۡ وَأَنفُسِكُمۡ وَلَتَسۡمَعُنَّ مِنَ ٱلَّذِينَ أُوتُواْ ٱلۡكِتَٰبَ مِن قَبۡلِكُمۡ وَمِنَ ٱلَّذِينَ أَشۡرَكُوٓاْ أَذٗى كَثِيرٗاۚ وَإِن تَصۡبِرُواْ وَتَتَّقُواْ فَإِنَّ ذَٰلِكَ مِنۡ عَزۡمِ ٱلۡأُمُورِ 186
Wọn yoo dan yin wo - ẹyin olugbagbọ ododo - nibi awọn dukia yin pẹlu yiyọ awọn ẹta kan ti o jẹ dandan nibẹ, ati pẹlu ohun ti yoo maa sọkalẹ pẹlu rẹ ninu awọn adanwo, ati wipe wọn yoo dan yin nibi awọn ẹmin yin pẹlu ididesi awọn alabọrun Ṣẹria, ati ohun ti yoo maa sọkalẹ pẹlu yin ninu awọn oniranran awọn adanwo, ati wipe ẹ o maa gbọ lati ọdọ awọn ti wọn fun ni tira siwaju yin, ati lati ọdọ awọn ti wọn se ẹbọ, nkan ti o pọ ninu ohun ti yoo maa ko suta ba yin, ninu fifi ẹnu ẹgan kan yin ati ẹsin yin, ati wipe ti ẹ ba se suuru lori ohun ti o ba kan yin ninu awọn oniranran adanwo ati awọn idanniwo, ti ẹ si tun paya Ọlọhun Ọba Allah pẹlu sise ohun ti O pasẹ, ati gbigbe ohun ti O kọ ju silẹ, ati wipe dajudaju nkan naa nbẹ ninu awọn alamọri eyiti o bukaata nini ipinnu, ati wipe awọn oluse alapantete yoo maa se alapantete sibẹ.
Ninu aburu isẹ awọn yahuudi ati aida awọn iwa wọn ni kikọja aala wọn lori awọn Anọbi Ọlọhun Ọba Allah pẹlu pipe ni irọ ati pipa.
Gbogbo erenjẹ ni ile aye, ohun ti yoo maa din ku ni, ati wipe dajudaju erenjẹ ti o pe nbẹ ni Ọjọ Ikẹyin pẹlu yiyege kuro nibi ina ati wiwọ Ọgba Idẹra.
Ninu awọn oniranran idaniwo ni suta eyiti yoo maa kan awọn olugbagbọ ododo nibi ẹsin wọn ati awọn ẹmin wọn lati ọdọ awọn ti wọn ni tita ati awọn ọsẹbọ, ati wipe ohun ti o wa jẹ dandan nigba naa ni nini suuru ati ipaya Ọlọhun Ọba Allah (ti ọla Rẹ ga) .