مَّن كَانَ يُرِيدُ ٱلۡعَاجِلَةَ عَجَّلۡنَا لَهُۥ فِيهَا مَا نَشَآءُ لِمَن نُّرِيدُ ثُمَّ جَعَلۡنَا لَهُۥ جَهَنَّمَ يَصۡلَىٰهَا مَذۡمُومٗا مَّدۡحُورٗا 18
Ẹniti o ba ngbero isẹmin aye nibi awọn isẹẹre, ti ko si nigbagbọ ninu ọjọ ikẹyin, bẹẹni ti ko ka a kun, a o kanju fun ni ounti A fẹ ninu rẹ, kii se ounti o ba fẹ ninu idẹkun, fun ẹniti A ba fẹ se bẹẹ fun, a o si se Jahannamọ ni ibuwọ rẹ ni ọjọ igbende ti yoo maa fi ara kin ooru ibẹ niti eebu lori sisa aye lẹsa ati sise keferi rẹ si ọrun ni ẹniti a o le jina kuro nibi ikẹ Allah.
وَمَنۡ أَرَادَ ٱلۡأٓخِرَةَ وَسَعَىٰ لَهَا سَعۡيَهَا وَهُوَ مُؤۡمِنٞ فَأُوْلَٰٓئِكَ كَانَ سَعۡيُهُم مَّشۡكُورٗا 19
Ẹniti o ba gbero ẹsan ọrun pẹlu awọn isẹ rere, ti o si ngbiyanju fun un niti igbiyanju ti o bọpa bọsẹ kuro nibi seka rimi ati seka gbọmi, ti o si nigbagbọ ninu ohun ti Allah se gbigbaa gbọ ni dandan, awọn wọnyi ni a royin pẹlu awọn iroyin naa, ipọsẹsẹ wọn yoo jẹ atẹwọgba ni ọdọ Allah, yoo si san wọn lẹsan le lori.
كُلّٗا نُّمِدُّ هَٰٓؤُلَآءِ وَهَٰٓؤُلَآءِ مِنۡ عَطَآءِ رَبِّكَۚ وَمَا كَانَ عَطَآءُ رَبِّكَ مَحۡظُورًا 20
A o se alekun fun ikini keji ninu awọn ipin mejeeji yii, ẹlẹsẹ ati ẹniire ninu ọrẹnta Ọlọhun Ọba Rẹ - irẹ ojisẹ - laini ja, ọrẹnta Ọlọhun Ọba rẹ ni ile aye kii se ohun ti a se leewọ fun ẹnikẹni o jẹ ẹniire ni tabi ẹlẹsẹ.
ٱنظُرۡ كَيۡفَ فَضَّلۡنَا بَعۡضَهُمۡ عَلَىٰ بَعۡضٖۚ وَلَلۡأٓخِرَةُ أَكۡبَرُ دَرَجَٰتٖ وَأَكۡبَرُ تَفۡضِيلٗا 21
Woye si - irẹ ojisẹ - bi a se gbọla fun apakan lori apakan ni ile aye nibi arisiki ati awọn ipo, bẹẹni ọrun si tobi nibi ijura ẹni lọ ni agbega idẹkun ju isẹmin aye lọ, o si tun tobi ni ohun ti a le fi sọla eleyi ki olugbagbọ ododo se oju kokoro si.
لَّا تَجۡعَلۡ مَعَ ٱللَّهِ إِلَٰهًا ءَاخَرَ فَتَقۡعُدَ مَذۡمُومٗا مَّخۡذُولٗا 22
Mase fi ijosin fun nkan miran mọ Ọlọhun Ọba Allah - irẹ ẹru - ki o ma baa di ẹni eebu ni ọdọ Allah ati ni ọdọ awọn ẹru Rẹ ti wọn jẹ ẹniire, ti ko waa nii si oludupẹ fun ọ, ni ẹniti yoo di idagunla si ni ọdọ Ọlọhun, ti ko si nii si alaranse fun ọ.
۞وَقَضَىٰ رَبُّكَ أَلَّا تَعۡبُدُوٓاْ إِلَّآ إِيَّاهُ وَبِٱلۡوَٰلِدَيۡنِ إِحۡسَٰنًاۚ إِمَّا يَبۡلُغَنَّ عِندَكَ ٱلۡكِبَرَ أَحَدُهُمَآ أَوۡ كِلَاهُمَا فَلَا تَقُل لَّهُمَآ أُفّٖ وَلَا تَنۡهَرۡهُمَا وَقُل لَّهُمَا قَوۡلٗا كَرِيمٗا 23
Ọlọhun Ọba rẹ pasẹ - irẹ ẹrusin - O si se ni dandan wipe o ko gbọdọ sin oun ti o yatọ si I, O si pasẹ ki o se daadaa si awọn obi mejeeji pataki julọ nigbati wọn ba de ipo agba, ti ọkan ninu wọn ba de ipo agba tabi awọn mejeeji ni wọn de ipo agba ni ọdọ rẹ, mase gbarata nitori awọn mejeeji pẹlu sisọ ohun ti yoo tọkasi si lọrọ, ma si se jagbe mọ wọn ki o si ma le ohun mọ wọn, ki o maa sọ gbolohun alapọnle fun wọn eyiti ẹrọ ati aanu wa nibẹ.
وَٱخۡفِضۡ لَهُمَا جَنَاحَ ٱلذُّلِّ مِنَ ٱلرَّحۡمَةِ وَقُل رَّبِّ ٱرۡحَمۡهُمَا كَمَا رَبَّيَانِي صَغِيرٗا 24
Tẹriba fun awọn mejeeji niti iyẹpẹrẹ ati sise ikẹ fun wọn, ki o si sọpe: irẹ Ọlọhun mi, kẹ awọn mejeeji ni ikẹ nitori itọju wọn fun mi ni igba ewe.
رَّبُّكُمۡ أَعۡلَمُ بِمَا فِي نُفُوسِكُمۡۚ إِن تَكُونُواْ صَٰلِحِينَ فَإِنَّهُۥ كَانَ لِلۡأَوَّٰبِينَ غَفُورٗا 25
Ọlọhun - ẹyin eniyan - nimọ nipa ohun ti o nbẹ ni igbaaya yin ninu isafọmọ fun Un nibi ijọsin ati awọn isẹẹre ati sise rere si awọn obi mejeeji, dajudaju ti erongba yin ba jẹ rere nibi ijọsin yin ati ibasepọ yin si awọn obi yin ati si awọn ti o yatọ si wọn, dajudaju Oun ti mimọ nbẹ fun yoo jẹ oluforijin fun awọn olusẹri ọdọ Rẹ pẹlu ironu piwada, ẹniti o ba sẹri nibi aseeto rẹ ti o siwaju nibi itẹle Ọlọhun Ọba rẹ tabi awọn obi rẹ, Ọlọhun Ọba Allah yoo fi ori jin in.
وَءَاتِ ذَا ٱلۡقُرۡبَىٰ حَقَّهُۥ وَٱلۡمِسۡكِينَ وَٱبۡنَ ٱلسَّبِيلِ وَلَا تُبَذِّرۡ تَبۡذِيرًا 26
Ki o si fun - irẹ olugbagbọ ododo - alasunmọ ni ẹtọ rẹ nibi okun ibi ki o si tun fun alaini ti o ni bukaata, bakannaa ki o fun ẹniti irin ajo rẹ ti ni ijakulẹ, o ko si gbọdọ na dukia rẹ sibi ẹsẹ tabi ojupọnna ina apa.
إِنَّ ٱلۡمُبَذِّرِينَ كَانُوٓاْ إِخۡوَٰنَ ٱلشَّيَٰطِينِۖ وَكَانَ ٱلشَّيۡطَٰنُ لِرَبِّهِۦ كَفُورٗا 27
Dajudaju awọn ti wọn nna dukia wọn sibi awọn ẹsẹ tabi awọn ti wọn nna ina apa jẹ ọmọ iya awọn esu, wọn tẹle wọn nibi ohun ti o ba pa wọn lasẹ rẹ gẹgẹ bi inakuna ati ina apa, bẹẹ ni esu jẹ alaimoore si Ọlọhun rẹ, ko nii se ohunkihun ayafi ohun ti ẹsẹ wa nibẹ, ko si ni pasẹ ayafi ohun ti yoo bi Ọlọhun Ọba rẹ ninu.
O di dandan fun ọmọ ẹda eniyan ki o se ohun ti o ba lagbara ninu rere, ki o si di adisọkan ohun ti ko ba lagbara rẹ; ki o le gbẹsan le lori.
Dajudaju idẹkun ni ile aye ko tọ ki a fi maa se itọka iyọnu Ọlọhun Ọba ti ọla Rẹ ga; nitoripe dajudaju aye le tẹni ti kiise olugbagbọ lọwọ, ki igbẹyin rẹ si jasi iya Allah.
Sise daadaa si awọn obi mejeeji jẹ ọranyan dandan gbọn, Ọlọhun Allah si ti fi didupẹ fun awọn mejeeji kun didupẹ fun Oun nitori titobi ọla awọn mejeeji.
Islam se inakuna ni eewọ, ohun ti o njẹ inakuna ni nina owo si ọna ti ko lẹtọ.