وَلَقَدۡ ذَرَأۡنَا لِجَهَنَّمَ كَثِيرٗا مِّنَ ٱلۡجِنِّ وَٱلۡإِنسِۖ لَهُمۡ قُلُوبٞ لَّا يَفۡقَهُونَ بِهَا وَلَهُمۡ أَعۡيُنٞ لَّا يُبۡصِرُونَ بِهَا وَلَهُمۡ ءَاذَانٞ لَّا يَسۡمَعُونَ بِهَآۚ أُوْلَٰٓئِكَ كَٱلۡأَنۡعَٰمِ بَلۡ هُمۡ أَضَلُّۚ أُوْلَٰٓئِكَ هُمُ ٱلۡغَٰفِلُونَ 179
A ti da awọn olujannu ti o pọ fun ina jahanamọ ati ọpọ ninu awọn eniyan; nitori wipe imọ wa wa lori wipe wọn yoo sisẹ ẹni ibẹ, wọn ni ọkan ti wọn kii fi mọ ohun ti o le se wọn ni anfaani, tabi yoo ko inira ba wọn, wọn si ni oju ti wọn ko fi wo awọn amin ti Ọlọhun Ọba lori ara wọn ati gbogbo agbegbe, ki wọn o waa ronu pẹlu rẹ, wọn ni awọn eti ti wọn kii fi gbọ awọn amin Ọlọhun, ki wọn le gbe ohun ti o yẹ ninu rẹ yẹwo, awọn wọnyi ni a fi iroyin ijẹranko royin nitoria aisi laakaye, bikose wipe ọna anu wọn ni o jinna ju awọn ẹranko lọ, awọn ni olufọnu kuro nibi igbagbọ si Ọlọhun Ọba Allah ati si ọjọ ikẹyin.
وَلِلَّهِ ٱلۡأَسۡمَآءُ ٱلۡحُسۡنَىٰ فَٱدۡعُوهُ بِهَاۖ وَذَرُواْ ٱلَّذِينَ يُلۡحِدُونَ فِيٓ أَسۡمَٰٓئِهِۦۚ سَيُجۡزَوۡنَ مَا كَانُواْ يَعۡمَلُونَ 180
Ọlọhun Ọba - ti mimọ nbẹ fun - ni O ni awọn orukọ ti o dara, ti o si ntọka si gbigbọngbọn ati titobi rẹ, ki ẹ se itẹgun si ọdọ Allah nibi wiwa nkan ti ẹ nfẹ, ki ẹ si maa yin le lori, ki ẹ gbe ara kuro ni ọdọ awọn ti o fi kuro nibi ododo nibi awọn orukọ yii pẹlu mima gbe fun ẹniti kii se Ọlọhun Ọba Allah, tabi ki wọn o ti lẹ ma fun Un, tabi ki wọn pa itumọ rẹ lofo, tabi ki o fi ẹlomiran jọ Ọ, a o se ẹsan fun awọn ti wọn kuro nibi ododo: ni ijiya ẹlẹta elero lori nkan ti wọn se.
وَمِمَّنۡ خَلَقۡنَآ أُمَّةٞ يَهۡدُونَ بِٱلۡحَقِّ وَبِهِۦ يَعۡدِلُونَ 181
Ninu awọn ti a da ni awọn ijọ kan ti wọn nfi ẹmin ara wọn mọ ọna ododo, ti wọn si npe ẹlomiran sibẹ lati mọ ọna, wọn si nse idajọ pẹlu rẹ laise abosi.
وَٱلَّذِينَ كَذَّبُواْ بَِٔايَٰتِنَا سَنَسۡتَدۡرِجُهُم مِّنۡ حَيۡثُ لَا يَعۡلَمُونَ 182
Awọn ti wọn pe amin wa nirọ, ti wọn ko nigbagbọ siI, ti wọn njaa niyan, a yoo si ilẹkun arisiki fun wọn, ti kii se apọnle fun wọn, sugbọn o jẹ idẹnilẹkẹ ki wọn le tẹ siwaju nibi ọna anu ti wọn wa, lẹyin eleyi ni iya wa yoo wa jẹ wọn nigbati wọn ko fura.
وَأُمۡلِي لَهُمۡۚ إِنَّ كَيۡدِي مَتِينٌ 183
Maa lọ iya mi lara fun wọn titi ti wọn yoo fi maa lero wipe awọn ko nii jiya, ti wọn yoo si maa tẹ siwaju nibi irọ ati sise keferi wọn, titi a o fi se iya wọn ni adipele, dajudaju ete mi lagbara, maa se afihan daradara sugbọn maa gbero iyẹpẹrẹ fun wọn.
أَوَلَمۡ يَتَفَكَّرُواْۗ مَا بِصَاحِبِهِم مِّن جِنَّةٍۚ إِنۡ هُوَ إِلَّا نَذِيرٞ مُّبِينٌ 184
Se awọn ti wọn npe awọn amin Ọlọhun Ọba ati ojisẹ Rẹ nirọ ko wa ronu ni, ki wọn o si lo laakaye wọn wipe Muhammad kii se were, o jẹ ojisẹ lati ọdọ Ọlọhun Ọba Allah, Ọlọhun Ọba gbe dide ki o le jẹ ikilọ kuro nibi iya Ọlọhun Ọba ni ikilọ ti o fi oju han.
أَوَلَمۡ يَنظُرُواْ فِي مَلَكُوتِ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِ وَمَا خَلَقَ ٱللَّهُ مِن شَيۡءٖ وَأَنۡ عَسَىٰٓ أَن يَكُونَ قَدِ ٱقۡتَرَبَ أَجَلُهُمۡۖ فَبِأَيِّ حَدِيثِۢ بَعۡدَهُۥ يُؤۡمِنُونَ 185
Se awọn wọnyi ko wa woye ni, ni iwoye si ọla Ọlọhun Ọba Allah ti o wa ni sanmọ ati ilẹ, ki o si wo nkan ti Ọlọhun Ọba da si aarin mejeeji, bi ẹranko, irugbin ati nkan miran, ki wọn o si tun wo asiko iku wọn eyiti o seese ki titan rẹ sun mọ, ki wọn o si ronu piwada ki asiko rẹ too bọ, ti wọn ko ba wa nigbagbọ si Alukuraani ati nkan ti o wa ninu rẹ, gẹgẹ bi adehun rere ati adehun iya, ewo ninu iwe ti o yatọ si i ni wọn wa fẹ gbagbọ?!
مَن يُضۡلِلِ ٱللَّهُ فَلَا هَادِيَ لَهُۥۚ وَيَذَرُهُمۡ فِي طُغۡيَٰنِهِمۡ يَعۡمَهُونَ 186
Ẹniti Ọlọhun Ọba ba dagunla si kuro nibi imọna sibi ododo, ti Ọlọhun Ọba Allah si sọnu kuro nibi ọna ti o duro tọ, ko si olufini mọna ti yoo tọ sọna, Ọlọhun Ọba Allah yoo si fi wọn silẹ ni oju ọna anu wọn ati keferi wọn, wọn yoo maa daamu, wọn ko nii mọ ọna kankan.
يَسَۡٔلُونَكَ عَنِ ٱلسَّاعَةِ أَيَّانَ مُرۡسَىٰهَاۖ قُلۡ إِنَّمَا عِلۡمُهَا عِندَ رَبِّيۖ لَا يُجَلِّيهَا لِوَقۡتِهَآ إِلَّا هُوَۚ ثَقُلَتۡ فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِۚ لَا تَأۡتِيكُمۡ إِلَّا بَغۡتَةٗۗ يَسَۡٔلُونَكَ كَأَنَّكَ حَفِيٌّ عَنۡهَاۖ قُلۡ إِنَّمَا عِلۡمُهَا عِندَ ٱللَّهِ وَلَٰكِنَّ أَكۡثَرَ ٱلنَّاسِ لَا يَعۡلَمُونَ 187
Awọn opurọ ti wọn ko gba ọjọ igbende gbọ yoo bi ọ leere: asiko wo ni yoo sẹlẹ ki imọ wa le daju nipa rẹ? Sọ wipe -irẹ Muhammad-: imọ rẹ ko si ni ọdọ mi, ko si si ni ọdọ ẹlomiran sugbọn imọ rẹ wa ni ọdọ Ọlọhun Ọba Allah nikan soso, ko nii se afihan asiko rẹ ti O pebubu fun un ayaafi Allah, ihan rẹ pamọ fun gbogbo ẹniti o wa ni sanmọ ati ilẹ, ko nii waa ba yin ayaafi ni ojiji, wọn yoo bi ọ leere nipa ọjọ ikẹyin, bi ẹni wipe o nse oju kokoro ni nini imọ nipa rẹ, wọn ko mọ wipe o ko beere nipa rẹ nitori pipe imọ rẹ si Ọlọhun Ọba, sọ fun wọn - irẹ Muhammad -: dajudaju imọ ọjọ ikẹyin wa ni ọdọ Ọlọhun Ọba Allah nikan soso, sugbọn ọpọ awọn eniyan ko mọ eleyi.
Ọlọhun Ọba da fun ọmọ ẹda eniyan awọn irinsẹ ti eniyan fi le mọ nkan - ohun ni awọn ọkan, awọn oju ati awọn eti - lati le mọ awọn nkan ti o le se ni ni anfaani ati lati kọdi awọn inira.
Pipe Ọlọhun Ọba pẹlu awọn orukọ Rẹ ti o dara nibi gbigba adua, a o maa pe nigbogbo ti a ba ni bukaata pẹlu eyiti o ba se deedee ohun ti a nfẹ ninu awọn orukọ Rẹ lapejuwe: iwọ Ọlọhun Ọba, fi orijin mi, tori wipe iwọ ni olufori jinni.
Rironu nipa titobi sanmọ ati ilẹ ati dide ipo ironu yii ma nmuni mọ wipe Ọlọhun Ọba nikan ẹniti o tọ ni ẹniti a njọsin fun yatọ si ẹlomiran; nitori wipe O jẹ Ọba aaso nibi isẹ Rẹ.