۞وَإِذۡ نَتَقۡنَا ٱلۡجَبَلَ فَوۡقَهُمۡ كَأَنَّهُۥ ظُلَّةٞ وَظَنُّوٓاْ أَنَّهُۥ وَاقِعُۢ بِهِمۡ خُذُواْ مَآ ءَاتَيۡنَٰكُم بِقُوَّةٖ وَٱذۡكُرُواْ مَا فِيهِ لَعَلَّكُمۡ تَتَّقُونَ 171
Ki o ranti - irẹ Muhammad - nigbati a mu oke tidi-tidi, a si gbe si oke awọn ọmọ isirẹla nigbati wọn kọ lati gba nkan ti nbẹ ninu taoreeta, oke waa da bi ẹsujo ti o sẹji bo wọn lori, ti wọn si mọ amọdaju wipe o le jabọ le awọn lori, wọn sọ fun wọn wipe: ẹ gba ohun ti a fun yin mu pẹlu igbiyanju ati ipinnu ẹmin, ẹ ranti awọn idajọ ati awọn ofin ti Ọlọhun Ọba se fun yin nibẹ, ẹ ko gbọdọ gbagbe rẹ; ki ẹ le ba paya Ọlọhun Ọba nigbati ẹ ba nse eleyi.
وَإِذۡ أَخَذَ رَبُّكَ مِنۢ بَنِيٓ ءَادَمَ مِن ظُهُورِهِمۡ ذُرِّيَّتَهُمۡ وَأَشۡهَدَهُمۡ عَلَىٰٓ أَنفُسِهِمۡ أَلَسۡتُ بِرَبِّكُمۡۖ قَالُواْ بَلَىٰ شَهِدۡنَآۚ أَن تَقُولُواْ يَوۡمَ ٱلۡقِيَٰمَةِ إِنَّا كُنَّا عَنۡ هَٰذَا غَٰفِلِينَ 172
Ki o ranti - irẹ Muhammad - nigbati Ọlọhun Ọba mu arọmọdọmọ anọbi Adam kuro ni ibara idi rẹ, O si fi wọn rinlẹ pẹlu itọju Rẹ ti O nse fun wọn ni ipilẹ adayeba, O si tun fi han wọn wipe Oun ni ẹlẹda wọn, Olutọju wọn, ti O nsọ fun wọn bayi wipe: kii wa se Emi ni olutọju yin ni? Wọn yi lapapọ bayi wipe: bẹẹ ni, Iwọ ni Ọlahun Ọba wa, O sọ wipe: a dan yin wo, a si gba adehun ki ẹ ma ba tako ọjọ igbende lori awijare Ọlọhun si yin, ki ẹ maa ba sọ wipe: ẹyin ko nimọ nipa rẹ.
أَوۡ تَقُولُوٓاْ إِنَّمَآ أَشۡرَكَ ءَابَآؤُنَا مِن قَبۡلُ وَكُنَّا ذُرِّيَّةٗ مِّنۢ بَعۡدِهِمۡۖ أَفَتُهۡلِكُنَا بِمَا فَعَلَ ٱلۡمُبۡطِلُونَ 173
Tabi ki ẹ maa ba wi awijare pe awọn baba yin ni wọn ja adehun, ti wọn si se ẹbọ pẹlu Ọlọhun Ọba Allah, wipe ẹyin kan nkọse awọn baba yin nibi ohun ti ẹ ri wọn, ti wọn nse ni ẹbọ ni, ki ẹ maa ba waa sọ wipe: se ẹ o gbawa mu ni - Irẹ Ọlọhun Ọba wa - lori nkan ti awọn baba wa bajẹ ninu isẹ wọn pẹlu wipe wọn sẹbọ si Ọ, ni iwọ yoo wa fi fi iya jẹ wa bi? Ko si ẹsẹ fun wa; nitori aimọkan ati ikọse awọn baba wa.
وَكَذَٰلِكَ نُفَصِّلُ ٱلۡأٓيَٰتِ وَلَعَلَّهُمۡ يَرۡجِعُونَ 174
Gẹgẹ bi a se salaye ibusẹri awọn ijọ okurọ, gẹgẹ bẹẹ naa ni a se nsalaye fun awọn neiyan wọnyi; ki wọn le ba kuro nibi ẹbọ ti wọn nse lọ si ibi mimọ Ọlọhun Ọba allah lọkan ati sise E ni aaso; gẹgẹ bi o se wa ni adehun eyiti wọn ja kuro ni ọdọ Ọlọhun lori ara wọn.
وَٱتۡلُ عَلَيۡهِمۡ نَبَأَ ٱلَّذِيٓ ءَاتَيۡنَٰهُ ءَايَٰتِنَا فَٱنسَلَخَ مِنۡهَا فَأَتۡبَعَهُ ٱلشَّيۡطَٰنُ فَكَانَ مِنَ ٱلۡغَاوِينَ 175
Ki o si ka - ire ojise - iro nipa ọkunrin kan ti a fun ni amin wa, ti o si mọ ọ, ti o si gbọ ododo ti ntọka si ye fun awọn ọmọ isirẹli, sugbọn ko se bẹẹ, o gbe ju silẹ, o si bọpa kuro nibẹ, osu waa pẹlu rẹ, o si di alabarin esu, o waa di ẹni anu, ẹni iparun, lẹyin igbati o ti wa ninu ẹni imọna, ẹni ọla.
وَلَوۡ شِئۡنَا لَرَفَعۡنَٰهُ بِهَا وَلَٰكِنَّهُۥٓ أَخۡلَدَ إِلَى ٱلۡأَرۡضِ وَٱتَّبَعَ هَوَىٰهُۚ فَمَثَلُهُۥ كَمَثَلِ ٱلۡكَلۡبِ إِن تَحۡمِلۡ عَلَيۡهِ يَلۡهَثۡ أَوۡ تَتۡرُكۡهُ يَلۡهَثۚ ذَّٰلِكَ مَثَلُ ٱلۡقَوۡمِ ٱلَّذِينَ كَذَّبُواْ بَِٔايَٰتِنَاۚ فَٱقۡصُصِ ٱلۡقَصَصَ لَعَلَّهُمۡ يَتَفَكَّرُونَ 176
Ti a ba fẹ ki o se anfaani pẹlu awọn amin yii, a ko ba gbee ga pẹlu ki a fi se kongẹ pẹlu sise isẹ pẹlu rẹ, ki ba si di ẹni igbega ni aye ati ni ọrun sugbọn o sa nkan ti o le mu lọ si ibi iyẹpẹrẹ ni ẹsa nitori wipe o fi si ibi awọn adun aye ni ẹniti o gbe ọla fun adun aye ju ọrun lọ, o si tẹle nkan ti ẹmin rẹ npee si ninu ibajẹ, apejuwe rẹ nibi oju kokoro rẹ ti o le si aye da gẹgẹ bi apejuwe aja ti kii yẹ tii gbo ẹniti yoo maa wa gbẹngbẹ ni gbogbo asiko, ti o ba ka jọ, yoo ma gbẹngbẹ, ti wọn ba le, yoo maa gbẹngbẹ, apejuwe ti a sọ yii jẹ apejuwe awọn ẹni anu nitori wipe wọn npe awọn amin wa nirọ, sọ itan naa fun wọn - ire ojise -; ki wọn le ronu, ki wọn si gbaikilọ kuro nibi irọ ti wọn npa ati ọna anu.
سَآءَ مَثَلًا ٱلۡقَوۡمُ ٱلَّذِينَ كَذَّبُواْ بَِٔايَٰتِنَا وَأَنفُسَهُمۡ كَانُواْ يَظۡلِمُونَ 177
Ko si ohun ti o buru to awọn ijọ ti wọn parọ, ti wọn si npe awọn amin wa nirọ ati awọn awijare wa nirọ, ti wọn ko si gbaa lododo, wọn ti se abosi si ẹmin ara wọn nitori wipe wọn mu lọ si ibi iparun.
مَن يَهۡدِ ٱللَّهُ فَهُوَ ٱلۡمُهۡتَدِيۖ وَمَن يُضۡلِلۡ فَأُوْلَٰٓئِكَ هُمُ ٱلۡخَٰسِرُونَ 178
Ẹniti Ọlọhun Ọba Allah ba fi se kongẹ imọna si oju ọna ti o tọ ni olumọna ododo; ẹniti Ọlọhun Ọba ba si gbe jina kuro ni oju ọna ti o duro tọ, awọn ni oludinku niti ipin niti ododo, awọn ti wọn padanu ẹmin ara wọn ati ara ile wọn ni ọjọ igbende, tẹti ẹ gbọ, eleyi ni ofo ti o fi oju han.
Ohun ti a gbero nibi sisọ awọn iwe kalẹ lati oke sanmọ ni ki a sisẹ pẹlu nkan ti o wa ninu rẹ, kii se kika pẹlu ahọn nikan tabi kika tẹlen tẹle, dajudaju eleyi jẹ ohun ti a ti fi sẹyin.
Dajudaju Ọlọhun Ọba da mọ ọmọ ẹda eniyan ni asiko ti O nsẹda rẹ, nini imọ nipa awọn ẹri jijẹ ọkan soso, ti ipilẹ rẹ ba jẹ ohun ti o mọ kanga, ti nkan ti o le baa jẹ ko si bẹ pẹlu rẹ, yoo mọ awọn ẹri yii, yoo si se awọn isẹ. inu rẹ.
Ninu awọn amin naa ohun ni ariwoye fun awọn ti wọn fi awọn amin inu alukuraani sisẹ, ki wọn le mọ ọla Ọlọhun Ọba ti nbẹ ni ori wọn pẹlu sisisẹ pẹlu rẹ; ki ẹmin wọn le ba mọ kanga.
Ninu awọn amin ni ninu awọn olugbagbọ ododo ni didojukọ Ọlọhun Ọba nikan pẹlu ki wọn o maa wa imọna ni ọdọ Rẹ, ati idaabobo kuro nibi gbogbo ikọsẹ anu.