يَٰٓأَهۡلَ ٱلۡكِتَٰبِ لَا تَغۡلُواْ فِي دِينِكُمۡ وَلَا تَقُولُواْ عَلَى ٱللَّهِ إِلَّا ٱلۡحَقَّۚ إِنَّمَا ٱلۡمَسِيحُ عِيسَى ٱبۡنُ مَرۡيَمَ رَسُولُ ٱللَّهِ وَكَلِمَتُهُۥٓ أَلۡقَىٰهَآ إِلَىٰ مَرۡيَمَ وَرُوحٞ مِّنۡهُۖ فََٔامِنُواْ بِٱللَّهِ وَرُسُلِهِۦۖ وَلَا تَقُولُواْ ثَلَٰثَةٌۚ ٱنتَهُواْ خَيۡرٗا لَّكُمۡۚ إِنَّمَا ٱللَّهُ إِلَٰهٞ وَٰحِدٞۖ سُبۡحَٰنَهُۥٓ أَن يَكُونَ لَهُۥ وَلَدٞۘ لَّهُۥ مَا فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَمَا فِي ٱلۡأَرۡضِۗ وَكَفَىٰ بِٱللَّهِ وَكِيلٗا 171
sọ - irẹ ojisẹ - fun awọn nasaara awọn ti a fun ni injiila: ẹ mase kọja ẹnu aala nibi ẹsin yin, ki ẹ si mase sọ nipa Ọlọhun Ọba Allah nibi ọrọ Anọbi Isa ayaafi ododo, dajudaju mimọ ọmọ Maryam jẹ ojisẹ Ọlọhun Ọba Allah, O si ran nisẹ pẹlu ododo, O daa pẹlu gbolohun Rẹ eyiti o fi ran malaika jibril si maryam ki alaafia Ọlọhun Ọba Allah maa bẹ fun un, ohun naa ni gbolohun Rẹ: ri bẹẹ, o si ri bẹẹ, oun naa ni imisi lati ọdọ Ọlọhun Ọba Allah eyiti malaika jibril mi lati ara asẹ Ọlọhun Ọba Allah, ki ẹ ya ni igbagbọ ninu Ọlọhun Ọba Allah ati awọn ojisẹ Rẹ lapapọ, laini se opinya laarin wọn, ẹ ko gbọdọ sọ wipe: awọn ọlọhun jẹ mẹta, ẹ jawọ kuro nibi awọn ọrọ yii, ti o jẹ ti ibajẹ, ki ẹ jawọ nibẹ loore fun yin ni aye ati ọrun, dajudaju Ọlọhun Ọba Allah jẹ Ọlọhun Ọba ọkan soso, O mọ kanga kuro nibi orogun ati ọmọ, Ọba Ọlọrọ ni, Oun ni O ni ikapa sanmọ ati ikapa ilẹ ati ikapa ohun ti nbẹ laarin mejeeji, O to ki ohun ti nbẹ ni sanmọ ati ilẹ jẹ nkan ti Ọlọhun Ọba Allah jẹ oludari fun.
لَّن يَسۡتَنكِفَ ٱلۡمَسِيحُ أَن يَكُونَ عَبۡدٗا لِّلَّهِ وَلَا ٱلۡمَلَٰٓئِكَةُ ٱلۡمُقَرَّبُونَۚ وَمَن يَسۡتَنكِفۡ عَنۡ عِبَادَتِهِۦ وَيَسۡتَكۡبِرۡ فَسَيَحۡشُرُهُمۡ إِلَيۡهِ جَمِيعٗا 172
Ko nii ba oju mu ki Anọbi Isa ọmọ maryam ki o tako ki ohun jẹ ẹru fun Ọlọhun Ọba Allah, bẹẹ ni awọn malaika ti Ọlọhun Ọba Allah sun mọ ara Rẹ, ti O si se agbega ipo wọn naa ko nii tako jijẹ ẹru fun Ọlọhun Ọba Allah, bawo ni awọn ọsẹbọ se wa mu awọn malaika ni Ọlọhun Ọba Allah? ! ẹniti o ba tako jijẹ ẹru fun Ọlọhun Ọba Allah, ti o se igberaga sii, dajudaju Ọlọhun Ọba Allah yoo ko wọn jọ ni ọdọ Rẹ ni ọjọ igbende, yoo si san gbogbo wọn ni ẹsan ti o tọ.
Nigbati o han wipe gbogbo wọn ni Ọlọhun Ọba Allah yoo ko jọ si ọdọ Rẹ, O wa salaye ẹsan wọn ninu gbolohun Rẹ:
فَأَمَّا ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَعَمِلُواْ ٱلصَّٰلِحَٰتِ فَيُوَفِّيهِمۡ أُجُورَهُمۡ وَيَزِيدُهُم مِّن فَضۡلِهِۦۖ وَأَمَّا ٱلَّذِينَ ٱسۡتَنكَفُواْ وَٱسۡتَكۡبَرُواْ فَيُعَذِّبُهُمۡ عَذَابًا أَلِيمٗا وَلَا يَجِدُونَ لَهُم مِّن دُونِ ٱللَّهِ وَلِيّٗا وَلَا نَصِيرٗا 173
Sugbọn awọn ti wọn nigbagbọ ninu Ọlọhun Ọba Allah, ti wọn gba awọn ojisẹ Rẹ lododo, ti wọn nse awọn isẹẹre ni ẹniti nse afọmọ fun Ọlọhun Ọba Allah, o si nsisẹ ni ibamun si ofin, yoo fun wọn ni ẹsan isẹẹ wọn laini ẹdinku, bẹẹ ni yoo si se alekun fun ninu ọla Rẹ ati daada Rẹ, sugbọn awọn ti wọn ba se igberaga kuro nibi ijọsin Ọlọhun Ọba Allah ati titẹle asẹ Rẹ, ti wọn se igberaga, yoo fun wọn ijiya ininira, wọn ko nii ri oluranlọwọ miran yatọ si Ọlọhun Ọba Allah, eyiti yoo mu anfaani wa ba wọn, bẹẹ ni wọn ko nii ri alaranse ti yoo mu inira kuro fun wọn.
يَٰٓأَيُّهَا ٱلنَّاسُ قَدۡ جَآءَكُم بُرۡهَٰنٞ مِّن رَّبِّكُمۡ وَأَنزَلۡنَآ إِلَيۡكُمۡ نُورٗا مُّبِينٗا 174
A pe ẹyin eniyan, paapaa julọ awijare ti o gbọngbọn ti wa ba yin lati ọdọ Ọlọhun Ọba yin, eyiti ti ko fi aaye gba awijare, ti o si mu iruju kuro - oun naa ni Muhammad (ti ikẹ ati ọla nbẹ fun) -, a sọ kalẹ fun yin, imọlẹ ti o fi oju han, ohun ni Alukuraani.
فَأَمَّا ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ بِٱللَّهِ وَٱعۡتَصَمُواْ بِهِۦ فَسَيُدۡخِلُهُمۡ فِي رَحۡمَةٖ مِّنۡهُ وَفَضۡلٖ وَيَهۡدِيهِمۡ إِلَيۡهِ صِرَٰطٗا مُّسۡتَقِيمٗا 175
Sugbọn awọn ti wọn ni igbagbọ ninu Ọlọhun Ọba Allah, ti wọn si di Alukuraani ti wọn sọkalẹ fun Anọbi wọn mu, Ọlọhun Ọba Allah yoo kẹ wọn pẹlu mimu wọn wọ Alujannah, yoo si se alekun ẹsan fun wọn, bẹẹ ni yoo si se alekun agbega, yoo fi wọn se kongẹ lati tọ oju ọna eyiti o duro tọ, ti ko si iwọgun nibẹ, ohun ni ọna ti yoo mu wọn wọ inu Alujannah onidẹra.
Sise alaye wipe Mọsiihu, abara nii se ati wipe dajudaju iya rẹ naa jẹ abara, bẹẹ ni awọn ti wọn sọ nu ninu awọn nasaara kọja ẹnu aala nibi awọn mejeeji, titi ti wọn fi mu awọn mejeeji kuro ni ipo abara.
Alaye nipa ibajẹ ẹbọ awọb nasaara ti wọn nsọ bayi wipe, mẹta lọkan, ti Ọlọhun Ọba ti ọla Rẹ ga si nse afọmọ wipe ko si akẹgbẹ pẹlu Oun tabi alafijọ tabi alasunmọ, ati alaye nipa jijẹ aaso Rẹ, -mimọ nbẹ fun Un- nibi ijọkan soso, bibẹẹ Rẹ, ati awọn orukọ, ati awọn iroyin naa.
Ifirinlẹ wipe Anọbi Isa ati awọn malaika, gbogbo wọn jẹ ẹrusin ti A da, wọn ko le se orikunkun siijẹwọ ẹru wọn si Ọlọhun Ọba Allah ti ọla Rẹ ga, ati titẹle awọn asẹ Rẹ, bawo ni mimu wọn ni ọlọhun se le jẹ, nigbati awọn naa ba jẹ ẹru fun Ọlọhun Ọba Allah ti ọla Rẹ ga? !
Ninu ẹsin, awijare ati awọn ẹri ti laakaye wa lati ti awọn iruju danu, bẹẹ ni imọlẹ ati itọsọna naa le ti idaamu ati awọn adun da nu.