وَإِذَا قِيلَ لَهُمُ ٱتَّبِعُواْ مَآ أَنزَلَ ٱللَّهُ قَالُواْ بَلۡ نَتَّبِعُ مَآ أَلۡفَيۡنَا عَلَيۡهِ ءَابَآءَنَآۚ أَوَلَوۡ كَانَ ءَابَآؤُهُمۡ لَا يَعۡقِلُونَ شَيۡٔٗا وَلَا يَهۡتَدُونَ 170
Ti wọn ba sọ fun awọn alaigbagbọ yii pe: ẹ tẹle ohun ti Ọlọhun Ọba Allah sọkalẹ ninu imana ati imọlẹ, wọn yoo maa sọ ni ẹniti ngunri wipe: bikose wipe awa yoo maa tẹle oun ti a ri awọn baba wa lori rẹ ninu awọn adisọkan ati awọn arikọse, se wọn yoo maa tẹle awọn baba wọn ni, koda bi awọn ko ni laakaye kankan ninu imana ati imọlẹ, ti wọn ko si mọna lọsi ibi ododo, eyiti Ọlọhun Ọba Allah yoo yọnu si? !
وَمَثَلُ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ كَمَثَلِ ٱلَّذِي يَنۡعِقُ بِمَا لَا يَسۡمَعُ إِلَّا دُعَآءٗ وَنِدَآءٗۚ صُمُّۢ بُكۡمٌ عُمۡيٞ فَهُمۡ لَا يَعۡقِلُونَ 171
Apẹrẹ awọn ti wọn se aigbagbọ nibi titẹle awọn baba wọn, da gẹgẹ bi ẹniti o da ẹran jẹ, eyiti o nke ni ẹniti npepe nipa awọn ẹran rẹ, ti wọn yoo si gbọ ohun rẹ, sugbọn ti wọn ko gbọ agbọye ọrọ rẹ, aditi ni awọn yii nipa gbigbọ ododo, ni gbigbọ ti wọn yoo se anfaani pẹlu rẹ, odi si ni wọn, ti ahọn wọn ti lọ nipa sisọ ododo jade, afọju si ni wọn pẹlu nibi ririi, tori idi eleyi, awọn ko nii se laakaye nipa imana eyiti o npe wọn lọ si ibẹ.
يَٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ كُلُواْ مِن طَيِّبَٰتِ مَا رَزَقۡنَٰكُمۡ وَٱشۡكُرُواْ لِلَّهِ إِن كُنتُمۡ إِيَّاهُ تَعۡبُدُونَ 172
Mo pe ẹyin ti ẹ gba Ọlọhun Ọba Allah gbọ lododo, ti ẹ si ntẹle ojisẹ Rẹ, ẹ maa jẹ ninu ohun ti o dara, eyiti Ọlọhun Ọba Allah se ni arisiki fun yin, ti O si se ni ẹtọ fun yin, ki ẹ si maa dupẹ fun Ọlọhun Ọba Allah ni gbangba ati ni kọkọ, ohun ti O fi se ọla fun yin ninu idẹra, ninu didupẹ fun Un Ẹniti ọla Rẹ ga, ohun ni ki ẹ sisẹ lati tẹle, ki ẹ si jina si yiyapa Rẹ, tobajẹ wipe lododo ni ẹ nsin Oun nikan, ti ẹ ko si mu orogun kankan pẹlu Rẹ, .
إِنَّمَا حَرَّمَ عَلَيۡكُمُ ٱلۡمَيۡتَةَ وَٱلدَّمَ وَلَحۡمَ ٱلۡخِنزِيرِ وَمَآ أُهِلَّ بِهِۦ لِغَيۡرِ ٱللَّهِۖ فَمَنِ ٱضۡطُرَّ غَيۡرَ بَاغٖ وَلَا عَادٖ فَلَآ إِثۡمَ عَلَيۡهِۚ إِنَّ ٱللَّهَ غَفُورٞ رَّحِيمٌ 173
Dajudaju Ohun ti Ọlọhun Ọba Allah se eewọ fun yin ninu awọn ounjẹ, ni ohun ti o ba ku laidunbu rẹ niti Ṣhẹria ati ẹjẹ ti o jade ti o nsan ati ẹran ẹlẹdẹ ati ohun ti wọn darukọ ti kii se orukọ Ọlọhun Ọba Allah si nigbati wọn ndunbu rẹ, sugbọn ti ọmọniyan ba ri inira lọsi ibi jijẹ nkankan ti kii sii se alabosi pẹlu jijẹ nibẹ laini bukaata sii ati jijẹ kọja odiwọn ‘laluuri’, ko si ẹsẹ fun un, bakanna ko si ijiya, dajudaju Ọlọhun Ọba Allah, Alaforijin ni fun ẹniti o ba ronu piwada ninu awọn ẹru Rẹ, Oun si ni Onikẹ wọn, ninu ikẹ Rẹ ni sise amojukuro nibi jijẹ awọn nkan eewọ yii nigbati ‘laluuri’ ba sẹlẹ.
إِنَّ ٱلَّذِينَ يَكۡتُمُونَ مَآ أَنزَلَ ٱللَّهُ مِنَ ٱلۡكِتَٰبِ وَيَشۡتَرُونَ بِهِۦ ثَمَنٗا قَلِيلًا أُوْلَٰٓئِكَ مَا يَأۡكُلُونَ فِي بُطُونِهِمۡ إِلَّا ٱلنَّارَ وَلَا يُكَلِّمُهُمُ ٱللَّهُ يَوۡمَ ٱلۡقِيَٰمَةِ وَلَا يُزَكِّيهِمۡ وَلَهُمۡ عَذَابٌ أَلِيمٌ 174
Dajudaju awọn ti wọn npa ohun ti Allah sọkalẹ mọ ninu awọn tira ati ohun ti nbẹ nibẹ ninu awọn itọkasi lori ododo ati jijẹ ti Muhammad (ki ikẹ ati igẹ Ọlọhun maa ba) jẹ Anọbi gẹgẹ bi awọn Yahuudu ati awọn Nasaara se ma nse, ti wọn si ma nra pẹlu pipamọ wọn yii, ifipaarọ kekere gẹgẹ bi sise olori ati ibi ati dukia; awọn ni ẹniti ti o jẹ wipe wọn ko jẹ nkankan si inu wọn ni paapaa ayaafi ohun ti yoo jẹ okunfa jijẹ wọn niya pẹlu ina, Ọlọhun Ọba Allah ko ni ba wọn sọrọ ni Ọjọ Igbende pẹlu ohun ti wọn nifẹsi bikose wipe pẹlu ohun ti yoo ba wọn ninujẹ, ko nii se afọmọ wọn, bakanna ko nii se ẹyin fun wọn, iya ẹlẹta-elero yoo si maa jẹ ti wọn.
أُوْلَٰٓئِكَ ٱلَّذِينَ ٱشۡتَرَوُاْ ٱلضَّلَٰلَةَ بِٱلۡهُدَىٰ وَٱلۡعَذَابَ بِٱلۡمَغۡفِرَةِۚ فَمَآ أَصۡبَرَهُمۡ عَلَى ٱلنَّارِ 175
Awọn ti wọn nroyin pẹlu fifi imọ pamọ eyiti awọn eniyan ni bukaata si, awọn ni ẹniti o fi anu paarọ ọnaamọ nigbati wọn fi imọ ododo pamọ, wọn si fi iya Ọlọhun Ọba Allah paarọ aforijin Rẹ, suuru wọn yoo pẹ gan lori sise ohun ti yoo se okunfa wiwọna fun wọn , toripe awọn ko nii bikita ohun ti nbẹ nibẹ ninu iya nitori suuru ti wn se le lori.
ذَٰلِكَ بِأَنَّ ٱللَّهَ نَزَّلَ ٱلۡكِتَٰبَ بِٱلۡحَقِّۗ وَإِنَّ ٱلَّذِينَ ٱخۡتَلَفُواْ فِي ٱلۡكِتَٰبِ لَفِي شِقَاقِۢ بَعِيدٖ 176
Ẹsan naa nbẹ lori pipa imọ ati imọna mọ, nitori pe Ọlọhun Ọba Allah sọ awọn tira ti o jẹ ti Ọlọhun Ọba Allah kalẹ pẹlu ododo, eleyi si bukaata si ki wọn se alaye rẹ, ki won si ma fi pamọ. Dajudaju awọn ti wọn se ifanfa nibi tira Ọlọhun Ọba Allah, ti wọn waa ni igbagbọ si apakan rẹ, ti wọn si pa apakan rẹ mọ, wa ninu abala ti o jina si ododo, .
Ọpọlọpọ sisọnu awọn ẹda nbẹ pẹlu sisọsẹẹlẹ laakaye ati titẹle awọn ti wọn siwaju wọn ninu anu wọn ati kikọse wọn laini oye.
Aise anfaani ọmọniyan pẹlu ohun ti Ọlọhun Ọba Allah ta ni ọrẹ ninu idẹra laakaye ati gbigbọ ati riri ran, yoo sọ di iru awọn ti wọn se afẹku idẹra yii.
Ninu awọn eniyan ti iya wọn yoo lagbara ju ni Ọjọ Igbende ni ẹniti o ba npa imọ ti Ọlọhun Ọba Allah sọkalẹ mọ ati imọna eyiti Ojisẹ Rẹ (ki ọla Rẹ ga) muwa.
Ninu idẹra Ọlọhun Ọba Allah (ti ọla Rẹ ga) lori awọn ẹru Rẹ ti wọn jẹ olugbagbọ ododo nipe O se ohun ti O se ni eewọ fun ni ohun ti o kere, ti o si ni aala, a ko waa ri ohun ti o jẹ ẹtọ pọ pupọ, ti ko si ni aala.