ٱذۡهَبۡ إِلَىٰ فِرۡعَوۡنَ إِنَّهُۥ طَغَىٰ 17
O sọ fun un nibi ohun ti o wi: lọsi ọdọ fir'aona, dajudaju o kọja ẹnu aala nibi abosi ati igbera.
فَقُلۡ هَل لَّكَ إِلَىٰٓ أَن تَزَكَّىٰ 18
Ki o sọ fun: se o le mọra kuro nibi keferi ati awọn ẹsẹ -irẹ fir'aona-?
وَأَهۡدِيَكَ إِلَىٰ رَبِّكَ فَتَخۡشَىٰ 19
O si tọka rẹ si Ọlọhun rẹ eyiti ti O da ọ, ti O si nre ọ, ki o le bẹru Rẹ, ki o si se ohun ti yoo yọ ninu, ki o si jinna si ohun ti yoo bi ninu?
فَأَرَىٰهُ ٱلۡأٓيَةَ ٱلۡكُبۡرَىٰ 20
Musa ẹniti ọla nbẹ fun si fi amin ti o tobi, ti o tọka si wipe ojisẹ ni o jẹ lati ọdọ Ọlọhun rẹ han fun un, ohun si ni ọwọ ati ọpa.
فَكَذَّبَ وَعَصَىٰ 21
Nkankan ko wa lati ọdọ fir'aona jupe o pe amin yii nirọ lọ, o si yapa si ohun ti Musa ẹniti ọla nbẹ fun pa lasẹ rẹ.
ثُمَّ أَدۡبَرَ يَسۡعَىٰ 22
Lẹyin naa o sẹri kuro nibi igbagbọ si ohun ti Musa mu wa ki ọla ma ba lẹni ti ngbiyanju nibi sisẹ Allah ati mimọ tako ododo.
فَحَشَرَ فَنَادَىٰ 23
O si ko awọn ọmọ ogun rẹ jọ o si tẹle lati bori Musa ki ọla ma ba, o wa pepe ni ẹniti o sọpe:
فَقَالَ أَنَا۠ رَبُّكُمُ ٱلۡأَعۡلَىٰ 24
Emi ni ọlọhun yin ti o ga julọ, ko si titẹle ẹlomiran le yin lori.
فَأَخَذَهُ ٱللَّهُ نَكَالَ ٱلۡأٓخِرَةِ وَٱلۡأُولَىٰٓ 25
Allah si gba mu, o fi itẹri si inu odo jẹ ni iya ni ile aye, o si fi mimu wọ iya ti o le jẹ ni iya ni ọrun.
إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَعِبۡرَةٗ لِّمَن يَخۡشَىٰٓ 26
Dajudaju nibi ohun ti a fi jẹ fir'aona niya ni aye ati ọrun jẹ isiti fun ẹniti o npaya Allah; oun ni ẹniti yoo se anfaani pẹlu isiti naa.
ءَأَنتُمۡ أَشَدُّ خَلۡقًا أَمِ ٱلسَّمَآءُۚ بَنَىٰهَا 27
Se mimu yin bẹ lati ọdọ Allah - ẹyin opurọ nipa ajinde - ni o le ni tabi mimu sanmọ eyiti a mọ bẹ?!
رَفَعَ سَمۡكَهَا فَسَوَّىٰهَا 28
O si aworan rẹ si abala oke ti o ga, o si se e ni dọgba ti ko si afonifoji nibẹ tabi sisdan tabi aleebu.
وَأَغۡطَشَ لَيۡلَهَا وَأَخۡرَجَ ضُحَىٰهَا 29
O si sọ oru rẹ di dudu nigbati oorun Rẹ ba wọ, O si mu imọlẹ rẹ jade nigbati o ba yọ.
وَٱلۡأَرۡضَ بَعۡدَ ذَٰلِكَ دَحَىٰهَآ 30
O si tẹ ilẹ lẹyin igbati o da sanmọ, o si fi awọn anfaani pamọ si ninurẹ.
أَخۡرَجَ مِنۡهَا مَآءَهَا وَمَرۡعَىٰهَا 31
O mu omin isẹlẹru ibẹ jade ti o nsan, o si mu awọn irugbin jade nibẹ, ti awọn ẹranko njẹ.
وَٱلۡجِبَالَ أَرۡسَىٰهَا 32
O se oke ni ohun ti o rinlẹ ni ori ilẹ.
مَتَٰعٗا لَّكُمۡ وَ لِأَنۡعَٰمِكُمۡ 33
Gbogbo eleyi jẹ anfaani fun yin - ẹyin eniyan - ati fun awọn ẹranko yin, ẹniti o da eleyi patapata dida isẹda wọn pada ni titun ko le ko agara ba A.
فَإِذَا جَآءَتِ ٱلطَّآمَّةُ ٱلۡكُبۡرَىٰ 34
Nigbati fifan fere ẹlẹẹkeji ba de eyiti ipaya rẹ yoo bo gbogbo nkan, ti igbedide si sun mọ.
يَوۡمَ يَتَذَكَّرُ ٱلۡإِنسَٰنُ مَا سَعَىٰ 35
Ọjọ ti yoo de, ti ọmọniyan yoo maa ranti ohun ti o ti siwaju ninu isẹ, rere ni o jẹ ni tabi aburu.
وَبُرِّزَتِ ٱلۡجَحِيمُ لِمَن يَرَىٰ 36
Ti wọn si mu ina jahannamọ wa, ti wọn si fi hande niri riri fun ẹniti o nwo o.
فَأَمَّا مَن طَغَىٰ 37
Ẹniti o ba kọja ẹnu aala si anu.
وَءَاثَرَ ٱلۡحَيَوٰةَ ٱلدُّنۡيَا 38
Ti o gbọla fun isẹmin aye ti yoo tan lori isẹmin ọrun ti yoo sẹku.
فَإِنَّ ٱلۡجَحِيمَ هِيَ ٱلۡمَأۡوَىٰ 39
Dajudaju ina ni ibusimin si ti yoo sẹri si.
وَأَمَّا مَنۡ خَافَ مَقَامَ رَبِّهِۦ وَنَهَى ٱلنَّفۡسَ عَنِ ٱلۡهَوَىٰ 40
Ẹniti o ba bẹru iduro rẹ niwaju Ọlọhun rẹ, ti o si mu ẹmin rẹ duro kuro nibi titẹle ohun ti o nifẹ si ninu ohun ti Allah se ni eewọ fun un.
فَإِنَّ ٱلۡجَنَّةَ هِيَ ٱلۡمَأۡوَىٰ 41
Dajudaju ọgba idẹra ni ibi isinmi si eyiti yoo sẹri si.
يَسَۡٔلُونَكَ عَنِ ٱلسَّاعَةِ أَيَّانَ مُرۡسَىٰهَا 42
Awọn olupe ajinde nirọ yoo bi ọ leere - irẹ ojisẹ - wipe: igba wo ni asiko ikẹyin yoo sẹlẹ?
فِيمَ أَنتَ مِن ذِكۡرَىٰهَآ 43
Ko si imọ fun ọ nipa rẹ, ti iwọ yoo fi sọ fun wọn, ko si si ninu isesi rẹ dajudaju isesi rẹ ni ki o mura silẹ fun un.
إِلَىٰ رَبِّكَ مُنتَهَىٰهَآ 44
Ọdọ Ọlọhun rẹ nikan ni opin asiko imọ asiko ikẹyin.
إِنَّمَآ أَنتَ مُنذِرُ مَن يَخۡشَىٰهَا 45
Dajudaju iwọ ni olukilọ fun ẹniti o npaya asiko ikẹyin naa; nitoripe oun ni yoo se anfaani pẹlu ikilọ rẹ.
كَأَنَّهُمۡ يَوۡمَ يَرَوۡنَهَا لَمۡ يَلۡبَثُوٓاْ إِلَّا عَشِيَّةً أَوۡ ضُحَىٰهَا 46
Ni ọjọ ti wọn ba ri asiko ikẹyin ni riri oju, wọn yoo da gẹgẹ bi ẹniti ko lo isẹmin ni aye wọn ayaafi irọlẹ ọjọ kan tabi idaji kutu rẹ lọ.
Jijẹ dandan sise pẹlẹ nigbati a ba nba ẹniti a npe sọrọ.
Pipaya Allah ati kiko ẹmin diro nibi ifẹ inu wa ninu awọn okunfa wiwọ ọgba idẹra naa.
Imọ asiko ikẹyin wa ninu kọkọ ti ẹnikankan ko mọ ọ ayaafi Allah.
Alaye Allah nipa ẹkunrẹrẹ sise ẹda sanmọ ati ilẹ.