إِنَّا بَلَوۡنَٰهُمۡ كَمَا بَلَوۡنَآ أَصۡحَٰبَ ٱلۡجَنَّةِ إِذۡ أَقۡسَمُواْ لَيَصۡرِمُنَّهَا مُصۡبِحِينَ 17
Dajudaju a dan awọn ẹlẹbọ wọnyi wo pẹlu ọda ati ebi gẹgẹ bi a se dan awọn ẹni ọgba naa wo nigbati wọn bura lati ge awọn eso rẹ ni asiko idaji ni yarayara ki alaini ma ba jẹ nibẹ.
وَلَا يَسۡتَثۡنُونَ 18
Wọn ko si sẹri kuro nibi ibura wọn pẹlu gbolohun wọn: (ti Allah ba fẹ).
فَطَافَ عَلَيۡهَا طَآئِفٞ مِّن رَّبِّكَ وَهُمۡ نَآئِمُونَ 19
Allah si ran ina si wọn, oo run si mu wọn ati awọn ẹni wọn, ti wọn ko nikapa lati daabobo kuro nibi ina naa.
فَأَصۡبَحَتۡ كَٱلصَّرِيمِ 20
O wa di dudu gẹgẹ bi oru ti o dudu biribiri.
فَتَنَادَوۡاْ مُصۡبِحِينَ 21
Apakan wọn si bẹrẹ si pe apakeji ni asiko idaji.
أَنِ ٱغۡدُواْ عَلَىٰ حَرۡثِكُمۡ إِن كُنتُمۡ صَٰرِمِينَ 22
Ni ẹniti wọn nsọ pe: ẹ jade ni idaji kutu kutu si awọn oko yin siwaju ki awọn alaini too de, ti ẹ ba fẹ ja awọn nkan eso ibẹ.
فَٱنطَلَقُواْ وَهُمۡ يَتَخَٰفَتُونَ 23
Wọn so lọ si ibi oko wọn ni yarayara ti apakan wọn nba apakan wọn sọrọ pẹlu ohun irẹlẹ.
أَن لَّا يَدۡخُلَنَّهَا ٱلۡيَوۡمَ عَلَيۡكُم مِّسۡكِينٞ 24
Apakan wọn sọ fun apakan: alaini ko gbọdọ wọ inu ọgba pẹlu yin loni.
وَغَدَوۡاْ عَلَىٰ حَرۡدٖ قَٰدِرِينَ 25
Wọn si lọ ni aarọ kutu lori kikọ awọn eso wọn niti ipinnu.
فَلَمَّا رَأَوۡهَا قَالُوٓاْ إِنَّا لَضَآلُّونَ 26
Nigbati wọn ri ti o jona, apakan wọn sọ fun apakan wipe: a ti sina oju ọna rẹ.
بَلۡ نَحۡنُ مَحۡرُومُونَ 27
Bikosepe wọn kọ fun wa lati kan awọn eso rẹ nitori pinpinnu wa lori kikọ fun awọn alaini ninu rẹ.
قَالَ أَوۡسَطُهُمۡ أَلَمۡ أَقُل لَّكُمۡ لَوۡلَا تُسَبِّحُونَ 28
Ẹniti o lọla ju ninu wọn sọpe: se emi ko sọ fun yin nigbati ẹ pinnu lori ipinnu kikọ fun awọn alaini ninu rẹ: se ẹ ko ni se afọmọ fun Allah bayi, ki ẹ si ronu piwada lọsi ọdọ Rẹ?!
قَالُواْ سُبۡحَٰنَ رَبِّنَآ إِنَّا كُنَّا ظَٰلِمِينَ 29
Wọn sọpe: mimọ Ọlọhun wa, dajudaju awa jẹ alabosi fun ẹmin ara wa lori kikọ awọn eso ọgba wa fun awọn alaini.
فَأَقۡبَلَ بَعۡضُهُمۡ عَلَىٰ بَعۡضٖ يَتَلَٰوَمُونَ 30
Wọn si kọju si ara wọn ni ẹniti o sẹri sibi ọrọ wọn ni ojupọnnọ ibuni.
قَالُواْ يَٰوَيۡلَنَآ إِنَّا كُنَّا طَٰغِينَ 31
Wọn sọ niti abamọ: irẹ ofo wa o, a ti jẹ olukọja ẹnu aalaa pẹlu kikọ ẹtọ awọn alaini fun wọn.
عَسَىٰ رَبُّنَآ أَن يُبۡدِلَنَا خَيۡرٗا مِّنۡهَآ إِنَّآ إِلَىٰ رَبِّنَا رَٰغِبُونَ 32
O seese ki Ọlọhun wa fi rere paarọ fun wa dipo ọgba naa, dajudaju ọdọ Allah nikan a rankan si, a nreti amojukuro lọdọ Rẹ, a si nwa rere lọdọ Rẹ.
كَذَٰلِكَ ٱلۡعَذَابُۖ وَلَعَذَابُ ٱلۡأٓخِرَةِ أَكۡبَرُۚ لَوۡ كَانُواْ يَعۡلَمُونَ 33
Iru ijiya kikọ arisiki fun ni yii ni a o maa fi jẹ ẹniti o ba ti yapa Wa, bẹẹni iya ọrun tobi ju ti wọn ba mọ lilekoko rẹ ati wiwa gbere rẹ.
إِنَّ لِلۡمُتَّقِينَ عِندَ رَبِّهِمۡ جَنَّٰتِ ٱلنَّعِيمِ 34
Dajudaju awọn ọgba idẹra ti wọn yoo maa gbadun nibẹ, ti idẹkun rẹ ko nii ja kuro fun wọn nbẹ fun awọn olupaya Allah pẹlu mimu awọn asẹ Rẹ sẹ ati jijinna si awọn ohun ti O kọ lọdọ Ọlọhun wọn.
أَفَنَجۡعَلُ ٱلۡمُسۡلِمِينَ كَٱلۡمُجۡرِمِينَ 35
Se a o sọ awọn olugbafa di awọn keferi nibi ẹsan ni gẹgẹ bi awọn ẹlẹbọ se nlero ninu awọn ara ilu Mekkah?!
مَا لَكُمۡ كَيۡفَ تَحۡكُمُونَ 36
Kin lo se yin - ẹyin ẹlẹbọ - ti ẹ fi ndajọ iru idajọ alabosi ti o wọgun yii?!
أَمۡ لَكُمۡ كِتَٰبٞ فِيهِ تَدۡرُسُونَ 37
Tabi iwe kan nbẹ fun yin ti ẹ nka didọgba laarin olutẹle ati ẹlẹsẹ nibẹ ni?!
إِنَّ لَكُمۡ فِيهِ لَمَا تَخَيَّرُونَ 38
Dajudaju ohun ti ẹ o sa lẹsa nbẹ fun yin ni ọrun ninu tira naa.
أَمۡ لَكُمۡ أَيۡمَٰنٌ عَلَيۡنَا بَٰلِغَةٌ إِلَىٰ يَوۡمِ ٱلۡقِيَٰمَةِ إِنَّ لَكُمۡ لَمَا تَحۡكُمُونَ 39
Tabi awọn adehun ti a kan pa mọ pẹlu awọn ibura nbẹ fun yin lori wa ti o ti ni amusẹ, ti ẹ fi nfi se idajọ lori ẹmin yin?!
سَلۡهُمۡ أَيُّهُم بِذَٰلِكَ زَعِيمٌ 40
Beere - irẹ ojisẹ - lọwọ awọn ti wọn sọ ọrọ yii: taani ninu yin ti yoo la a bọrun?!
أَمۡ لَهُمۡ شُرَكَآءُ فَلۡيَأۡتُواْ بِشُرَكَآئِهِمۡ إِن كَانُواْ صَٰدِقِينَ 41
Tabi awọn akẹgbẹ yatọ si Allah nbẹ fun wọn ti wọn yoo jọ kẹgbẹ nibi ẹsan pẹlu awọn olugbagbọ ododo wọn?! Ki wọn yaa mu awọn akẹgbẹ wọn yii wa ti wọn ba jẹ olododo nibi ohun ti wọn npe apemọra rẹ yii nibi wipe wọn jọ dọgba pẹlu awọn olugbagbọ ododo nibi ẹsan.
يَوۡمَ يُكۡشَفُ عَن سَاقٖ وَيُدۡعَوۡنَ إِلَى ٱلسُّجُودِ فَلَا يَسۡتَطِيعُونَ 42
Ipaya yoo han, Ọlọhun wọn yoo si si gaga kuro ni ojugun rẹ ni ọjọ igbende, wọn yoo si pe awọn eniyan lọsi ibi iforikanlẹ, bayi ni awọn olugbagbọ ododo yoo fi ori kanlẹ, yoo si sẹku awọn keferi ati awọn sọbẹ selu, ti wọn ko nii nikapa lati fi ori kanlẹ.
Titako ẹtọ alaini jẹ okunfa iparun dukia.
Kikanju iya ni ile aye wa ninu erongba rere fun ẹru ki o le ronu piwada ki o si sẹri.
Olugbagbọ ododo ati keferi ko le dọgba nibi ẹsan gẹgẹ bi awọn iroyin wọn ko se le dọgba.