فَكَانَ عَٰقِبَتَهُمَآ أَنَّهُمَا فِي ٱلنَّارِ خَٰلِدَيۡنِ فِيهَاۚ وَذَٰلِكَ جَزَٰٓؤُاْ ٱلظَّٰلِمِينَ 17
Igbẹyin ọọ esu ati ẹniti o tẹle e (itumọ rẹ ni: esu ti wọn tẹle, ati ẹniyan ti o tẹle e) awọn mejeeji ni ọjọ igbende yoo maa bẹ gbere lọ lailai ninu ina, eleyi ni ẹsan ti o nreti wọn, eleyi si ni ẹsan awọn ti wọn se abosi si ẹmin ara wọn pẹlu kikọja ẹnu aala Allah.
يَٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ ٱتَّقُواْ ٱللَّهَ وَلۡتَنظُرۡ نَفۡسٞ مَّا قَدَّمَتۡ لِغَدٖۖ وَٱتَّقُواْ ٱللَّهَۚ إِنَّ ٱللَّهَ خَبِيرُۢ بِمَا تَعۡمَلُونَ 18
Mo pe ẹyin ti ẹ nigbagbọ ninu Allah, ti wọn si se ohun ti wọn se lofin fun wọn, ẹ paya Allah pẹlu mimu sẹ awọn ohun ti o pa lasẹ ati jijinna si awọn ohun ti O kọ, ki ẹmin kọọkan si ronu ohun ti o ti siwaju ninu isẹ rere ni ọjọ igbende, ki ẹ si paya Allah, dajudaju Allah jẹ olufunni niro ohun ti ẹ nse nisẹ, nkankan ko pamọ fun Un ninu awọn isẹ yin, yoo si san yin lẹsan le lori.
وَلَا تَكُونُواْ كَٱلَّذِينَ نَسُواْ ٱللَّهَ فَأَنسَىٰهُمۡ أَنفُسَهُمۡۚ أُوْلَٰٓئِكَ هُمُ ٱلۡفَٰسِقُونَ 19
Ẹ masi se da gẹgẹ bi awọn ti o gbagbe Allah pẹlu gbigbe ju silẹ imusẹ asẹ Rẹ ati ijina si awọn nkan ti O kọ, Allah mu wọn gbagbe ẹmin ara wọn, wọn ko si se ohun ti yoo mu wọn la kuro nibi ibinu Allah ati iya Rẹ, awọn wọnyi ni ẹniti o gbagbe Allah - wọn ko mu asẹ Rẹ sẹ, wọn ko koraro nibi ohun ti O kọ - awọn ni ẹniti o jade kuro nibi itẹle ti Allah.
لَا يَسۡتَوِيٓ أَصۡحَٰبُ ٱلنَّارِ وَأَصۡحَٰبُ ٱلۡجَنَّةِۚ أَصۡحَٰبُ ٱلۡجَنَّةِ هُمُ ٱلۡفَآئِزُونَ 20
Awọn ẹni ina ati awọn ẹni ọgba idẹra ko dagba bikosepe wọn yapa si ara wọn nibi ẹsan wọn gẹgẹ bi iyapa awọn isẹ wọn ni ile aye, awọn ẹni ọgba idẹra ni olujere pẹlu titẹ lọwọ ohun ti wọn nwa, awọn ti yoo la nibi ohun ti wọn nbẹru.
لَوۡ أَنزَلۡنَا هَٰذَا ٱلۡقُرۡءَانَ عَلَىٰ جَبَلٖ لَّرَأَيۡتَهُۥ خَٰشِعٗا مُّتَصَدِّعٗا مِّنۡ خَشۡيَةِ ٱللَّهِۚ وَتِلۡكَ ٱلۡأَمۡثَٰلُ نَضۡرِبُهَا لِلنَّاسِ لَعَلَّهُمۡ يَتَفَكَّرُونَ 21
Ti a ba sọ Alukuraani yii kalẹ lori oke, paapaa iwọ yoo ri - irẹ ojisẹ - oke naa pẹlu bi o se le koko ni ohun ti yoo rọ, ti yoo si san nitori lile ipaya Allah; nitori ohun ti o wa ninu Alukuraani ninu awọn isiti ijagbemọ ati adehun iya ti o le koko, a nfi awọn apejuwe yii lelẹ fun awọn eniyan boya wọn yoo lo laakaye wọn lati gba isiti pẹlu ohun ti awọn amin rẹ ninu awọn isiti ati awọn ariwoye ko sinu.
هُوَ ٱللَّهُ ٱلَّذِي لَآ إِلَٰهَ إِلَّا هُوَۖ عَٰلِمُ ٱلۡغَيۡبِ وَٱلشَّهَٰدَةِۖ هُوَ ٱلرَّحۡمَٰنُ ٱلرَّحِيمُ 22
Oun ni Allah ti ko si ẹniti ijọsin tootọ tọ si yatọ si I, Onimimọ nipa ohun ti o pamọ ati ohun ti o han, nkankan ko pamọ fun Un ninu eleyi, ajọkẹ aye ati ọrun ati asanikẹ mejeeji, ikẹ Rẹ gbaaye fun gbogbo agbanla aye.
هُوَ ٱللَّهُ ٱلَّذِي لَآ إِلَٰهَ إِلَّا هُوَ ٱلۡمَلِكُ ٱلۡقُدُّوسُ ٱلسَّلَٰمُ ٱلۡمُؤۡمِنُ ٱلۡمُهَيۡمِنُ ٱلۡعَزِيزُ ٱلۡجَبَّارُ ٱلۡمُتَكَبِّرُۚ سُبۡحَٰنَ ٱللَّهِ عَمَّا يُشۡرِكُونَ 23
Oun ni Allah ti ko si ẹniti ijọsin tootọ tọ si yatọ si I, Ọlọla, Ẹni mimọ, Ẹni afọmọ kuro nibi gbogbo adinku, Ẹniti o la kuro nibi gbogbo aleebu, Olugba awọn ojisẹ Rẹ lododo pẹlu awọn amin ti o o fojuhan, Olusọ awọn isẹ awọn ẹru Rẹ, Alagbara ti ẹnikẹni ko le bori Rẹ, Ajẹninipa eyiti o bori gbogbo nkan pẹlu gbigbọngbọn Rẹ, Onigberaga, Allah mọ, O si mọ kanga nibi gbogbo ohun ti awọn ẹlẹbọ nmu pẹlu Rẹ gẹgẹ bi awọn oosa ati ohun ti o yatọ si I.
هُوَ ٱللَّهُ ٱلۡخَٰلِقُ ٱلۡبَارِئُ ٱلۡمُصَوِّرُۖ لَهُ ٱلۡأَسۡمَآءُ ٱلۡحُسۡنَىٰۚ يُسَبِّحُ لَهُۥ مَا فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِۖ وَهُوَ ٱلۡعَزِيزُ ٱلۡحَكِيمُ 24
Oun ni Allah asẹda ti O da gbogbo nkan, olumu gbogbo nkan waye, oluyaworan gbogbo awọn ẹda RẸ nibamun bi O se fẹ, Oun ti mimọ nbẹ fun ni O ni awọn orukọ ti o dara ju, eyiti o ko gbogbo awọn iroyin Rẹ ti o ga julọ sinu, ohun gbogbo ti nbẹ ni sanmọ ati ilẹ nse afọmọ Rẹ kuro nibi ẹdinku, alagbara ti ẹnikankan ko le bori Rẹ, ọjọgbọn nibi isẹda Rẹ ati isofin Rẹ ati ipebubu Rẹ.
Ninu awọn amin konẹ Allah fun olugbagbọ ododo nipe yoo se isiro ara rẹ ni ile aye siwaju isiro rẹ ni ọjọ igbende.
Nibi riran ẹru leti lilekoko oripa Alukuraani lori oke ti o tobi; jẹ itaniji lori wipe awọn ni wọn lẹtọ ju si ilapa ọlẹ ti o wa lara wọn.
Awọn orukọ naa tọka (asẹda, olumọkanga, oluyaworan) si awọn ipele kiko ẹda jọ nibi pipe bubu Rẹ, lẹyin naa ni mimu u bẹ, lẹyin naa O se aworan ẹsa fun un pẹlu riranti ikọọkan rẹ lẹyọ ẹyọ jẹ ohun ti o ntọka si awọn yoku.