يَطُوفُ عَلَيۡهِمۡ وِلۡدَٰنٞ مُّخَلَّدُونَ 17
Awọn ọmọ ti wọn ko le darugbo, ti titan ko si le ba yoo maa yipo wọn fun sise isẹ sin wọn.
بِأَكۡوَابٖ وَأَبَارِيقَ وَكَأۡسٖ مِّن مَّعِينٖ 18
wọn yoo maa yipo wọn pẹlu awọn ife ti ko si ebibo fun un ati awọn age ti o ni ebibo ati ife ti o kun fun oti, ti o nsan, ti ko si nii tan.
لَّا يُصَدَّعُونَ عَنۡهَا وَلَا يُنزِفُونَ 19
Ko da gẹgẹ bi oti ile aye, ori fifọ ko si nii kan ẹniti o ba mu un bẹẹ ni mimu laakaye lọ ko si.
وَفَٰكِهَةٖ مِّمَّا يَتَخَيَّرُونَ 20
Awọn ọmọkunrin yoo maa yipo wọn pẹlu ipapanu ninu ohun ti wọn ba sa lẹsa.
وَلَحۡمِ طَيۡرٖ مِّمَّا يَشۡتَهُونَ 21
Wọn yoo maa gbe ẹran ẹyẹ fun ohun ti wọn ba fẹ fun ẹmin ara wọn yipo wọn.
وَحُورٌ عِينٞ 22
Awọn obinrin ti o oju wọn fẹ ni ẹwa si nbẹ fun wọn ninu ọgba idẹra naa.
كَأَمۡثَٰلِ ٱللُّؤۡلُوِٕ ٱلۡمَكۡنُونِ 23
Gẹgẹbi apejuwe aluuluu ti a pọnle ninu apopo rẹ.
جَزَآءَۢ بِمَا كَانُواْ يَعۡمَلُونَ 24
Ki o le jẹ ẹsan fun lori nkan ti wọn se ninu awọn isẹẹre ni ile aye.
لَا يَسۡمَعُونَ فِيهَا لَغۡوٗا وَلَا تَأۡثِيمًا 25
Wọn ko nii gbọ ọrọ ibajẹ tabi ohun ti o le ẹsẹ ba ẹni rẹ ni inu ọgba idẹra naa.
إِلَّا قِيلٗا سَلَٰمٗا سَلَٰمٗا 26
Wọn ko nii gbọ ju ikini alaafia awọn Malaika si wọn lọ ati ikini alaafia apakan wọn si apakan.
وَأَصۡحَٰبُ ٱلۡيَمِينِ مَآ أَصۡحَٰبُ ٱلۡيَمِينِ 27
Awọn ẹni ọtun - awọn ti wọn yoo fun ni tira wọn pẹlu ọwọ ọtun wọn - bawo ni titobi ipo wọn ati isesi wọn ni ọdọ Allah!.
فِي سِدۡرٖ مَّخۡضُودٖ 28
Ni ibi igi sidiri ti ẹgun rẹ ti ge ti ko si suta nibẹ.
وَطَلۡحٖ مَّنضُودٖ 29
Ati ọgẹdẹ ti o gbọmọpọn, ti apakan rẹ to tẹle apakan.
وَظِلّٖ مَّمۡدُودٖ 30
Ati ooji ti o gun tẹle ara wọn, ti ko nii yẹ.
وَمَآءٖ مَّسۡكُوبٖ 31
Ati omin ti o nsan ti koo nii duro.
وَفَٰكِهَةٖ كَثِيرَةٖ 32
Ati ipapanu ti o pọ ti ko se ka.
لَّا مَقۡطُوعَةٖ وَلَا مَمۡنُوعَةٖ 33
Ko nii ja kuro lọdọ wọn lailai, ko si ni asiko kan pato, ikọdi kan ko si le kọdi ni eyikeyi asiko ti wọn ba fẹ.
وَفُرُشٖ مَّرۡفُوعَةٍ 34
Ati awọn itẹ ti a gbe ga, ti o wa ni ori awọn ibusun.
إِنَّآ أَنشَأۡنَٰهُنَّ إِنشَآءٗ 35
Awa ni a se awọn ẹlẹyinju ẹgẹ ni sise ti a ko barẹ.
فَجَعَلۡنَٰهُنَّ أَبۡكَارًا 36
A se wọn ni ọmọge, ti wọn ko fi ọwọ kan siwaju.
عُرُبًا أَتۡرَابٗا 37
Ẹni inifẹsi ni ọdọ awọn ọkọ wọnm, ẹni idọgba nibi ọjọ ori.
لِّأَصۡحَٰبِ ٱلۡيَمِينِ 38
A se wọn fun awọn ẹni ọtun, awọn ti wọn yoo mu gba abala ọtun ni amin si ijẹ oriire wọn.
ثُلَّةٞ مِّنَ ٱلۡأَوَّلِينَ 39
Awọn ni ijọ kan ninu awọn ijọ anọbi ti o re kọja.
وَثُلَّةٞ مِّنَ ٱلۡأٓخِرِينَ 40
Ati awọn ijọ kan ninu awọn ijọ Muhammad ti ikẹ ati ọla nbẹ fun, ohun si ni ijọ ikẹyin.
وَأَصۡحَٰبُ ٱلشِّمَالِ مَآ أَصۡحَٰبُ ٱلشِّمَالِ 41
Ati awọn ẹni osi - awọn ti wọn yoo fun ni tira wọn pẹlu ọwọ osi wọn - Ewo bi isesi wọn se buru to ati ibudarisi wọn.
فِي سَمُومٖ وَحَمِيمٖ 42
Nibi atẹgun ti o le ni igbona ati nibi omin ti o le ni igbona.
وَظِلّٖ مِّن يَحۡمُومٖ 43
Ati nibi booju eefin ti o dudu.
لَّا بَارِدٖ وَلَا كَرِيمٍ 44
Atẹgun naa ko dara, ko si se ri loju.
إِنَّهُمۡ كَانُواْ قَبۡلَ ذَٰلِكَ مُتۡرَفِينَ 45
Dajudaju siwaju ki wọn too di ẹni iya, wọn jẹ ẹniti o ngbadun ni ile aye, ti ko si ibanujẹ fun wọn ayaafi igbadun wọn.
وَكَانُواْ يُصِرُّونَ عَلَى ٱلۡحِنثِ ٱلۡعَظِيمِ 46
Wọn jẹ ẹniti o wo mọ keferi si Allah ati sinsin awọn oosa yatọ si I.
وَكَانُواْ يَقُولُونَ أَئِذَا مِتۡنَا وَكُنَّا تُرَابٗا وَعِظَٰمًا أَءِنَّا لَمَبۡعُوثُونَ 47
Wọn jẹ ẹniti o ntako ajinde, wọn yoo si maa sọ niti yẹyẹ sise ati mimu jinna si i: se ti a ba ku, ti a si di yerupẹ ati eegun ti o ti kẹfun, se wọn yoo gbe wa dide lẹyin eleyi bi?!
أَوَ ءَابَآؤُنَا ٱلۡأَوَّلُونَ 48
Se wọn yoo gbe awọn baba wa akọkọ ti wọn ti ku siwaju wa dide bi?
قُلۡ إِنَّ ٱلۡأَوَّلِينَ وَٱلۡأٓخِرِينَ 49
Sọ - irẹ ojisẹ - fun awọn olutako ajinde: dajudaju awọn ẹni akọkọ ninu awọn eniyan ati awọn ẹni ikẹyin ninu wọn.
لَمَجۡمُوعُونَ إِلَىٰ مِيقَٰتِ يَوۡمٖ مَّعۡلُومٖ 50
Wọn yo ko wọn jọ ni ọjọ igbende fun isiro ati ẹsan ti ko si ibuyẹ.
Isẹ rere jẹ okunfa riri idẹkun ni ọrun.
Ayọpọrọ ati igbadun wa ninu awọn okunfa ti o nmuni bọ sinu awọn ẹsẹ.
Ewo wiwomọ ẹsẹ.