ٱلۡيَوۡمَ تُجۡزَىٰ كُلُّ نَفۡسِۢ بِمَا كَسَبَتۡۚ لَا ظُلۡمَ ٱلۡيَوۡمَۚ إِنَّ ٱللَّهَ سَرِيعُ ٱلۡحِسَابِ 17
Oni ni wọn yoo san ẹsan fun gbogbo ẹmin kọọkan ni ori ohun ti o kojọ ni isẹ, ti o ba jẹ rere, ẹsan rẹ yoo jẹ rere, ti o ba jẹ aburu, ẹsan rẹ yoo jẹ aburu, ko si abosi ni ọjọ yii; nitoripe oludajọ ni Allah, onideedee, dajudaju Allah si yara ni isiro fun awọn ẹru Rẹ; nitori imọ Rẹ ti o kari gbogbo wọn.
وَأَنذِرۡهُمۡ يَوۡمَ ٱلۡأٓزِفَةِ إِذِ ٱلۡقُلُوبُ لَدَى ٱلۡحَنَاجِرِ كَٰظِمِينَۚ مَا لِلظَّٰلِمِينَ مِنۡ حَمِيمٖ وَلَا شَفِيعٖ يُطَاعُ 18
Fi dẹru ba wọn - irẹ ojisẹ - ọjọ igbende, eleyi ni igbende eyiti o sun mọ, o jẹ ohun ti o nbọ, gbogbo ohun ti o nbọ ni o ti sun mọ, ni ọjọ yii gbogbo ọkan yoo ga de ibi ogongo ẹniti o ni nitori lile ipaya rẹ, awọn ti wọn dakẹ ẹnikankan ko nii sọrọ ayaafi ẹniti ọba ajọkẹ aye ba yọnda fun, ko si si ọrẹ kankan fun awọn alabosi lati ibi ẹbọ sise ati awọn ẹsẹ, bẹẹni ko si alasunmọ, ko si tun si olusipẹ ti wọn le tẹle nigbati wọn ba yọnda fun lati sipẹ.
يَعۡلَمُ خَآئِنَةَ ٱلۡأَعۡيُنِ وَمَا تُخۡفِي ٱلصُّدُورُ 19
Allah mọ ohun ti oju awọn oluworan nde mọlẹ ni kọkọ, O si mọ ohun ti o pamọ si igbaaya, nkankan ko pamọ fun Un ninu eleyi.
وَٱللَّهُ يَقۡضِي بِٱلۡحَقِّۖ وَٱلَّذِينَ يَدۡعُونَ مِن دُونِهِۦ لَا يَقۡضُونَ بِشَيۡءٍۗ إِنَّ ٱللَّهَ هُوَ ٱلسَّمِيعُ ٱلۡبَصِيرُ 20
Allah ma nse idajọ deedee kii si se abosi si ẹnikẹni nipa dindin daadaa rẹ ku tabi lile aburu rẹ kun, sugbọn awọn ti awọn ẹlẹbọ nsin yatọ si Allah wọn kii dajọ pẹlu nkankan; nitoripe wọn ko nikapa nkankan, dajudaju Allah ni olugbọ awọn ọrọ awọn ẹru Rẹ, Oun si ni oluri awọn adisọkan wọn ati awọn isẹ wọn, yoo si san wọn lẹsan le lori.
۞أَوَلَمۡ يَسِيرُواْ فِي ٱلۡأَرۡضِ فَيَنظُرُواْ كَيۡفَ كَانَ عَٰقِبَةُ ٱلَّذِينَ كَانُواْ مِن قَبۡلِهِمۡۚ كَانُواْ هُمۡ أَشَدَّ مِنۡهُمۡ قُوَّةٗ وَءَاثَارٗا فِي ٱلۡأَرۡضِ فَأَخَذَهُمُ ٱللَّهُ بِذُنُوبِهِمۡ وَمَا كَانَ لَهُم مِّنَ ٱللَّهِ مِن وَاقٖ 21
Se awọn ẹlẹbọ wọnyi ko rin lori ilẹ ni; ki wọn le ronu si bawo ni igbẹyin awọn ijọ opurọ siwaju wọn se ri, paapaa igbẹyin wọn jẹ aburu, awọn ijọ naa le koko ni agbara ju awọn wọnyi lọ, wọn si ni oripa lorilẹ pẹlu mimọ ile eyiti awọn ile yii ko lapa rẹ, Allah si wa pa wọn run nitori awọn ẹsẹ wọn, ko si oludaabobo kankan fun wọn ti o le kọ iya Allah kuro fun wọn.
ذَٰلِكَ بِأَنَّهُمۡ كَانَت تَّأۡتِيهِمۡ رُسُلُهُم بِٱلۡبَيِّنَٰتِ فَكَفَرُواْ فَأَخَذَهُمُ ٱللَّهُۚ إِنَّهُۥ قَوِيّٞ شَدِيدُ ٱلۡعِقَابِ 22
Iya ti o sẹlẹ si wọn yii jẹ nitoripe awọn ojisẹ wọn wa ba wọn lati ọdọ Allah pẹlu awọn ẹri ti o fi oju han ati awọn awijare eyiti o gbajumọ, wọn se keferi si Allah, wọn si tun parọ mọ awọn ojisẹ Rẹ, pẹlu gbogbo agbara ti o wa pẹlu wọn, paapaa Allah gba wọn mu, O si pa wọn run, dajudaju Oun ti mimọ nbẹ fun jẹ oniya ti o lagbara fun ẹniti o ba se aimoore si I, ti o si pe awọn ojisẹ Rẹ nirọ.
Nigbati ojisẹ ti ikẹ ati ọla nbẹ fun da oju kọ irọ pipa awọn ijọ rẹ, Allah sọ nipa itan Musa pẹlu fir'aona; pe ki o le fi dun un ninu wipe dajudaju igbẹyin alamọri rẹ jẹ aranse, O wa sọpe:
وَلَقَدۡ أَرۡسَلۡنَا مُوسَىٰ بَِٔايَٰتِنَا وَسُلۡطَٰنٖ مُّبِينٍ 23
Paapaa a gbe Musa dide pẹlu awọn amin Wa eyiti o fi oju han ati awọn awijare eyiti o mu bere.
إِلَىٰ فِرۡعَوۡنَ وَهَٰمَٰنَ وَقَٰرُونَ فَقَالُواْ سَٰحِرٞ كَذَّابٞ 24
Si fir'aona ati asoju rẹ Hamana ati si Qọruna gbogbo wọn sọpe: Musa onidan opurọ nibi ohun ti npe ara rẹ wipe ojisẹ ni oun.
فَلَمَّا جَآءَهُم بِٱلۡحَقِّ مِنۡ عِندِنَا قَالُواْ ٱقۡتُلُوٓاْ أَبۡنَآءَ ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ مَعَهُۥ وَٱسۡتَحۡيُواْ نِسَآءَهُمۡۚ وَمَا كَيۡدُ ٱلۡكَٰفِرِينَ إِلَّا فِي ضَلَٰلٖ 25
Nigbati Musa mu awijare ti o tọka si ododo rẹ wa ba wọn, fir'aona sọpe: ẹ pa awọn ọmọ awọn ẹniti wọn nigbagbọ pẹlu rẹ, ẹ si sẹ awọn obinrin wọn ku ki o jẹ iyẹpẹrẹ fun wọn, ete awọn keferi lori ọrọ naa pẹlu dindin onka awọn olugbagbọ ododo ko jẹ nkankan ayaafi iparun ti yoo lọ, ko si oripa fun un.
Riranni leti ọjọ igbende wa ninu ọna ti o tobi ju lati dẹru bani kuro nibi ẹsẹ.
Kikari imọ allah si gbogbo isẹ awọn ẹda Rẹ; o pamọ ni tabi o hande.
Pipasẹ ririn lorilẹ lati gba isiti pẹlu isesi awọn ẹlẹbọ awọn ti wọn parun.