ٱصۡبِرۡ عَلَىٰ مَا يَقُولُونَ وَٱذۡكُرۡ عَبۡدَنَا دَاوُۥدَ ذَا ٱلۡأَيۡدِۖ إِنَّهُۥٓ أَوَّابٌ 17
Se suuru - irẹ ojisẹ - lori ohun ti awọn olupurọ yii nsọ ninu ohun ti ko yọ ọ ninu, ki o si ranti ẹru wa daud alagbara lati le fi ga gbaga pẹlu awọn ọta rẹ ati suuru lori itẹle ti Allah, o jẹ ẹniti o ma nsẹri lọ si ọdọ Allah ni ọpọ pẹlu ironu piwada ati sise ohun ti yoo ma yọ ninu.
إِنَّا سَخَّرۡنَا ٱلۡجِبَالَ مَعَهُۥ يُسَبِّحۡنَ بِٱلۡعَشِيِّ وَٱلۡإِشۡرَاقِ 18
Dajudaju awa rọ oke fun dawud, ti o nse afọmọ lati ibi isafọmọ rẹ nigbati o ba nse afọmọ ni igbẹyin ẹsan ati akọkọ rẹ ni igba yiyọ oorun.
وَٱلطَّيۡرَ مَحۡشُورَةٗۖ كُلّٞ لَّهُۥٓ أَوَّابٞ 19
A si tun rọ ẹyẹ ti a daabobo si inu atẹgun, gbogbo jẹ olutẹle ti wọn si nse afọmọ niti titẹle e.
وَشَدَدۡنَا مُلۡكَهُۥ وَءَاتَيۡنَٰهُ ٱلۡحِكۡمَةَ وَفَصۡلَ ٱلۡخِطَابِ 20
A fun ọla rẹ lagbara lati ibi ọwọ ti a fi ta a lọrẹ ati agbara ati aranse lori awọn ọta rẹ, a si tun ni jijẹ anọbi ati kongẹ nibi alamọri rẹ, a tun fun ni alaye ti o pe nibi gbogbo erongba ati ẹkunrẹrẹ nibi ọrọ ati idajọ.
۞وَهَلۡ أَتَىٰكَ نَبَؤُاْ ٱلۡخَصۡمِ إِذۡ تَسَوَّرُواْ ٱلۡمِحۡرَابَ 21
Njẹ o wa ba ọ - irẹ ojisẹ - iro awọn onija meji kan nigbati wọn rapala lọ si ọdọ dawud ẹniti ọla nbẹ fun nibi aaye ijọsin rẹ.
إِذۡ دَخَلُواْ عَلَىٰ دَاوُۥدَ فَفَزِعَ مِنۡهُمۡۖ قَالُواْ لَا تَخَفۡۖ خَصۡمَانِ بَغَىٰ بَعۡضُنَا عَلَىٰ بَعۡضٖ فَٱحۡكُم بَيۡنَنَا بِٱلۡحَقِّ وَلَا تُشۡطِطۡ وَٱهۡدِنَآ إِلَىٰ سَوَآءِ ٱلصِّرَٰطِ 22
Nigbati wọn wọle ti dawud ni ojiji, o wa jaya nibi wiwọle awọn mejeeji ni ọna yii ti wọn ko barẹ lati gbawọle, nigbati ijaya rẹ han si awọn mejeeji, o sọpe: mase bẹru; awa jẹ onija meji, ti ẹnikan ninu wa se abosi ẹnikeji, se idajọ laarin wa pẹlu deedee, ma si se fi si ibikan nigbati o ba dajọ laarin wa, ki o si tọ wa si oju ọna eyiti o dọgba eyiti o jẹ oju ọna ti se deedee.
إِنَّ هَٰذَآ أَخِي لَهُۥ تِسۡعٞ وَتِسۡعُونَ نَعۡجَةٗ وَلِيَ نَعۡجَةٞ وَٰحِدَةٞ فَقَالَ أَكۡفِلۡنِيهَا وَعَزَّنِي فِي ٱلۡخِطَابِ 23
Ọkan ninu awọn oluja meji sọ fun Dawud ẹniti ọla nbẹ fun: dajudaju arakunrin yii jẹ ọmọ iya mi, o ni aadọrun din ni ẹyọkan agutan, emi si ni agutan kan, o tun wa nwa lọdọ mi ki nfun ni ẹyọkan naa, o si bori mi nibi awijare.
قَالَ لَقَدۡ ظَلَمَكَ بِسُؤَالِ نَعۡجَتِكَ إِلَىٰ نِعَاجِهِۦۖ وَإِنَّ كَثِيرٗا مِّنَ ٱلۡخُلَطَآءِ لَيَبۡغِي بَعۡضُهُمۡ عَلَىٰ بَعۡضٍ إِلَّا ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَعَمِلُواْ ٱلصَّٰلِحَٰتِ وَقَلِيلٞ مَّا هُمۡۗ وَظَنَّ دَاوُۥدُ أَنَّمَا فَتَنَّٰهُ فَٱسۡتَغۡفَرَ رَبَّهُۥ وَخَرَّۤ رَاكِعٗاۤ وَأَنَابَ۩ 24
Dawud dajọ laarin awọn mejeeji, o wa sọrọ ni ẹniti o nda oju kọ ẹniti o npe apemọra yii: ọmọ iya rẹ ti se abosi rẹ nigbati o bi ọ leere ki o mu ẹran kan rẹ wa sibi awọn ẹran tirẹ, bẹẹni dajudaju ọpọ ninu awọn olubanisepọ apakan wọn ma nkọja ẹnu aala si apakan pẹlu ki o gba ẹtọ rẹ, ki o si mase dọgbandọgba ayaafi awọn olugbagbọ ododo ti nse awọn isẹẹre, awọn ni wọn ma nse dọgba pẹlu akẹgbẹ wọn, ti wọn kii se abosi si wọn, sugbọn awọn ti o gba iru iroyin yii kere, dawud mọ amọdaju ẹniti ọla nbẹ fun wipe dajudaju a ko sinu idaamun pẹlu ija yii ni, o wa wa aforijin ni ọdọ Ọlọhun rẹ, o wa fi orikanlẹ niti isunmọ Allah, o si sẹri lọ si ọdọ Rẹ.
فَغَفَرۡنَا لَهُۥ ذَٰلِكَۖ وَإِنَّ لَهُۥ عِندَنَا لَزُلۡفَىٰ وَحُسۡنَ مََٔابٖ 25
Awa da lohun, a si fi ori eleyi jin in, dajudaju o wa ninu awọn olusunmọ ni ọdọ Wa, o si tun ni ibusẹri si daadaa ni ọrun.
يَٰدَاوُۥدُ إِنَّا جَعَلۡنَٰكَ خَلِيفَةٗ فِي ٱلۡأَرۡضِ فَٱحۡكُم بَيۡنَ ٱلنَّاسِ بِٱلۡحَقِّ وَلَا تَتَّبِعِ ٱلۡهَوَىٰ فَيُضِلَّكَ عَن سَبِيلِ ٱللَّهِۚ إِنَّ ٱلَّذِينَ يَضِلُّونَ عَن سَبِيلِ ٱللَّهِ لَهُمۡ عَذَابٞ شَدِيدُۢ بِمَا نَسُواْ يَوۡمَ ٱلۡحِسَابِ 26
Irẹ Dawud Awa ni A sọ ọ di arole lorilẹ, ti o nmu awọn idajọ sẹ ati awọn ofin ẹsin ati ti aye, ki o ya maa dajọ laarin awọn eniyan pẹlu deedee, ki o si mase tẹle ifẹ inu nibi idajọ rẹ laarin awọn eniyan; pẹlu ki o fi si ọdọ ẹnikan ninu awọn onija meji nitori isunmọ tabi ijọrẹ tabi ki o yẹ kuro ni ọdọ rẹ nitori ibasọta, ki ifẹ inu maa ba sọ ọ nu kuro ni oju ọna Allah ti o duro tọ, dajudaju awọn ti o sọnu kuro ni oju ọna Allah ti o duro tọ, iya ti o lagbara nbẹ fun nitori igbagbe wọn nipa ọjọ isiro; nitoripe ti wọn ba ranti rẹ ni, ti wọn si npaya ọjọ naa, wọn ko ba ti fi si ibi awọn ifẹ inu wọn.
Sise alaye awọn ọla anọbi Allah tii se dawud ati awọn amin ti Allah fi sa a lẹsa.
Awọn anọbi - ti awọn ikẹ Allah ati ọla Rẹ nbẹ fun wọn - jẹ ẹni idaabobo kuro nibi asise nipa ohun ti wọn nmude etigbọ lati ọdọ Allah ti O ga; nitoripe ohun ti a gbero nibi isẹ riran ko le sẹlẹ ayaafi pẹlu rẹ, sugbọn apakan awọn isẹlẹ adamọ le sẹlẹ lati ọdọ wọn gẹgẹ bi igbagbe tabi ifọnu nipa idajọ sugbọn Allah ma nmu wọn lepa ba a, O si ma nfi aanu Rẹ le wọn ba.
Apakan awọn onimimọ fi gbolohun Rẹ ti o ga se ẹri (وَإِنَّ كَثِيرٗا مِّنَ ٱلۡخُلَطَآءِ لَيَبۡغِي بَعۡضُهُمۡ عَلَىٰ بَعۡضٍ) (atipe dajudaju ọpọ ninu awọn alajọsepọ paapaa apakan wọn a maa kọja ẹnu aala si apa miran) lori sise lofin ajọsepọ laarin eniyan meji tabi ju bẹẹ lọ.
Dandan ni ki a dunni mọ ẹkọ nibi wiwọ ile awọn ọlọla tabi awọn onipo.