وَمَآ أَصَٰبَكُمۡ يَوۡمَ ٱلۡتَقَى ٱلۡجَمۡعَانِ فَبِإِذۡنِ ٱللَّهِ وَلِيَعۡلَمَ ٱلۡمُؤۡمِنِينَ 166
Ati wipe ohun ti o sẹlẹ si yin ninu pipa ati sisa ni ọgbọẹ ati jijẹ-ọja ni Ọjọ Uhud, nigbati akojọ yin ati akojọ awọn ọsẹbọ pade, o wa pẹlu iyọnda Ọlọhun Ọba Allah ati kadara Rẹ ni, nitori ọgba kan ti o de ogongo titi ti Ọlọhun Ọba Allah yoo fi se afihan awọn olugbagbọ ododo ti wọn jẹ olu sọ ododo.
وَلِيَعۡلَمَ ٱلَّذِينَ نَافَقُواْۚ وَقِيلَ لَهُمۡ تَعَالَوۡاْ قَٰتِلُواْ فِي سَبِيلِ ٱللَّهِ أَوِ ٱدۡفَعُواْۖ قَالُواْ لَوۡ نَعۡلَمُ قِتَالٗا لَّٱتَّبَعۡنَٰكُمۡۗ هُمۡ لِلۡكُفۡرِ يَوۡمَئِذٍ أَقۡرَبُ مِنۡهُمۡ لِلۡإِيمَٰنِۚ يَقُولُونَ بِأَفۡوَٰهِهِم مَّا لَيۡسَ فِي قُلُوبِهِمۡۚ وَٱللَّهُ أَعۡلَمُ بِمَا يَكۡتُمُونَ 167
Ki O le se afihan awọn oloju-eji, awọn ti o jẹ wipe nigbati wọn sọ fun wọn wipe ẹ jagun si oju ọna Ọlọhun Ọba Allah, tabi ki ẹ se idaabobo pẹlu ki ẹ jẹ ki akojọ awọn olugbagbọ ododo pọ si; wọn sọ wipe: ti a ba mọ wipe dajudaju ogun yoo waye ni, a ko ba tẹle yin, sugbọn awa, a ko ri wipe dajudaju ogun yoo waye laarin yin ati laarin awọn ijọ naa, awọn nibi isesi wọn nigba naa sun mọ oun ti o ntọka si aini igbagbọ wọn ju oun ti o ntọka si ini igbagbọ wọn lọ, wọn yoo waa maa sọ lenu wọn oun ti ko si ninu awọn ọkan wọn, ati wipe Ọlọhun Ọba Allah ni O ni imọ julọ si oun ti wọn fi pamọ si awọn igbaaya wọn, ati wipe yoo pada jẹ wọn niya lori rẹ.
ٱلَّذِينَ قَالُواْ لِإِخۡوَٰنِهِمۡ وَقَعَدُواْ لَوۡ أَطَاعُونَا مَا قُتِلُواْۗ قُلۡ فَٱدۡرَءُواْ عَنۡ أَنفُسِكُمُ ٱلۡمَوۡتَ إِن كُنتُمۡ صَٰدِقِينَ 168
Awọn ni awọn ti wọn sa sẹyin fun ogun ati wipe wọn waa sọ fun awọn alasunmọ wọn awọn ti ọwọ ba ni Ọjọ Uhud wipe: ti o ba jẹ wipe dajudaju awọn tẹle wa ni, ati wipe ti wọn ko jade lati lọ jagun, wọn ko ba ti pa wọn, sọ -irẹ Anọbi- ni ẹniti nda ọrọ pada fun wọn wipe: ẹ kọ di iku fun ẹmin ara yin nigbati wọn ba sọkalẹ pẹlu yin, ti o ba jẹ wipe ẹ jẹ ẹniti o sọ ododo nibi ohun ti ẹ npe apemọra rẹ, nibi wipe dajudaju awọn ti wọn ba tẹle yin, wọn ko nii pa wọn, ati wipe dajudaju okunfa iyege yin nibi iku ni jijoko tẹtẹrẹ nibi jijagun si oju ọna Ọlọhun Ọba Allah.
وَلَا تَحۡسَبَنَّ ٱلَّذِينَ قُتِلُواْ فِي سَبِيلِ ٱللَّهِ أَمۡوَٰتَۢاۚ بَلۡ أَحۡيَآءٌ عِندَ رَبِّهِمۡ يُرۡزَقُونَ 169
Ati wipe mase lero - irẹ Anọbi - pe dajudaju awọn ti wọn pa si oju ogun, si oju ọna Ọlọhun Ọba Allah, pe awọn oku ni, bikose wipe awọn jẹ alaaye, ti o sẹmi kan, ti o da yatọ ni ọdọ Ọlọhun Ọba wọn ni inu ile alapọnle Rẹ, ti O nse ijẹ-imu fun wọn ninu awọn oniranran idẹra eyiti ko lee nimọ npa rẹ ayaafi Ọlọhun Ọba Allah.
فَرِحِينَ بِمَآ ءَاتَىٰهُمُ ٱللَّهُ مِن فَضۡلِهِۦ وَيَسۡتَبۡشِرُونَ بِٱلَّذِينَ لَمۡ يَلۡحَقُواْ بِهِم مِّنۡ خَلۡفِهِمۡ أَلَّا خَوۡفٌ عَلَيۡهِمۡ وَلَا هُمۡ يَحۡزَنُونَ 170
Paapaa oriire ti bo wọn daru, idunnu si ti ko wọn jọ pẹlu ohun ti Ọlọhun Ọba allah fi se idẹkun fun wọn ninu ọla Rẹ, ati wipe wọn nlero, wọn si tun nreti ki awọn ọmọ iya wọn ti wọn sẹku ni aye waa lepa ba wọn, pe dajudaju awọn ti wọn ba pa wọn so oju ogun, ọwọ wọn naa yoo pada tẹ ninu ọla iru ti wọn, ati wipe ko si ibẹru fun wọn nibi ohun ti wọn da oju kọ ninu alamọri Ọjọ Ikẹyin, ati wipe awọn ko nii maa banujẹ lori ohun ti o bọ fun wọn ninu awọn erenjẹ aye.
۞يَسۡتَبۡشِرُونَ بِنِعۡمَةٖ مِّنَ ٱللَّهِ وَفَضۡلٖ وَأَنَّ ٱللَّهَ لَا يُضِيعُ أَجۡرَ ٱلۡمُؤۡمِنِينَ 171
Ati wipe wọn yoo maa dunnu pẹlu eleyi pẹlu ẹsan ti o tobi ti o nreti wọn lati ọdọ Ọlọhun Ọba Allah, ati alekun kan lori ẹsan ti o tobi, ati wipe Oun (ti ọla Rẹ ga) ko nii ba ẹsan awọn olugbagbọ ododo pẹlu Rẹ jẹ, bikose wipe Yoo pe awọn ẹsan wọn fun wọn ni perepere, ati wipe Yoo si tun se alekun wọn lori rẹ.
ٱلَّذِينَ ٱسۡتَجَابُواْ لِلَّهِ وَٱلرَّسُولِ مِنۢ بَعۡدِ مَآ أَصَابَهُمُ ٱلۡقَرۡحُۚ لِلَّذِينَ أَحۡسَنُواْ مِنۡهُمۡ وَٱتَّقَوۡاْ أَجۡرٌ عَظِيمٌ 172
Awọn ti wọn dahun fun asẹ Ọlọhun Ọba Allah ati ojisẹ Rẹ nigbati wọn pe wọn lọsi ibi jijade fun ogun si oju ọna Ọlọhun Ọba Allah, ati lati lọ pade awọn ọsẹbọ nibi ogun (Hamrọọrul asad) eyiti o gbẹyin Uhud, lẹyin igbati ọgbẹ ti ba wọn ni Ọjọ Uhud, ti awọn ọgbẹ wọn ko si kọ fun wọn nibi jijẹpe ipe Ọlọhun Ọba Allah ati ojisẹ Rẹ, yoo maa bẹ fun ti wọn se daadaa ninu wọn nibi awọn isẹ wọn, ti wọn si tun npaya Ọlọhun Ọba Allah pẹlu mimu awọn asẹ Rẹ wa si imusẹ, ati jijinna si awọn ohun ti O kọ, ẹsan ti o tobi lati ọdọ Ọlọhun Ọba Allah, ohun naa ni Alujanna.
ٱلَّذِينَ قَالَ لَهُمُ ٱلنَّاسُ إِنَّ ٱلنَّاسَ قَدۡ جَمَعُواْ لَكُمۡ فَٱخۡشَوۡهُمۡ فَزَادَهُمۡ إِيمَٰنٗا وَقَالُواْ حَسۡبُنَا ٱللَّهُ وَنِعۡمَ ٱلۡوَكِيلُ 173
Awọn ti awọn kan ninu awọn ọsẹbọ sọ fun wipe: dajudaju awọn Kuraeṣhi pẹlu idari baba Sufiyaan, paapaa wọn ti ko jọ fun yin akojọ ti o pọ lati ba yin ja, ati lati bori yin, ẹ ya sọra fun wọn, ki ẹ si tun paya pipade wọn, ni ọrọ yii ati idẹru bani yii waa le wọn kun ni isododo pẹlu Ọlọhun Ọba Allah ati nini igbẹkẹle nibi adehun Rẹ, ni wọn waa jade lati lọ pade wọn, ni ẹniti wọn wa nsọ wipe: Ọlọhun Ọba (ti ọla Rẹ ga) to wa, ati wipe Oun ni Ẹniti O dara lati fi alamọri wa ti si lọdọ.
Ninu awọn ilana Ọlọhun Ọba Allah (ti ọla Rẹ ga) ni ko dan awọn ẹrusin Rẹ wo; ki awọn olugbagbọ ododo ni tootọ le ba yatọ si awọn oloju-eji, ati ki wọn le ba mọ olododo ninu onirọ.
Titobi ipo jijagun ati kiku si oju ọna Ọlọhun Ọba Allah ati ẹsan awọn ti wọn ba se bẹẹ ni ọdọ Ọlọhun Ọba Allah (ti ọla Rẹ ga) ni ibi ti Ọlọhun Ọba Allah (ti ọla Rẹ ga) yoo ti sọ wọn kalẹ si eyiti o ga ju ninu awọn aaye.
Ọla awọn ọmọlẹyin Anọbi ati alaye giga ipo wọn ni aye ati ni ọrun, nitori ohun ti wọn na ninu awọn ẹmin wọn ati awọn dukia wọn si oju ọna Ọlọhun Ọba Allah (ti ọla Rẹ ga) .