إِنَّ فِي خَلۡقِ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِ وَٱخۡتِلَٰفِ ٱلَّيۡلِ وَٱلنَّهَارِ وَٱلۡفُلۡكِ ٱلَّتِي تَجۡرِي فِي ٱلۡبَحۡرِ بِمَا يَنفَعُ ٱلنَّاسَ وَمَآ أَنزَلَ ٱللَّهُ مِنَ ٱلسَّمَآءِ مِن مَّآءٖ فَأَحۡيَا بِهِ ٱلۡأَرۡضَ بَعۡدَ مَوۡتِهَا وَبَثَّ فِيهَا مِن كُلِّ دَآبَّةٖ وَتَصۡرِيفِ ٱلرِّيَٰحِ وَٱلسَّحَابِ ٱلۡمُسَخَّرِ بَيۡنَ ٱلسَّمَآءِ وَٱلۡأَرۡضِ لَأٓيَٰتٖ لِّقَوۡمٖ يَعۡقِلُونَ 164
Dajudaju o nbẹ nibi dida awọn sanmọ ati ilẹ ati ohun ti nbẹ ninu mejeeji ninu awọn ẹda ti o yani lẹnu, o si nbẹ ninu titẹle ti oru ati ọsan ntẹle ara wọn, ati ninu ọkọ oju omi eyiti o nlọ nibi omin ibudo, ti o ngbe ohun ti yoo maa se awọn eniyan ni anfaani ninu ounjẹ ati asọ ati nkan owo ati awọn nkan ti o yatọ si ninu awọn nkan ti wọn ni bukaata si, o si nbẹ ninu ohun ti Ọlọhun Ọba Allah sọkalẹ lati sanmọ ninu omi eyiti O fi ma nji ilẹ pẹlu ohun ti yoo maa hu jade ninu ọgbin ati koriko ati ninu ohun ti o fanka silẹ ninu awọn nkan ti o nbẹ, ti o si nsẹmi, o si nbẹ ninu didari atẹgun lati agbegbe kan si agbegbe kan, ati ninu ẹsujo eyiti A rọọ laarin sanmọ ati ilẹ, dajudaju o nbẹ ninu gbogbo nkan naa awọn itọka ti o fi oju han lori ijọkan soso Rẹ, mimọ fun Un, fun ẹniti o ba le ronu si awọn awijare, ti o si le gbọ awọn ẹri ati awọn awijare ye.
وَمِنَ ٱلنَّاسِ مَن يَتَّخِذُ مِن دُونِ ٱللَّهِ أَندَادٗا يُحِبُّونَهُمۡ كَحُبِّ ٱللَّهِۖ وَٱلَّذِينَ ءَامَنُوٓاْ أَشَدُّ حُبّٗا لِّلَّهِۗ وَلَوۡ يَرَى ٱلَّذِينَ ظَلَمُوٓاْ إِذۡ يَرَوۡنَ ٱلۡعَذَابَ أَنَّ ٱلۡقُوَّةَ لِلَّهِ جَمِيعٗا وَأَنَّ ٱللَّهَ شَدِيدُ ٱلۡعَذَابِ 165
Pẹlu awọn amin ti o han yii, o nbẹ ninu awọn eniyan, ẹniti ti o mu nkan miran ni Ọlọhun Ọba Allah lẹyin Ọlọhun Ọba Allah, ti wọn yoo si maa fi wọn kẹgbẹ Ọlọhun Ọba Allah (ti ọla Rẹ ga) , ti wọn yoo si maa nifẹ wọn gẹgẹ bi wọn se nnifẹ Ọlọhun Ọba Allah, ẹ ko ri awọn ni ni igbagbọ ododo, awọn ni wọn nifẹ Ọlọhun Ọba Allah ju awọn wọnyi lọ si awọn ohun ti wọn njọsin fun un; toripe awọn ko nii mu ororgun kankan pẹlu Ọlọhun Ọba Allah, wọn yoo si maa nifẹ Rẹ ninu idunnu ati inira, ẹ ko ri awọn wọn nni, dajudaju awọn nifẹ awọn oosa wọn, nigba idẹkun sugbọn nigba inira, wọn ko nii pe ẹnikankan ayaafi Ọlọhun Ọba Allah. Tobajẹ wipe awọn alabosi ri pẹlu iwa orogun wọn ati mima dẹsẹ wọn isesi wọn ni Ọjọ Ikẹyin nigbati wọn yoo maa ri iya ni oju koroju; wọn ko ba mọ wipe Ẹniti gbogbo agbara nbẹ lọwọ nikan Ọlọhun Ọba Allah, ati dajudaju wipe Oun ni Ẹniti iya Rẹ le koko fun ẹniti o ba sẹ Ẹ, tobajẹ wipe wọn ri nkan naa ni, wọn ko ba ti mu orogun kankan pẹlu Ọlọhun Ọba Allah.
إِذۡ تَبَرَّأَ ٱلَّذِينَ ٱتُّبِعُواْ مِنَ ٱلَّذِينَ ٱتَّبَعُواْ وَرَأَوُاْ ٱلۡعَذَابَ وَتَقَطَّعَتۡ بِهِمُ ٱلۡأَسۡبَابُ 166
Nkan naa yoo maa sẹlẹ nigbati awọn olori ba nyọwọ kuro lọdọ awọn ti wọn tẹle wọn ninu awọn ọlẹ ti wọn ntẹle wọn; nitori ohun ti wọn yoo maa ri ni oju koroju ninu awọn ibẹru ọjọ igbende ati awọn ilekoko rẹ, ti gbogbo okunfa ti o le mu wọn la si ti ja ati awọn oju ọna rẹ.
وَقَالَ ٱلَّذِينَ ٱتَّبَعُواْ لَوۡ أَنَّ لَنَا كَرَّةٗ فَنَتَبَرَّأَ مِنۡهُمۡ كَمَا تَبَرَّءُواْ مِنَّاۗ كَذَٰلِكَ يُرِيهِمُ ٱللَّهُ أَعۡمَٰلَهُمۡ حَسَرَٰتٍ عَلَيۡهِمۡۖ وَمَا هُم بِخَٰرِجِينَ مِنَ ٱلنَّارِ 167
Awọn ọlẹ yoo maa sọ ati awọn olutẹle wipe: o ma se fun wa ti a ko le pada si ile aye, a o si bọpa-bọsẹ kuro ni ọdọ awọn olori wa gẹgẹ bi awọn naa se bọpa-bọsẹ kuro ni ọdọ wa, ati gẹgẹ bi Ọlọhun Ọba Allah se fi iya ti o le han wọn ni Ọjọ Ikẹyin, Ni Yoo si fi han wọn, igbẹyin titẹle awọn olori wọn lori anu, awọn abamọ ati awọn ibanujẹ wọn ko si nii jade lailai kuro ninu ina.
يَٰٓأَيُّهَا ٱلنَّاسُ كُلُواْ مِمَّا فِي ٱلۡأَرۡضِ حَلَٰلٗا طَيِّبٗا وَلَا تَتَّبِعُواْ خُطُوَٰتِ ٱلشَّيۡطَٰنِۚ إِنَّهُۥ لَكُمۡ عَدُوّٞ مُّبِينٌ 168
Ẹyin eniyan, ẹ maa jẹ ninu ohun ti nbẹ ni ilẹ ninu ẹranko ati irugbin ati igi nibi ohun ti ọwọ rẹ ba tẹ ni ẹtọ, ti o si dara ninu ẹmin rẹ, ti ko si jẹ ẹlẹgbin, ki ẹ si ma se tẹle awọn ilana eso eyiti o fi ndẹ yin, dajudaju oun jẹ ọta ti isọta rẹ fi oju han fun yin, ko si ni ẹtọ fun ẹniti o ba ni laakaye, ki o tẹle ọta rẹ eyiti o nse oju kokoro lati fi suta kan ati sisọọnu.
إِنَّمَا يَأۡمُرُكُم بِٱلسُّوٓءِ وَٱلۡفَحۡشَآءِ وَأَن تَقُولُواْ عَلَى ٱللَّهِ مَا لَا تَعۡلَمُونَ 169
Oun, dajudaju yoo ma pa yin lasẹ pẹlu ohun ti o buru ninu awọn ẹsẹ ati eyiti o tobi ninu awọn ẹsẹ, ati ki ẹ maa sọ nipa Ọlọhun Ọba Allah nibi awọn adisọkan ati awọn ofin laini imọ kankan ti o waa ba yin lati ọdọ Ọlọhun Ọba Allah tabi awọn ojisẹ Rẹ.
Awọn ti wọn gba Ọlọhun Ọba Allah gbọ lododo, ni awọn ẹda ti ifẹ wọn tobi ju si Ọlọhun Ọba Allah, toripe awọn ma ntẹle ni gbogbo isesi ninu idẹkun ati ninu inira, wọn ko si nii mu ẹnikankan ni orogun pẹlu Rẹ.
Ni Ọjọ Igbende, gbogbo awọn asopọ ni yoo ja danu, ti gbogbo ọrẹ yoo si maa bọpa-bọsẹ kuro ni ọdọ ọrẹ rẹ, ti ko si nii sẹku ayaafi ohun ti o ba jẹ afọmọ fun Ọlọhun Ọba Allah (ti ọla Rẹ ga) .
Ikilọ fun ni nibi ete esu nitori oniranran awọn ọna rẹ ati pipamọ rẹ ati sisunmọ rẹ mọ awọn ohun ti ẹmin fẹ.