وَقَطَّعۡنَٰهُمُ ٱثۡنَتَيۡ عَشۡرَةَ أَسۡبَاطًا أُمَمٗاۚ وَأَوۡحَيۡنَآ إِلَىٰ مُوسَىٰٓ إِذِ ٱسۡتَسۡقَىٰهُ قَوۡمُهُۥٓ أَنِ ٱضۡرِب بِّعَصَاكَ ٱلۡحَجَرَۖ فَٱنۢبَجَسَتۡ مِنۡهُ ٱثۡنَتَا عَشۡرَةَ عَيۡنٗاۖ قَدۡ عَلِمَ كُلُّ أُنَاسٖ مَّشۡرَبَهُمۡۚ وَظَلَّلۡنَا عَلَيۡهِمُ ٱلۡغَمَٰمَ وَأَنزَلۡنَا عَلَيۡهِمُ ٱلۡمَنَّ وَٱلسَّلۡوَىٰۖ كُلُواْ مِن طَيِّبَٰتِ مَا رَزَقۡنَٰكُمۡۚ وَمَا ظَلَمُونَا وَلَٰكِن كَانُوٓاْ أَنفُسَهُمۡ يَظۡلِمُونَ 160
A pin awọn isirẹla si idile mejila, a si ransẹ si musa nigbati awọn ijọ rẹ beere lọwọ rẹ wipe ki o bẹ Ọlọhun Ọba pe ki o fun awọn ni omin: pi ọpa rẹ lu - irẹ Musa - okuta naa, musa si fi lu, ibusun mejila si sẹ jade ni deedee onka idile mejila, gbogbo idile kọọkan ti mọ ibimumin rẹ ti a sa lẹsa fun un, idile miran ko le ba kẹgbẹ nibẹ, a si fi ẹsu ojo si oke wọn, ti nrin bi awọn naa ti nrin, o si nduro bi wọn ti nduro, a sọ idẹkun wa ninu nkan mimu ti o dun le wọn lori, gẹgẹ bi oyin, ẹyẹ kekere ti ẹran rẹ dun, ti o jọ ẹyẹ “As-sumaani”, awa sọ fun wọn wipe ẹ maa jẹ ninu nkan mimọ ti a se fun yin, ako din nkankan ku fun wọn pẹlu abosi ati aimoore si idẹkun wa ti o sẹlẹ ni ọdọ wọn, ati aika nkan ti a se fun wọn kun nkan ti o se pataki sugbọn ẹmin ara wọn ni wọn se abosi si pẹlu dindin ẹtọ wọn ku, nitori mimu lọ si ibi iparun pẹlu yiyapa asẹ Ọlọhun Ọba, ati aika idẹkun Rẹ kun.
وَإِذۡ قِيلَ لَهُمُ ٱسۡكُنُواْ هَٰذِهِ ٱلۡقَرۡيَةَ وَكُلُواْ مِنۡهَا حَيۡثُ شِئۡتُمۡ وَقُولُواْ حِطَّةٞ وَٱدۡخُلُواْ ٱلۡبَابَ سُجَّدٗا نَّغۡفِرۡ لَكُمۡ خَطِيٓـَٰٔتِكُمۡۚ سَنَزِيدُ ٱلۡمُحۡسِنِينَ 161
Ranti - ire ojise - nigbati Ọlọhun Ọba Allah sọ fun awọn ọmọ isirẹli: ẹ wọ ilu Kudusi, ki ẹ si maa jẹ ninu esi abule bẹ ni eyikeyi aaye nibẹ ati ni asiko ki asiko ti ẹ ba fẹ, ki ẹ wa maa sọ wipe: irẹ Ọlọhun Ọba wa, pa awọn asise wa rẹ, ki ẹ si wọ ẹnu ọna naa ni ẹniti ntẹriba fun Ọlọhun Ọba yin; ti ẹ ba se eleyi, a o se amojukuro ẹsẹ yin, awa yoo si se aleekun oore aye ati ti ọrun fun awọn oluse daradara.
فَبَدَّلَ ٱلَّذِينَ ظَلَمُواْ مِنۡهُمۡ قَوۡلًا غَيۡرَ ٱلَّذِي قِيلَ لَهُمۡ فَأَرۡسَلۡنَا عَلَيۡهِمۡ رِجۡزٗا مِّنَ ٱلسَّمَآءِ بِمَا كَانُواْ يَظۡلِمُونَ 162
Awọn alabosi ninu wọn si yi ọrọ ti wọn pa wọn lasẹ pada, wọn si sọ wipe: horo shẹiru kan ni ifidipo nkan ti wọn pa wọn lasẹ ki wọn wa aforijin, wọn si yin gbolohun isẹ eyiti wọn pa wọn lasẹ rẹ, wọn si wọle ni idifunfun lati ẹyin dipo wiwọle ni itẹriba fun Ọlọhun Ọba ni ẹniti yoo so ori kọ, a si ransẹ iya si wọn lati sanmọ nitori abosi wọn.
وَسَۡٔلۡهُمۡ عَنِ ٱلۡقَرۡيَةِ ٱلَّتِي كَانَتۡ حَاضِرَةَ ٱلۡبَحۡرِ إِذۡ يَعۡدُونَ فِي ٱلسَّبۡتِ إِذۡ تَأۡتِيهِمۡ حِيتَانُهُمۡ يَوۡمَ سَبۡتِهِمۡ شُرَّعٗا وَيَوۡمَ لَا يَسۡبِتُونَ لَا تَأۡتِيهِمۡۚ كَذَٰلِكَ نَبۡلُوهُم بِمَا كَانُواْ يَفۡسُقُونَ 163
Beere - ire ojise - lọwọ yahuudi ni ẹniti nse iranti fun wọn lori ohun ti Ọlọhun Ọba Allah fi se igbẹyin awọn ti wọn siwaju wọn nipa itan abule kan ti o sun mọ ẹgbẹ odo ti nsan, nigbati wọn kọja ẹnu aala nibi didẹdẹ ni ọjọ asibi, lẹyin igbati wọn ti kọ fun wọn kuro nibẹ, nigbati Ọlọhun Ọba Allah dan wọn wo pẹlu ki awọn ẹja wọn bọ si ori omin ni ọjọ asibi, ti ko si nii wa ni awọn ọjọ yoku, Ọlọhun Ọba Allah dan wọn wo pẹlu eleyi nitori wọn kuro nibi itẹle asẹ, wọn si nda ẹsẹ, wọn ndẹdẹ pẹlu jiju awọn si inu omin, wọn si gbẹ koto ki awọn ẹja le maa bọ si ibẹ ni ọjọ asibi, ti o ba di ọjọ alaadi, wọn yoo mu, ti wọn yoo si jẹ.
Ijiyan ati sise aimoore jẹ idina idẹkun.
Ninu awọn nini ẹtọ si iya ati sisọkalẹ rẹ ni mima dete nibi ofin; toripe o jẹ abosi ati ikẹja ẹnu aala Ọlọhun Ọba Allah.