كَذَّبَتۡ قَوۡمُ لُوطٍ ٱلۡمُرۡسَلِينَ 160
Ijọ Luth pe awọn ojisẹ nirọ nitori pipe anọbi wọn ẹniti ọla nbẹ fun nirọ.
إِذۡ قَالَ لَهُمۡ أَخُوهُمۡ لُوطٌ أَلَا تَتَّقُونَ 161
Nigbati ọmọ iya wọn Luth sọ fun wipe: se ẹ ko paya Allah pẹlu gbigbe sinsin ẹlomiran ti o yatọ si I ju silẹ niti ibẹru Rẹ ni?!
إِنِّي لَكُمۡ رَسُولٌ أَمِينٞ 162
Dajudaju mo jẹ ojisẹ fun yin, Ọlọhun Ọba Allah ran mi si yin, ẹni ifọkantan nibi ohun ti mo nmu de etigbọ yin, nko ni le kun, bẹẹni nko ni din ku.
فَٱتَّقُواْ ٱللَّهَ وَأَطِيعُونِ 163
Ki ẹ paya Allah pẹlu titẹle awọn asẹ Rẹ ati jijinna si awọn nkan ti o kọ, ki ẹ si tẹle mi nibi ohun ti mo ba payin lasẹ ati ohun ti mo kọ fun yin.
وَمَآ أَسَۡٔلُكُمۡ عَلَيۡهِ مِنۡ أَجۡرٍۖ إِنۡ أَجۡرِيَ إِلَّا عَلَىٰ رَبِّ ٱلۡعَٰلَمِينَ 164
Nko si wa ẹsan lori ounti mo fi to yin leti lati ọdọ Ọlọhun Ọba mi, ẹsan ko wa ayaafi lati ọdọ Ọlọhun Ọba Olutọju gbogbo ẹda, kii se lati ọdọ ẹlomiran.
أَتَأۡتُونَ ٱلذُّكۡرَانَ مِنَ ٱلۡعَٰلَمِينَ 165
Se ẹ o maa ba awọn ọkunrin ninu awọn eniyan lo ni lati ẹyin wọn ni?!
وَتَذَرُونَ مَا خَلَقَ لَكُمۡ رَبُّكُم مِّنۡ أَزۡوَٰجِكُمۚ بَلۡ أَنتُمۡ قَوۡمٌ عَادُونَ 166
Ẹ wa ngbe ju silẹ lilọ ba ohun ti Ọlọhun Allah da ki ẹ le ri adun yin nibẹ nibi abẹ awọn iyawo yin?! Bikose wipe ẹ jẹ olukọja ẹnu ala Allah pẹlu nkan airiri yii.
قَالُواْ لَئِن لَّمۡ تَنتَهِ يَٰلُوطُ لَتَكُونَنَّ مِنَ ٱلۡمُخۡرَجِينَ 167
Awọn ijọ rẹ sọ fun pe: ti o ko ba jawọ irẹ Luth lati maa kọ fun wa kuro nibi isẹ yii ati titako wa le lori, iwọ ati awọn ti o wa pẹlu rẹ yoo wa ninu ẹni ti a o le jade ninu abule wa.
قَالَ إِنِّي لِعَمَلِكُم مِّنَ ٱلۡقَالِينَ 168
Luth sọ fun pe: dajudaju emi wa ninu olutako ati olukorira isẹ ti ẹ nse yii.
رَبِّ نَجِّنِي وَأَهۡلِي مِمَّا يَعۡمَلُونَ 169
O sọ ni ẹniti o npe Ọlọhun Ọba rẹ: Ọlọhun mi la mi, ki o si la ara ile mi nibi iya ti yoo kan awọn eniyan wọnyi nitori nkan ti wọn nse ti ko dara.
فَنَجَّيۡنَٰهُ وَأَهۡلَهُۥٓ أَجۡمَعِينَ 170
A jẹpe adua rẹ, bẹẹni a la a ati awọn ara ile rẹ lapapọ.
إِلَّا عَجُوزٗا فِي ٱلۡغَٰبِرِينَ 171
Ayaafi iyawo rẹ, paapaa o jẹ keferi, o si wa ninu awọn ti o lọ, ti o si parun.
ثُمَّ دَمَّرۡنَا ٱلۡأٓخَرِينَ 172
Lẹyin igba naa ti Luth jade ati ara ile rẹ ni abule (saduumu), a mu iparun ba awọn ijọ ti o sẹku ni iparun ti o le koko.
وَأَمۡطَرۡنَا عَلَيۡهِم مَّطَرٗاۖ فَسَآءَ مَطَرُ ٱلۡمُنذَرِينَ 173
A si sọ okuta kalẹ lati sanmọ le wọn lori gẹgẹ bi sisọ ojo kalẹ, ojo awọn ti Luth nse ikilọ fun yii buru, ti o si nki wọn nilọ kuro nibi iya Allah, dajudaju o jẹ ẹniti o tẹsiwaju lori ohun ti wọn wa nibi sise nkan ti ko tọ.
إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَأٓيَةٗۖ وَمَا كَانَ أَكۡثَرُهُم مُّؤۡمِنِينَ 174
Dajudaju nibi iya ti o sọkalẹ fun ijọ Luth ti a sọ yii jẹ okunfa isẹ ibajẹ, o si jẹ ariwoye fun awọn oloye, bẹẹ ni ọpọ wọn kii se olugbagbọ.
وَإِنَّ رَبَّكَ لَهُوَ ٱلۡعَزِيزُ ٱلرَّحِيمُ 175
Ati wipe dajudaju Ọlọhun Ọba rẹ - irẹ ojisẹ - jẹ alagbara eyiti ngbẹsan lara awọn ọta Rẹ; onikẹ fun ẹniti o ba sẹri ninu awọn ẹru Rẹ.
كَذَّبَ أَصۡحَٰبُ لَۡٔيۡكَةِ ٱلۡمُرۡسَلِينَ 176
Awọn ara abule ti o ni igi ti o yika ni ẹgbẹ ‘madiyana’ pe awọn ojisẹ nirọ nigbati wọn pe anọbi wọn Shuaibu - ti ọla nbẹ fun - nirọ.
إِذۡ قَالَ لَهُمۡ شُعَيۡبٌ أَلَا تَتَّقُونَ 177
Nigbati anọbi wọn Shuaibu sọ fun wọn pe: se ẹ ko ni paya Allah pẹlu gbigbe ẹbọ ju silẹ niti ijaya rẹ?!
إِنِّي لَكُمۡ رَسُولٌ أَمِينٞ 178
Dajudaju emi jẹ ojisẹ fun yin, Allah si ran mi si yin, ohun ni ifọkantan nibi ohun ti mo mu de etigbọ, nko ni fi kun ohun ti wọn pa mi lasẹ mimu de etigbọ rẹ, bẹẹ ni nko ni din ku.
فَٱتَّقُواْ ٱللَّهَ وَأَطِيعُونِ 179
Ki ẹ ya paya Allah pẹlu titẹle awọn asẹ Rẹ ati jijina si ounti O kọ, ki ẹ si tẹle mi nibi ohun ti mo ba payin lasẹ rẹ ati ohun ti mo ba kọ fun yin kuro nibẹ.
وَمَآ أَسَۡٔلُكُمۡ عَلَيۡهِ مِنۡ أَجۡرٍۖ إِنۡ أَجۡرِيَ إِلَّا عَلَىٰ رَبِّ ٱلۡعَٰلَمِينَ 180
Bẹẹni nko wa ẹsan lori ohun ti mo nmu de etigbọ yin lati ọdọ Ọlọhun Ọba mi, ẹsan mi ko jẹ lati ibi kankan ayaafi ọdọ Allah olutọju gbogbo ẹda, ko si lọdọ ẹlomiran.
۞أَوۡفُواْ ٱلۡكَيۡلَ وَلَا تَكُونُواْ مِنَ ٱلۡمُخۡسِرِينَ 181
Ẹ pe osunwọn fun awọn eniyan nigbati ẹ ba nta ọja fun wọn, ẹ si mase wa ninu awọn ẹniti yoo maa din osunwọn ku nigbati ẹ ba nta ọja fun wọn.
وَزِنُواْ بِٱلۡقِسۡطَاسِ ٱلۡمُسۡتَقِيمِ 182
Ẹ wọn ọn pe ni osunwọn ti o duro tọ nigbati ẹ ba nwọn ọn fun ẹlomiran ti o yatọ si yin.
وَلَا تَبۡخَسُواْ ٱلنَّاسَ أَشۡيَآءَهُمۡ وَلَا تَعۡثَوۡاْ فِي ٱلۡأَرۡضِ مُفۡسِدِينَ 183
Ẹ mase din ẹtọ awọn eniyan ku, ẹ mase jẹ ki ibajẹ pọ ni ori ilẹ pẹlu dida awọn ẹsẹ.
Ibakọrun lopọ jẹ nkan eemọ ninu adamọ ati nkan ikorira ti o tobi.
Ninu aluba fun olupepe niki keferi tabi ẹlẹsẹ wa ninu ara ile rẹ.
Awọn ibasepọ ori ilẹ ti ko ni igbagbọ ninu ko le se anfaani fun ẹniti o nii nigbati iya ba de.
Jijẹ dandan pipe osunwọn ati jijẹ eewọ dindin osunwọn ku.