قُل لِّلۡمُخَلَّفِينَ مِنَ ٱلۡأَعۡرَابِ سَتُدۡعَوۡنَ إِلَىٰ قَوۡمٍ أُوْلِي بَأۡسٖ شَدِيدٖ تُقَٰتِلُونَهُمۡ أَوۡ يُسۡلِمُونَۖ فَإِن تُطِيعُواْ يُؤۡتِكُمُ ٱللَّهُ أَجۡرًا حَسَنٗاۖ وَإِن تَتَوَلَّوۡاْ كَمَا تَوَلَّيۡتُم مِّن قَبۡلُ يُعَذِّبۡكُمۡ عَذَابًا أَلِيمٗا 16
Sọ - irẹ ojisẹ - fun awọn ti o yapa ninu awọn larubawa lati rin pẹlu rẹ lọsi ilu Mẹkkah ni ẹniti o ndan wọn wo: wọn yoo pe yin lọ si bi biba awọn ijọ kan ja, awọn ti wọn ni nkan ija ti o lagbara nibi ogun, ẹ o ba wọn ja ni oju ọna Allah tabi wọn yoo wọ inu ẹsan alaafia laisi ija, ti ẹ ba tẹle Allah nibi ohun ti O pe yin lọ si ibẹ nibi biba wọn ja, yoo fun yin ni ẹsan ti o dara ohun si ni ọgba idẹra naa, ti ẹ ba si gunri kuro nibi titẹle ti Rẹ - gẹgẹ bi ki ẹ pẹyin da kuro nibẹ nibi yiyapa ririn pẹlu rẹ lọsi ilu Mẹka - yoo fi iya inira jẹ yin.
لَّيۡسَ عَلَى ٱلۡأَعۡمَىٰ حَرَجٞ وَلَا عَلَى ٱلۡأَعۡرَجِ حَرَجٞ وَلَا عَلَى ٱلۡمَرِيضِ حَرَجٞۗ وَمَن يُطِعِ ٱللَّهَ وَرَسُولَهُۥ يُدۡخِلۡهُ جَنَّٰتٖ تَجۡرِي مِن تَحۡتِهَا ٱلۡأَنۡهَٰرُۖ وَمَن يَتَوَلَّ يُعَذِّبۡهُ عَذَابًا أَلِيمٗا 17
Ko si ẹsẹ fun awọn ẹni awijare lati ibi ifọju tabi imukun tabi aarẹ nigbati wọn ba yapa kuro nibi ija ni oju ọna ti Allah, ẹniti o ba tẹle Allah, ti o si tun tẹle ojisẹ Rẹ, yoo fi wọ awọn ọgba idẹra eyiti awọn akeremọdo nsan ni abẹ awọn orule rẹ ati awọn igi rẹ, ẹniti o ba si gunri kuro nibi titẹle ti awọn mejeeji Allah yoo fi iya inira jẹ ẹ.
۞لَّقَدۡ رَضِيَ ٱللَّهُ عَنِ ٱلۡمُؤۡمِنِينَ إِذۡ يُبَايِعُونَكَ تَحۡتَ ٱلشَّجَرَةِ فَعَلِمَ مَا فِي قُلُوبِهِمۡ فَأَنزَلَ ٱلسَّكِينَةَ عَلَيۡهِمۡ وَأَثَٰبَهُمۡ فَتۡحٗا قَرِيبٗا 18
Paapaa Allah ti yọnusi awọn olugbagbọ ododo nigbati wọn nse adehun pẹlu rẹ nibi hudaybiyah tii se adehun iyọnu labẹ igi naa, o si mọ igbagbọ ati afọmọ ati ododo ti o wa ni ọkan wọn, o wa sọ ifọkanbalẹ si ọkan wọn, o si san wọn lẹsan isipaya ti o sun mọ, ohun si ni isipaya kaebar lori eleyi; ki o le jẹ ipaarọ fun wọn nipa wiwọ Mẹka ti o bọ mọ wọn lọwọ.
وَمَغَانِمَ كَثِيرَةٗ يَأۡخُذُونَهَاۗ وَكَانَ ٱللَّهُ عَزِيزًا حَكِيمٗا 19
O si fun wọn ni awọn ọrọ ti o pọ, ti wọn gba a lọdọ awọn ara kaebar, Allah jẹ alagbara ti ẹnikankan ko le bori Rẹ, Ọjọgbọ ni isẹda Rẹ, ipe bubu Rẹ ati idari eto Rẹ.
وَعَدَكُمُ ٱللَّهُ مَغَانِمَ كَثِيرَةٗ تَأۡخُذُونَهَا فَعَجَّلَ لَكُمۡ هَٰذِهِۦ وَكَفَّ أَيۡدِيَ ٱلنَّاسِ عَنكُمۡ وَلِتَكُونَ ءَايَةٗ لِّلۡمُؤۡمِنِينَ وَيَهۡدِيَكُمۡ صِرَٰطٗا مُّسۡتَقِيمٗا 20
Allah se adehun awọn ọrọ ti o pọ fun yin -ẹyin olugbagbọ ododo- ti ẹ o mu nibi awọn isipaya ẹsin alaafia ti o wa niwaju, o wa kanju fun yin ni awọn ọrọ kaebar, o kọ ọwọ awọn yahuudi nigbati wọn ngbero ki o kan awọn ara ile yin lẹyin yin ati ki awọn ọrọ kiakia yii le jẹ amin fun yin lori aranse Allah ati iunlọwọ Rẹ fun yin, Allah si fi yin mọ ọna ti o duro tọ, ti ko si iwọgun nibẹ.
وَأُخۡرَىٰ لَمۡ تَقۡدِرُواْ عَلَيۡهَا قَدۡ أَحَاطَ ٱللَّهُ بِهَاۚ وَكَانَ ٱللَّهُ عَلَىٰ كُلِّ شَيۡءٖ قَدِيرٗا 21
Allah tun se adehun awọn ọrọ miran ti ẹ ko nikapa rẹ ni asiko yii, Allah nikan ni alagbara le lori, O wa ninu imọ Rẹ ati idari eto Rẹ, Allah si jẹ alagbara lori gbogbo nkan, nkankan ko le ko agara ba A.
وَلَوۡ قَٰتَلَكُمُ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ لَوَلَّوُاْ ٱلۡأَدۡبَٰرَ ثُمَّ لَا يَجِدُونَ وَلِيّٗا وَلَا نَصِيرٗا 22
Ti wọn ba ba yin ja - ẹyin olugbagbọ ododo - awọn ti wọn se keferi si Allah si ojisẹ Rẹ, wọn ko ba pẹyinda ni ẹniti o nsalọ ti a ti bori ni iwaju yin, lẹyin naa wọn ko nii ri alatilẹyin ti yoo gba ọrọ wọn ro, wọn ko si nii ri alaranse ti yoo ran wọn lori ibayinja.
سُنَّةَ ٱللَّهِ ٱلَّتِي قَدۡ خَلَتۡ مِن قَبۡلُۖ وَلَن تَجِدَ لِسُنَّةِ ٱللَّهِ تَبۡدِيلٗا 23
Ibori awọn olugbagbọ ododo ati ijakulẹ awọn keferi rinlẹ ni gbogbo asiko ati aaye, o si jẹ isesi Allah ninu awọn ijọ eyiti o ti kọja ninu awọn opurọ yii, iwọ ko si le ri - irẹ ojisẹ - yiypada fun isesi Allah.
Mimu iro wa Alukuraani nipa awọn nkan ti o pamọ, ti yoo si pada sẹlẹ -gẹgẹ bi isipaya ẹsin alaafia, Gẹgẹ bi isipaya ẹsin jẹ ẹri ti o mu lori wipe Alukuraani alapọnle wa lati ọdọ Allah.
Awọn idajọ ofin ẹsin duro lori pẹlẹpẹlẹ ati irọrun.
O wa ninu ẹsan awọn olusadehun iyọnu eyiti o kanju rẹ, ti o si lọ lara fun wọn di ọrun naa wa ninu rẹ.
Ibori ododo ati awọn ẹniirẹ lori ibajẹ ati awọn ẹniirẹ jẹ isesi Ọlọhun.