قُل لَّن يَنفَعَكُمُ ٱلۡفِرَارُ إِن فَرَرۡتُم مِّنَ ٱلۡمَوۡتِ أَوِ ٱلۡقَتۡلِ وَإِذٗا لَّا تُمَتَّعُونَ إِلَّا قَلِيلٗا 16
Sọ - irẹ ojisẹ - fun awọn wọnyi: sisa yin ko le se yin lanfaani ti ẹ ba sa kuro nibi ogun niti ipaya iku tabi pipa; nitoripe asiko ti ni ebubu, ti ẹ ba wa sa ti asiko yin ko si tii to, ẹ ko le gbadun isẹmin aye ayaafi fun asiko diẹ.
قُلۡ مَن ذَا ٱلَّذِي يَعۡصِمُكُم مِّنَ ٱللَّهِ إِنۡ أَرَادَ بِكُمۡ سُوٓءًا أَوۡ أَرَادَ بِكُمۡ رَحۡمَةٗۚ وَلَا يَجِدُونَ لَهُم مِّن دُونِ ٱللَّهِ وَلِيّٗا وَلَا نَصِيرٗا 17
Sọ fun wọn - irẹ ojisẹ -: taani o nkọ fun kuro ni ọdọ Allah, ti o ba gbero ohun ti ẹ ko fẹ fun yin ninu iku tabi pipa, tabi O gbero ohun ti ẹ nrankan fun yin ninu alaafia tabi rere, ko si ẹnikẹni ti o le kọ fun yin nibẹ, awọn sọbẹ selo yii ko le ri alatilẹyin yatọ si Allah ti yoo la ọrọ wọn bọrun, bẹẹni ko si alaranse ti yoo kọ fun yin kuro nibi iya Allah ti o ba se fun wọn.
۞قَدۡ يَعۡلَمُ ٱللَّهُ ٱلۡمُعَوِّقِينَ مِنكُمۡ وَٱلۡقَآئِلِينَ لِإِخۡوَٰنِهِمۡ هَلُمَّ إِلَيۡنَاۖ وَلَا يَأۡتُونَ ٱلۡبَأۡسَ إِلَّا قَلِيلًا 18
Ọlọhun Ọba Allah ti mọ awọn oludi ninu yin mọ awọn miran kuro nibi ogun jija pẹlu ojisẹ Allah - ti ikẹ ati ọla nbẹ fun - ati awọn ti o nsọ fun awọn ọmọ iya wọn: ẹ wa si ọdọ wa, ẹ mase jagun pẹlu rẹ ki wọn maa ba pa yin, nitoripe awa nbẹru pipa yin, bẹẹni awọn wọnyi ti wọn ndagunla ko nii wa si ogun, bẹẹni wọn ko nii kopa nibẹ ayaafi igba ti o kere; ki wọn le daabobo ẹmin wọn kuro nibi osi, kii se la ti se aranse fun Allah ati ojisẹ Rẹ.
أَشِحَّةً عَلَيۡكُمۡۖ فَإِذَا جَآءَ ٱلۡخَوۡفُ رَأَيۡتَهُمۡ يَنظُرُونَ إِلَيۡكَ تَدُورُ أَعۡيُنُهُمۡ كَٱلَّذِي يُغۡشَىٰ عَلَيۡهِ مِنَ ٱلۡمَوۡتِۖ فَإِذَا ذَهَبَ ٱلۡخَوۡفُ سَلَقُوكُم بِأَلۡسِنَةٍ حِدَادٍ أَشِحَّةً عَلَى ٱلۡخَيۡرِۚ أُوْلَٰٓئِكَ لَمۡ يُؤۡمِنُواْ فَأَحۡبَطَ ٱللَّهُ أَعۡمَٰلَهُمۡۚ وَكَانَ ذَٰلِكَ عَلَى ٱللَّهِ يَسِيرٗا 19
Wọn jẹ ahun si yin - ẹyin olugbagbọ ododo - pẹlu awọn dukia wọn, wọn ko nii ran yin lọwọ pẹlu nina a, wọn si tun jẹ ahun si ẹmin ara wọn, wọn ko nii jagun pẹlu yin, wọn tun jẹ ahun pẹlu ifẹ wọn, wọn ko si ni nifẹ yin, nigbati ipaya ba de nigba ipade ọta, iwọ yoo ri wọn ti wọn yoo maa gbe oju wo ọ -ire ojise- oju wọn yoo maa yipo niti ojo gẹgẹ bi yiyi oju ẹniti o npọka iku, nigbati ipaya ba kuro fun wọn, ti wọn fi ọkan balẹ, wọn yoo maa fi ọrọ lati ori ahọn wọn ti o mu se yin ni suta niti sise ahun lori awọn ọrọ ti eyiti wọn nwa, awọn wọnyi ni a fi iroyin yii royin, wọn ko nigbagbọ lododo, Allah waa ba ẹsan isẹ wọn jẹ, biba a jẹ si jẹ ohun ti o rọrun fun Allah.
يَحۡسَبُونَ ٱلۡأَحۡزَابَ لَمۡ يَذۡهَبُواْۖ وَإِن يَأۡتِ ٱلۡأَحۡزَابُ يَوَدُّواْ لَوۡ أَنَّهُم بَادُونَ فِي ٱلۡأَعۡرَابِ يَسَۡٔلُونَ عَنۡ أَنۢبَآئِكُمۡۖ وَلَوۡ كَانُواْ فِيكُم مَّا قَٰتَلُوٓاْ إِلَّا قَلِيلٗا 20
Awọn ojo yii nlero wipe awọn ijọ ti a kọ lẹkọ fun jija ojisẹ Allah logun ti ikẹ ati ọla nbẹ fun ati jija awọn olugbagbọ ododo logun, wọn ko le lọ titi wọn yoo fi pa awọn olugbagbọ ododo finfin, ti wọn ba pebubu ki awọn ijọ naa wa ni igba miran, awọn sọbẹ selu yii yoo nifẹ si ki wọn jade kuro ni inu ilu pẹlu awọn larubawa oko, wọn yoo maa beere nipa awọn iroyin yin: kinni o sẹlẹ si yin lẹyin ti ọta yin pa yin? Ti wọn ba wa ninu yin - ẹyin olugbagbọ ododo - wọn ko nii jagun pẹlu yin ayaafi igba diẹ, ẹ mase ka wọn kun, ẹ si mase banujẹ le wọn lori.
لَّقَدۡ كَانَ لَكُمۡ فِي رَسُولِ ٱللَّهِ أُسۡوَةٌ حَسَنَةٞ لِّمَن كَانَ يَرۡجُواْ ٱللَّهَ وَٱلۡيَوۡمَ ٱلۡأٓخِرَ وَذَكَرَ ٱللَّهَ كَثِيرٗا 21
Paapaa awokẹse ti o dara ti nbẹ fun yin nibi ounti ojisẹ Allah sọ fun yin, ti o si duro tii, ti o si nse e, ohun gan gan ti o ni apọnle ti wa, o si bọ si oju ogun, bawo ni ẹyin gangan se wa nse ahun si ẹmin rẹ? ẹnikan ko nii kọse ojisẹ Allah - ti ikẹ ati ọla nbẹ fun - ayaafi ẹniti o nrankan ẹsan Allah ati ikẹ Rẹ, ti o si nrankan ọjọ ikẹyin ti o si nsisẹ fun un, ti o si nranti Allah ni iranti ti o pọ, sugbọn ẹniti ko rankan ọjọ ikẹyin, ti ko si ranti Allah lọpọ, dajudaju ko nii kọ se ojisẹ Rẹ - ti ikẹ ati ọla nbẹ fun -.
وَلَمَّا رَءَا ٱلۡمُؤۡمِنُونَ ٱلۡأَحۡزَابَ قَالُواْ هَٰذَا مَا وَعَدَنَا ٱللَّهُ وَرَسُولُهُۥ وَصَدَقَ ٱللَّهُ وَرَسُولُهُۥۚ وَمَا زَادَهُمۡ إِلَّآ إِيمَٰنٗا وَتَسۡلِيمٗا 22
Nigbati awọn olugbagbọ ododo fi oju ri awọn ijọ ti o ko jọ lati pa wọn, wọn sọpe: eleyi ni ohun ti Allah ati ojisẹ Rẹ se ni adehun fun wa ninu awọn adanwo, idaamun ati aranse, Allah ati ojisẹ Rẹ sọ ododo nibi eleyi, paapaa o si ti ni imusẹ, riri wọn si awọn ijọ yii ko le nkankan fun wọn ju igbagbọ si Allah lọ ati itẹriba fun Un.
Awọn isẹlẹ ti ni aala; ogun ko le mu sun mọ, bẹẹni sisa kuro ko si le mu jinna.
Ifadisẹyin nibi ijagun si oju ọna Allah jẹ isesi awọn sọbẹselu ni gbogbo igba.
Ojisẹ naa ti ikẹ ati ọla nbẹ fun jẹ awokọse awọn olugbagbọ ododo nibi awọn ọrọ rẹ ati awọn isẹ rẹ.
Inigbẹkẹle ninu Allah ati gbigba fun Un jẹ ninu iroyin awọn olugbagbọ ododo.