وَأَمَّا ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ وَكَذَّبُواْ بَِٔايَٰتِنَا وَلِقَآيِٕ ٱلۡأٓخِرَةِ فَأُوْلَٰٓئِكَ فِي ٱلۡعَذَابِ مُحۡضَرُونَ 16
Sugbọn awọn ti wọn se keferi si Allah, ti wọn si pe awọn amin Wa ti a sọkalẹ fun ojisẹ Wa nirọ, wọn tun pe igbende ati isiro nirọ, awọn wọnyi ni wọn yoo mu wa fun iya, ti wọn yoo si lẹ mọ ọ.
فَسُبۡحَٰنَ ٱللَّهِ حِينَ تُمۡسُونَ وَحِينَ تُصۡبِحُونَ 17
Ẹ maa se afọmọ fun Allah nigbati asiko irọlẹ ba wọle, ohun si ni asiko irun meji naa: asalẹ ati alẹ, ki ẹ si tun se afọmọ fun Un nigbati ẹ ba wọ inu asiko aarọ, ohun ni asiko irun idaji.
وَلَهُ ٱلۡحَمۡدُ فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِ وَعَشِيّٗا وَحِينَ تُظۡهِرُونَ 18
Oun nikan ti mimọ nbẹ fun ni O ni ẹyin; ni sanmọ ti awọn Malaika Rẹ ndupẹ fun Un, bẹẹni awọn ẹda Rẹ si ndupẹ fun lorilẹ, ẹ tun maa se afọmọ Rẹ nigbati ẹ ba nwọ asiko irọlẹ, ohun ni asiko irun irọlẹ, ki ẹ si maa se afọmọ fun Un nigbati ẹ ba nwọ inu asiko ọsan.
يُخۡرِجُ ٱلۡحَيَّ مِنَ ٱلۡمَيِّتِ وَيُخۡرِجُ ٱلۡمَيِّتَ مِنَ ٱلۡحَيِّ وَيُحۡيِ ٱلۡأَرۡضَ بَعۡدَ مَوۡتِهَاۚ وَكَذَٰلِكَ تُخۡرَجُونَ 19
O nmu alaaye jade ninu oku gẹgẹ bi mimu ọmọniyan jade ninu omin lọgbọ ati oromọdiyẹ ninu ẹyin, O si nmu oku jade ninu alaaye gẹgẹ bi o se nmu omin lọgbọ jade lati ara eniyan ati ẹyin jade ninu abo dirẹ, O si nta ilẹ ji lẹyin gbigbẹ rẹ pẹlu sisọ ojo kalẹ pẹlu mimu irugbin jade ninu rẹ ati gẹgẹ bi tita ilẹ ji pẹlu mimu irugbin jade ninu rẹ, ẹ o jade ninu saare yin fun isiro ati ẹsan.
وَمِنۡ ءَايَٰتِهِۦٓ أَنۡ خَلَقَكُم مِّن تُرَابٖ ثُمَّ إِذَآ أَنتُم بَشَرٞ تَنتَشِرُونَ 20
Ninu awọn amin Allah ti o tobi, ti o si ntọka si agbara Rẹ ati ijọkan soso Rẹ: ni sisẹda yin - ẹyin eniyan - lati inu yẹpẹ nigbati o da baba yin lati inu amọ, lẹyin naa ẹ yoo di abara ti ẹ npọ niti ibi si i, ti ẹ si nfanka ni ibuyọ oorun ati ibuwọ rẹ.
وَمِنۡ ءَايَٰتِهِۦٓ أَنۡ خَلَقَ لَكُم مِّنۡ أَنفُسِكُمۡ أَزۡوَٰجٗا لِّتَسۡكُنُوٓاْ إِلَيۡهَا وَجَعَلَ بَيۡنَكُم مَّوَدَّةٗ وَرَحۡمَةًۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَأٓيَٰتٖ لِّقَوۡمٖ يَتَفَكَّرُونَ 21
Ninu awọn amin Rẹ ti o tobi, ti ntọka si agbara Rẹ ati ijọkan soso Rẹ, ni dida ti O da nitori yin - ẹyin ọkunrin - iran yin ni iyawo ki ẹ le fi ẹmin balẹ si ọdọ wọn ati ki iran le maa bẹ laarin yin, o si fi ifẹ ati aanu si aarin yin ati aarin wọn, dajudaju nibi eleyi ti a sọ jẹ awijare ati awọn itọka ti o fi oju han fun ijọ ti o nronu; nitoripe awọn ni yoo se anfaani nibi lilo laakaye wọn.
وَمِنۡ ءَايَٰتِهِۦ خَلۡقُ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِ وَٱخۡتِلَٰفُ أَلۡسِنَتِكُمۡ وَأَلۡوَٰنِكُمۡۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَأٓيَٰتٖ لِّلۡعَٰلِمِينَ 22
Ninu awọn amin Rẹ ti o tobi, ti o ntọka si agbara Rẹ ati ijọkan soso Rẹ: ni dida sanmọ ati dida ile, ninuj rẹ naa ni yiyapa ede yin ati yiyatọ awọn ahọn yin, dajudaju nibi eleyi ti a sọ yii jẹ awọn awijare ati awọn itọka fun awọn onimimọ ati awọn oloju inu.
وَمِنۡ ءَايَٰتِهِۦ مَنَامُكُم بِٱلَّيۡلِ وَٱلنَّهَارِ وَٱبۡتِغَآؤُكُم مِّن فَضۡلِهِۦٓۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَأٓيَٰتٖ لِّقَوۡمٖ يَسۡمَعُونَ 23
Ninu awọn amin Rẹ ti o tobi, ti o si ntọka si agbara Rẹ ati ijọkan soso Rẹ: ni oorun yin loru ati oorun yin lọsan ki ẹ le simin nibi idaamun isẹ yin ati ninu awọn amin Rẹ ni ki o se ọsan fun yin ki ẹ le fan ka nibẹ lati wa arisiki ni ọdọ Ọlọhun Ọba yin, dajudaju nibi eleyi ti a sọ yii jẹ awọn awijare ati awọn itọka fun ijọ ti o ngbọrọ ni gbigbọ rironu ati gbigbọ gbigba.
وَمِنۡ ءَايَٰتِهِۦ يُرِيكُمُ ٱلۡبَرۡقَ خَوۡفٗا وَطَمَعٗا وَيُنَزِّلُ مِنَ ٱلسَّمَآءِ مَآءٗ فَيُحۡيِۦ بِهِ ٱلۡأَرۡضَ بَعۡدَ مَوۡتِهَآۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَأٓيَٰتٖ لِّقَوۡمٖ يَعۡقِلُونَ 24
Ninu awọn amin Rẹ ti o tobi, ti o ntọka si agbara Rẹ ati ijọkan soso Rẹ: ni mimu yin ri mọnamọna ni sanmọ, O si npaapọ fun yin nibẹ laarin ipaya ara ati irankan si ojo, O si nsọ omin ojo kalẹ fun yin ni sanmọ, o wa nfi ta ilẹ ji lẹyin gbigbẹ rẹ pẹlu ohun ti yoo hu nibẹ ninu awọn irugbin, dajudaju nibi eleyi jẹ awọn awijare ati awọn itọka fun ijọ ti o nse laakaye, ti wọn yoo fi maa se ẹri lori igbende lẹyin iku fun isiro ati ẹsan.
Ki ẹru lo awọn asiko rẹ fun irun ati afọmọ jẹ amin kan lori didara igbẹyin.
Wiwa ẹri lori igbende pẹlu sise lọtun lọtun isẹmin nigbati o jasi pe Allah nda alaaye lati inu oku ati oku lati inu alaaye.
Awọn amin Allah nbẹ ninu ẹmin ati oferefe, ẹnikankan ko si le anfaani ninu rẹ ayaafi ẹniti o nlo awọn ojupọnna ilepa ba a rẹ ti o jẹ ti ifuramọ tabi itumọ ti Allah se idẹkun rẹ fun un.