وَكَذَٰلِكَ أَنزَلۡنَٰهُ ءَايَٰتِۢ بَيِّنَٰتٖ وَأَنَّ ٱللَّهَ يَهۡدِي مَن يُرِيدُ 16
Gẹgẹ bi a se salaye fun nipa awijare ti o fi oju han nipa ajinde, bẹẹ naa ni a sọ Alukuraani kalẹ fun Muhammad ti ikẹ ati ọla nbẹ fun ki o le jẹ amin ti o fi oju han, ati wipe dajudaju Allah yoo fi ẹniti o ba wu U se kongẹ oju ọna imọna ati itọsọna lati ibi ọla Rẹ.
إِنَّ ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَٱلَّذِينَ هَادُواْ وَٱلصَّٰبِِٔينَ وَٱلنَّصَٰرَىٰ وَٱلۡمَجُوسَ وَٱلَّذِينَ أَشۡرَكُوٓاْ إِنَّ ٱللَّهَ يَفۡصِلُ بَيۡنَهُمۡ يَوۡمَ ٱلۡقِيَٰمَةِۚ إِنَّ ٱللَّهَ عَلَىٰ كُلِّ شَيۡءٖ شَهِيدٌ 17
Dajudaju awọn ti o nigbagbọ ninu Allah ninu awọn ijọ yii ati awọn yahuudi ati awọn sọbihiina (abala kan ninu awọn olutẹle apakan awọn anọbi), ati awọn nasaara ati awọn abọna ati awọn abọrisa - dajudaju Allah yoo se idajọ laarin wọn ni ọjọ igbende, yoo si fi awọn olugbagbọ ododo wọ inu Alujannah, yoo si ẹniti o yatọ si wọn wọ inu ina, dajudaju Allah jẹ olujẹri lori gbogbo nkan ninu awọn ọrọ awọn ẹru Rẹ ati awọn isẹ wọn, nkankan ko pamọ fun Un ninu Rẹ, yoo si san wọn lẹsan le lori.
أَلَمۡ تَرَ أَنَّ ٱللَّهَ يَسۡجُدُۤ لَهُۥۤ مَن فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَمَن فِي ٱلۡأَرۡضِ وَٱلشَّمۡسُ وَٱلۡقَمَرُ وَٱلنُّجُومُ وَٱلۡجِبَالُ وَٱلشَّجَرُ وَٱلدَّوَآبُّ وَكَثِيرٞ مِّنَ ٱلنَّاسِۖ وَكَثِيرٌ حَقَّ عَلَيۡهِ ٱلۡعَذَابُۗ وَمَن يُهِنِ ٱللَّهُ فَمَا لَهُۥ مِن مُّكۡرِمٍۚ إِنَّ ٱللَّهَ يَفۡعَلُ مَا يَشَآءُ۩ 18
Se iwọ ko mọ ni - ire ojise - dajudaju Allah, gbogbo ohun ti nbẹ ni sanmọ ati awọn Malaika ati ohun ti nbẹ ni ori ilẹ ati awọn olugbagbọ ninu eeyan ati alujannu ni o nfi oribalẹ ti itẹle asẹ fun Un, bẹẹ ni awọn irawọ ti nbẹ ni sanmọ ati oke ati igi ati awọn ohun ti o nrin lori ilẹ nfi ori balẹ fun Un; ni iforibalẹ itẹriba, ọpọ awọn eniyan si nfi ori balẹ fun Un ni iforibalẹ ilẹle asẹ, bẹẹni ọpọ naa si nkọ lati fi ori balẹ fun Un niti itẹle asẹ, iya Ọlọhun Ọba Allah si tọ le wọn lori nitori sise keferi wọn, ẹni Ọlọhun ba kadara iyẹpẹrẹ ati irẹlẹ mọ nitori sise keferi rẹ, ko si ẹnikankan ti o le pọn ọn le, dajudaju Allah ma nse bi o se wu U, ko si ẹniti o le jẹ Ẹ nipa ti mimọ nbẹ fun.
Nigbati Ọlọhun Allah ti mimọ nbẹ fun salaye ẹniti o nfi oribalẹ fun niti itẹle asẹ ati ẹniti o nkọ, o fi igbẹyin awọn mejeeji kẹyin ọrọ naa, O si waa sọpe:
۞هَٰذَانِ خَصۡمَانِ ٱخۡتَصَمُواْ فِي رَبِّهِمۡۖ فَٱلَّذِينَ كَفَرُواْ قُطِّعَتۡ لَهُمۡ ثِيَابٞ مِّن نَّارٖ يُصَبُّ مِن فَوۡقِ رُءُوسِهِمُ ٱلۡحَمِيمُ 19
Awọn ipin mejeeji yii ti wọn ba ara wọn ja nipa Ọlọhun wọn, e wo ni o lẹtọ ninu wọn: se ipin igbagbọ ni tabi ipin keferi; ipin keferi ina yoo yi wọn ka gẹgẹ bi a sọ se ma nyi ẹniti o wọ ọ ka, wọn yoo si maa fun ni omin ti o ti gbona tan yan anyan lati oke ori wọn.
يُصۡهَرُ بِهِۦ مَا فِي بُطُونِهِمۡ وَٱلۡجُلُودُ 20
Yoo maa yọ ohun ti o nbẹ ninu ikun wọn ninu ifun nitori lilekoko igbona rẹ, yoo si de ibi awọ wọn yoo si yọ ọ.
وَلَهُم مَّقَٰمِعُ مِنۡ حَدِيدٖ 21
Ootu irin kan ninu ina si tun nbẹ fun wọn, ti awọn Malaika yoo fi maa gba ori wọn.
كُلَّمَآ أَرَادُوٓاْ أَن يَخۡرُجُواْ مِنۡهَا مِنۡ غَمٍّ أُعِيدُواْ فِيهَا وَذُوقُواْ عَذَابَ ٱلۡحَرِيقِ 22
Gbogbo igbati wọn ba ngbiyanju lati jade ninu ina nitori ilekoko ti wọn ba pade ninu isoro, wọn yoo da wọn pada si ibẹ, wọn yoo wa sọ fun wọn: ẹ maa jẹ iya ina eyiti o njo ni.
إِنَّ ٱللَّهَ يُدۡخِلُ ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَعَمِلُواْ ٱلصَّٰلِحَٰتِ جَنَّٰتٖ تَجۡرِي مِن تَحۡتِهَا ٱلۡأَنۡهَٰرُ يُحَلَّوۡنَ فِيهَا مِنۡ أَسَاوِرَ مِن ذَهَبٖ وَلُؤۡلُؤٗاۖ وَلِبَاسُهُمۡ فِيهَا حَرِيرٞ 23
Ipin igbagbọ si ni awọn ti wọn nigbagbọ ninu Allah, ti wọn si nsisẹẹre, Ọlọhun Ọba Allah yoo fi wọn wọ inu ọgba idẹra eyiti awọn akeremọdo nsan ni abẹ awọn orule rẹ ati igi rẹ, Ọlọhun Allah yoo se wọn lọsọ lati ibi okun ọrun wura, bẹẹni yoo se wọn lọsọ lati ibi nkan olowo iye biye, asọ wọn yoo si jẹ lati ibi ariiri.
Imọna wa ni ọwọ Allah ti O ma nfi ta ẹniti o ba wu U ninu ẹru Rẹ.
Akiyesi Allah lori gbogbo nkan wa lori isẹ ẹru Rẹ ati isesi wọn.
Itẹriba gbogbo ẹda fun Allah niti odiwọn ati itẹriba awọn olugbagbọ ododo fun Un niti itẹle asẹ.
Iya yoo sọkalẹ fun awọn ẹni keferi ati ẹsẹ, bẹẹ ni ikẹ yoo rinlẹ fun awọn igbagbọ ati itẹle asẹ.