وَلَقَدۡ جَعَلۡنَا فِي ٱلسَّمَآءِ بُرُوجٗا وَزَيَّنَّٰهَا لِلنَّٰظِرِينَ 16
Paapaa A ti fi irawọ ti o tobi si inu sanmọ, ti awọn eniyan nti ara rẹ mọ ọna nibi iri ajo wọn ni igba okunkun ori ilẹ ati ori omin, A si se lọsọ fun ẹniti o nwo tabi ẹniti o nri; ki wọn le maa fi tọka si agbara Ọlọhun Ọba ti mimọ nbẹ fun.
وَحَفِظۡنَٰهَا مِن كُلِّ شَيۡطَٰنٖ رَّجِيمٍ 17
A si sọ sanmọ kuro nibi esu ẹni igbejinna si ikẹ Allah.
إِلَّا مَنِ ٱسۡتَرَقَ ٱلسَّمۡعَ فَأَتۡبَعَهُۥ شِهَابٞ مُّبِينٞ 18
Ayaafi ẹniti o ba tẹti si awọn ijọ ti o ga ju niti jijigbọ, bayi ni irawọ onimọlẹ yoo wa ba lati jo ni ina.
وَٱلۡأَرۡضَ مَدَدۡنَٰهَا وَأَلۡقَيۡنَا فِيهَا رَوَٰسِيَ وَأَنۢبَتۡنَا فِيهَا مِن كُلِّ شَيۡءٖ مَّوۡزُونٖ 19
A tẹ ilẹ pẹrẹsẹ ki awọn eniyan le duro le lori, A si fi awọn oke ti o rinlẹ sibẹ ki o ma ba gbe awọn eniyan min, A si mu awọn oniranran irugbin jade ninu rẹ eyiti o jẹ odiwọn ti a fi aala si ni ibamun si ọgbọn ti o tọ si.
وَجَعَلۡنَا لَكُمۡ فِيهَا مَعَٰيِشَ وَمَن لَّسۡتُمۡ لَهُۥ بِرَٰزِقِينَ 20
A si se fun yin - ẹyin eniyan - nkan ti yoo maa mu yin sẹmin lori ilẹ ninu jijẹ ati mimu ni iwọnba igba ti ẹ ba nsẹmin ni ile aye, A si se fun awọn ti o yatọ si yin ninu awọn ẹniti ẹ ko le se aranse fun ninu awọn ati ẹranko, ohun ti yoo mu wọn sẹmin.
وَإِن مِّن شَيۡءٍ إِلَّا عِندَنَا خَزَآئِنُهُۥ وَمَا نُنَزِّلُهُۥٓ إِلَّا بِقَدَرٖ مَّعۡلُومٖ 21
Ko si ohun ti ọmọ ẹda eniyan nse anfaani lara rẹ ati awọn ẹranko ayaafi ki o jẹ si wipe awa ni a n mu bẹ, ti a si nje ki awọn eniyan se anfaani pẹlu rẹ, A ko si mu awọn nkan yi bẹ ayaafi pẹlu odiwọn ti o se deede ọgbọn wa ati fifẹ wa.
وَأَرۡسَلۡنَا ٱلرِّيَٰحَ لَوَٰقِحَ فَأَنزَلۡنَا مِنَ ٱلسَّمَآءِ مَآءٗ فَأَسۡقَيۡنَٰكُمُوهُ وَمَآ أَنتُمۡ لَهُۥ بِخَٰزِنِينَ 22
A ran atẹgun ni isẹ ki o le maa ba ẹsujo se papọ, Awa nsọ ojo kalẹ lati inu ẹsujo eyiti atẹgun ti se asepọ pẹlu rẹ, Awa nfun yin ni omin mu lati inu omin ojo, kii se ẹyin - ẹyin eniyan - ni olufi omin yii pamọ si inu ilẹ, ki o le pada jẹ isẹlẹru ati awọn odo, bikose wipe Ọlọhun Ọba Allah ni O fi pamọ si inu ilẹ.
وَإِنَّا لَنَحۡنُ نُحۡيِۦ وَنُمِيتُ وَنَحۡنُ ٱلۡوَٰرِثُونَ 23
Dajudaju Awa ni a nji awọn oku pẹlu didawọn lati ibi aisi ati gbigbe wọn dide lẹyin iku, Awa ni A si npa awọn alaaye nigbati wọn ba lo asiko wọn tan, Awa ni ẹniti yoo sẹku, ti yoo si jogun ilẹ ati awọn ti o nbẹ ni ori rẹ.
وَلَقَدۡ عَلِمۡنَا ٱلۡمُسۡتَقۡدِمِينَ مِنكُمۡ وَلَقَدۡ عَلِمۡنَا ٱلۡمُسۡتَٔۡخِرِينَ 24
Paapaa, A ti mọ ẹniti o gbawaju ninu yin niti ibi ati kiku, A si mọ ẹniti o kẹyin nibi mejeeji, nkankan ko pamọ fun wa nibi eleyi.
وَإِنَّ رَبَّكَ هُوَ يَحۡشُرُهُمۡۚ إِنَّهُۥ حَكِيمٌ عَلِيمٞ 25
Ati wipe dajudaju Ọlọhun Ọba rẹ - irẹ ojisẹ - ni ẹniti yoo ko wọn jọ ni ọjọ igbende alukiyaamọ, ki O le san oluse daadaa ni ẹsan daadaa rẹ ati oluse aidara ni aida rẹ, dajudaju o jẹ ọjọgbọn nibi idari rẹ, onimimọ ti nkankan ko pamọ fun.
وَلَقَدۡ خَلَقۡنَا ٱلۡإِنسَٰنَ مِن صَلۡصَٰلٖ مِّنۡ حَمَإٖ مَّسۡنُونٖ 26
Ati wipe paapaa, A da Aadamọ lati ibi abata gbigbẹ, ti A fi lulẹ, yoo dun, abata yii ti A da ninu rẹ yii jẹ dudu, ti oorun rẹ ti yi pada nitori gigun asiko ti o lo.
وَٱلۡجَآنَّ خَلَقۡنَٰهُ مِن قَبۡلُ مِن نَّارِ ٱلسَّمُومِ 27
A si tun da baba alujannu siwaju dida Aadamọ ẹniti ọla nbẹ fun lati inu ina ti gbigbonna rẹ le kokooko.
وَإِذۡ قَالَ رَبُّكَ لِلۡمَلَٰٓئِكَةِ إِنِّي خَٰلِقُۢ بَشَرٗا مِّن صَلۡصَٰلٖ مِّنۡ حَمَإٖ مَّسۡنُونٖ 28
Tun ranti - irẹ ojisẹ - nigbati Ọlọhun Ọba rẹ sọ fun awọn Malaika ati ibiliisu - ti o si wa pẹlu wọn -: dajudaju Emi yoo da abara kan lati inu abata gbigbẹ, ti yoo ni ohun nigbati a ba gba, dudu ti oorun rẹ ti yi pada.
فَإِذَا سَوَّيۡتُهُۥ وَنَفَخۡتُ فِيهِ مِن رُّوحِي فَقَعُواْ لَهُۥ سَٰجِدِينَ 29
Ti Mo ba se aworan rẹ deedee, ti Mo si pe dida rẹ, ki ẹ fi ori balẹ fun un niti mimu asẹ mi sẹ ati ki o le jẹ ikini fun un.
فَسَجَدَ ٱلۡمَلَٰٓئِكَةُ كُلُّهُمۡ أَجۡمَعُونَ 30
Awọn Malaika si mu asẹ sẹ, gbogbo wọn si fi ori balẹ fun un patapata gẹgẹ bi Ọlọhun Ọba se pa wọn lasẹ.
إِلَّآ إِبۡلِيسَ أَبَىٰٓ أَن يَكُونَ مَعَ ٱلسَّٰجِدِينَ 31
Sugbọn ibilisu - eyiti o wa pẹlu awọn Malaika, ti kii si se ara wọn - o kọ lati fi ori kanlẹ fun Aadamọ pẹlu awọn Malaika.
O tọ fun ẹru ki o ronu ki o si tun woye si sanmọ ati ọsọ rẹ, ki o si le maa fi se itọka si ẹniti o nmuu bẹ.
Gbogbo arisiki ati oniranran akọsilẹ, ẹnikankan ko lagbara rẹ ju Allah lọ, pẹpẹ ọrọ rẹ wa ni ọwọ rẹ, o ma nfun ẹniti o ba wu U, O si ma nkọ fun ẹniti O ba wu U ni ibamun si ọgbọn Rẹ.
Ilẹ jẹ ohun ti a da, ti o tẹ pẹrẹsẹ ni ibamun si irọrun isẹmin ọmọ ẹda eniyan le lori, o si jẹ ohun ti a fi awọn oke kan mọ ilẹ, ki o maa ba maa da awọn ohun ti o nbẹ ni ori rẹ laamun, bẹẹ ni awọn irugbin oniranran wa ninu rẹ eyiti o ni odiwọn ti a ti mọ, ni ibamun si ọgbọn ati iwulo.
Pipa awọn Malaika lasẹ fifi ori balẹ fun Aadamọ jẹ apọnle fun iran ọmọ ẹda eniyan.