وَلَئِن مُّتُّمۡ أَوۡ قُتِلۡتُمۡ لَإِلَى ٱللَّهِ تُحۡشَرُونَ 158
Ati wipe ti ẹ ba ku lori eyikeyi isesi ti iku yin gba wa, tabi wọn pa yin, tori naa ọdọ Ọlọhun Ọba Allah nikan ni ẹ o sẹri pada si lapapọ, ki O le ba san yin lẹsan lori awọn isẹ yin.
فَبِمَا رَحۡمَةٖ مِّنَ ٱللَّهِ لِنتَ لَهُمۡۖ وَلَوۡ كُنتَ فَظًّا غَلِيظَ ٱلۡقَلۡبِ لَٱنفَضُّواْ مِنۡ حَوۡلِكَۖ فَٱعۡفُ عَنۡهُمۡ وَٱسۡتَغۡفِرۡ لَهُمۡ وَشَاوِرۡهُمۡ فِي ٱلۡأَمۡرِۖ فَإِذَا عَزَمۡتَ فَتَوَكَّلۡ عَلَى ٱللَّهِۚ إِنَّ ٱللَّهَ يُحِبُّ ٱلۡمُتَوَكِّلِينَ 159
Pẹlu okunfa ikẹ kan ti o tobi lati ọdọ Ọlọhun Ọba Allah ni iwa rẹ - irẹ Anọbi - fi jẹ ohun ti o rọ pẹlu awọn eniyan rẹ, ati wipe ti o ba jẹ ẹniti o le nibi gbolohun rẹ ati isẹ rẹ ni ẹniti ọkan rẹ le, wọn ko ba fọn kan kuro ni ọdọ rẹ, waa maa se amojukuro aseeto wọn nibi ẹtọ rẹ fun wọn, ki o si maa wa aforijin fun wọn, ki o si maa beere fun irori wọn nibi ohun ti o bukaata si ajọro, ti o ba wa ti takoko ipinnu rẹ lori alamọri kan lẹyin ijiroro, waa maa lọ nibẹ, ati wipe ki o gbe ara le Ọlọhun Ọba Allah, dajudaju Ọlọhun Ọba Allah ma nnifẹ awọn ti wọn ma ngbe ara le E, ni O fi ma nfi wọn se kongẹ, ti O si tun ma nkun wọn lọwọ.
إِن يَنصُرۡكُمُ ٱللَّهُ فَلَا غَالِبَ لَكُمۡۖ وَإِن يَخۡذُلۡكُمۡ فَمَن ذَا ٱلَّذِي يَنصُرُكُم مِّنۢ بَعۡدِهِۦۗ وَعَلَى ٱللَّهِ فَلۡيَتَوَكَّلِ ٱلۡمُؤۡمِنُونَ 160
Ti Ọlọhun Ọba Allah ba kun yin lọwọ pẹlu iranlọwọ ati aranse Rẹ, ko si ẹnikankan ti yoo bo ori yin, koda ki gbogbo ara ile ko jọ lori yin, ati wipe nigbati wọn ba fi riran yin se silẹ, ti O ti yin si ara yin, ko si ẹnikankan ti yoo kapa lati ran yin lọwọ lẹyin Rẹ, nitori wipe aranse ọwọ Rẹ nikan soso ni o wa, ati wipe Ọlọhun Ọba Allah ni ki awọn olugbagbọ ododo maa gbe ara le, kii se lori ẹnikankan ti o yatọ si.
وَمَا كَانَ لِنَبِيٍّ أَن يَغُلَّۚ وَمَن يَغۡلُلۡ يَأۡتِ بِمَا غَلَّ يَوۡمَ ٱلۡقِيَٰمَةِۚ ثُمَّ تُوَفَّىٰ كُلُّ نَفۡسٖ مَّا كَسَبَتۡ وَهُمۡ لَا يُظۡلَمُونَ 161
Ko ni ẹtọ fun Anọbi kankan ninu awọn Anọbi ki o se ijanba pẹlu mimu nkankan ninu ọrọ ogun yatọ si Ọlọhun Ọba Allah sa ni ẹsa pẹlu rẹ, ẹniti o ba wa janba ninu yin pẹlu mimu nkankan ninu ọrọ ogun, wọn yoo jẹ niya pẹlu ki wọn tu sita ni Ọjọ Igbende, yoo waa wa ni ẹniti yoo gbe ohun ti o mu ru ni iwaju ẹda, lẹyin igba naa ni wọn yoo fun ẹmin kọọkan ni ẹsan ohun ti o ba se, ni ohun ti o pe perepere, ti ko nii dinku, ati wipe awọn , wọn ko nii se abosi wọn pẹlu lile awọn asise wọn kun tabi didin awọn isẹẹre wọn ku.
أَفَمَنِ ٱتَّبَعَ رِضۡوَٰنَ ٱللَّهِ كَمَنۢ بَآءَ بِسَخَطٖ مِّنَ ٱللَّهِ وَمَأۡوَىٰهُ جَهَنَّمُۖ وَبِئۡسَ ٱلۡمَصِيرُ 162
Ko le se deede ni ọdọ Ọlọhun Ọba Allah ẹniti o tẹle ohun ọwọ rẹ yoo fi tẹ iyọnu Ọlọhun Ọba Allah ninu nini igbagbọ ati isẹ oloore, ati ẹniti o se aigbagbọ pẹlu Ọlọhun Ọba Allah, ti o tun waa se awọn isẹ buburu, ti o waa sẹri pẹlu ibinu kan ti o lagbara lati ọdọ Ọlọhun Ọba Allah, ati wipe ibujoko rẹ ni Jahannamọ, ati wipe o si buru ni ibupadasi ati ibujoko.
هُمۡ دَرَجَٰتٌ عِندَ ٱللَّهِۗ وَٱللَّهُ بَصِيرُۢ بِمَا يَعۡمَلُونَ 163
Awọn jẹ ẹniti o ga ju ara wọn ni ibi awọn ipo wọn ni ile aye ati ni ọrun ni ọdọ Ọlọhun Ọba Allah, ati wipe Ọlọhun Ọba Allah ni Oluri ohun ti wọn nse nisẹ, nkankan ko si lee pamọ fun Un, Yoo si pada san olukuluku ni ẹsan pẹlu isẹ rẹ.
لَقَدۡ مَنَّ ٱللَّهُ عَلَى ٱلۡمُؤۡمِنِينَ إِذۡ بَعَثَ فِيهِمۡ رَسُولٗا مِّنۡ أَنفُسِهِمۡ يَتۡلُواْ عَلَيۡهِمۡ ءَايَٰتِهِۦ وَيُزَكِّيهِمۡ وَيُعَلِّمُهُمُ ٱلۡكِتَٰبَ وَٱلۡحِكۡمَةَ وَإِن كَانُواْ مِن قَبۡلُ لَفِي ضَلَٰلٖ مُّبِينٍ 164
Paapaa Ọlọhun Ọba Allah ti se idẹra lori awọn olugbagbọ ododo, ati wipe O si daadaa si wọn nigbati O gbe dide laarin wọn ojisẹ kan ninu iran wọn, ti o nka Alukuraani fun wọn, ti o si nfọ wọn mọ kuro nibi ẹbọ ati awọn iwa iyẹpẹrẹ, ati wipe o nkọ wọn ni Alukuraani ati ilana Anọbi, ati wipe paapaa wọn wa siwaju gbigbe ojisẹ yii dide ninu anu ti o fi oju han kuro nibi imọna ati ọnaamọ.
أَوَلَمَّآ أَصَٰبَتۡكُم مُّصِيبَةٞ قَدۡ أَصَبۡتُم مِّثۡلَيۡهَا قُلۡتُمۡ أَنَّىٰ هَٰذَاۖ قُلۡ هُوَ مِنۡ عِندِ أَنفُسِكُمۡۗ إِنَّ ٱللَّهَ عَلَىٰ كُلِّ شَيۡءٖ قَدِيرٞ 165
Se nigbati o sẹlẹ yin - ẹyin olugbagbọ ododo - adanwo kan nigbati wọn bori yin ni Uhud, ati wipe wọn pa ẹniti wọn pa ninu yin, ti o si jẹ wipe paapaa ẹ ti fi ọwọ ba ọta yin ni adipele rẹ nibi awọn ti wọn pa, ati awọn ti wọn ko ni ẹru ni Ọjọ Badiri, ti ẹ wa sọ wipe: nibo ni eleyi ti kan wa, ti o si jẹ wipe olugbagbọ ododo ni wa, ati wipe Anọbi Ọlọhun Ọba si nbẹ laarin wa? ! Sọ - irẹ Anọbi - wipe: ohun ti o ba kan yin ninu nkan naa, o waa de ba yin pẹlu okunfa ara yin ni, nigbati ẹ se ifanfan, ti ẹ si tun wa yapa ojisẹ naa, dajudaju Ọlọhun Ọba Allah ni Alagbara lori gbogbo nkan, ni O fi ma nran ẹniti O ba fẹ se, ati wipe O si ma nyẹpẹrẹ ẹniti O ba fẹ.
Aranse ododo lati ọdọ Ọlọhun Ọba Allah (ti ọla Rẹ ga) ni o ti ma nwa, toripe Oun ni Alagbara ti wọn ko le ja ni ogun, ati wipe Olubori ni ti wọn ko lee bori.
Ko lee se deedee ni ile aye isesi ẹniti o ba tẹle imọna Ọlọhun Ọba Allah, ti o si tun sisẹ pẹlu rẹ ati isesi ẹniti o gunri , ti o si tun pe ni irọ, gẹgẹ bi o se jẹ wipe awọn ipo wọn naa ko lee se deedee ni Ọjọ Ikẹyin.
Ohun ti o ba sọkalẹ pẹlu ẹru ninu adanwo ati awọn idaamu, o wa pẹlu okunfa awọn ẹsẹ rẹ, ati wipe paapaa o le jẹ adanwo ati gbigbe awọn ipo ga, ati wipe Ọlọhun Ọba Allah ma nse amojukuro, O si tun ma ngbe ẹmin kuro nibi ọpọlọpọ rẹ.