فَبِمَا نَقۡضِهِم مِّيثَٰقَهُمۡ وَكُفۡرِهِم بَِٔايَٰتِ ٱللَّهِ وَقَتۡلِهِمُ ٱلۡأَنۢبِيَآءَ بِغَيۡرِ حَقّٖ وَقَوۡلِهِمۡ قُلُوبُنَا غُلۡفُۢۚ بَلۡ طَبَعَ ٱللَّهُ عَلَيۡهَا بِكُفۡرِهِمۡ فَلَا يُؤۡمِنُونَ إِلَّا قَلِيلٗا 155
A le wọn jinna kuro nibi ikẹ wa nitori okunfa adehun ti o kanpa ti wọn ja, ati nitori okunfa sise keferi si awọn amin Ọlọhun Ọba Allah ati igboya wọn si pipa awọn Anọbi, ati gbolohun wọn ti wọn sọ fun Muhammad ti ikẹ ati ọla nbẹ fun: ọkan wa ninu ebibo, kiyesi nkan ti o nsọ, bẹẹni alamọri ọrọ ko ri bi wọn ti sọ, bikose wipe Ọlọhun Ọba Allah di ọkan wọn nititori aigbagbo won, ti rere ko lee de ibẹ, wọn ko le ni igbagbọ ayaafi igbagbọ kekere ti ko le se anfaani fun wọn.
وَبِكُفۡرِهِمۡ وَقَوۡلِهِمۡ عَلَىٰ مَرۡيَمَ بُهۡتَٰنًا عَظِيمٗا 156
A le wọn jinna si ikẹ naa nitori okunfa keferi wọn ati titori okunfa adapa irọ ti wọn si Maryam pẹlu agbere niti ẹri eke ati adapa irọ.
وَقَوۡلِهِمۡ إِنَّا قَتَلۡنَا ٱلۡمَسِيحَ عِيسَى ٱبۡنَ مَرۡيَمَ رَسُولَ ٱللَّهِ وَمَا قَتَلُوهُ وَمَا صَلَبُوهُ وَلَٰكِن شُبِّهَ لَهُمۡۚ وَإِنَّ ٱلَّذِينَ ٱخۡتَلَفُواْ فِيهِ لَفِي شَكّٖ مِّنۡهُۚ مَا لَهُم بِهِۦ مِنۡ عِلۡمٍ إِلَّا ٱتِّبَاعَ ٱلظَّنِّۚ وَمَا قَتَلُوهُ يَقِينَۢا 157
A sẹbi le wọn nitori gbolohun wọn ni ẹniti nfi irọ se iyanran: awa ni a pa Isa ẹni mimọ ọmọ maryam ojisẹ Allah, wọn ko paa gẹgẹ bi wọn se npe apemọra rẹ, wọn ko kan mọ agbelebu sugbọn wọn pa arakunrin kan ti Ọlọhun Ọba Allah fi afijọ Isa sii lara, wọn si kan mọ agbelebu, wọn wa nlero wipe ẹniti wọn pa ni Anọbi Isa ki ike ati ọla maa ba, awọn ti wọn npe apemọra pipaa ninu awọn yahuudi ati awọn ti wọn faa le wọn lọwọ ninu awọn nasaara, awọn mejeeji ni wọn wa ni idaamu nipa ọrọ rẹ ati iyemeji, wọn nimọ nipa rẹ, wọn kan ntẹle erongba ni, bẹẹni erongba ko le roni lọrọ nibi ododo rara, wọn ko pa Isa, bẹẹni wọn ko kan mọ agbelebu kankan rara.
بَل رَّفَعَهُ ٱللَّهُ إِلَيۡهِۚ وَكَانَ ٱللَّهُ عَزِيزًا حَكِيمٗا 158
Bikose wipe Ọlọhun Ọba Allah laa kuro nibi ete wọn, Ọlọhun Ọba Allah si gbe pẹlu ara ati ẹminrẹ si ọdọ Rẹ, bẹẹni O jẹ Alagbara ninu ọla Rẹ, ẹnikankan ko le bori Rẹ, Ọjọgbọn ni nibi idari Rẹ ati ise Rẹ ati ofin Rẹ.
وَإِن مِّنۡ أَهۡلِ ٱلۡكِتَٰبِ إِلَّا لَيُؤۡمِنَنَّ بِهِۦ قَبۡلَ مَوۡتِهِۦۖ وَيَوۡمَ ٱلۡقِيَٰمَةِ يَكُونُ عَلَيۡهِمۡ شَهِيدٗا 159
Ko si ẹnikankan ninu awọn ti a fun ni tira ayaafi ki o ni igbagbọ si Isa lẹyin sisọkalẹ rẹ ni igbẹyin igba ati siwaju iku rẹ, ni ọjọ igbende, Anọbi Isa yoo jẹ olujẹri lori awọn isẹẹ wọn; eyiti o ba se deede ofin ninu rẹ tabi ti o yapa.
فَبِظُلۡمٖ مِّنَ ٱلَّذِينَ هَادُواْ حَرَّمۡنَا عَلَيۡهِمۡ طَيِّبَٰتٍ أُحِلَّتۡ لَهُمۡ وَبِصَدِّهِمۡ عَن سَبِيلِ ٱللَّهِ كَثِيرٗا 160
Okunfa abosi yahuudi nipe a se leewọ fun wọn apakan wọn, nojẹ ti o dara, eyiti o jẹ ẹtọ fun wọn, a se leewọ fun wọn gbogbo nkan ti o jẹ eekanna, gẹgẹ bi maalu ati agutan, a se ọra awọn mejeeji ni eewọ fun wọn ayaafi ohun ti o ba han de ni ara mejeeji, ati nitori okunfa ikọdi ara wọn ati kikọdi ẹlomiran kuro ni oju ọna ti Ọlọhun Ọba Allah titi ti ikọdi kuro nibi rere fi di adamọ wọn.
وَأَخۡذِهِمُ ٱلرِّبَوٰاْ وَقَدۡ نُهُواْ عَنۡهُ وَأَكۡلِهِمۡ أَمۡوَٰلَ ٱلنَّاسِ بِٱلۡبَٰطِلِۚ وَأَعۡتَدۡنَا لِلۡكَٰفِرِينَ مِنۡهُمۡ عَذَابًا أَلِيمٗا 161
Ati nitori riba jijẹ lẹyin igbati Ọlọhun Ọba Allah ti kọ fun wọn kuro nibi gbigbaa, ati nitori gbigba dukia awọn eniyan ni ọna ti ofin ẹsin ko se ni ẹtọ, A ti pese fun awọn keferi iya onitara.
Nigbati wọn nsọ awọn kudiẹ-kudiẹ awọn ti a fun ni tira, bẹẹnaa ni wọn sọ nipa awọn olugbagbọ ninu wọn, wọn wa sọ wipe:
لَّٰكِنِ ٱلرَّٰسِخُونَ فِي ٱلۡعِلۡمِ مِنۡهُمۡ وَٱلۡمُؤۡمِنُونَ يُؤۡمِنُونَ بِمَآ أُنزِلَ إِلَيۡكَ وَمَآ أُنزِلَ مِن قَبۡلِكَۚ وَٱلۡمُقِيمِينَ ٱلصَّلَوٰةَۚ وَٱلۡمُؤۡتُونَ ٱلزَّكَوٰةَ وَٱلۡمُؤۡمِنُونَ بِٱللَّهِ وَٱلۡيَوۡمِ ٱلۡأٓخِرِ أُوْلَٰٓئِكَ سَنُؤۡتِيهِمۡ أَجۡرًا عَظِيمًا 162
Sugbọn awọn ti wọn fẹsẹ rinlẹ ti wọn si ni amọdaju ninu imọ ninu awọn yahuudi, ati awọn olugbagbọ ododo, wọn npe ohun ti Ọlọhun Ọba Allah sọkalẹ funn ọ lododo - irẹ ojisẹ - gẹgẹ bi Alukuraani, wọn si tun npe lododo ohun ti wọn sọkalẹ ninu awọn tira, fun awọn ti wọn ti siwaju rẹ ninu ojisẹ, gẹgẹ bi taoreeta ati injiila, wọn si ngbe irun duro, wọn si nyọ saka ninu dukia wọn, wọn si gba ijọkan soso Ọlọhun Ọba Allah lododo ti wọn ko mu ororgun mọ Ọ, bẹẹ ni wọn gba ọjọ igbende lododo; awọn eleyi a royin pẹlu awọn iroyin naa, a o fun wọn ni ẹsan ti o tobi.
Igbeyin aigbagbo ni ki edidi di awon okan, ki edidi di awọn ọkan jẹ okunfa sise agbọye ni eewọ fun un.
Sise alaye mimu ti yahuudi mu Anọbi Ọlọhun Ọba Allah tii se Isa ni ọta, titi ti o fi debi ipo gbigbero lati paa.
Sise alaye aimọkan nasaara ati didaamu wọn nipa ọrọ agbelebu ati igbesẹ wọn nipa rẹ pẹlu erongba ti ko dara.
Sise alaye ọla imọ, dajudaju o nbẹ ninu awọn ti a fun ni tira ẹniti o jindo ninu imọ titi ti imọ rẹ fi gbe de bi nini igbagbọ si Anọbi Muhammad ẹniti ike ati ọla nbẹ fun.