مَا لَكُمۡ كَيۡفَ تَحۡكُمُونَ 154
Kilo se yin - ẹyin ẹlẹbọ - ti ẹ nse idajọ ti o fi si ibi kan nigbati ẹ wa nlọ fi ọmọbinrin ti si ọdọ Allah, ti ẹ wa nfi ọmọkunrin ti si ọdọ ara yin?!
أَفَلَا تَذَكَّرُونَ 155
Se ẹ ko ronu si jijẹ ibajẹ ohun ti ẹ wa lori rẹ nipa adisọkan ti ko dara yii?! Ti ẹ ba ronu ni, ẹ ko nii wi gbolohun yii.
أَمۡ لَكُمۡ سُلۡطَٰنٞ مُّبِينٞ 156
Tabi awijare ti o gbọngbọ ati ẹri ti o hande nbẹ fun yin ninu iwe tabi ojisẹ?!
فَأۡتُواْ بِكِتَٰبِكُمۡ إِن كُنتُمۡ صَٰدِقِينَ 157
Ẹ mu iwe yin wa ti o gbe yin lọsi ibi awijare le lori ti ẹ ba jẹ sootọ sootọ nibi ohun ti ẹ npe E.
وَجَعَلُواْ بَيۡنَهُۥ وَبَيۡنَ ٱلۡجِنَّةِ نَسَبٗاۚ وَلَقَدۡ عَلِمَتِ ٱلۡجِنَّةُ إِنَّهُمۡ لَمُحۡضَرُونَ 158
Awọn ẹlẹbọ fi gaga si aarin wọn ati awọn Malaaika lati kọ di wọn kuro nibi mọlẹbi nigbati wọn nro wipe awọn Malaaika jẹ ọmọbinrin fun Allah, paapaa awọn Malaaika si ti mọ wipe Allah yoo mu awọn ẹlẹbọ ti o sẹ fun isiro.
سُبۡحَٰنَ ٱللَّهِ عَمَّا يَصِفُونَ 159
Allah mọ, bẹẹni O si fọmọ kuro nibi ohun ti awọn ẹlẹbọ fi nroyin Rẹ ninu awọn nkan ti ko lẹtọ si mimọ Rẹ gẹgẹ bi ọmọ ati akẹgbẹ ati nkan miran.
إِلَّا عِبَادَ ٱللَّهِ ٱلۡمُخۡلَصِينَ 160
Ayaafi awọn ẹru Allah ti wọn jẹ oluse afọmọ; dajudaju wọn ko nii royin Allah ayaafi ohun ti o lẹtọ si mimọ Rẹ ninu awọn iroyin gbigbọngbọ ati pipe.
فَإِنَّكُمۡ وَمَا تَعۡبُدُونَ 161
Dajudaju ẹyin -ẹyin ẹlẹbọ- ati ohun ti ẹ nsin yatọ si Allah.
مَآ أَنتُمۡ عَلَيۡهِ بِفَٰتِنِينَ 162
Ẹ kii se olusọ ẹnikẹni nu kuro nibi ẹsin ododo.
إِلَّا مَنۡ هُوَ صَالِ ٱلۡجَحِيمِ 163
Ayaafi ẹniti Allah ti kọ akọsilẹ rẹ lori wiwa ninu awọn ọmọ ina, dajudaju Allah yoo mu akọsilẹ Rẹ sẹ, yoo se aimoore, yoo si wọ ina, sugbọn ẹyin ati awọn ohun ti ẹ nsin ko si agbara fun yin lori eleyi.
وَمَا مِنَّآ إِلَّا لَهُۥ مَقَامٞ مَّعۡلُومٞ 164
Awọn Malaaika nsọ ni ẹniti o nsalaye ijẹ ẹru wọn fun Allah ati mimọ kanga wọn kuro nibi ohun ti awọn ẹlẹbọ nlero: ko si ẹnikankan ninu wa ayaafi ko ni aaye ti a mọ fun ijọsin Allah ati itẹle asẹ Rẹ.
وَإِنَّا لَنَحۡنُ ٱلصَّآفُّونَ 165
Ati wipe dajudaju awa - awa Malaaika - paapaa a ma nduro niti tito le raa wọn nibi ijọsin Allah ati itẹle asẹ Rẹ, bẹẹni a si jẹ ẹniti o se afọmọ Allah kuro nibi awọn iroyin ti ko lẹtọ si I ati awọn ẹwa.
وَإِنَّا لَنَحۡنُ ٱلۡمُسَبِّحُونَ 166
Ati wipe dajudaju awa - awa Malaaika - paapaa a ma nduro niti tito le raa wọn nibi ijọsin Allah ati itẹle asẹ Rẹ, bẹẹni a si jẹ ẹniti o se afọmọ Allah kuro nibi awọn iroyin ti ko lẹtọ si I ati awọn ẹwa.
وَإِن كَانُواْ لَيَقُولُونَ 167
Ati wipe dajudaju awọn ẹlẹbọ ninu awọn ara Mẹka wọn jẹ ẹniti o ma nsọ siwaju igbedide Muhammad - ẹniti ọla nbẹ fun -: ti iwe kan ba wa lọdọ wa ninu awọn iwe akọkọ gẹgẹ bi Taoreeta lapejuwe; a ko ba se afọmọ ijọsin fun Allah, opurọ ni wọn nibi eleyi, paapaa Muhammad - ti ikẹ ati ọla nbẹ fun - ti waa ba wọn pẹlu Alukuraani, wọn si se aimoore si i, wọn yoo pada wa mọ ohun ti o nreti wọn ninu iya ni ọjọ igbende.
لَوۡ أَنَّ عِندَنَا ذِكۡرٗا مِّنَ ٱلۡأَوَّلِينَ 168
Ati wipe dajudaju awọn ẹlẹbọ ninu awọn ara Mẹka wọn jẹ ẹniti o ma nsọ siwaju igbedide Muhammad - ẹniti ọla nbẹ fun -: ti iwe kan ba wa lọdọ wa ninu awọn iwe akọkọ gẹgẹ bi Taoreeta lapejuwe; a ko ba se afọmọ ijọsin fun Allah, opurọ ni wọn nibi eleyi, paapaa Muhammad - ti ikẹ ati ọla nbẹ fun - ti waa ba wọn pẹlu Alukuraani, wọn si se aimoore si i, wọn yoo pada wa mọ ohun ti o nreti wọn ninu iya ni ọjọ igbende.
لَكُنَّا عِبَادَ ٱللَّهِ ٱلۡمُخۡلَصِينَ 169
Ati wipe dajudaju awọn ẹlẹbọ ninu awọn ara Mẹka wọn jẹ ẹniti o ma nsọ siwaju igbedide Muhammad - ẹniti ọla nbẹ fun -: ti iwe kan ba wa lọdọ wa ninu awọn iwe akọkọ gẹgẹ bi Taoreeta lapejuwe; a ko ba se afọmọ ijọsin fun Allah, opurọ ni wọn nibi eleyi, paapaa Muhammad - ti ikẹ ati ọla nbẹ fun - ti waa ba wọn pẹlu Alukuraani, wọn si se aimoore si i, wọn yoo pada wa mọ ohun ti o nreti wọn ninu iya ni ọjọ igbende.
فَكَفَرُواْ بِهِۦۖ فَسَوۡفَ يَعۡلَمُونَ 170
Ati wipe dajudaju awọn ẹlẹbọ ninu awọn ara Mẹka wọn jẹ ẹniti o ma nsọ siwaju igbedide Muhammad - ẹniti ọla nbẹ fun -: ti iwe kan ba wa lọdọ wa ninu awọn iwe akọkọ gẹgẹ bi Taoreeta lapejuwe; a ko ba se afọmọ ijọsin fun Allah, opurọ ni wọn nibi eleyi, paapaa Muhammad - ti ikẹ ati ọla nbẹ fun - ti waa ba wọn pẹlu Alukuraani, wọn si se aimoore si i, wọn yoo pada wa mọ ohun ti o nreti wọn ninu iya ni ọjọ igbende.
وَلَقَدۡ سَبَقَتۡ كَلِمَتُنَا لِعِبَادِنَا ٱلۡمُرۡسَلِينَ 171
Paapaa gbolohun wa ti siwaju fun awọn ojisẹ wa wipe awọn ni wọn yoo jẹ ẹni aranse lori awọn ọta wọn lati ibi ẹri ati agbara ti Allah fi se idẹkun fun wọn, ati wipe dajudaju ibori nbẹ fun awọn ọmọ ogun wa, ti wọn njagun si oju ọna Allah, ki gbolohun Allah le jẹ ohun ti o ga.
إِنَّهُمۡ لَهُمُ ٱلۡمَنصُورُونَ 172
Paapaa gbolohun wa ti siwaju fun awọn ojisẹ wa wipe awọn ni wọn yoo jẹ ẹni aranse lori awọn ọta wọn lati ibi ẹri ati agbara ti Allah fi se idẹkun fun wọn, ati wipe dajudaju ibori nbẹ fun awọn ọmọ ogun wa, ti wọn njagun si oju ọna Allah, ki gbolohun Allah le jẹ ohun ti o ga.
وَإِنَّ جُندَنَا لَهُمُ ٱلۡغَٰلِبُونَ 173
Paapaa gbolohun wa ti siwaju fun awọn ojisẹ wa wipe awọn ni wọn yoo jẹ ẹni aranse lori awọn ọta wọn lati ibi ẹri ati agbara ti Allah fi se idẹkun fun wọn, ati wipe dajudaju ibori nbẹ fun awọn ọmọ ogun wa, ti wọn njagun si oju ọna Allah, ki gbolohun Allah le jẹ ohun ti o ga.
فَتَوَلَّ عَنۡهُمۡ حَتَّىٰ حِينٖ 174
Ki o ya gunri - irẹ ojisẹ - kuro ni ọdọ awọn ẹlẹbọ olorikunkun naa fun asiko kan ti Allah mọ titi asiko iya wọn yoo fi de.
وَأَبۡصِرۡهُمۡ فَسَوۡفَ يُبۡصِرُونَ 175
Maa wo wọn niran nigbati iya ba nsọkalẹ fun wọn, wọn yoo pada riran nigbati iriran ko nii se wọn ni anfaani mọ.
أَفَبِعَذَابِنَا يَسۡتَعۡجِلُونَ 176
Se awọn ẹlẹbọ wọnyi nkanju iya Allah ni bi?!
فَإِذَا نَزَلَ بِسَاحَتِهِمۡ فَسَآءَ صَبَاحُ ٱلۡمُنذَرِينَ 177
Nigbati iya Allah ba sọkalẹ fun wọn, biburu aarọ naa fun wọn.
وَتَوَلَّ عَنۡهُمۡ حَتَّىٰ حِينٖ 178
Ki o si tun gunri - irẹ ojisẹ - kuro ni ọdọ wọn titi Allah yoo fi kadara iya wọn.
وَأَبۡصِرۡ فَسَوۡفَ يُبۡصِرُونَ 179
Ki o maa woye, awọn wọnyi naa yoo maa woye si iya Allah ati ẹsan Rẹ.
سُبۡحَٰنَ رَبِّكَ رَبِّ ٱلۡعِزَّةِ عَمَّا يَصِفُونَ 180
Ọlọhun Ọba rẹ mọ - irẹ Muhammad - Ọba Alagbara, O si mọ kanga kuro nibi ohun ti awọn ẹlẹbọ fi nroyin Rẹ ninu awọn iroyin adinku.
وَسَلَٰمٌ عَلَى ٱلۡمُرۡسَلِينَ 181
Ikini Allah ati ẹyin Rẹ ki o maa bẹ fun awọn ojisẹ alapọnle.
وَٱلۡحَمۡدُ لِلَّهِ رَبِّ ٱلۡعَٰلَمِينَ 182
Ẹyin naa patapata fun Allah ti mimọ nbẹ fun ti o si ga julọ, Oun ni o lẹtọ si i, Oun si ni olutọju gbogbo agbanla aye lapapọ, ko si ọlọhun miran fun wọn yatọ si I.
Isesi Allah ni ki O se aranse fun awọn ojisẹ Rẹ, yoo si sogun awijare ati ibori fun wọn, bẹẹni ninu awọn aayah naa iwe idunnu ti o tobi wa nibẹ; fun ẹniti o ba gba iroyin wipe o wa ninu ọmọ ogun Allah, dajudaju oun ni yoo bori ti yoo si ri aranse.
Ẹri lori alaye ikagara awọn ẹlẹbọ ati ikagara awọn ọlọhun wọn kuro nibi sisọ ẹnikẹni nu wa ninu awọn aayah naa ati ifun awọn ẹru Allah ti wọn jẹ alafọmọ ni iro idunnu wipe dajudaju Allah yoo la wọn nibi sisọ awọn ẹni anu alusọninu pẹlu agbara Rẹ.