ثُمَّ أَنزَلَ عَلَيۡكُم مِّنۢ بَعۡدِ ٱلۡغَمِّ أَمَنَةٗ نُّعَاسٗا يَغۡشَىٰ طَآئِفَةٗ مِّنكُمۡۖ وَطَآئِفَةٞ قَدۡ أَهَمَّتۡهُمۡ أَنفُسُهُمۡ يَظُنُّونَ بِٱللَّهِ غَيۡرَ ٱلۡحَقِّ ظَنَّ ٱلۡجَٰهِلِيَّةِۖ يَقُولُونَ هَل لَّنَا مِنَ ٱلۡأَمۡرِ مِن شَيۡءٖۗ قُلۡ إِنَّ ٱلۡأَمۡرَ كُلَّهُۥ لِلَّهِۗ يُخۡفُونَ فِيٓ أَنفُسِهِم مَّا لَا يُبۡدُونَ لَكَۖ يَقُولُونَ لَوۡ كَانَ لَنَا مِنَ ٱلۡأَمۡرِ شَيۡءٞ مَّا قُتِلۡنَا هَٰهُنَاۗ قُل لَّوۡ كُنتُمۡ فِي بُيُوتِكُمۡ لَبَرَزَ ٱلَّذِينَ كُتِبَ عَلَيۡهِمُ ٱلۡقَتۡلُ إِلَىٰ مَضَاجِعِهِمۡۖ وَلِيَبۡتَلِيَ ٱللَّهُ مَا فِي صُدُورِكُمۡ وَلِيُمَحِّصَ مَا فِي قُلُوبِكُمۡۚ وَٱللَّهُ عَلِيمُۢ بِذَاتِ ٱلصُّدُورِ 154
Lẹyin igba naa ni O wa sọkalẹ fun yin ifọkanbalẹ ati igbẹkẹle lẹyin inira ati ifunpinpin, ti O wa sọ ikọ kan ninu yin - awọn naa ni awọn ti wọn ni igbẹkẹle pẹlu adehun Ọlọhun Ọba Allah - di ẹniti oogbe waa mu nibi ohun ti nbẹ ninu awọn ọkan wọn ninu ifọkanbalẹ ati ifayabalẹ, ati wipe awọn ikọ miran ifakanbalẹ ati oogbe ko to wọn lọwọ, awọn naa ni awọn oloju-eji, awọn ti ko si ero kankan fun wọn ayaafi lila awọn ẹmin wọn, awọn ni wọn wa ninu ila-ilo ati ibẹru, ti wọn wa nlero buburu pẹlu Ọlọhun Ọba Allah nibi wipe dajudaju Ọlọhun Ọba Allah ko nii ran ojisẹ Rẹ se, ati wipe ko nii kun awọn ẹrusin Rẹ lọwọ, gẹg bi ero awọn eeyan igba aimọkan, awọn ti wọn ko gbe Ọlọhun Ọba Allah si ipo to yẹ Ẹ, awọn oloju-eji yii wa nsọ niti aimọkan wọn pẹlu Ọlọhun Ọba Allah wipe: ko si irori kankan fun wa nibi alamọri jijade lọsi oju ogun, ati wipe ti o ba se wipe o wa fun wa ni, a ba ti jade, sọ - irẹ Anọbi - ni ẹniti nda awọn wọnyi lohun wipe : dajudaju alamọri, gbogbo rẹ ti Ọlọhun Ọba Allah ni, Oun ni Ẹniti O ma nkadara ohun ti O ba fẹ, ti O si tun ma ndajọ ohun ti ba wu U, ati wipe Oun ni Ẹniti O kadara jijade yin. Awọn oloju-eji yii nfi pamọ si inu ẹmin wọn ohun ti wn ko le fi han si yin ninu iyemeji ati ero buburu, nibi ti wọn ti ma nsọ wipe ti o ba jẹ wipe irori nbẹ fun wa nibi jijade ni, wọn ko nii pa wa si aaye yii, sọ - irẹ Anọbi - ni ẹniti o nda ọrọ pada fun wọn wipe: ti o ba jẹ wipe ẹ wa ninu awọn ile yin ni ẹniti o jinna si awọn aaye pipa ati iku, awọn ti Ọlọhun Ọba Allah kọ iku le lori ninu yin ko ba jade lọ si ibi ti wọn yoo ti paa wọn, ati wipe Ọlọhun Ọba Allah ko kọ nkan naa ayaafi lati se ayẹwo fun ohun ti nbẹ ninu igbaaya yin ninu awọn adisọkan ati awọn ero, ati wipe Yoo waa se iyatọ nibi ohun ti nbẹ nibẹ ninu nini igbagbọ ati sise oju-eji, ati wipe Ọlọhun Ọba Allah ni Onimimọ nipa ohun ti o nbẹ ninu agbaaya awọn ẹrusin Rẹ, ti nkankan ko si lee pamọ fun nibẹ.
إِنَّ ٱلَّذِينَ تَوَلَّوۡاْ مِنكُمۡ يَوۡمَ ٱلۡتَقَى ٱلۡجَمۡعَانِ إِنَّمَا ٱسۡتَزَلَّهُمُ ٱلشَّيۡطَٰنُ بِبَعۡضِ مَا كَسَبُواْۖ وَلَقَدۡ عَفَا ٱللَّهُ عَنۡهُمۡۗ إِنَّ ٱللَّهَ غَفُورٌ حَلِيمٞ 155
Dajudaju awọn ti wọn bori wọn ninu yin, - ẹyin ijọ Muhammad (ki Ọlọhun se ikẹ ati igẹ fun un) - ni ọjọ ti akojọ awọn ọsẹbọ pade pẹlu akojọ awọn Musulumi ni Huud, dajudaju esu ni o gbe wọn lọ si bi yiyẹ pẹlu okunfa apakan ohun ti wọn se ninu awọn iyapa, ati wipe paapaa Ọlọhun Ọba Allah ti se amojukuro fun wọn, ko si fi nkan naa mu wọn ni ọla lati ọdọ Rẹ ati ikẹ, dajudaju Ọlọhun Ọba Allah ni Olufi ori jin ẹniti o ba ronu piwada, Oni suuru si ni ti kii si kanju fifi iya jẹni.
يَٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ لَا تَكُونُواْ كَٱلَّذِينَ كَفَرُواْ وَقَالُواْ لِإِخۡوَٰنِهِمۡ إِذَا ضَرَبُواْ فِي ٱلۡأَرۡضِ أَوۡ كَانُواْ غُزّٗى لَّوۡ كَانُواْ عِندَنَا مَا مَاتُواْ وَمَا قُتِلُواْ لِيَجۡعَلَ ٱللَّهُ ذَٰلِكَ حَسۡرَةٗ فِي قُلُوبِهِمۡۗ وَٱللَّهُ يُحۡيِۦ وَيُمِيتُۗ وَٱللَّهُ بِمَا تَعۡمَلُونَ بَصِيرٞ 156
Ẹyin ti ẹ ni igbagbọ pẹlu Ọlọhun Ọba Allah, ti wọn si ntẹle ojisẹ Rẹ, ẹ mase da gẹgẹ bi awọn alaigbagbọ ninu awọn oloju-eji, ti wọn ma nsọ fun awọn alasunmọ wọn nigbati wọn ba rin irin-ajo ni ẹniti nwa arisiki, tabi ti wọn ba jẹ jagun-jagun ti wọn waa ku tabi wọn pa wọn wipe: ti o ba jẹ wipe wọn wa ni ọdọ wa ni, ati wipe ti wọn ko jade, ti wọn ko si tun jagun, wọn ko nii ku, wọn ko si tun nii pa wọn, Ọlọhun Ọba Allah fi adisọkan yii si inu awọn ọkan wọn, ki wọn le baa maa lekun ni abamọ ati ibanujẹ ninu awọn ọkan wọn, ati wipe Ọlọhun Ọba Allah nikan soso, Oun ni Ẹniti O le ye, ti O si lee pa pẹlu fifẹ Rẹ, ko le kọ kadara Rẹ jijoko tẹtẹrẹ, ko si le jẹ ki o yara jijade sita, ati wipe Ọlọhun Ọba Allah ni Oluri gbogbo ohun ti ẹ nse, awọn isẹ ko lee pamọ fun Un, ati wipe Yoo pada waa san yin lẹsan lori rẹ.
وَلَئِن قُتِلۡتُمۡ فِي سَبِيلِ ٱللَّهِ أَوۡ مُتُّمۡ لَمَغۡفِرَةٞ مِّنَ ٱللَّهِ وَرَحۡمَةٌ خَيۡرٞ مِّمَّا يَجۡمَعُونَ 157
Ati wipe ti wọn ba pa yin si oju ọna Ọlọhun Ọba Allah, tabi ti ẹ ba ku - ẹyin olugbagbọ ododo - Ọlọhun Ọba Allah Yoo fi ori jin yin ni aforijin kan ti o tobi, ati wipe Yoo si kẹ yin ni ikẹ kan lati ọdọ Rẹ, ohun ni o ni oore ju aye yii lọ ati ohun ti awọn eniyan ibẹ nko jọ nibẹ ninu awọn igbadun rẹ eyiti yoo yẹ.
Sise aimọkan pẹlu Ọlọhun Ọba Allah (ti ọla Rẹ ga) , ati awọn iroyin Rẹ yoo jogun adisọkan buburu ati biba jẹ awọn isẹ.
Awọn asiko awọn ẹrusin jẹ ohun ti wọn ti fi lelẹ, ti wọn si ti fi aala si, gbigba iwaju ati sise akin ko le jẹ ki o yara, ati wipe sise ojo ati sise oju kokoro ko le lọ lara.
Ninu ilana Ọlọhun Ọba Allah (ti ọla Rẹ ga) eyiti o nlọ ni didan awọn ẹrusin Rẹ wo ki O le baa se iyatọ ohun ti ko dara kuro nibi ohun ti o dara.
Ninu awọn ipo ti o ga ju, ati eyiti o ni apọnle ju ni ọdọ Ọlọhun Ọba Allah (ti ọla Rẹ ga) ni ipo awọn ti wọn ku si oju ọna Rẹ.