وَلَا تَقُولُواْ لِمَن يُقۡتَلُ فِي سَبِيلِ ٱللَّهِ أَمۡوَٰتُۢۚ بَلۡ أَحۡيَآءٞ وَلَٰكِن لَّا تَشۡعُرُونَ 154
Ẹ ma se sọ - ẹyin olugbagbọ ododo - nibi alamọri ẹniti wọn pa si oju ogun, ni oju ọna Ọlọhun Ọba Allah wipe: dajudaju awọn wọnyi, oku ni wọn, wọn ti ku gẹgẹ bi awọn miran naa se ma nku, bikose wipe alaaye niwọn ni ọdọ Ọlọhun Ọba Allah wọn sugbọn ẹyin ko lee ma isẹmin wọn, toripe isẹmin ti o dayatọ ni, ti ko si ọna lati mọọ ayaafi pẹlu imisi lati ọdọ Ọlọhun Ọba Allah.
وَلَنَبۡلُوَنَّكُم بِشَيۡءٖ مِّنَ ٱلۡخَوۡفِ وَٱلۡجُوعِ وَنَقۡصٖ مِّنَ ٱلۡأَمۡوَٰلِ وَٱلۡأَنفُسِ وَٱلثَّمَرَٰتِۗ وَبَشِّرِ ٱلصَّٰبِرِينَ 155
Awa yoo maa danyin wo pẹlu oniranran adanwo; pẹlu nkankan ninu ibẹru awọn ọta yin ati pẹlu ebi lati ara kikere ounjẹ ati pẹlu adinku ninu dukia latari lilọ rẹ tabi lile koko sisẹlẹ rẹ ati pẹlu adinku ninu ẹmin nitori awọn aisan eyiti yoo maa run awọn eniyan tabi pẹlu kiku si oju ọna Ọlọhun Ọba Allah, ati pẹlu adinku ninu awọn nkan eleso eyiti ilẹ nmu jade, waa fun ni iro idunnu - irẹ Anọbi - awọn oni ti wọn ba nse suuru lori awọn adanwo naa pẹlu nkan ti yoo dun wọn ninu ni aye ati ni ọjọ Ikẹyin.
ٱلَّذِينَ إِذَآ أَصَٰبَتۡهُم مُّصِيبَةٞ قَالُوٓاْ إِنَّا لِلَّهِ وَإِنَّآ إِلَيۡهِ رَٰجِعُونَ 156
Awọn ti o jẹ wipe ti adanwo kan ba sẹlẹ si wọn, ninu awọn adanwo naa, wọn yoo sọ pẹlu iyọnu ati ijuwọ silẹ wipe: dajudaju awa o, wa ni abẹ ikapani Ọlọhun Ọba Allah, ti O si le se bi o se wu U lori wa, dajudaju awa yoo si pada si ọdọ Rẹ ni Ọjọ Igbende, Oun ni Ẹniti O da wa, ti O si gbe ọla fun wa pẹlu oniranran idẹra, ọdọ Rẹ ni ibupada sii wa ati ikẹyin alamọri wa.
أُوْلَٰٓئِكَ عَلَيۡهِمۡ صَلَوَٰتٞ مِّن رَّبِّهِمۡ وَرَحۡمَةٞۖ وَأُوْلَٰٓئِكَ هُمُ ٱلۡمُهۡتَدُونَ 157
Awọn ti wọn royin pẹlu awọn iroyin yii, ẹyin nbẹ fun lati ọdọ Ọlọhun Ọba Allah ni agbo awọn Malaika ti o ga, ati ikẹ kan ti yoo maa sọkalẹ le wọn lori, awọn wọn nni, ni ẹniti o mọ ọna lọsi oju ọna ododo.
۞إِنَّ ٱلصَّفَا وَٱلۡمَرۡوَةَ مِن شَعَآئِرِ ٱللَّهِۖ فَمَنۡ حَجَّ ٱلۡبَيۡتَ أَوِ ٱعۡتَمَرَ فَلَا جُنَاحَ عَلَيۡهِ أَن يَطَّوَّفَ بِهِمَاۚ وَمَن تَطَوَّعَ خَيۡرٗا فَإِنَّ ٱللَّهَ شَاكِرٌ عَلِيمٌ 158
Dajudaju oke meji eyiti wọn mọ ni Safa ati Marwah, nibi ti o sun mọ Kaaba ninu awọn amin Ṣeria ti o fi oju han, ẹniti o ba gbero ile naa lati le mu awọn isẹ ‘Hajji’ abi awọn isẹ ‘Umrah’; ko si ẹsẹ fun nibi ki o se apọsẹsẹ laarin awọn mejeeji. O nbẹ nibi lile ẹsan jinna nibi yii, ifi ọkan ẹni balẹ fun ẹniti o ba nri inira ninu awọn Musulumi nibi apọsẹsẹ laarin awọn mejeeji ni ẹniti o nni adisọkan wipe dajudaju o wa ninu alamọri igba aimọkan, paapaa, Ọba (ti ọla Rẹ ga) ti salaye pe dajudaju ohun naa wa ninu isẹ “Hajj”. ẹniti o ba se awọn isẹ asegbọrẹ ninu awọn itẹle ni ẹniti o fi nse asegbọrẹ ati afọmọ; dajudaju Ọlọhun Ọba Allah Yoo dupẹ fun, Yoo da lọwọ rẹ, Yoo si tun san ni ẹsan lori rẹ, Oun ni Ẹniti o ni imọ pẹlu ẹniti o se daadaa, ti o si tun ni ẹtọ si ẹsan.
إِنَّ ٱلَّذِينَ يَكۡتُمُونَ مَآ أَنزَلۡنَا مِنَ ٱلۡبَيِّنَٰتِ وَٱلۡهُدَىٰ مِنۢ بَعۡدِ مَا بَيَّنَّٰهُ لِلنَّاسِ فِي ٱلۡكِتَٰبِ أُوْلَٰٓئِكَ يَلۡعَنُهُمُ ٱللَّهُ وَيَلۡعَنُهُمُ ٱللَّٰعِنُونَ 159
Dajudaju awọn ti wọn nfi oun ti A sọkalẹ pamọ ninu awọn alaye ọrọ eyiti o ntọkasi sisọ ododo Anọbi ati oun ti o mu wa pe re, ninu awọn Yahuudi ati awọn Nasaara ati awon ti o yato siwon, lẹyin oun ti A ti se afihan rẹ si awọn eniyan ninu tira wọn, awọn ni ẹniti Ọlọhun Ọba Allah yoo le jinna kuro nibi ikẹẹ Rẹ, ti awọn Malaika yoo si maa sepe fun won ati awọn Anọbi ati awọn eniyan l’apapọ pẹlu gbigbe jinna si ikẹ Rẹ.
إِلَّا ٱلَّذِينَ تَابُواْ وَأَصۡلَحُواْ وَبَيَّنُواْ فَأُوْلَٰٓئِكَ أَتُوبُ عَلَيۡهِمۡ وَأَنَا ٱلتَّوَّابُ ٱلرَّحِيمُ 160
Ayaafi awọn ti wọn ba pada si ọdọ Ọlọhun Ọba Allah ni ẹniti o kabamọ lori fifi awọn amin ti han naa pamọ, ti wọn si se atunse isẹ wọn, eyiti o han ati eyiti o pamọ, ti wọn si tun se alaye ohun ti wọn fipamọ ninu ododo ati imọna, awọn ni ẹniti maa gba ipada wọn sibi titẹle Mi, Emi si Ẹniti O ma ngba tituuba ẹniti o ba tuuba ninu awọn ẹru, ti o si tun jẹ Ẹniti O nkẹ wọn.
إِنَّ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ وَمَاتُواْ وَهُمۡ كُفَّارٌ أُوْلَٰٓئِكَ عَلَيۡهِمۡ لَعۡنَةُ ٱللَّهِ وَٱلۡمَلَٰٓئِكَةِ وَٱلنَّاسِ أَجۡمَعِينَ 161
Dajudaju awọn ti wọn se aigbagbọ, ti wọn si ku lori aigbagbọ siwaju ki wọn to ronu piwada nibẹ, awọn ni ẹniti ibinu Ọlọhun Ọba Allah yoo maa bẹ lewọn lori pẹli lile wn jinna kuro nibi ikẹ Rẹ, bakanna ni epe awọn Malaika ati awọn eniyan lapapọ yoo maa sẹ le wọn lori pẹlu lile kuro nibi ikẹ Ọlọhun Ọba Allah ati gbigbe jinna kuro nibẹ.
خَٰلِدِينَ فِيهَا لَا يُخَفَّفُ عَنۡهُمُ ٱلۡعَذَابُ وَلَا هُمۡ يُنظَرُونَ 162
Wọn yoo maa wa pẹlu isẹbile yii, ti wọn ko si nii se iya ni fifuyẹ fun wọn koda ko se ọjọ kan pere, wọn ko si nii maa wo wọn niran ni Ọjọ Igbende.
وَإِلَٰهُكُمۡ إِلَٰهٞ وَٰحِدٞۖ لَّآ إِلَٰهَ إِلَّا هُوَ ٱلرَّحۡمَٰنُ ٱلرَّحِيمُ 163
Ẹniti ẹ njọsin fun niti ododo - ẹyin eniyan - ọkan soso ni, ti O si dawa ninu bibẹ Rẹ ati iroyin Rẹ, ko si ẹlomiran ti ijọsin tọsi ni tootọ ti o yatọ si Oun nikan, Oun ni Ọba Onikẹ ti ikẹ Rẹ gbaaye, Ẹniti O si ma nkẹ awọn ẹru Rẹ, ni bi O se pe awọn idẹra ti ko see ka lewọn lori.
Didanni wo ninu ilana Ọlọhun Ọba Allah (ti ọla Rẹ ga) ni ọdọ awọn ẹru Rẹ, paapaa o si ti se adehun fun awọn ti wọn ba se ifarada lori nkan naa pẹlu ẹsan ti o tobi ati ibudesi ti o lapọnle.
Sise ipọsẹsẹ lofin laarin Safa ati Mọrwah fun ẹniti o ba se Hajj lọ si ile naa tabi Umrah.
Ninu awọn ẹsẹ ti o tobi, ti iya rẹ si le koko ni pipa ododo ti Ọlọhun Ọba Allah sọkalẹ rẹ ati didaru mọ awọn eniyan loju ati sisọ won nu kuro ni oju ọna eyiti awọn ojisẹ mu wa.