وَلَا تَقۡرَبُواْ مَالَ ٱلۡيَتِيمِ إِلَّا بِٱلَّتِي هِيَ أَحۡسَنُ حَتَّىٰ يَبۡلُغَ أَشُدَّهُۥۚ وَأَوۡفُواْ ٱلۡكَيۡلَ وَٱلۡمِيزَانَ بِٱلۡقِسۡطِۖ لَا نُكَلِّفُ نَفۡسًا إِلَّا وُسۡعَهَاۖ وَإِذَا قُلۡتُمۡ فَٱعۡدِلُواْ وَلَوۡ كَانَ ذَا قُرۡبَىٰۖ وَبِعَهۡدِ ٱللَّهِ أَوۡفُواْۚ ذَٰلِكُمۡ وَصَّىٰكُم بِهِۦ لَعَلَّكُمۡ تَذَكَّرُونَ 152
O tun se leewọ ki ẹ ma de ibi dukia ọmọ orukan - oun ni ẹniti o padanu baba rẹ siwaju ki o to balaga - ayaafi ohun ti o ba le jẹ anfaani fun un, ti yoo si le dukia rẹ kun titi ti yoo fi balaga, tabi fura si nini igbọnmọ, O si se didin osunwọn ku ni eewọ, bikose wipe deede di dandan fun yin nigbati ẹ ba fa gba tabi ẹ fẹẹ fun nibi tita ati rira, a ko la bọ wọn lọrun ayaafi ohun ti wọn lagbara, nkan ti ko ba rọrun lati sọra fun gẹgẹ bi alekun tabi ẹdiku nibi osunwọn tabi nkan miran, ko si igbanimu le lori, O tun se leewọ fun yin ki ẹ maa sọ ohun ti ko bamun nibi iro, bẹẹ naa ni O tun se ijẹri laini wo ẹniti o sun mọ tabi jinna leewọ, O si tun se jija adehun Ọlọhun Ọba Allah leewọ fun yin nigbati ẹ ba nfi Ọlọhun Ọba Allah se adehun fun awọn eniyan tabi ẹ ba nse adehun fun Ọlọhun Ọba, dandan ni ki ẹ pe adehun, eyi ti o gbawaju yii, Ọlọhun Ọba Allah se ni asẹ ti O kanpa mọ, ki ẹ le baa mọ ranti igbẹyin ọrọ yin.
وَأَنَّ هَٰذَا صِرَٰطِي مُسۡتَقِيمٗا فَٱتَّبِعُوهُۖ وَلَا تَتَّبِعُواْ ٱلسُّبُلَ فَتَفَرَّقَ بِكُمۡ عَن سَبِيلِهِۦۚ ذَٰلِكُمۡ وَصَّىٰكُم بِهِۦ لَعَلَّكُمۡ تَتَّقُونَ 153
O si se leewọ fun yin ki ẹ maa tọ awọn oju ọna anu, O si jẹ dandan fun yin ki ẹ maa tọ oju ọna Ọlọhun Ọba Allah ti o duro tọ eyiti ko si iwọgun nibẹ, oju ọna anu yoo mu yin de bi iyapa ati ijina si oju ọna ododo, itẹle oju ọna Ọlọhun Ọba Allah ti o dutọ yii ni asọtẹlẹ ti nsọ fun yin; ki ẹ le ba maa paya Rẹ pẹlu ki ẹ tẹle awọn asẹ Rẹ, ki ẹ si jinna si ohun ti O kọ.
ثُمَّ ءَاتَيۡنَا مُوسَى ٱلۡكِتَٰبَ تَمَامًا عَلَى ٱلَّذِيٓ أَحۡسَنَ وَتَفۡصِيلٗا لِّكُلِّ شَيۡءٖ وَهُدٗى وَرَحۡمَةٗ لَّعَلَّهُم بِلِقَآءِ رَبِّهِمۡ يُؤۡمِنُونَ 154
Lẹyin igba ti wọn mu iro wa pẹlu ohun ti wọn sọ yii, a mu iro wa wipe awa ni a fun Musaa ni taoreeta niti pipe idẹkun ti o jẹ ẹsan lori isẹ daadaa rẹ ati alaye fun gbogbo ohun ti o ni bukaata si ninu ẹsẹ, ati ẹri lori ododo ati ikẹ ki o le ba nigbagbọ si pipade Ọlọhun Ọba wọn ni ọjọ igbende, ki wọn o si fi isẹ rere mura silẹ fun un.
وَهَٰذَا كِتَٰبٌ أَنزَلۡنَٰهُ مُبَارَكٞ فَٱتَّبِعُوهُ وَٱتَّقُواْ لَعَلَّكُمۡ تُرۡحَمُونَ 155
Alukuraani jẹ iwe kan ti a sọkalẹ pẹlu ọpọlọpọ ibukun; nitori awọn anfaani ẹsin ati ti aye eyiti o ko sinu, ki ẹ ya tẹle ohun ti sọkalẹ ninu rẹ, ki ẹ si sọra fun yiyapa rẹ, ki wọn o le baa kẹ yin.
أَن تَقُولُوٓاْ إِنَّمَآ أُنزِلَ ٱلۡكِتَٰبُ عَلَىٰ طَآئِفَتَيۡنِ مِن قَبۡلِنَا وَإِن كُنَّا عَن دِرَاسَتِهِمۡ لَغَٰفِلِينَ 156
Ki ẹ mọ baa sọ wipe - ẹyin ọlọsẹbọ larubawa -: Ọlọhun Ọba Allah sọ taoreeta ati injiila kalẹ siwaju wa, ko si sọ iwe kankan kalẹ fun wa, awa ko si mọ iwe wọn ọn ka nitori wipe ede wọn kii se ede tiwa.
أَوۡ تَقُولُواْ لَوۡ أَنَّآ أُنزِلَ عَلَيۡنَا ٱلۡكِتَٰبُ لَكُنَّآ أَهۡدَىٰ مِنۡهُمۡۚ فَقَدۡ جَآءَكُم بَيِّنَةٞ مِّن رَّبِّكُمۡ وَهُدٗى وَرَحۡمَةٞۚ فَمَنۡ أَظۡلَمُ مِمَّن كَذَّبَ بَِٔايَٰتِ ٱللَّهِ وَصَدَفَ عَنۡهَاۗ سَنَجۡزِي ٱلَّذِينَ يَصۡدِفُونَ عَنۡ ءَايَٰتِنَا سُوٓءَ ٱلۡعَذَابِ بِمَا كَانُواْ يَصۡدِفُونَ 157
Ati ki ẹ mọ baa sọ wipe: ti Ọlọhun Ọba ba sọ iwe kan kalẹ fun wa ni gẹgẹ bi O se sọ iwe kalẹ fun yahuudi ati nasaara, idurosinsin wa ki ba pọ ju ti wọn lọ, paapaa iwe kan ti waa ba yin, ti Ọlọhun Ọba sọkalẹ fun Anọbi Muhamad ki ikẹ ati maa jẹ tirẹ pẹlu ahọn yin, eleyi si jẹ awijare ti o fi oju han ati awijare lọ si ibi ododo, ati ikẹ fun ijọ naa, ẹ mase maa wa awijare ti ko ni imi ninu, ti yoo wa maa mu ẹri ibajẹ wa, ko si ẹniti o nse abosi to ẹniti npe awọn amin Ọlọhun Ọba Allah nirọ, ti o si gunri kuro nibẹ, a o fi iya jẹ awọn ti wọn gunri kuro nibi awọn amin wa ni iya ti o le koko pẹlu kiki wọn bọ inu ina jahanamọ gẹgẹ bi ẹsan lori isẹri ati igunri kuro nibẹ.
Ko tọ ki a se bi o se wuni nibi dukia ọmọ orukan ayaafi odiwọn ohun ti yoo wulo fun un, a ko si gbọdọ fi dukia rẹ silẹ fun un ayaafi ti o ba de ipo igbọnmọ.
Awọn oju ọna anu pọ, oju ọna Ọlọhun Ọba Allah si jẹ ẹyọ kan, ohun ni o le muni de bi lila kuro nibi iya.
Titẹle iwe yii niti imọ ati isẹ, o wa nibi okunfa ti o tobi lati ri ikẹ Ọlọhun Ọba Allah.