أَفَسِحۡرٌ هَٰذَآ أَمۡ أَنتُمۡ لَا تُبۡصِرُونَ 15
Se idan ni eyiti ẹ fi oju kan ni iya yii?! Tai ẹyin ko fi oju ri ni?!
ٱصۡلَوۡهَا فَٱصۡبِرُوٓاْ أَوۡ لَا تَصۡبِرُواْ سَوَآءٌ عَلَيۡكُمۡۖ إِنَّمَا تُجۡزَوۡنَ مَا كُنتُمۡ تَعۡمَلُونَ 16
Ẹ maa tọ gbigbona ina yii wo, ki ẹ si maa fi ara kin in, ki ẹ si maa se suuru lori inira gbigbona rẹ, bi ẹ ko ba ti ẹ se suuru le lori, deedee ni suuru ati aise suuru yin jẹ, wọn ko nii san yin lẹsan loni ju ohun ti ẹ se ni ile aye gẹgẹ bi keferi ati awọn ẹsẹ.
Nigbati Allah sọ ẹsan awọn onirọ, o tun sọ ẹsan awọn sootọ sootọ olubẹru, O sọpe:
إِنَّ ٱلۡمُتَّقِينَ فِي جَنَّٰتٖ وَنَعِيمٖ 17
dajudaju awọn ti wọn nbẹru Ọlọhun Ọba wọn –pẹlu mimu awọn asẹ Rẹ sẹ ati jinna si awọn nkan ti o kọ- wọn yoo maa wa ninu ọgba idẹra ati idẹkun ti o tobi ti ko nii ja.
فَٰكِهِينَ بِمَآ ءَاتَىٰهُمۡ رَبُّهُمۡ وَوَقَىٰهُمۡ رَبُّهُمۡ عَذَابَ ٱلۡجَحِيمِ 18
Wọn yoo maa fi ohun ti Allah fun wọn se ipapanu ẹgẹ bi awọn adun ohun jijẹ ati ohun mimu ati ifẹ, Ọlọhun wọn ti mimọ nbẹ fun yoo si la wọn kuro nibi iya jahiim; wọn wa jere pẹlu titẹ wọn lọwọ ohun ti wọn fẹ ninu adun ati didaabobo wọn kuro nibi daru dapọ.
كُلُواْ وَٱشۡرَبُواْ هَنِيَٓٔۢا بِمَا كُنتُمۡ تَعۡمَلُونَ 19
Wọn si sọ fun wọn: ẹ maa jẹ, ẹ maa mu ninu ohun ti ẹmin yin nifẹ si niti ifọkanbalẹ ti ẹ ni paya inira tabi suta nibi ohun ti ẹ njẹ tabi ti ẹ nmu; ni ẹsan fun lori awọn isẹ yin ti o dara ni ile aye.
مُتَّكِِٔينَ عَلَىٰ سُرُرٖ مَّصۡفُوفَةٖۖ وَزَوَّجۡنَٰهُم بِحُورٍ عِينٖ 20
Ni ẹniti wọn yoo maa rọgbọku lori awọn ferese ti a se lọsọ, ti wọn ti se ni ohun ti apakan yoo maa da oju kọ apakan, a o si fẹ awọn obinrin ti o funfun, ti oju wọn si fẹ.
وَٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَٱتَّبَعَتۡهُمۡ ذُرِّيَّتُهُم بِإِيمَٰنٍ أَلۡحَقۡنَا بِهِمۡ ذُرِّيَّتَهُمۡ وَمَآ أَلَتۡنَٰهُم مِّنۡ عَمَلِهِم مِّن شَيۡءٖۚ كُلُّ ٱمۡرِيِٕۢ بِمَا كَسَبَ رَهِينٞ 21
Awọn ti o nigbagbọ, ti awọn ọmọ wọn si tẹle wọn ninu igbagbọ naa, a o fi awọn ọmọ wọn pẹlu wọn, ki wọn le jẹ itutu oju fun wọn, koda bi isẹ wọn ko de ibẹ, a ko nii din nkankan ku ninu awọn ẹsan isẹ wọn, gbogbo eniyan ni a o fi isẹ ti o ba se ti ko dara dogo si lọdọ, ẹlomiran ko ni ba gbe nkankan ninu isẹ rẹ.
وَأَمۡدَدۡنَٰهُم بِفَٰكِهَةٖ وَلَحۡمٖ مِّمَّا يَشۡتَهُونَ 22
A o si tun se alekun fun awọn ẹni ọgba idẹra pẹlu awọn oniranran ipapanu, a o si tun se alekun fun wọn pẹlu ohun ti wọn nifẹ si ni ẹran.
يَتَنَٰزَعُونَ فِيهَا كَأۡسٗا لَّا لَغۡوٞ فِيهَا وَلَا تَأۡثِيمٞ 23
Wọn yoo maa fi ife jagba ni inu ọgba idẹra naa, eyiti ohun ti o ma nti ẹyin nkan mimu ni ile aye ko nii ti ẹyin rẹ yọ gẹgẹ bi ọrọ ibajẹ ati ẹsin nitori ihunrira.
۞وَيَطُوفُ عَلَيۡهِمۡ غِلۡمَانٞ لَّهُمۡ كَأَنَّهُمۡ لُؤۡلُؤٞ مَّكۡنُونٞ 24
Awọn ọmọkunrin yoo maa yi wọn ka, ti wọn ti rọ wọn fun sisisẹ sin wọn, wọn yoo da gẹgẹ bi wura ti a tọju pamọ si inu apopo rẹ nibi mimọ kanga ẹran ara wọn ati fifunfun rẹ.
وَأَقۡبَلَ بَعۡضُهُمۡ عَلَىٰ بَعۡضٖ يَتَسَآءَلُونَ 25
Apakan awọn ẹni ọgba idẹra naa yoo da oju kọ apa miran, ti apakan yoo maa beere lọwọ apa miran nipa isesi wọn ni ile aye.
قَالُوٓاْ إِنَّا كُنَّا قَبۡلُ فِيٓ أَهۡلِنَا مُشۡفِقِينَ 26
Wọn yoo wa maa fun wọn lesi: a jẹ ẹniti o npaya nibi iya Allah laarin awọn eniyan wa ni ile aye.
فَمَنَّ ٱللَّهُ عَلَيۡنَا وَوَقَىٰنَا عَذَابَ ٱلسَّمُومِ 27
Allah wa se idẹkun fun wa pẹlu imọna lọsi inu ẹsin alaafia, O si la wa kuro nibi iya ti o de ogongo nibi igbona.
إِنَّا كُنَّا مِن قَبۡلُ نَدۡعُوهُۖ إِنَّهُۥ هُوَ ٱلۡبَرُّ ٱلرَّحِيمُ 28
Dajudaju a jẹ ẹniti o nsin ni isẹmin ile aye, a si npe ki o la wa kuro nibi iya ina, dajudaju Oun jẹ oluse daadaa olododo nibi adehun Rẹ fun awọn ẹru Rẹ onikẹ si wọn, ninu daadaa Rẹ ati ikẹ Rẹ si wa ni ki o fi wa mọ ọna igbagbọ ati ki O si fi wa wọ ọgba idẹra naa, O si tun mu wa jinna si ina.
فَذَكِّرۡ فَمَآ أَنتَ بِنِعۡمَتِ رَبِّكَ بِكَاهِنٖ وَلَا مَجۡنُونٍ 29
Se iranti - irẹ ojisẹ - pẹlu Alukuraani, iwọ kii se alagbegba ti alujannu nriran fun ọ pẹlu idẹkun ti Allah se le ọ lori ninu igbagbọ ati laakaye, bẹẹni o kii se were.
أَمۡ يَقُولُونَ شَاعِرٞ نَّتَرَبَّصُ بِهِۦ رَيۡبَ ٱلۡمَنُونِ 30
Tabi awọn onirọ yii nsọ wipe: dajudaju Muhammad kii se ojisẹ bikosepe o jẹ kọrin kọrin ti a nreti ki iku jabọ, ki a le sin min nipa rẹ.
قُلۡ تَرَبَّصُواْ فَإِنِّي مَعَكُم مِّنَ ٱلۡمُتَرَبِّصِينَ 31
Sọ fun wọn - irẹ ojisẹ -: ẹ maa reti iku mi, emi naa yoo si maa reti iya ti yoo sẹlẹ si yin nitori pe ẹ pe mi nirọ.
Pipa awọn baba ati awọn ọmọ pọ ninu ọgba idẹra naa si inu ibugbe kan soso, koda bi isẹ abala kan ninu wọn ba din ku, ki o le jẹ apaọnle fun lapapọ, ti ayọ naa yoo fi kun.
Ọti ọrun ohun ti a ko fẹ kii gbẹyin mimu rẹ.
Ẹniti o ba bẹru Ọlọhun rẹ ni aye rẹ yoo fi lọkan balẹ ni ọrun rẹ.