وَوَصَّيۡنَا ٱلۡإِنسَٰنَ بِوَٰلِدَيۡهِ إِحۡسَٰنًاۖ حَمَلَتۡهُ أُمُّهُۥ كُرۡهٗا وَوَضَعَتۡهُ كُرۡهٗاۖ وَحَمۡلُهُۥ وَفِصَٰلُهُۥ ثَلَٰثُونَ شَهۡرًاۚ حَتَّىٰٓ إِذَا بَلَغَ أَشُدَّهُۥ وَبَلَغَ أَرۡبَعِينَ سَنَةٗ قَالَ رَبِّ أَوۡزِعۡنِيٓ أَنۡ أَشۡكُرَ نِعۡمَتَكَ ٱلَّتِيٓ أَنۡعَمۡتَ عَلَيَّ وَعَلَىٰ وَٰلِدَيَّ وَأَنۡ أَعۡمَلَ صَٰلِحٗا تَرۡضَىٰهُ وَأَصۡلِحۡ لِي فِي ذُرِّيَّتِيٓۖ إِنِّي تُبۡتُ إِلَيۡكَ وَإِنِّي مِنَ ٱلۡمُسۡلِمِينَ 15
A pa ọmọniyan lasẹ ni asẹ ti a kan pa mọ wipe ki o se daadaa si awọn obi rẹ mejeeji, ki o si se rere fun wọn ni isẹmin aye wọn ati lẹyin iku wọn pẹlu ohun ti ko nii yapa si ofin paapaa julọ iya rẹ eyiti o gbe pẹlu wahala, ti o si sọ pẹlu wahala ati ni asiko ti o fi ninu oyun ti o lo nibẹ ati ibẹrẹ ifunlọyan: tii se ọgbọn osu titi yoo fi de igbati laakaye rẹ ati ara rẹ yoo lagbara, ti o fi de ogoji ọdun, o sọpe: Ọlọhun mi, ni mu ni imọ ki nle dupẹ idẹkun Rẹ eyiti o se fun mi ati fun awọn obi mi mejeeji, ki o si tun nu mi ni imọ ki nle sisẹ rere ti iwọ yoo yọnu si, ti oo si tẹwọ gba lọwọ mi, ba mi tun awọn ọmọ mi se, dajudaju emi sẹri si ọdọ Rẹ kuro nibi awọn ẹsẹ mi, bẹẹ ni dajudaju mo wa ninu awọn olutẹriba fun itẹle ti Rẹ ati awọn olujupa jusẹ silẹ fun awọn asẹ Rẹ.
أُوْلَٰٓئِكَ ٱلَّذِينَ نَتَقَبَّلُ عَنۡهُمۡ أَحۡسَنَ مَا عَمِلُواْ وَنَتَجَاوَزُ عَن سَئَِّاتِهِمۡ فِيٓ أَصۡحَٰبِ ٱلۡجَنَّةِۖ وَعۡدَ ٱلصِّدۡقِ ٱلَّذِي كَانُواْ يُوعَدُونَ 16
Awọn wọnyi ni a o tẹwọgba ẹyiti o dara ninu awọn isẹ rere ti wọn se, a o si se amojukuro awọn asise wọn, a ko ni gba wọn mu le lori, wọn yoo si wa ninu awujọ awọn ẹni ọgba idẹra, adehun yii ti wọn se fun wọn jẹ adehun ododo, yoo si di otitọ ti ko si iyemeji.
Nigbati O sọ apejuwe fun ọmọ rere si awọn obi rẹ mejeeji lati fi se loju kokoro sibi rere, O tun sọ apejuwe fun oluyapa si awọn obi lati lei kuro nibi iyapa obi, O wa sọpe:
وَٱلَّذِي قَالَ لِوَٰلِدَيۡهِ أُفّٖ لَّكُمَآ أَتَعِدَانِنِيٓ أَنۡ أُخۡرَجَ وَقَدۡ خَلَتِ ٱلۡقُرُونُ مِن قَبۡلِي وَهُمَا يَسۡتَغِيثَانِ ٱللَّهَ وَيۡلَكَ ءَامِنۡ إِنَّ وَعۡدَ ٱللَّهِ حَقّٞ فَيَقُولُ مَا هَٰذَآ إِلَّآ أَسَٰطِيرُ ٱلۡأَوَّلِينَ 17
Ẹniti o sọ fun awọn obi rẹ mejeeji, egbe ki o bẹ fun ẹyin mejeeji, se ẹyin mejeeji nse adehun fun mi wipe ki njade ninu saare mi laaye lẹyin iku mi, ti awọn ọgọrun ọdun ti o pọ si ti re kọja, ti awọn eniyan si ti ku nibẹ, ti wọn ko gbe ẹnikankan dide ninu wọn ni aaye?! Awọn obi rẹ mejeeji nwa iranlọwọ lọdọ Allah, ki O fun ọmọ wọn nigbagbọ, awọn mejeeji wa sọ fun ọmọ wọn: iparun ki o bẹ fun ọ, ti iwọ ko ba nigbagbọ si ajinde, ki o ya gba a gbọ, dajudaju adehun Allah si ajinde jẹ ododo ti ko si iyemeji nibẹ, Oun yoo maa sọ ni ẹniti o nsọ itako rẹ si ajinde di tuntun: kinni ohun ti wọn nsọ nipa ajinde yii jẹ, ti kii ba se ohun ti wọn nmu wa ninu awọn tira ti o ti gbawaju ati ohun ti wọn kọ rinlẹ lati ọdọ Allah.
أُوْلَٰٓئِكَ ٱلَّذِينَ حَقَّ عَلَيۡهِمُ ٱلۡقَوۡلُ فِيٓ أُمَمٖ قَدۡ خَلَتۡ مِن قَبۡلِهِم مِّنَ ٱلۡجِنِّ وَٱلۡإِنسِۖ إِنَّهُمۡ كَانُواْ خَٰسِرِينَ 18
Awọn wọnyi ni iya di dandan fun wọn ni awujọ awọn ijọ ti o siwaju wọn ninu alujannu ati eniyan, dajudaju wọn ti jẹ ẹni ofo; wọn sofo ẹmin wọn ati ara ile wọn lati ibi wiwọ ina.
وَلِكُلّٖ دَرَجَٰتٞ مِّمَّا عَمِلُواْۖ وَلِيُوَفِّيَهُمۡ أَعۡمَٰلَهُمۡ وَهُمۡ لَا يُظۡلَمُونَ 19
O nbẹ fun awọn ipin mejeeji - ipin ọgba idẹra ati ipin ina sahiiri - ni ipo ibamun si awọn isẹ wọn, awọn ipo ẹni ọgba idẹra jẹ ngbaega ti o ga, bẹẹni awọn ipo awọn ẹni ina jẹ irẹsilẹ ti o lọọlẹ, ki Allah le san wọn lẹsan isẹ wọn, wọn ko si nii se abosi wọn ni ọjọ igbende pẹlu dindin daadaa wọn ku, bẹẹni wọn ko nii le awọn asise wọn kun.
وَيَوۡمَ يُعۡرَضُ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ عَلَى ٱلنَّارِ أَذۡهَبۡتُمۡ طَيِّبَٰتِكُمۡ فِي حَيَاتِكُمُ ٱلدُّنۡيَا وَٱسۡتَمۡتَعۡتُم بِهَا فَٱلۡيَوۡمَ تُجۡزَوۡنَ عَذَابَ ٱلۡهُونِ بِمَا كُنتُمۡ تَسۡتَكۡبِرُونَ فِي ٱلۡأَرۡضِ بِغَيۡرِ ٱلۡحَقِّ وَبِمَا كُنتُمۡ تَفۡسُقُونَ 20
Ni ọjọ ti wọn yoo sẹri awọn ti o se keferi si Allah, ti wọn si pe awọn ojisẹ Rẹ nirọ si ina ki wọn le fi iya jẹ wọn nibẹ, wọn yoo wa maa sọ fun niti eebu ati idẹruba: eyiti o dara ninu isẹmin aye yin ti di ohun ti ẹ mu lọ, ẹ si gbadun awọn yodo yindin ibẹ, sugbọn ni oni wọn yoo san yin lẹsan iya ti yoo yẹpẹrẹ yin, ti yoo sọ yin di ẹni ilẹ nitori igberaga yin lorilẹ laisi ododo ati nitori jijade yin kuro nibi itẹle ti Allah pẹlu sise keferi ati awọn ẹsẹ.
Sise alaye ipo sise daadaa si awọn obi mejeeji ninu ẹsin alaafia, paapaa julọ nibi ẹtọ ti iya ati isekilọ kuro nibi iyapa obi.
Sise alaye ewu gbigbaaye nibi igbadun aye; nitoripe o ma ndini lọwọ ọrun.
Sise alaye adehun iya ti o le koko fun awọn ẹni igberaga ati poki.