وَٱلَّٰتِي يَأۡتِينَ ٱلۡفَٰحِشَةَ مِن نِّسَآئِكُمۡ فَٱسۡتَشۡهِدُواْ عَلَيۡهِنَّ أَرۡبَعَةٗ مِّنكُمۡۖ فَإِن شَهِدُواْ فَأَمۡسِكُوهُنَّ فِي ٱلۡبُيُوتِ حَتَّىٰ يَتَوَفَّىٰهُنَّ ٱلۡمَوۡتُ أَوۡ يَجۡعَلَ ٱللَّهُ لَهُنَّ سَبِيلٗا 15
Ati wipe awọn obirin, ti wọn wu iwa ibajẹ sina ninu awọn obirin yin, ti wọn si jẹ ẹniti o ti ni ọkọ ati awọn ti ko ni ọkọ, ẹ fi awọn ọkunrin mẹrin ti wọn jẹ Musulumi onideede jẹri le wọn lori, ti wọn ba waa jẹri le wọn lori pẹlu sise ẹsẹ naa, ki ẹ se wọn mọ awọn inu ile, ki o maa jẹ iya fun wọn, titi ti awọn isẹmi wọn yoo fi pari pẹlu iku tabi ki Ọlọhun Ọba Allah wa ọna miran fun wọn ti o yatọ si ọna sise mọ ile, lẹyin naa ni Ọlọhun Ọba Allah waa se alaye oju ọna fun wọn lẹyin nkan naa, ni O waa se nina ọmọge ti o se sina ni ọgba ọgọrun ati gbigbe jinna ọdun kan ni ofin, ati sise lilẹko pa ẹniti o ti ni ọkọ.
وَٱلَّذَانِ يَأۡتِيَٰنِهَا مِنكُمۡ فََٔاذُوهُمَاۖ فَإِن تَابَا وَأَصۡلَحَا فَأَعۡرِضُواْ عَنۡهُمَآۗ إِنَّ ٱللَّهَ كَانَ تَوَّابٗا رَّحِيمًا 16
Ati wipe awọn meji ti wọn ba se ibajẹ sina ninu awọn ọkunrin, ti awọn mejeeji ti ni iyawo tabi wọn ko tii ni iyawo, ẹ jẹ awọn mejeeji naa ni iya pẹlu ẹnu ati ọwọ, pẹlu ohun ti yoo mu iyẹpẹrẹ wa ati ijagbemọ, ti awọn mejeeji ba wa bọpa kuro nibi ohun ti wọn wa lori rẹ, ti awọn isẹ awọn mejeeji si dara, ki ẹ ya gunri kuro nibi fifi suta kan awọn mejeeji; toripe ẹniti o ba ronu piwada kuro nibi ẹsẹ da gẹgẹ bi ẹniti ko ni ẹsẹ rara ni, dajudaju Ọlọhun Ọba Allah jẹ Olugba Ironu piwada ẹniti o ba ronu piwada ninu awọn ẹru rẹ, Olukẹ wọn si ni. Ati wipe ttito pẹlu iran yii ninu iya jẹ ibẹrẹ alamọri naa, lẹyin naa ni wọn wa parẹ lẹyin igba naa pẹlu nina ọdọkunrin ni ẹgba ati gbigbe jinna ọdun kan, ati lilẹko pa ẹniti o ti ni iyawo.
إِنَّمَا ٱلتَّوۡبَةُ عَلَى ٱللَّهِ لِلَّذِينَ يَعۡمَلُونَ ٱلسُّوٓءَ بِجَهَٰلَةٖ ثُمَّ يَتُوبُونَ مِن قَرِيبٖ فَأُوْلَٰٓئِكَ يَتُوبُ ٱللَّهُ عَلَيۡهِمۡۗ وَكَانَ ٱللَّهُ عَلِيمًا حَكِيمٗا 17
Dajudaju Ọlọhun Ọba Allah ma ngba tituuba awọn ti wọn ba se aya gbangba lori dida awọn ẹsẹ ati awọn iyapa pẹlu aimọkan lati ọdọ wọn fun igbẹyin rẹ ati aburu rẹ - ati wipe eleyi ni isesi gbogbo ẹniti o ba da ẹsẹ kan, o mọọmọ ni tabi ko mọọmọ -, lẹyin naa ti wọn wa sẹri pada ni ẹniti o ndari pada si ọdọ Ọlọhun Ọba wọn siwaju ki wọn to ri iku ni ojukoroju, awọn naa ni Ọlọhun Ọba Allah yoo gba ironu piwada wọn, Yoo si tun moju kuro nibi awọn asise wọn ati wipe Ọlọhun Ọba Allah jẹ Onimimọ pẹlu awọn isesi awọn ẹda Rẹ, O si jẹ Ọlọgbọn nibi pipebubu Rẹ ati sise ofin Rẹ.
وَلَيۡسَتِ ٱلتَّوۡبَةُ لِلَّذِينَ يَعۡمَلُونَ ٱلسَّئَِّاتِ حَتَّىٰٓ إِذَا حَضَرَ أَحَدَهُمُ ٱلۡمَوۡتُ قَالَ إِنِّي تُبۡتُ ٱلۡـَٰٔنَ وَلَا ٱلَّذِينَ يَمُوتُونَ وَهُمۡ كُفَّارٌۚ أُوْلَٰٓئِكَ أَعۡتَدۡنَا لَهُمۡ عَذَابًا أَلِيمٗا 18
Ati wipe Ọlọhun Ọba Allah ko nii gba ironu piwada awọn ti wọn nse orikunkun lori awọn ese, ati wipe wọn ko nii tuuba nibẹ titi wọn yoo fi ri inira hihunrira iku, nigba naa ọkan ninu wọn yoo maa sọ wipe: dajudaju emi ronu piwada nisinsin yii kuro nibi ohun ti mo ti se ninu awọn ese. Ati wipe Ọlọhun Ọba Allah ko nii gba - bakanna - ironu piwada awọn ti wọn ku ni ẹniti o nse ori kunkun lori sise aigbagbọ, awọn ẹlẹsẹ naa, ti wọn jẹ oluse ori kunkun lori awọn ese, ati awọn ti wọn ku ti wọn si wa lori aini igbagbọ wọn, A ti pese iya ẹlẹta-elero kan silẹ fun wọn.
يَٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ لَا يَحِلُّ لَكُمۡ أَن تَرِثُواْ ٱلنِّسَآءَ كَرۡهٗاۖ وَلَا تَعۡضُلُوهُنَّ لِتَذۡهَبُواْ بِبَعۡضِ مَآ ءَاتَيۡتُمُوهُنَّ إِلَّآ أَن يَأۡتِينَ بِفَٰحِشَةٖ مُّبَيِّنَةٖۚ وَعَاشِرُوهُنَّ بِٱلۡمَعۡرُوفِۚ فَإِن كَرِهۡتُمُوهُنَّ فَعَسَىٰٓ أَن تَكۡرَهُواْ شَيۡٔٗا وَيَجۡعَلَ ٱللَّهُ فِيهِ خَيۡرٗا كَثِيرٗا 19
Ẹyin ti ẹ ni igbagbọ pẹlu Ọlọhun Ọba Allah, ti wọn si ntẹle ojisẹ Rẹ, ko lẹtọ fun yin ki ẹ jogun awọn obirin awọn baba yin, ati awon alasunmo yin, gẹgẹ bi wọn se ma njogun dukia, ti ẹ yoo wa ma se bi o se wu yin fun wọn pẹlu fifẹ wọn, tabi fifi wọn fun ẹniti ẹ ba fẹ, tabi kikọ fun wọn nibi nini ọkọ, ati wipe ko lẹtọ fun yin ki e mu awọn iyawo duro, awọn ti ẹ korira wọn lati maa fi inira kan wọn, titi ti wọn yoo fi jọwọ silẹ fun yin apakan oun ti ẹ fun wọn ninu owo ori ati oun ti o yatọ sii, ayaafi ti wọn ba hu iwa ibajẹ ti o fi oju han, gẹgẹ bi sina sise, ti wọn ba waa se nkan naa, o lẹtọ fun yin lati mu wọn duro ati fifun ilẹ mọ wọn titi ti wọn yoo fi gba ara wọn silẹ lọwọ yin pẹlu ohun ti ẹ fun wọn, ati wipe ẹ maa ba awọn obirin yin lo ni ibalo ti o dara pẹlu mima fi suta kan wọn ati mima se daadaa, ti o ba wa jẹ wipe ẹ korira wọn nitori alamọri kan ti o jẹ ti aye, ki ẹ ya se suuru fun wọn, toripe o seese fun Ọlọhun Ọba Allah ko fi oore ti o pọ sibi oun ti ẹ nkorira ninu isẹmin ile aye ati ti ọrun.
Wiwu ibajẹ sina ninu awọn ẹsẹ ti ewu rẹ pọ ni fun ẹnikọọkan ati awujọ, ati wipe ti ri idi eleyi ni awọn ijiya ti o le koko fi wa lori rẹ.
Aanu Ọlọhun Ọba Allah ati ikẹ rẹ nbẹ pẹlu awọn ẹru Rẹ, nibi ti o ti si ilẹkun rironu piwada fun gbogbo ẹlẹsẹ, ati wipe O se awọn okunfa rẹ ni irọrun, O si tun ran lọwọ lori titọ oju ọna naa.
Gbogbo ẹniti o ba yapa Ọlọhun Ọba Allah (ti ọla Rẹ ga) pẹlu mimọọmọ tabi aimọọmọ, yoo maa jẹ alaimọkan pẹlu odiwọn bi o se sẹ Ẹ, ti O gbọngbọn, ti O si ga, ati wipe alaimọkan ni pẹlu awọn oripa awọn ẹsẹ ati aburu rẹ le lori.
Ninu awọn okunfa ti isẹmin lọkọ-laya fi ma ntẹsiwaju ni ki iwoye ọkọ jẹ dọgban-dagbọ, ko gbọdọ wa ko iwoye rẹ jọ sibi ohun ti o korira, bikose wipe o gbọdọ maa boju wo bakanna ohun ti o nbẹ nibẹ ninu daadaa, ati wipe o seese ki Ọlọhun Ọba Allah fi oore ti o pọ sibẹ.