فَأَنجَيۡنَٰهُ وَأَصۡحَٰبَ ٱلسَّفِينَةِ وَجَعَلۡنَٰهَآ ءَايَةٗ لِّلۡعَٰلَمِينَ 15
A la Nuha ati awọn ti o wa pẹlu rẹ ninu awọn olugbagbọ ododo nibi ọkọ oju omin kuro nibi iparun itẹri, a si se ọkọ oju omin naa ni ariwoye fun awọn eniyan ki wọn le woye pẹlu rẹ.
وَإِبۡرَٰهِيمَ إِذۡ قَالَ لِقَوۡمِهِ ٱعۡبُدُواْ ٱللَّهَ وَٱتَّقُوهُۖ ذَٰلِكُمۡ خَيۡرٞ لَّكُمۡ إِن كُنتُمۡ تَعۡلَمُونَ 16
Ranti - irẹ ojisẹ - itan Ibrahim nigbati o sọ fun awọn ijọ rẹ: ẹ sin Allah nikan soso ki ẹ si paya iya Rẹ pẹlu mima se awọn asẹ Rẹ ati jijinna si ohun ti o kọ, eleyi ti a pa asẹ rẹ jẹ ohun ti o loore fun yin ti ẹ ba mọ bẹẹ.
إِنَّمَا تَعۡبُدُونَ مِن دُونِ ٱللَّهِ أَوۡثَٰنٗا وَتَخۡلُقُونَ إِفۡكًاۚ إِنَّ ٱلَّذِينَ تَعۡبُدُونَ مِن دُونِ ٱللَّهِ لَا يَمۡلِكُونَ لَكُمۡ رِزۡقٗا فَٱبۡتَغُواْ عِندَ ٱللَّهِ ٱلرِّزۡقَ وَٱعۡبُدُوهُ وَٱشۡكُرُواْ لَهُۥٓۖ إِلَيۡهِ تُرۡجَعُونَ 17
Dajudaju ohun ti ẹ nsin - ẹyin ẹlẹbọ - jẹ oosa ti ko le se anfaani tabi ko inira ba ni, ẹ si nhun irọ nigbati ẹ nlero wipe awọn oosa naa lẹtọ si ijọsin, dajudaju awọn ti ẹ nsin yatọ si Allah wọn ko nikapa aranse ti wọn yoo fi ran yin se, ki ẹ ya wa aranse ni ọdọ Allah toripe Oun ni olurannise, ki ẹ si maa sin In ni Oun nikan, bakanna ki ẹ dupẹ fun Un lori idẹkuin ti O se le yin lori ninu arisiki, ọdọ Rẹ nikan ni ẹ o sẹri si ni ọjọ igbende fun isiro ati ẹsan kii se ọdọ awọn ẹbọ yin.
وَإِن تُكَذِّبُواْ فَقَدۡ كَذَّبَ أُمَمٞ مِّن قَبۡلِكُمۡۖ وَمَا عَلَى ٱلرَّسُولِ إِلَّا ٱلۡبَلَٰغُ ٱلۡمُبِينُ 18
Ti ẹ ba pe nirọ - ẹyin ẹlẹbọ - nkan ti Muhammad ti ikẹ ati ọla nbẹ fun mu wa, paapaa awọn ijọ kan siwaji ti pe nirọ gẹgẹ bi ijọ Nuha ati hadi ati samudawa, ko si nkankan lori ojisẹ naa ju imudopin ti o fi oju han lọ, paapaa o si ti mu de etigbọ yin ohun ti Ọlọhun Ọba rẹ pa lasẹ ki o mu de etigbọ yin.
أَوَ لَمۡ يَرَوۡاْ كَيۡفَ يُبۡدِئُ ٱللَّهُ ٱلۡخَلۡقَ ثُمَّ يُعِيدُهُۥٓۚ إِنَّ ذَٰلِكَ عَلَى ٱللَّهِ يَسِيرٞ 19
Se awọn opurọ yii ko woye si bi Allah se da ẹda Rẹ ni ipilẹ ni lẹyin naa ti o sẹri rẹ pada lẹyin titan rẹ, dajudaju eleyi rọrun fun Allah, O jẹ alagbara ti nkankan ko le ko agara ba A.
قُلۡ سِيرُواْ فِي ٱلۡأَرۡضِ فَٱنظُرُواْ كَيۡفَ بَدَأَ ٱلۡخَلۡقَۚ ثُمَّ ٱللَّهُ يُنشِئُ ٱلنَّشۡأَةَ ٱلۡأٓخِرَةَۚ إِنَّ ٱللَّهَ عَلَىٰ كُلِّ شَيۡءٖ قَدِيرٞ 20
Sọ - irẹ ojisẹ - fun awọn opurọ yii nipa igbende: ẹ rin lori ilẹ ki ẹ si woye si bi Allah se bẹrẹ ẹda Rẹ, lẹyin naa yoo ji awọn eniyan lẹyin iku wọn ni isẹmin ẹlẹẹkeji fun igbende ati isiro, dajudaju Allah jẹ alagbara lori gbogbo nkan, nkankan ko le ko agara ba A, ko le kagara nipa gbigbe awọn eniyan dide, bẹẹni ko le kagara nipa dida wọn ni akọkọ.
يُعَذِّبُ مَن يَشَآءُ وَيَرۡحَمُ مَن يَشَآءُۖ وَإِلَيۡهِ تُقۡلَبُونَ 21
Yoo fi iya jẹ ẹniti o ba wu U ninu awọn ẹda Rẹ niti deede Rẹ, Yoo si kẹ ẹniti o ba wu U ninu ẹda Rẹ niti ọla Rẹ, ọdọ nikan si ni ibusẹri si ni ọjọ igbende fun isiro nigbati o ba ngbeyin dide ninu saare yin ni alaaye.
وَمَآ أَنتُم بِمُعۡجِزِينَ فِي ٱلۡأَرۡضِ وَلَا فِي ٱلسَّمَآءِۖ وَمَا لَكُم مِّن دُونِ ٱللَّهِ مِن وَلِيّٖ وَلَا نَصِيرٖ 22
Ẹ kii se ẹniti yoo bọ ni ọdọ Ọlọhun Ọba yin, bẹẹni ẹ ko le bọ nibi iya Rẹ lori ilẹ tabi ni sanmọ, ko si si fun yin ẹlomiran yatọ si Allah ni alatilẹyin ti yoo la ọrọ yin bọrun, kosi si fun yin yatọ si Allah alaranse ti yoo gbe iya Rẹ kuro fun yin.
وَٱلَّذِينَ كَفَرُواْ بَِٔايَٰتِ ٱللَّهِ وَلِقَآئِهِۦٓ أُوْلَٰٓئِكَ يَئِسُواْ مِن رَّحۡمَتِي وَأُوْلَٰٓئِكَ لَهُمۡ عَذَابٌ أَلِيمٞ 23
Awọn ti wọn se keferi si awọn aayah Ọlọhun Ọba ti mimọ nbẹ fun ati si ipade Rẹ ni ọjọ igbende, awọn wọnyi ti jakan kuro nibi ikẹ Mi, wọn ko si le wọ Alujannah lailai nitori aimoore wọn, bẹẹni awọn wọnyi iya inira nreti wọn ni ọrun.
Awọn ẹbọ ko nikapa aranse ti wọn yoo fi waa lẹtọ si ijọsin.
Wiwa aranse gbọdọ jẹ lati ọdọ Allah eyiti o nikapa aranse.
Bibẹrẹ idẹda jẹ itọka lori igbende.
Wiwọ alujanna jẹ eewẹ fun ẹniti o ba ku lori keferi.