وَأَلۡقَىٰ فِي ٱلۡأَرۡضِ رَوَٰسِيَ أَن تَمِيدَ بِكُمۡ وَأَنۡهَٰرٗا وَسُبُلٗا لَّعَلَّكُمۡ تَهۡتَدُونَ 15
O si tun fi awọn oke si ilẹ ti o mu duro ki o maa ba maa gban mọ yin tabi yẹ, O si nmu awọn omin rin ninu rẹ ki ẹ le ba maa mu ninu rẹ, ki ẹ tun le maa fun awọn ẹranko yin ati irugbin yin ni omin mu, O si tun la ọna fun yin ninu rẹ naa, ki ẹ maa de awọn ibi ti ẹ ba gbero laini sọnu.
وَعَلَٰمَٰتٖۚ وَبِٱلنَّجۡمِ هُمۡ يَهۡتَدُونَ 16
O si tun se awọn omin fun yin ni ori ilẹ ti o fi oju han ki ẹ le mọna nigbati ẹ ba rin ni ọsan, O tun se awọn irawọ fun yin ki ẹ le maa fi mọ ọna ni oru.
أَفَمَن يَخۡلُقُ كَمَن لَّا يَخۡلُقُۚ أَفَلَا تَذَكَّرُونَ 17
Njẹ ẹniti o da awọn nkan wọnyi ati nkan miran da gẹgẹ bi ẹniti ko le da nkankan?! Se ẹ ko nii se iranti Allah Ẹniti O da gbogbo nkan, ki ẹ si mu U lọkan nibi ijọsin, ki ẹ si mase mu nkan miran ti ko le da nkankan mọ Ọ?
وَإِن تَعُدُّواْ نِعۡمَةَ ٱللَّهِ لَا تُحۡصُوهَآۗ إِنَّ ٱللَّهَ لَغَفُورٞ رَّحِيمٞ 18
Ti ẹ ba ngbiyanju - ẹyin eniyan - lati ka idẹkun Allah ti o pọ eyiti o se le yin lori ati kika a ni ẹyọ-ẹyọ, ẹ ko le ni agbara rẹ nitori pipọ rẹ ati jijẹ oniranran rẹ, dajudaju Allah jẹ olufi orin njinin nitori aigbayin mu lati ara fifọnu lati dupẹ, onikẹ ti ko ja ikẹ Rẹ kuro ni ọdọ yin nitori awọn ẹsẹ ati aise koto lati dupẹ fun Un.
وَٱللَّهُ يَعۡلَمُ مَا تُسِرُّونَ وَمَا تُعۡلِنُونَ 19
Bẹẹ ni Allah mọ oun ti ẹ nfi pamọ - ẹyin ẹru - ninu awọn isẹ yin, O si mọ eyiti ẹ nse afihan nibẹ, nkankan ko pamọ fun Un ninu rẹ, Yoo si san yin lẹsan le lori.
وَٱلَّذِينَ يَدۡعُونَ مِن دُونِ ٱللَّهِ لَا يَخۡلُقُونَ شَيۡٔٗا وَهُمۡ يُخۡلَقُونَ 20
Awọn ti awọn ẹlẹbọ nsin yatọ si Allah, wọn ko le da nkankan koda bi o kere, ẹniti wọn si nsin yatọ si Allah awọn naa ni wọn se e, bawo wọn se wa nsin ẹniti o yatọ si Allah eyiti wọn se pẹlu ọwọ wọn ninu awọn oosa?!
أَمۡوَٰتٌ غَيۡرُ أَحۡيَآءٖۖ وَمَا يَشۡعُرُونَ أَيَّانَ يُبۡعَثُونَ 21
Pẹlu wipe awọn ti nsin wọn ni wọn se wọn lati ọwọ ara wọn, wọn jẹ ọbọrọgidi ti ko le sẹmin, bẹẹ ni ko si imọ, wọn ko mọ igbati wọn yoo gbe ẹniti wọn nsin dide pẹlu wọn ni ọjọ igbende; ki wọn le ju wọn pẹlu wọn si inu ina jahanamọ.
إِلَٰهُكُمۡ إِلَٰهٞ وَٰحِدٞۚ فَٱلَّذِينَ لَا يُؤۡمِنُونَ بِٱلۡأٓخِرَةِ قُلُوبُهُم مُّنكِرَةٞ وَهُم مُّسۡتَكۡبِرُونَ 22
Ẹniti wọn gbọdọ jọsin fun niti ododo, Oun ni Ẹni ijọsin fun kan soso ti ko si orogun fun Un, Oun si ni Allah, awọn ti ko nigbagbọ si igbende fun ẹsan, ẹkan wọn jẹ olujiyan si ọkan soso Allah nitori aipaya rẹ, ko nigbagbọ si isiro bẹẹ ni ijiya, oluse igberaga ni wọn, wọn ko le gba ododo, wọn ko si le tẹriba fun Un.
لَا جَرَمَ أَنَّ ٱللَّهَ يَعۡلَمُ مَا يُسِرُّونَ وَمَا يُعۡلِنُونَۚ إِنَّهُۥ لَا يُحِبُّ ٱلۡمُسۡتَكۡبِرِينَ 23
Lododo dajudaju Allah mọ ohun ti awọn wọnyi fi pamọ ninu isẹ, O si mọ eyiti wọn fi nhan nibẹ, nkankan ko pamọ fun Un, Yoo si san wọn lẹsan le lori, dajudaju Ọba ti mimọ nbẹ fun ko nifẹ si awọn onigberaga lati ma se ijọsin fun Un tabi tẹriba fun Un, bikose wipe wọn nbinu si wọn gidigidi.
وَإِذَا قِيلَ لَهُم مَّاذَآ أَنزَلَ رَبُّكُمۡ قَالُوٓاْ أَسَٰطِيرُ ٱلۡأَوَّلِينَ 24
Ti wọn ba sọ fun awọn ti o ntako ijọkan soso Ọba adẹda, ti wọn si npe igbedide nirọ: kinni ohun ti Ọlọhun Ọba sọkalẹ fun Muhammad ti ikẹ ati ọla nbẹ fun? Wọn sọ wipe: nkankan ko sọkalẹ fun un, o kan mu itan awọn ẹni akọkọ ati irọ wọn wa lati ọdọ ara rẹ.
لِيَحۡمِلُوٓاْ أَوۡزَارَهُمۡ كَامِلَةٗ يَوۡمَ ٱلۡقِيَٰمَةِ وَمِنۡ أَوۡزَارِ ٱلَّذِينَ يُضِلُّونَهُم بِغَيۡرِ عِلۡمٍۗ أَلَا سَآءَ مَا يَزِرُونَ 25
Ki ẹgbẹyin wọn le jẹsi wipe awọn ni wọn yoo gbe ẹsẹ wọn laini dinku, ki wọn si tun le gbe ẹsẹ awọn ti wọn sọ wọn nu kuro nibi Islam niti aimọkan ati ikọse, kinni o fi buru to ohun ti wọn gbe ni ẹsẹ yii ati ẹsẹ awọn ti wọn tẹle wọn.
قَدۡ مَكَرَ ٱلَّذِينَ مِن قَبۡلِهِمۡ فَأَتَى ٱللَّهُ بُنۡيَٰنَهُم مِّنَ ٱلۡقَوَاعِدِ فَخَرَّ عَلَيۡهِمُ ٱلسَّقۡفُ مِن فَوۡقِهِمۡ وَأَتَىٰهُمُ ٱلۡعَذَابُ مِنۡ حَيۡثُ لَا يَشۡعُرُونَ 26
Paapaa awọn keferi ti mu ete fun awọn ojisẹ wọn siwaju awọn wọnyi, Ọlọhun Allah waa wo awọn ile wọn lati ipilẹ, O si ja aja rẹ le wọn lori lati oke, iya si waa ba wọn nibi ti wọn ko ti lero, paapaa wọn ti jẹ ẹniti nfi ọkan si wipe ile wọn ni yoo sọ wọn, O wa pa wọn run pẹlu rẹ.
Nkan ti o tobi ninu awọn oniranran idẹkun Allah lori ẹru wa ninu awọn aayah naa ni akojọ ati ni ifọsi wẹwẹ eyiti Allah npe awọn ẹru Rẹ lati dupẹ rẹ, ki wọn si maa ranti Rẹ, ki wọn si maa pe E.
Adamọ ọmọniyan ni abosi ati nini akin lori ẹsẹ ati sise ẹdinku nibi ẹtọ Ọlọhun Ọba Allah, alaimoore si idẹkun Allah, wọn kii dupẹ bẹẹ ni wọn kii jẹwọ idẹkun Rẹ ayaafi ẹniti Allah ba fi mọ ọna.
Sise dọgbọ olusini lọna ati olusina nibi ẹsẹ isina; nitori wipe ti kii ba se sisi i lọna ki ba mọ ọna lati ibi iwoye rẹ tabi ibeere olutọni sọna.
Igbamun Ọlọhun Ọba fun awọn ẹlẹsẹ jẹ ojiji iya ti o le; nitori ipaya lile ti yoo fun un yatọ si nkan ti yoo wa ni idẹni lẹkẹ.