فَلَمَّا ذَهَبُواْ بِهِۦ وَأَجۡمَعُوٓاْ أَن يَجۡعَلُوهُ فِي غَيَٰبَتِ ٱلۡجُبِّۚ وَأَوۡحَيۡنَآ إِلَيۡهِ لَتُنَبِّئَنَّهُم بِأَمۡرِهِمۡ هَٰذَا وَهُمۡ لَا يَشۡعُرُونَ 15
Bayi ni Ya'quub ran pẹlu wọn, nigbati wọn rin jinna tan, ti wọn wa pinnu lati ju sinu ọgbun kanga, a ransẹ si yusuf ni asiko yii: iwọ yoo fun wọn niro ohun ti wọn se yii, wọn ko si ni fura mọ ọ nigbati o ba nfun wọn niro.
وَجَآءُوٓ أَبَاهُمۡ عِشَآءٗ يَبۡكُونَ 16
Awọn ọmọ baba yusuf wa ba baba wọn ni asiko asalẹ ni ẹniti o nsun kun lati fi se ikunlọwọ nibi ete wọn.
قَالُواْ يَٰٓأَبَانَآ إِنَّا ذَهَبۡنَا نَسۡتَبِقُ وَتَرَكۡنَا يُوسُفَ عِندَ مَتَٰعِنَا فَأَكَلَهُ ٱلذِّئۡبُۖ وَمَآ أَنتَ بِمُؤۡمِنٖ لَّنَا وَلَوۡ كُنَّا صَٰدِقِينَ 17
Wọn sọ wipe: irẹ baba wa, awa nlọ, ẹsẹ wa si gba waju, awa nju ọrun sugbọn a fi yusuf sẹyin nibiti asọ wa ati awọn nkan eelo wa wa ki o maa ba wa sọ ọ, ni ikoko ba jẹ ẹ, o ko le gba wa gba ọ koda ki o jẹ wipe olododo niwa nibi iro ti a fun ọ yii.
وَجَآءُو عَلَىٰ قَمِيصِهِۦ بِدَمٖ كَذِبٖۚ قَالَ بَلۡ سَوَّلَتۡ لَكُمۡ أَنفُسُكُمۡ أَمۡرٗاۖ فَصَبۡرٞ جَمِيلٞۖ وَٱللَّهُ ٱلۡمُسۡتَعَانُ عَلَىٰ مَا تَصِفُونَ 18
Wọn kanpa mọ iro wọn pẹlu ete, wọn si mu asọ yusuf wa ni ohun ti ẹjẹ ti ro papọ mọ ti kii se ẹjẹ rẹ ni ẹniti o npe apemọra oripa wipe ikoko jiẹ ẹ ni, Ya'quub wa mọ amọdaju - pẹlu nkan ti o sun mọ wipe asọ naa ko ya - nitori irọ ti wọn npa, o wa sọ fun wọn: ọrọ ko ri bi ẹ se mu iro rẹ wa, ẹmin yin ni o se ọrọ aburu yii lọsọ fun yin nibi nkan ti ẹ se, ohun ti o tọ si mi ni suuru ti o rẹwa ti ko gbọdọ si ikanra nibẹ, Ọlọhun Ọba Allah si ni ẹniti a gbọdọ maa wa aanu lọ si ọdọ Rẹ lori nkan ti ẹ sọ nipa ọrọ yusuf.
وَجَآءَتۡ سَيَّارَةٞ فَأَرۡسَلُواْ وَارِدَهُمۡ فَأَدۡلَىٰ دَلۡوَهُۥۖ قَالَ يَٰبُشۡرَىٰ هَٰذَا غُلَٰمٞۚ وَأَسَرُّوهُ بِضَٰعَةٗۚ وَٱللَّهُ عَلِيمُۢ بِمَا يَعۡمَلُونَ 19
Awọn eniyan ti wọn nrekọja lọ de, wọn wa nsewadi ẹniti o le fun wọn ni omin, bayi ni ẹni naa ju ifamin rẹ sinu kanga, ni okun ba so pọ mọ yusuf nigbati o ri ẹniti o ju okun naa, o sọrọ ni ẹniti inu rẹ ndun: irẹ idunnu mi o, ọmọkunrin ni eleyi, ẹniti o ba wọn bu omin se afipamọ rẹ, ati apakan ninu awọn ti o nre kọja ni ẹniti o npinnu wipe, dukia awọn kan ni eleyi ti awọn ti nwa, Ọlọhun Ọba Allah nikan ni o mọ ohun ti wọn se pẹlu yusuf nibi inawo ati kata kara, nkankan ninu isẹ wọn ko pamọ fun Ọlọhun Ọba.
وَشَرَوۡهُ بِثَمَنِۢ بَخۡسٖ دَرَٰهِمَ مَعۡدُودَةٖ وَكَانُواْ فِيهِ مِنَ ٱلزَّٰهِدِينَ 20
Olufami ati awọn ẹniyan rẹ ta si ilẹ misirọ ni iye irayesa ohun si ni dirihamu ti o rọrun lati ka nitori kikere rẹ, wọn jẹ ẹniti o raye sa nibẹ nitori oju kokoro wọn si bibọpa bọsẹ kuro nibẹ ni kiakia, paapaa wọn ti mọ lati ara isesi rẹ wipe kii se ẹru, wọn wa nbẹru ki awọn eniyan rẹ ma gba wọn mu, eleyi si jẹ ninu pipe ikẹ Ọlọhun Ọba fun un ti ko fi ni wa pẹlu wọn pẹ.
وَقَالَ ٱلَّذِي ٱشۡتَرَىٰهُ مِن مِّصۡرَ لِٱمۡرَأَتِهِۦٓ أَكۡرِمِي مَثۡوَىٰهُ عَسَىٰٓ أَن يَنفَعَنَآ أَوۡ نَتَّخِذَهُۥ وَلَدٗاۚ وَكَذَٰلِكَ مَكَّنَّا لِيُوسُفَ فِي ٱلۡأَرۡضِ وَلِنُعَلِّمَهُۥ مِن تَأۡوِيلِ ٱلۡأَحَادِيثِۚ وَٱللَّهُ غَالِبٌ عَلَىٰٓ أَمۡرِهِۦ وَلَٰكِنَّ أَكۡثَرَ ٱلنَّاسِ لَا يَعۡلَمُونَ 21
Arakunrin ti o ra a lati ilẹ misira sọ fun obinrin rẹ wipe: maa se daadaa si, ki o si se apanle ibugbe rẹ pẹlu wa; o seese ki o se wa ni anfaani lati maa ba wa se awọn nkan ti a ni bukaata si tabi ki a sọ di ọmọ pẹlu ki a mọọ fi orukọ wa pe, gẹgẹ bi a se wa la yusuf kuro nibi pipa a, ti a si tun mu jade kuro ninu kanga, a wa so ọkan ọba mọ ọ; a gba a laaye ni ilẹ misirọ, ati ki a le fi itumọ ala lila mọ ọ, Ọlọhun Ọba Allah jẹ olubori lori ọrọ Rẹ, asẹ Rẹ jẹ ohun ti yoo sẹlẹ, ko si si ẹniti o le jẹ nipa, mimọ Rẹ, sugbọn ọpọ ninu awọn eniyan - awọn naa ni awọn keferi - wọn ko mọ eleyi.
وَلَمَّا بَلَغَ أَشُدَّهُۥٓ ءَاتَيۡنَٰهُ حُكۡمٗا وَعِلۡمٗاۚ وَكَذَٰلِكَ نَجۡزِي ٱلۡمُحۡسِنِينَ 22
Nigbati yuusuf de ogongo ọjọ ori ti ara ma nlagbara, a fun ni agbọye ati imọ, iru ẹsan ti a san fun yii ni a ma nsan fun awọn oluse daadaa nibi ijọsin wọn fun Allah.
Sise alaye ewu keeta eyiti o mu awọn ọmọ baba yusuf lọ si ibi didete si i ati pipete pero lati pa a.
Sise lofin sise isẹ pẹlu ohun ti o ba sun mọ ninu awọn idajọ.
Ninu idari eto Ọlọhun Ọba fun yusuf ẹniti ọla nbẹ fun ati aanu Rẹ si i ni ki o ju ifẹ si ọkan ọba misirọ ti o nfura mọ ijẹ baba fun un lẹyin igbati esu ti fi gaga si ibi ijẹ ọmọ iya ọmọ baba si i.