يَٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُوٓاْ إِن تُطِيعُواْ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ يَرُدُّوكُمۡ عَلَىٰٓ أَعۡقَٰبِكُمۡ فَتَنقَلِبُواْ خَٰسِرِينَ 149
Ẹyin ti ni igbagbọ pẹlu Ọlọhun Ọba Allah, ti wọn si ntẹle ojisẹ Rẹ, ti ẹ ba tẹle awọn ti wọn se aigbagbọ ninu awọn yahuudi ati awọn nasaara ati awọn ọsẹbọ nibi ohun ti wọn npa yin lasẹ pẹlu rẹ ninu anu, wọn yoo da yin pada lẹyin ini igbagbọ yin si ohun ti wọn wa ni ori rẹ, ni awọn ti ko ni igbagbọ, ẹ o si waa sẹri pada ni ẹniti o se ofo ni aye ati ọrun.
بَلِ ٱللَّهُ مَوۡلَىٰكُمۡۖ وَهُوَ خَيۡرُ ٱلنَّٰصِرِينَ 150
Awọn alaigbagbọ yii, wọn ko le ran yin se nigbati ẹ ba tẹle wọn, bikose wipe Ọlọhun Ọba Allah, Oun ni Alaranse yin lori awọn ọta yin, ki ẹ yaa tẹle E, ati wipe Oun, mimọ fun Un, ni Ẹniti O loore ju ni awọn Alaranse, ẹ ko si nii ni bukaata si ẹnikankan lẹyin Rẹ.
سَنُلۡقِي فِي قُلُوبِ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ ٱلرُّعۡبَ بِمَآ أَشۡرَكُواْ بِٱللَّهِ مَا لَمۡ يُنَزِّلۡ بِهِۦ سُلۡطَٰنٗاۖ وَمَأۡوَىٰهُمُ ٱلنَّارُۖ وَبِئۡسَ مَثۡوَى ٱلظَّٰلِمِينَ 151
A o pada fi si inu awọn ọkan awọn ti wọn se aigbagbọ pẹlu Ọlọhun Ọba Allah, ibẹru ti o lagbara, titi ti wọn ko fi nii kapa lati duro sinsin lati ba yin ja pẹlu okunfa mimu ti wọn mu olujọsin miran ni orogun pẹlu Ọlọhun Ọba Allah, ti wọn jọsin fun un pẹlu awọn ifẹ inu wọn, ti wọn ko sọ awijare kankan pẹlu rẹ le wọn lori, ati wipe ibudesi wọn eyiti wọn yoo sẹri pada sibẹ ni Ọjọ Ikẹyin, ohun ni ina, ati wipe ina buru ni ibudesi awọn alabosi.
وَلَقَدۡ صَدَقَكُمُ ٱللَّهُ وَعۡدَهُۥٓ إِذۡ تَحُسُّونَهُم بِإِذۡنِهِۦۖ حَتَّىٰٓ إِذَا فَشِلۡتُمۡ وَتَنَٰزَعۡتُمۡ فِي ٱلۡأَمۡرِ وَعَصَيۡتُم مِّنۢ بَعۡدِ مَآ أَرَىٰكُم مَّا تُحِبُّونَۚ مِنكُم مَّن يُرِيدُ ٱلدُّنۡيَا وَمِنكُم مَّن يُرِيدُ ٱلۡأٓخِرَةَۚ ثُمَّ صَرَفَكُمۡ عَنۡهُمۡ لِيَبۡتَلِيَكُمۡۖ وَلَقَدۡ عَفَا عَنكُمۡۗ وَٱللَّهُ ذُو فَضۡلٍ عَلَى ٱلۡمُؤۡمِنِينَ 152
Ati wipe paapaa Ọlọhun Ọba Allah ti pe adehun Rẹ ti O se fun yin nibi aranse lori awọn ọta yin ni Ọjọ Uhud, nigbati ẹyin npawọn ni pipa ti o le pẹlu iyọnda Rẹ (ti ọla Rẹ ga) titi ti o fi di igbati ẹyin nse ojo, ti ẹ si kọlẹ lati duro sinsin lori oun ti ojisẹ payin lasẹ pẹlu rẹ, ati wipe ti ẹ wa yapa laarin sisẹku si awọn aaye yin tabi fifi silẹ, ati lati ko awọn ọrọ ogun jọ, ti ẹ yapa ojisẹ nibi asẹ rẹ fun yin pẹlu sisẹku si awọn aaye yin lori gbogbo isesi, nkan naa sẹlẹ ni ọdọ yin lẹyin igbati Ọlọhun Ọba Allah fi oun ti ẹ fẹ han yin ninu aranse lori awọn ọta yin, nbẹ ninu yin ẹniti o ngbero awọn ọrọ aye, awọn naa ni awọn ti wọn fi awọn aaye wọn silẹ, ati wipe o si nbẹ ninu yin ẹniti o ngbero ẹsan Ọjọ Ikẹyin, awọn naa ni awọn ti wọn sẹku si awọn aaye wọn, ni olutẹle asẹ ojisẹ, lẹyin igba naa ni Ọlọhun Ọba Allah waa yi yin kuro ni ọdọ wọn, O si waa fun wọn ni agbara lori yin, ki O le baa dan yin wo, ti olugbagbọ ododo ti o ni suuru lori adanwo yoo wa jere yatọ si ẹniti ẹsẹ rẹ ti yẹ, ti ẹmin rẹ si tun kọlẹ, ati wipe paapaa Ọlọhun Ọba Allah ti se amojukuro fun yin oun ti ẹ se ninu iyapa asẹ ojisẹ Rẹ, Ọlọhun Ọba Allah ti Ọlọla ti o tobi lori awọn olugbagbọ ododo nibi ti O ti fi wọn mọna lọsi bi ini igbagbọ, ati wipe O se amojukuro awọn asise wọn fun wọn, O si tun waa san wọn lẹsan lori awọn adanwo wọn.
۞إِذۡ تُصۡعِدُونَ وَلَا تَلۡوُۥنَ عَلَىٰٓ أَحَدٖ وَٱلرَّسُولُ يَدۡعُوكُمۡ فِيٓ أُخۡرَىٰكُمۡ فَأَثَٰبَكُمۡ غَمَّۢا بِغَمّٖ لِّكَيۡلَا تَحۡزَنُواْ عَلَىٰ مَا فَاتَكُمۡ وَلَا مَآ أَصَٰبَكُمۡۗ وَٱللَّهُ خَبِيرُۢ بِمَا تَعۡمَلُونَ 153
Ẹ ranti - ẹyin olugbagbọ ododo - nigbati ẹyin jinna si ilẹ ni ẹniti nsaalọ ni Ọjọ Uhud fun ijakulẹ ti o ba yin pẹlu yiyapa asẹ ojisẹ naa, ti ẹnikan ko ri ẹnikan ninu yin, ati wipe ojisẹ naa npe yin lati ẹyin yin laarin yin lati laarin awọn ọsẹbọ ni ẹniti nsọ wipe: ẹ maa bọ si ọdọ mi ẹyin ẹrusin Ọlọhun Ọba Allah, ẹ maa bọ si ọdọ mi ẹyin ẹrusin Ọlọhun Ọba Allah, ni Ọlọhun Ọba Allah waa fi inira ati ifunpinpin san yin lẹsan lori eleyi pẹlu ohun ti o bọ fun yin ninu aranse ati ọrọ ogun, ti inira ati ifunpinpin tun tẹle, ati pẹlu ohun ti o fan kan laarin yin nibi pipa Anọbi, ati wipe paapaa O sọ eleyi kalẹ pẹlu yin nitori ki ẹ ma ba banujẹ lori ohun ti o bọ fun yin ninu aranse, ati ọrọ ogun, ati lori ohun ti o kan yin ninu pipa ati sisa lọgbẹ lẹyin igbati ẹ ti mọ wipe dajudaju wọn ko pa Anọbi nibi ti gbogbo adanwo ati inira ti rọ fun yin, ati wipe Ọlọhun Ọba Allah ni olufun yin niro ohun ti ẹ ba nse nisẹ, nkankan ko si le pamọ fun ninu awọn isesi awọn ọkan yin, ati awọn isẹ awọn orikerike yin.
Ikilọ fun ni nibi titẹle awọn alaigbagbọ ati mimaa rin ninu awọn ifẹ inu wọn, toripe igbẹyin nkan naa jẹ ofo ni aye ati ọrun.
Jiju ibẹru si awọn ọkan awọn ọta Ọlọhun Ọba Allah, aworan kan ni ninu awọn aworan aranse Ọlọhun Ọba Allah fun awọn aayo Rẹ ti wọn jẹ olugbagbọ ododo.
Ninu okunfa ti o tobi ju fun ijakulẹ ni oju ogun ni ki eniyan rọ mọ ile aye ati ki o maa ni irankan si awọn ọrọ rẹ, ati yiyapa asẹ adari ọmọ ogun.
Ninu awọn itọka ọla awọn ọmọlẹyin Anọbi ni wipe dajudaju Ọlọhun Ọba Allah ma nfi aforijin gbẹyin lẹyin ti o ba ti sọ asise wọn.