فَإِن كَذَّبُوكَ فَقُل رَّبُّكُمۡ ذُو رَحۡمَةٖ وَٰسِعَةٖ وَلَا يُرَدُّ بَأۡسُهُۥ عَنِ ٱلۡقَوۡمِ ٱلۡمُجۡرِمِينَ 147
Ti wọn ba pe ọ nirọ - ire ojise -, ti wọn ko si gba ohun ti o mu wa lati ọdọ Ọlọhun Ọba rẹ lododo, sọ gbolohun yi lati le se wọn loju kokoro: Ọlọhun Ọba yin jẹ onikẹ ti o gbaaye, ninu ikẹ Rẹ ni ki o maa lọyin lara, ati aikanju lati fi iya jẹ yin, ki o si sọ fun wọn niti sise ikilọ fun wọn: dajudaju iya Ọlọhun Ọba Allah ko ni yẹ kuro fun awọn ti wọn nsẹ ẹsẹ ati aida.
سَيَقُولُ ٱلَّذِينَ أَشۡرَكُواْ لَوۡ شَآءَ ٱللَّهُ مَآ أَشۡرَكۡنَا وَلَآ ءَابَآؤُنَا وَلَا حَرَّمۡنَا مِن شَيۡءٖۚ كَذَٰلِكَ كَذَّبَ ٱلَّذِينَ مِن قَبۡلِهِمۡ حَتَّىٰ ذَاقُواْ بَأۡسَنَاۗ قُلۡ هَلۡ عِندَكُم مِّنۡ عِلۡمٖ فَتُخۡرِجُوهُ لَنَآۖ إِن تَتَّبِعُونَ إِلَّا ٱلظَّنَّ وَإِنۡ أَنتُمۡ إِلَّا تَخۡرُصُونَ 148
Awọn ọlọsẹbọ yoo maa sọ ni ẹniti yoo maa fi fifẹ Ọlọhun Ọba se ẹri ati agbara Rẹ lori lilẹtọ mimu nkan miran mọ Ọlọhun Ọba Allah: ti Ọlọhun Ọba Allah ba fẹ ki awa ati awọn baba wa ma se ẹbọ, a ko ba ti se ẹbọ, ti Ọlọhun Ọba Allah ba fẹ ki a ma se leewọ fun ara wa, a ko ba ti se ni eewọ, pẹlu ẹri wọn eyiti ko loorin yii ni awọn ti wọn siwaju wọn fi pe awọn ojisẹ wọn nirọ, ni ẹniti ti nsọ wipe ti Ọlọhun Ọba Allah ba fẹ ni ki a ma pe wọn nirọ, a ko ba ti pe wọn nirọ, wọn si tẹ siwaju lori ipenirọ yii titi ti wọn fi tọ iya wa wo eyiti a sọkalẹ le wọn lori, sọ - irẹ ojisẹ yii - fun awọn ọlọsẹbọ: njẹ ẹri kan wa ni ọdọ yin lori wipe Ọlọhun Ọba Allah yọnu si yin wipe ki ẹ maa se ẹbọ pẹlu Rẹ, tabi sọ di ẹtọ ohun ti O se ni eewọ tabi se ni eewọ ohun ti O se lẹtọ? ọwọ wipe eleyi sẹlẹ ni ọdọ yin jẹ ẹri lori aiyọnu sii yin, ẹ ko tẹle nkankan nibẹ ju erongba lọ, bẹẹ ni erongba ko ni ipin kankan nibi ododo, ẹ ko si jẹ ẹnikankan ju parọparọ lọ.
قُلۡ فَلِلَّهِ ٱلۡحُجَّةُ ٱلۡبَٰلِغَةُۖ فَلَوۡ شَآءَ لَهَدَىٰكُمۡ أَجۡمَعِينَ 149
Sọ - ire ojise - fun awọn ọlọsẹbọ: ti ẹ ko ba ni ẹri kankan ju ẹri fifuyẹ yii lọ dajudaju Ọlọhun Ọba Allah ni ẹri eyiti o mun yanran, ti yoo jẹ awijare lori nkan ẹ fi si ọdọ Rẹ lọ, ti yoo si fi ba iruju ti ẹ so pọ mọ lọ jẹ, ti Ọlọhun Ọba Allah ba fẹ fi yin se kongẹ ododo ni lapapọ - ẹyin ẹlẹbọ - ki ba fi yin se kongẹ rẹ.
قُلۡ هَلُمَّ شُهَدَآءَكُمُ ٱلَّذِينَ يَشۡهَدُونَ أَنَّ ٱللَّهَ حَرَّمَ هَٰذَاۖ فَإِن شَهِدُواْ فَلَا تَشۡهَدۡ مَعَهُمۡۚ وَلَا تَتَّبِعۡ أَهۡوَآءَ ٱلَّذِينَ كَذَّبُواْ بَِٔايَٰتِنَا وَٱلَّذِينَ لَا يُؤۡمِنُونَ بِٱلۡأٓخِرَةِ وَهُم بِرَبِّهِمۡ يَعۡدِلُونَ 150
Sọ - ire ojise - fun awọn ẹlẹbọ yii ti wọn nse leewọ nkan ti Ọlọhun Ọba Allah se lẹtọ, ti wọn si npe apemọra wipe Ọlọhun Ọba Allah ni o se ni eewọ: ẹ mu awọn ẹlẹri yin ti yoo jẹri wipe Ọlọhun Ọba Allah ni O se awọn nkan ti ẹ se ni eewọ fun ara yin wa, ti wọn ba jẹri laisi imọ lori wipe Ọlọhun Ọba Allah ni O se ni eewọ, ẹ mase gba wọn gbọ - irẹ ojisẹ yii - nibi ijẹri wọn; nitori wipe ẹri eke ni, wọn si tẹle awọn ti wọn nlo ifẹ inu nibi idajọ, paapaa wọn ti pe awọn amin wa nirọ nitori wipe wọn se leewọ nkan ti Ọlọhun Ọba Allah se lẹtọ, wọn si tẹle awọn ti ko nigbagbọ nipa ọjọ ikẹyin, wọn nse ẹbọ, wọn si fi we nkan miran, bawo wọn yoo se wa maa tẹle ẹniti ojupọnna rẹ ri bayi pẹlu Ọlọhun Ọba Allah? !
۞قُلۡ تَعَالَوۡاْ أَتۡلُ مَا حَرَّمَ رَبُّكُمۡ عَلَيۡكُمۡۖ أَلَّا تُشۡرِكُواْ بِهِۦ شَيۡٔٗاۖ وَبِٱلۡوَٰلِدَيۡنِ إِحۡسَٰنٗاۖ وَلَا تَقۡتُلُوٓاْ أَوۡلَٰدَكُم مِّنۡ إِمۡلَٰقٖ نَّحۡنُ نَرۡزُقُكُمۡ وَإِيَّاهُمۡۖ وَلَا تَقۡرَبُواْ ٱلۡفَوَٰحِشَ مَا ظَهَرَ مِنۡهَا وَمَا بَطَنَۖ وَلَا تَقۡتُلُواْ ٱلنَّفۡسَ ٱلَّتِي حَرَّمَ ٱللَّهُ إِلَّا بِٱلۡحَقِّۚ ذَٰلِكُمۡ وَصَّىٰكُم بِهِۦ لَعَلَّكُمۡ تَعۡقِلُونَ 151
Sọ - ire ojise - fun awọn eniyan: ẹ wa ki nka fun yin ohun ti Ọlọhun Ọba Allah se ni eewọ, O se leewọ fun yin pe ki ẹ ma mu nkankan miran mọ ninu awọn nkan ti O da, ki ẹ ma yapa awọn obi yin, dandan ni ki ẹ si maa se daadaa si wọn, ki ẹ ma pa awọn ọmọ yin nitori osi gẹgẹ bi awọn alaimọkan se ma nse, awa ni a nse arisiki fun yin ati fun awọn naa, O si se leewọ ki ẹ ma sun mọ ibajẹ eyiti wọn fi han ni tabi eyiti wọn fi pa mọ, ki ẹ si ma pa ẹmin eyiti Ọlọhun Ọba Allah se pipa rẹ ni eewọ ayaafi pẹlu ododo gẹgẹ bi agbere sise lẹyin idaabobo tabi kikoomọ lẹyin Islam, gbogbo eleyi ni Ọlọhun Ọba Allah nsọ asọtẹlẹ rẹ fun yin ki ẹ le ba se laakaye pẹlu awọn ohun ti O kọ.
Sisọra kuro nibi ẹsẹ ti yoo muni de ibi iya Ọlọhun Ọba Allah nitori wipe ko si ohun ti o le kọdi awọn ijọ ẹlẹsẹ kuro nibi iya Ọlọhun Ọba Allah ti o ba gbero ro wọn.
Wiwa ẹri pẹlu akọsilẹ ati kadara lẹyin igba ti Ọlọhun Ọba Allah ba ti fun ẹda ni agbara ati erongba lati le se nkan ti a la bọ lọrun; o jẹ abosi pọnbele ati sise ori kunkun tan yanyan.
Awọn amin naa tọka si wipe ni ibamun laakaye ẹru ni yoo fi ma se ohun ti Ọlọhun Ọba Allah paa lasẹ rẹ.
Kikọ fun ni kuro nibi sisunmọ awọn ibajẹ, o rinlẹ ju ikọfunni kuro nibi sise lọ tori wipe ohun yoo ti kọ gbogbo ohun ti o jẹ atẹgun si ati ohun ti o le mu de ibẹ.