قَالَ يَٰمُوسَىٰٓ إِنِّي ٱصۡطَفَيۡتُكَ عَلَى ٱلنَّاسِ بِرِسَٰلَٰتِي وَبِكَلَٰمِي فَخُذۡ مَآ ءَاتَيۡتُكَ وَكُن مِّنَ ٱلشَّٰكِرِينَ 144
ỌLọhun Ọba Allah sọ fun Musa: irẹ Musa, Mo sa ọ lẹsa, Mo si gbọ la fun ọ lori awọn eniyan pẹlu isẹ ti Mo fi ran ọ si awọn eniyan, Mo si fi ọrọ biba ọ sọ gbe ọla fun ọ laisi alagbata, gba iyi ati apọnle ti mo fun ọ yii, ki o si jẹ oludupẹ lori ọrẹnta ti o tobi ju.
وَكَتَبۡنَا لَهُۥ فِي ٱلۡأَلۡوَاحِ مِن كُلِّ شَيۡءٖ مَّوۡعِظَةٗ وَتَفۡصِيلٗا لِّكُلِّ شَيۡءٖ فَخُذۡهَا بِقُوَّةٖ وَأۡمُرۡ قَوۡمَكَ يَأۡخُذُواْ بِأَحۡسَنِهَاۚ سَأُوْرِيكُمۡ دَارَ ٱلۡفَٰسِقِينَ 145
A si kọ si inu awọn ọpọn igi fun Musa ati ohun ti o yatọ sii, ninu gbogbo nkan ti awọn ọmọ isirẹla ni bukaata si ninu alamọri ọrọ ẹsin ati aye wọn, ki o le jẹ isiti fun ẹniti o ba gba, ati alaye fun awọn idajọ ti o ni bukaata si alaye, gba taoreeta yii –irẹ Musa- pẹlu igbamun daradara ati igbiyanju, ki o si maa pa awọn ijọ rẹ tii se arọmọdọmọ isirẹla lasẹ ki awọn naa gbamun daradara, ninu ohun ti ẹsan rẹ tobi gẹgẹ bi sise ohun ti wọn pa lasẹ rẹ ni ojupọnna ti o pe, ati gẹgẹ bi suuru ati amojukuro, maa fi igbẹyin ẹniti o ba yapa asẹ Mi han yin, ti o si kuro nibi itẹle asẹ Mi, ati iru titan ati iparun ti yoo sẹri si.
سَأَصۡرِفُ عَنۡ ءَايَٰتِيَ ٱلَّذِينَ يَتَكَبَّرُونَ فِي ٱلۡأَرۡضِ بِغَيۡرِ ٱلۡحَقِّ وَإِن يَرَوۡاْ كُلَّ ءَايَةٖ لَّا يُؤۡمِنُواْ بِهَا وَإِن يَرَوۡاْ سَبِيلَ ٱلرُّشۡدِ لَا يَتَّخِذُوهُ سَبِيلٗا وَإِن يَرَوۡاْ سَبِيلَ ٱلۡغَيِّ يَتَّخِذُوهُ سَبِيلٗاۚ ذَٰلِكَ بِأَنَّهُمۡ كَذَّبُواْ بَِٔايَٰتِنَا وَكَانُواْ عَنۡهَا غَٰفِلِينَ 146
Maa yi rironu nipa awọn amin Mi ti o wa ni oke ati ni ara ẹmin kuro, ati gbigbọ awọn amin inu iwe Mi ye; awọn ti wọn se igbaraga lori awọn ẹru Ọlọhun Ọba ati lori ododo ni ọna ti ko tọ, ti wọn ba ri gbogbo amin, wọn ko nii gba lododo; nitori wipe wọn ti gunri sii, wọn si gunri si awọn eniyan rẹ naa, ati nitori ibanisọrọ Ọlọhun Ọba ati ojisẹ Rẹ, ti wọn ba ri oju ọna ododo ti yoo mu wọn de bi iyọnu Ọlọhun Ọba, wọn ko nii tọọ, bẹẹ ni wọn ko nii se oju kokoro si i, ti wọn ba ri oju ọna anu ati isina ti yoo mu wọn debi ibinu Ọlọhun Ọba, wọn yoo tọ ọ, eleyi ti o sẹlẹ si wọn jẹ nitori wipe wọn npe awọn amin Ọlọhun Ọba Allah ti o tobi nirọ, eyiti o ntọka si ijododo ohun ti awọn ojisẹ muwa, ati fifọnu kuro nibi rironu si i.
وَٱلَّذِينَ كَذَّبُواْ بَِٔايَٰتِنَا وَلِقَآءِ ٱلۡأٓخِرَةِ حَبِطَتۡ أَعۡمَٰلُهُمۡۚ هَلۡ يُجۡزَوۡنَ إِلَّا مَا كَانُواْ يَعۡمَلُونَ 147
Awọn ti wọn npe awọn amin wa ti o tọka si ijẹ ododo awọn ojisẹ wa nirọ, ti wọn si tun npe ipade Ọlọhun Ọba Allah ni ọjọ igbende nirọ, isẹ wọn eyiti ti o jọ itẹle asẹ ti bajẹ, wọn ko nii gba ẹsan kankan le lori nitori majẹmu igbagbọ ti o se afẹku rẹ, wọn ko si ni san wọn lẹsan ni ọjọ igbende, ayaafi lori keferi ti wọn nse nisẹ ati isẹbọ pẹlu Ọlọhun Ọba, ẹsan eleyi si ni wiwa gbere ninu ina.
وَٱتَّخَذَ قَوۡمُ مُوسَىٰ مِنۢ بَعۡدِهِۦ مِنۡ حُلِيِّهِمۡ عِجۡلٗا جَسَدٗا لَّهُۥ خُوَارٌۚ أَلَمۡ يَرَوۡاْ أَنَّهُۥ لَا يُكَلِّمُهُمۡ وَلَا يَهۡدِيهِمۡ سَبِيلًاۘ ٱتَّخَذُوهُ وَكَانُواْ ظَٰلِمِينَ 148
Ijọ Musa fi awaoran ogedengbe maalu lelẹ, ti ko si ẹmin nibẹ sugbọn ni o ni ohun lelẹ lẹyin igbati Musa ti lọọ ba Ọlọhun Ọba rẹ sọrọ lati ibi awọn nkan ọsọ wọn, se wọn ko mọ ni wipe ogedengbe malu ko le ba wọn sọrọ, ko si le tọ wọn si oju ọna rere ti o see fi oju ri tabi eyiti ko see fi oju ri, ko si le mu anfaani kankan fun wọn tabi ki o mu inira kuro? Wọn ni olujọsin, wọn si se abosi si ẹmin ara wọn nibẹ.
وَلَمَّا سُقِطَ فِيٓ أَيۡدِيهِمۡ وَرَأَوۡاْ أَنَّهُمۡ قَدۡ ضَلُّواْ قَالُواْ لَئِن لَّمۡ يَرۡحَمۡنَا رَبُّنَا وَيَغۡفِرۡ لَنَا لَنَكُونَنَّ مِنَ ٱلۡخَٰسِرِينَ 149
Nigbati wọn kabamọ, wọn si daamu, ti wọn si mọ wipe awọn ti sọnu kuro ni oju ọna ti o duro tọ nitori mimu ogedengbe malu ni ẹniti a njọsin fun yatọ si Ọlọhun Ọba Allah, wọn wa rawọ rasẹ si ọdọ Ọlọhun Ọba ni ẹniti wọn nsọ wipe: ti O ko ba kẹ wa pẹlu fifi wa se kongẹ itẹle tiRẹ, ki O si tun fi ori jin wa lori nkan ti a tisiwaju lori sinsin ogedengbe malu, a ko ba wa lori awọn ti yoo se ofo aye ati ọrun wọn.
O di dandan fun ẹru ki o maa se afihan oore Ọlọhun Ọba Allah nitori daadaa ti Ọlọhun Ọba se fun un ati ọla Rẹ, dajudaju ọpẹ didu so papọ mọ alekun.
Dandan ni fun ẹru ki o maa sọ eyiti o dara ju ninu ọrọ ati ise.
Dandan ni ki a gba ofin ẹsin pẹlu ipinu ẹmin ati igbiyanju ati pipinnu lati tẹle asẹ, ati sise nkan ti daadaa ati atunse wa nibẹ, ki a si kọ ibajẹ ati sise ibajẹ.
Dandan ni fun ẹru nigbati o ba se asise tabi se ẹdinku nibi ẹtọ Ọlọhun Ọba rẹ ki o jẹwọ titobi ẹsẹ rẹ ti o sẹ siwaju, ati wipe ko si ibusẹri si fun un ni ọdọ Ọlọhun nibi pipada sẹyin nibi ikọsẹ ayaafi si ọdọ Rẹ.