ثَمَٰنِيَةَ أَزۡوَٰجٖۖ مِّنَ ٱلضَّأۡنِ ٱثۡنَيۡنِ وَمِنَ ٱلۡمَعۡزِ ٱثۡنَيۡنِۗ قُلۡ ءَآلذَّكَرَيۡنِ حَرَّمَ أَمِ ٱلۡأُنثَيَيۡنِ أَمَّا ٱشۡتَمَلَتۡ عَلَيۡهِ أَرۡحَامُ ٱلۡأُنثَيَيۡنِۖ نَبُِّٔونِي بِعِلۡمٍ إِن كُنتُمۡ صَٰدِقِينَ 143
Wọn da iran mẹjọ fun yin; bii aguntan takọ-tabo: akọ ati abo, bẹẹ naa ni ewurẹ meji, sọ - irẹ ojisẹ - fun awọn ọsẹbọ -: njẹ Ọlọhun Ọba Allah ti ọla Rẹ ga se akọ meji ninu wọn ni eewọ nitori jijẹ akọ ni? Ti wọn ba sọ wipe: bẹẹ ni, sọ fun wọn: nitori ki ni ẹ fi se awọn abo ni eewọ? abi o se abo meji ni eewọ nitori jijẹ abo? Ti wọn ba sọ wipe: bẹẹ ni, sọ fun wọn: ki lo de ti ẹ fi se akọ meji ni eewọ? abi wọn se eyiti apo ibi rẹ jẹ abo meji nitori wiwa ninu apo ibi papọ? Ti wọn ba sọ wipe: bẹẹ ni, sọ fun wọn: nitori ki ni ẹ fi se opinya laarin eyiti apo ibi rẹ papọ pẹlu sise akọ rẹ ni eewọ ni asiko kan ati sise abo rẹ ni eewọ ni asiko miran, ẹ fun mi niro - ẹyin olusẹbọ - ki ni ẹ gbara le lori nibi imọ ti o ni alaafia, ti o ba je wipe sootọ sootọ ni ẹ jẹ, nibi sise afiti jijẹ eewọ nkan yii si ọdọ Ọlọhun Ọba Allah.
وَمِنَ ٱلۡإِبِلِ ٱثۡنَيۡنِ وَمِنَ ٱلۡبَقَرِ ٱثۡنَيۡنِۗ قُلۡ ءَآلذَّكَرَيۡنِ حَرَّمَ أَمِ ٱلۡأُنثَيَيۡنِ أَمَّا ٱشۡتَمَلَتۡ عَلَيۡهِ أَرۡحَامُ ٱلۡأُنثَيَيۡنِۖ أَمۡ كُنتُمۡ شُهَدَآءَ إِذۡ وَصَّىٰكُمُ ٱللَّهُ بِهَٰذَاۚ فَمَنۡ أَظۡلَمُ مِمَّنِ ٱفۡتَرَىٰ عَلَى ٱللَّهِ كَذِبٗا لِّيُضِلَّ ٱلنَّاسَ بِغَيۡرِ عِلۡمٍۚ إِنَّ ٱللَّهَ لَا يَهۡدِي ٱلۡقَوۡمَ ٱلظَّٰلِمِينَ 144
Awọn eyiti o sẹku ninu iran mẹjọ ni: akọ ati abo ninu rakunmi ati akọ ati abo ninu maalu, sọ wipe - ire ojise - fun awọn ọsẹbọ: Ọlọhun Ọba Allah se ni eewọ ninu rẹ nitori jijẹ akọ rẹ tabi nitori jijẹ abo rẹ tabi nitori pipapọ apo ibi rẹ bi? Tabi ẹ jẹ - ẹyin ọlọsẹbọ - ẹniti o wa nibẹ - pẹlu erongba yin - nigbati Ọlọhun Ọba Allah sọ asọtẹle nkan ti ẹ se ni eewọ ninu ẹranko? ! Ko si ẹniti abosi rẹ tobi tabi ẹsẹ rẹ ga to ẹniti o pa irọ mọ Ọlọhun Ọba Allah, ti o fi afiti jijẹ eewọ si lọdọ nkan ti kii se eewọ; jẹ lati le sọ awọn eniyan nu kuro oju ọna eyiti o duro tọ laisi imọ ti o fi idi rẹ mulẹ, dajudaju Ọlọhun Ọba Allah ko nii fi alabosi se kongẹ imọna nitori piparọ mọ Ọ.
قُل لَّآ أَجِدُ فِي مَآ أُوحِيَ إِلَيَّ مُحَرَّمًا عَلَىٰ طَاعِمٖ يَطۡعَمُهُۥٓ إِلَّآ أَن يَكُونَ مَيۡتَةً أَوۡ دَمٗا مَّسۡفُوحًا أَوۡ لَحۡمَ خِنزِيرٖ فَإِنَّهُۥ رِجۡسٌ أَوۡ فِسۡقًا أُهِلَّ لِغَيۡرِ ٱللَّهِ بِهِۦۚ فَمَنِ ٱضۡطُرَّ غَيۡرَ بَاغٖ وَلَا عَادٖ فَإِنَّ رَبَّكَ غَفُورٞ رَّحِيمٞ 145
Sọpe - ire ojise - emi kori nkankan ninu ohun ti Ọlọhun Ọba Allah fi ransẹ si mi ti o jẹ eewọ ayaafi nkan ti o ku laijẹ wipe a du, tabi o jẹ ẹjẹ ti nsan tabi ẹran ẹlẹdẹ nitori wipe o jẹ ẹgbin ati eewọ, tabi eyiti wọn pa laisi orukọ Ọlọhun Ọba Allah nibẹ gẹgẹ bi eyiti wọn du fun oosa wọn, ẹniti laluuri ba mu jẹ nkan ti o jẹ eewọ nitori ebi ti o le koko, ti kii se wipe o nwa adun nibi jijẹ rẹ, ti ko si gbero ikọja ẹnu aala ti idi pataki, ko si ẹsẹ fun un nibi eleyi, dajudaju Ọlọhun Ọba rẹ - ire ojise - alaforijin ni O jẹ fun ẹniti ara nni nigbati o ba jẹ nibẹ, Yoo si kẹ ẹ.
Nigbati Ọlọhun Ọba Allah darukọ nkan ti O se ni eewọ fun awọn ijọ yii, bẹẹ naa ni O darukọ ohun ti O se ni eewọ fun yahuudi; nitori ki o le salaye wipe ohun ti awọn ẹlẹbọ se ni eewọ ninu ẹranko, wọn ko ni igbarale ẹri kankan lati ọdọ Ọlọhun Ọba Allah, wọn kan ntẹle ohun ti eesu npe si wọn lẹnu ni, O wa sọ wipe:
وَعَلَى ٱلَّذِينَ هَادُواْ حَرَّمۡنَا كُلَّ ذِي ظُفُرٖۖ وَمِنَ ٱلۡبَقَرِ وَٱلۡغَنَمِ حَرَّمۡنَا عَلَيۡهِمۡ شُحُومَهُمَآ إِلَّا مَا حَمَلَتۡ ظُهُورُهُمَآ أَوِ ٱلۡحَوَايَآ أَوۡ مَا ٱخۡتَلَطَ بِعَظۡمٖۚ ذَٰلِكَ جَزَيۡنَٰهُم بِبَغۡيِهِمۡۖ وَإِنَّا لَصَٰدِقُونَ 146
A se leewọ fun yahuudi ohun ti awọn ika ọwọ rẹ ko ba pin ya gẹgẹ bi rakunmi, ati ogongo, bẹẹ ni a tun se ọra maalu ati agutan leewọ fun wọn, ayaafi eyiti wọn ba fi si ode rẹ, tabi ifun ti o gbe jade, tabi eyiti o ti ro papọ mọ egungun orikerike ati ti ẹgbẹ, paapaa a ti san wọn lẹsan lori abosi wọn pẹlu sisọ di eewọ fun wọn, bẹẹ ni awa jẹ sootọ sootọ nibi gbogbo iro ti a ba nmu wa.
O nbẹ ninu awọn aayah naa ẹri ti o rinlẹ lori awọn ariwoye ninu awọn alaye imọ, ati ririnlẹ gbolohun pẹlu ariwoye ati ifiwọn.
Imisi tabi ohun ti o jẹ jade ni ọna lati mọ ẹtọ ati eewọ.
Dajudaju ninu abosi ni ẹnikan se aya gbangba lati maa se alaye ẹsin, ti ko si da loju wipe oun wa lori ododo ti yoo yọ Ọlọhun Ọba Allah ninu.
Ninu ikẹ Ọlọhun Ọba Allah si ẹru ni ki o yọnda jijẹ nkan eewọ nigbati inira ba sẹlẹ.