۞سَيَقُولُ ٱلسُّفَهَآءُ مِنَ ٱلنَّاسِ مَا وَلَّىٰهُمۡ عَن قِبۡلَتِهِمُ ٱلَّتِي كَانُواْ عَلَيۡهَاۚ قُل لِّلَّهِ ٱلۡمَشۡرِقُ وَٱلۡمَغۡرِبُۚ يَهۡدِي مَن يَشَآءُ إِلَىٰ صِرَٰطٖ مُّسۡتَقِيمٖ 142
Awọn alaimọkan ti laakaye wọn fuyẹ ninu awọn Yahuudi ati awọn ti wọn ba jọ wọn ninu awọn oloju-eji yoo maa sọ wipe: kini ohun ti o yi awọn Musulumi kuro nibi didojukọ “Baytul Maqdisi” eyiti o jẹ adojukọ wọn tẹlẹ? ! Sọ - irẹ Anọbi - ni ẹni to nda wọn lohun wipe: ti Ọlọhun Ọba Allah nikan nii se, ibuyọ oorun ati ibuwọ rẹ, ati ohun ti o yatọ si awọn mejeeji ninu awọn agbegbe, O si ma ndoju ẹniti O ba wu U ninu awọn ẹru Rẹ kọ eyikeyi ninu agbegbe ti O ba wu U, Oun, mimọ fun Un, ni O ma nfi ẹniti O ba wu U nimnu awọn ẹru Rẹ mọna lọ si oju ọna ti o tọ, ti ko si gbigbun nibẹ tabi yiyẹ.
وَكَذَٰلِكَ جَعَلۡنَٰكُمۡ أُمَّةٗ وَسَطٗا لِّتَكُونُواْ شُهَدَآءَ عَلَى ٱلنَّاسِ وَيَكُونَ ٱلرَّسُولُ عَلَيۡكُمۡ شَهِيدٗاۗ وَمَا جَعَلۡنَا ٱلۡقِبۡلَةَ ٱلَّتِي كُنتَ عَلَيۡهَآ إِلَّا لِنَعۡلَمَ مَن يَتَّبِعُ ٱلرَّسُولَ مِمَّن يَنقَلِبُ عَلَىٰ عَقِبَيۡهِۚ وَإِن كَانَتۡ لَكَبِيرَةً إِلَّا عَلَى ٱلَّذِينَ هَدَى ٱللَّهُۗ وَمَا كَانَ ٱللَّهُ لِيُضِيعَ إِيمَٰنَكُمۡۚ إِنَّ ٱللَّهَ بِٱلنَّاسِ لَرَءُوفٞ رَّحِيمٞ 143
Gẹgẹ bi A se se adojukọ ti A yọnu si fun yin; be ni A se se yin ni ijọ ẹsa ti o dọgba, ti o wa laarin gbogbo awọn ijọ patapata, nibi awọn adisọkan, awọn ijọsin ati awọn ibasepọ; ki e le baa jẹ ẹlẹri ni ọjọ igbende fun awọn oji sẹ Ọlọhun Ọba Allah pe dajudaju awọn mu isẹ ti Ọlọhun Ọba Allah pa wọn lasẹ de ogongo, pelu siso fun awọn ijọ wọn, ati ki Ojisẹ tii se Muhammad (ki ikẹ ati igẹ Ọlahun maa ba) le baa jẹ olujẹri leyin lori pe dajudaju o mu isẹ ti wọn ran dogongo fun yin. A ko se yiyi ti A yi adojukọ yin pada, eyiti ẹ ndojukọ tẹlẹ, ohun naa ni “baytul Makdisi” ayaafi ki a lee mọ - imọ ti o han, ti o se wipe ẹsan yoo tibẹ jade - ẹniti yoo yọnu si oun ti Ọlọhun Ọba Allah se lofin, ti yoo si tẹriba fun Un, ti yoo waa tẹle ojisẹ, ẹniti o ba yi pada kuro nibi ẹsin rẹ, ti o si tẹle ifẹ inu rẹ, ko le tẹriba fun oun ti Ọlọhun Ọba Allah se lofin, paapaa asẹ yiyi adojukọ akọkọ pada jẹ oun ti o tobi ayaafi fun awọn ti Ọlọhun Ọba Allah fi se kongẹ ini igbagbọ pẹlu Rẹ ati wipe dajudaju oun ti O ba se lofin fun awọn ẹru Rẹ, O se lofin nitori idi kan ti o dogongo, kii se wipe Ọlọhun Ọba Allah fẹẹ ra igbagbọ ti e ni si lare, ninu rẹ naa ni irun yin, eyiti ẹ ki siwaju yiyi adojukọ pada, dajudaju Ọlọhun Ọba Allah jẹ Allanu, Onikẹ fun awọn ẹru Rẹ, Ko nii mu inira ba yin, Ko si nii ra awọn ẹsan isẹ yin lare.
قَدۡ نَرَىٰ تَقَلُّبَ وَجۡهِكَ فِي ٱلسَّمَآءِۖ فَلَنُوَلِّيَنَّكَ قِبۡلَةٗ تَرۡضَىٰهَاۚ فَوَلِّ وَجۡهَكَ شَطۡرَ ٱلۡمَسۡجِدِ ٱلۡحَرَامِۚ وَحَيۡثُ مَا كُنتُمۡ فَوَلُّواْ وُجُوهَكُمۡ شَطۡرَهُۥۗ وَإِنَّ ٱلَّذِينَ أُوتُواْ ٱلۡكِتَٰبَ لَيَعۡلَمُونَ أَنَّهُ ٱلۡحَقُّ مِن رَّبِّهِمۡۗ وَمَا ٱللَّهُ بِغَٰفِلٍ عَمَّا يَعۡمَلُونَ 144
Ati paapaa A ti ri - irẹ Anọbi - yiyi oju rẹ pada ati wiwo ti o wo agbegbe sanmọ ni ẹni to nrankan, ti o si nreti sisọkalẹ ifisẹran pẹlu ọrọ adojukọ ati yiyi si ibi ti o fẹ, Awa yoo yi oju rẹ pada si adojukọ ti o yọnu si, ti o si fẹ -, ohun naa ni ile Ọlọhun Ọba Allah ti o jẹ eewọ nni lati pi paarọ “Baytul Maqdisi” nisinsin yii, waa yi oju rẹ pada lọsi agbegbe ile Ọlọhun Ọba Allah ti o jẹ eewọ nni, ti o wa ni Mẹkka alapọnle, ati wipe gbogbo ibi ti ẹ ba ti wa - ẹyin ti ẹ jẹ olugbagbọ ododo - ni ki ẹ maa doju yin kọ agbegbe rẹ nigbati ẹ ba fẹ mu irun wa. Dajudaju awọn ti A fun ni tira ninu awọn Yahuudi ati awọn Nasaara, wọn yoo mọ pe dajudaju yiyi adojukọ yii, ohun ni ododo, eyiti o sọkalẹ lati ọdọ adẹda wọn ati oludari alamọri wọn; nitori rinrinlẹ ti o rinlẹ ninu tira wọn, Ọlọhun Ọba Allah kii se afọnufọnu nipa ohun ti awọn ti wọn gunri kuro nibi ododo nse bikose wipe, Oun, mimọ fun Un, O nimọ nipa nkan naa, Yoo si san wọn lẹsan le lori.
وَلَئِنۡ أَتَيۡتَ ٱلَّذِينَ أُوتُواْ ٱلۡكِتَٰبَ بِكُلِّ ءَايَةٖ مَّا تَبِعُواْ قِبۡلَتَكَۚ وَمَآ أَنتَ بِتَابِعٖ قِبۡلَتَهُمۡۚ وَمَا بَعۡضُهُم بِتَابِعٖ قِبۡلَةَ بَعۡضٖۚ وَلَئِنِ ٱتَّبَعۡتَ أَهۡوَآءَهُم مِّنۢ بَعۡدِ مَا جَآءَكَ مِنَ ٱلۡعِلۡمِ إِنَّكَ إِذٗا لَّمِنَ ٱلظَّٰلِمِينَ 145
Mo fi Ọlọhun Ọba Allah bura, ti o ba waa ba –Irẹ Anọbi- awọn ti A fun ni tira ninu awọn Yahuudi awọn Nasaara lẹni ti o mu gbogbo arisamin ati wọn awijare da lori yiyi adojukọ pada niti ododo, wọn ko nii dojukọ adojukọ rẹ ni ẹniti o nse ori kunkun si ohun ti o mu wa, ti o si nse agbẹrugbọnri nibi titẹle ododo, iwọ naa ko si nii dojukọ adojukọ wọn lẹyin igbati Ọlọhun Ọba Allah ti yi ọ kuro nibẹ, awọn apakan wọn ko si nii dojukọ adojukọ apakan wọn; toripe olukuluku wọn ni o npe ikọ miran ni alaigbagbọ, ti o ba lọọ tẹle ifẹ inu awọn wọnyi nibi ọrọ adojukọ ati ohun ti o yatọ sii ninu awọn ofin ati awọn idajọ lẹyin ohun ti o ti waa de ba ọ ninu imọ eyiti o ni alaafia, eyiti ko si iyemeji nibẹ, dajudaju iwọ nigba naa yoo maa wa ninu alabosi pẹlu fifi ọnaamọ silẹ. Ati titẹle ifẹẹnu, ibanisọrọ yii wa fun Anọbi (ki ikẹ ati igẹ Ọlọhun maa ba) lati le ba tọka si aburu titẹle wọn, tikoba ri bẹẹ, dajudaju Ọlọhun Ọba Allah ti sọ Anọbi Rẹ kuro nibi nkan naa, ikilọ ni fun awọn ijọ rẹ lẹyin rẹ.
Dajudaju igunri si awọn idajọ Ọlọhun Ọba Allah ati ofin Rẹ ati fifọnufọra ni awọn nkan ti O ntọka si, itọka lori jijẹ omugọ ni ati aini laakaye to.
Ọla ti nbẹ fun ijọ yii ati iyi rẹ nigbati Ọlọhun Ọba Allah yan wọn, ti O si royin wọn pẹlu wiwa laarin gbogbo awọn ijọ yoku.
Kikilọ fun ni nibi mima tẹle awọn ti wọn ni tira nibi ifẹ inuu wọn toripe; wọn gunri kuro nibi ododo lẹyin igbati wọn ti mọọ.
Siselẹtọ pipa awọn ṣẹria kan rẹ ninu Islam, ni asiko ti ifisẹranni nlọ, nigbati wọn pa didojukọ “Baytul Makdisi” rẹ, ti wọn si yi pada si Masalaa si abeewọ.