ٱلَّذِينَ يَتَرَبَّصُونَ بِكُمۡ فَإِن كَانَ لَكُمۡ فَتۡحٞ مِّنَ ٱللَّهِ قَالُوٓاْ أَلَمۡ نَكُن مَّعَكُمۡ وَإِن كَانَ لِلۡكَٰفِرِينَ نَصِيبٞ قَالُوٓاْ أَلَمۡ نَسۡتَحۡوِذۡ عَلَيۡكُمۡ وَنَمۡنَعۡكُم مِّنَ ٱلۡمُؤۡمِنِينَۚ فَٱللَّهُ يَحۡكُمُ بَيۡنَكُمۡ يَوۡمَ ٱلۡقِيَٰمَةِۗ وَلَن يَجۡعَلَ ٱللَّهُ لِلۡكَٰفِرِينَ عَلَى ٱلۡمُؤۡمِنِينَ سَبِيلًا 141
Awọn ti wọn nreti nkan ti yoo sẹlẹ si yin ninu daradara tabi aburu, ti aranse ba wa fun yin lati ọdọ Ọlọhun Ọba Allah, tabi ẹ ko ọrọ loju ogun, wọn yoo sọ fun yin wipe: kii wa se wipe a wa pẹlu yin ni, a fi oju ri ohun ti ẹ fi oju ri? ! ki wọn le baa ri ọrọ oju ogun, sugbọn ti awọn keferi ba ni ipin, wọn yoo sọ fun wọn wipe: kii wa se wipe awa ni a ndaabo bo yin ti a nsi nkọọ fun yin kuro ni ọdọ awọn olugbagbọ ododo pẹlu riranyin lọwọ ati didagunla si wọn? ! Ọlọhun Ọba Allah ni yoo se idajọ laarin yin ni apapọ ni ọjọ igbende, yoo san awọn olugbagbọ ododo ni ẹsan pẹlu wiwọ Alujannah, bẹẹni yoo si san awọn sọbẹselu ni ẹsan pẹlu wiwọ isalẹ-salẹ ina, Ọlọhun Ọba Allah pẹlu ọla Rẹ ko nii gbe ijẹ gaba lati ọwọ awọn keferi lori awọn olugbagbọ ododo, bikose wipe yoo se igbẹyin ti o dara fun wọn.
إِنَّ ٱلۡمُنَٰفِقِينَ يُخَٰدِعُونَ ٱللَّهَ وَهُوَ خَٰدِعُهُمۡ وَإِذَا قَامُوٓاْ إِلَى ٱلصَّلَوٰةِ قَامُواْ كُسَالَىٰ يُرَآءُونَ ٱلنَّاسَ وَلَا يَذۡكُرُونَ ٱللَّهَ إِلَّا قَلِيلٗا 142
Dajudaju awọn sọbẹselu ntan Ọlọhun Ọba Allah jẹ pẹlu sise afihan ẹsin Islam ati fifه keferi pamọ, bẹẹni Oun naa si ntan wọn jẹ; nitori wipe O la ẹjẹ wọn, ti o si mọ si keferi wọn, o wa tọju iya ti o le koko ni ọjọ ikẹyin, ti wọn ba dide lati kirun, wọn yoo dide niti oroju ati ikorira rẹ, wọn kii ranti Ọlọhun Ọba Allah ayaafi asiko diẹ nigbati wọn ba ri awọn olugbagbọ ododo.
مُّذَبۡذَبِينَ بَيۡنَ ذَٰلِكَ لَآ إِلَىٰ هَٰٓؤُلَآءِ وَلَآ إِلَىٰ هَٰٓؤُلَآءِۚ وَمَن يُضۡلِلِ ٱللَّهُ فَلَن تَجِدَ لَهُۥ سَبِيلٗا 143
Awọn sọbẹselu yii jẹ oludaamu lọ daamu bọ, wọn kii wa pẹlu awọn olugbagbọ ododo niti ode ati inu, bẹẹni wọn kii si pẹlu awọn keferi, ode wọn ma nwa pẹlu awọn olugbagbọ ododo, inu wọn si ma nwa pẹlu awọn keferi, ẹniti Ọlọhun Ọba Allah ba fi silẹ sinu isina, ko lee si fun un - ire ojise - oju ọna imọna kuro nibi anu.
يَٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ لَا تَتَّخِذُواْ ٱلۡكَٰفِرِينَ أَوۡلِيَآءَ مِن دُونِ ٱلۡمُؤۡمِنِينَۚ أَتُرِيدُونَ أَن تَجۡعَلُواْ لِلَّهِ عَلَيۡكُمۡ سُلۡطَٰنٗا مُّبِينًا 144
Ẹyin olugbagbọ ododo ninu Ọlọhun Ọba Allah ati olutẹle ojisẹ Rẹ, ẹ mase mu awọn keferi si Ọlọhun ni ẹni ayanfẹ, ti yoo ran yin lọwọ yatọ si awọn olugbagbọ ododo, se ngbero pẹlu nkan ti ẹ nse yii, ki Ọlọhun Ọba Allah ri awijare ti o fi oju han le yin lori, eyiti yoo tọka si ilẹtọ yin si iya Rẹ? !
إِنَّ ٱلۡمُنَٰفِقِينَ فِي ٱلدَّرۡكِ ٱلۡأَسۡفَلِ مِنَ ٱلنَّارِ وَلَن تَجِدَ لَهُمۡ نَصِيرًا 145
Dajudaju Ọlọhun Ọba Allah yoo fi awọn sọbẹselu si isalẹ-salẹ ina ni ọjọ igbende, ko si nii si alaranse kankan fun wọn, ti yoo la wọn kuro nibi iya naa.
إِلَّا ٱلَّذِينَ تَابُواْ وَأَصۡلَحُواْ وَٱعۡتَصَمُواْ بِٱللَّهِ وَأَخۡلَصُواْ دِينَهُمۡ لِلَّهِ فَأُوْلَٰٓئِكَ مَعَ ٱلۡمُؤۡمِنِينَۖ وَسَوۡفَ يُؤۡتِ ٱللَّهُ ٱلۡمُؤۡمِنِينَ أَجۡرًا عَظِيمٗا 146
Ayaafi awọn ti wọn ba sẹri si ọdọ Ọlọhun Ọba Allah pẹlu tituuba kuro nibi sọbẹ-selu wọn, ti wọn si se atunse inu wọn, ti wọn si gba adedehun Ọlọhun Ọba Allah mu, ti wọn si afọmọ isẹ wọn fun Ọlọhun Ọba Allah ni eyi ti ko si sekarimi nibẹ, awọn eniyan yii ni wọn royin pẹlu awọn iroyin naa, pẹlu awọn olugbagbọ ododo ni ile aye ati ni ọrun, Ọlọhun Ọba Allah yoo si pada fun awọn olugbagbọ ododo ni ẹsan ti o pọ.
مَّا يَفۡعَلُ ٱللَّهُ بِعَذَابِكُمۡ إِن شَكَرۡتُمۡ وَءَامَنتُمۡۚ وَكَانَ ٱللَّهُ شَاكِرًا عَلِيمٗا 147
Ko si ohun ti Ọlọhun Ọba Allah fẹẹ fi ifiya jẹ yin se, ti ẹ ba ndupẹ fun Un, ti ẹ si ni igbagbọ siI, Oun ni Ọba oluse daradara, Onikẹẹ, Yoo maa jẹ yin niya nitori ẹsẹ yin, ti ẹ ba se atunse isẹ, ti ẹ si dupẹ lori awọn idẹkun Rẹ, ti ẹ si nigbagbọ si ni ode ati inu, ko lee fi iya jẹ yin, Ọlọhun Ọba Allah jẹ oludepẹ fun ẹniti o ba se afihan idẹkun Rẹ, Yoo si san wọn ni ẹsan ti o pọ le lori, O si jẹ onimimọ pẹlu igbagbọ ti ẹda Rẹ ni, Yoo si san ẹnikọọkan lori isẹ rẹ.
Sise alaye awọn iroyin awọn munaafiki, ninu rẹ: sise ou kokoro wọn si ipin wọn, boya wọn wa pẹlu awọn olugbagbọ ododo tabi pẹlu awọn keferi.
Eyi ti o tobi julọ ninu iroyin awọn munaafiki, lilọ bibọ wọn ati pipaara wọn ati darudapọ wọn, wọn ko nii si pẹlu awọn olugbagbo ododo ni tootọ, bẹẹni wọn ko nii si pẹlu awọn keferi.
Ikọfunni ti o le dan-in dan in nipa mimu awọn keferi ni alatilẹyin dipo awọn olugbagbọ ododo.
Nkan ti o tobi ju, ti ọmọniyan le fi daabobo ara rẹ nibi iya Ọlọhun Ọba Allah ni ọjọ ikẹyin, ohun ni igbagbọ ati isẹẹre.